Joh 9
Jesu Wo Ẹni tí Wọ́n Bí Ní Afọ́jú Sàn
1 BI o si ti nkọja lọ, o ri ọkunrin kan ti o fọju lati igba ibí rẹ̀ wá. 2 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe. Olukọni, tani dẹṣẹ, ọkunrin yi tabi awọn obi rẹ̀, ti a fi bi i li afọju? 3 Jesu dahùn pe, Kì iṣe nitoriti ọkunrin yi dẹṣẹ, tabi awọn obi rẹ̀: ṣugbọn ki a le fi iṣẹ Ọlọrun hàn lara rẹ̀. 4 Emi kò le ṣe alaiṣe iṣẹ ẹniti o rán mi, nigbati iṣe ọsan: oru mbọ̀ wá nigbati ẹnikan kì o le ṣe iṣẹ. 5 Niwọn igba ti mo wà li aiye, emi ni imọlẹ aiye. 6 Nigbati o ti wi bẹ̃ tan, o tutọ́ silẹ, o si fi itọ́ na ṣe amọ̀, o si fi amọ̀ na pa oju afọju na, 7 O si wi fun u pe, Lọ, wẹ̀ ninu adagun Siloamu, (itumọ̀ eyi ti ijẹ Ránlọ.) Nitorina o gbà ọ̀na rẹ̀ lọ, o wẹ̀, o si de, o nriran. 8 Njẹ awọn aladugbo ati awọn ti o ri i nigba atijọ pe alagbe ni iṣe, wipe, Ẹniti o ti njoko ṣagbe kọ́ yi? 9 Awọn kan wipe, On ni: awọn ẹlomiran wipe, Bẹ̃kọ, o jọ ọ ni: ṣugbọn on wipe, Emi ni. 10 Nitorina ni nwọn wi fun u pe, Njẹ oju rẹ ti ṣe là? 11 O dahùn o si wi fun wọn pe, ọkunrin kan ti a npè ni Jesu li o ṣe amọ̀, o si fi kùn mi loju, o si wi fun mi pe, Lọ si adagun Siloamu, ki o si wẹ̀: emi si lọ, mo wẹ̀, mo si riran.
12 Nwọn si wi fun u pe, On na ha dà? O wipe, emi kò mọ̀.Àwọn Farisi Wádìí Ìwòsàn Afọ́jú Náà
13 Nwọn mu ẹniti oju rẹ̀ ti fọ́ ri wá sọdọ awọn Farisi. 14 Njẹ ọjọ isimi lọjọ na nigbati Jesu ṣe amọ̀ na, ti o si là a loju. 15 Nitorina awọn Farisi pẹlu tún bi i lẽre, bi o ti ṣe riran. O si wi fun wọn pe, O fi amọ̀ le oju mi, mo si wẹ̀ mo si riran. 16 Nitorina awọn kan ninu awọn Farisi wipe, ọkunrin yi kò ti ọdọ Ọlọrun wá, nitoriti kò pa ọjọ isimi mọ́. Awọn ẹlomiran wipe, ọkunrin ti iṣe ẹlẹṣẹ yio ha ti ṣe le ṣe irú iṣẹ àmi wọnyi? Iyapa si wà larin wọn. 17 Nitorina nwọn si tun wi fun afọju na pe, Kini iwọ wi nitori rẹ̀, nitoriti o là ọ loju? O si wipe, Woli ni iṣe. 18 Nitorina awọn Ju kò gbagbọ́ nitori rẹ̀ pe, oju rẹ̀ ti fọ́ ri, ati pe o si tún riran, titi nwọn fi pe awọn obi ẹniti a ti là loju. 19 Nwọn si bi wọn lẽre, wipe, Eyi li ọmọ nyin, ẹniti ẹnyin wipe, a bí i li afọju? ẽhaṣe ti o riran nisisiyi? 20 Awọn obi rẹ̀ da wọn lohùn wipe, Awa mọ̀ pe ọmọ wa li eyi, ati pe a bí i li afọju: 21 Ṣugbọn bi o ti ṣe nriran nisisiyi awa kò mọ̀; tabi ẹniti o la a loju, awa kò mọ̀: ẹniti o gbọ́njú ni iṣe; ẹ bi i lẽre: yio wi fun ara rẹ̀. 22 Nkan wọnyi li awọn obi rẹ̀ sọ, nitoriti nwọn bẹ̀ru awọn Ju: nitori awọn Ju ti fi ohùn ṣọkan pe, bi ẹnikan ba jẹwọ pe, Kristi ni iṣe, nwọn ó yọ ọ kuro ninu sinagogu. 23 Nitori eyi li awọn obi rẹ̀ fi wipe, Ẹniti o gbọ́njú ni iṣe; ẹ bi i lẽre. 24 Nitorina nwọn pè ọkunrin afọju na lẹ̃keji, nwọn si wi fun u pe, Fi ogo fun Ọlọrun: awa mọ̀ pe ẹlẹṣẹ li ọkunrin yi iṣe. 25 Nitorina o dahùn o si wipe, Bi ẹlẹṣẹ ni, emi kò mọ̀: ohun kan ni mo mọ̀, pe mo ti fọju ri, mo riran nisisiyi. 26 Nitorina nwọn wi fun u pe, Kili o ṣe si ọ? o ti ṣe là ọ loju? 27 O da wọn lohùn wipe, Emi ti sọ fun nyin na, ẹnyin ko si gbọ́: nitori kini ẹnyin ṣe nfẹ tún gbọ́? ẹnyin pẹlu nfẹ ṣe ọmọ-ẹhin rẹ̀ bi? 28 Nwọn si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn si wipe, Iwọ li ọmọ-ẹhin rẹ̀; ṣugbọn ọmọ-ẹhin Mose li awa. 29 Awa mọ̀ pe Ọlọrun ba Mose sọ̀rọ: ṣugbọn bi o ṣe ti eleyi, awa kò mọ̀ ibiti o gbé ti wá. 30 Ọkunrin na dahùn o si wi fun wọn pe, Ohun iyanu sá li eyi, pe, ẹnyin kò mọ̀ ibiti o gbé ti wá, ṣugbọn on sá ti là mi loju. 31 Awa mọ̀ pe, Ọlọrun ki igbọ́ ti ẹlẹṣẹ: ṣugbọn bi ẹnikan ba ṣe olufọkansin si Ọlọrun, ti o ba si nṣe ifẹ rẹ̀, on ni igbọ́ tirẹ̀. 32 Lati igba ti aiye ti ṣẹ̀, a kò ti igbọ́ pe, ẹnikan là oju ẹniti a bí li afọju rí. 33 Ibaṣepe ọkunrin yi ko ti ọdọ Ọlọrun wá, kì ba ti le ṣe ohunkohun. 34 Nwọn si dahùn wi fun u pe, Ninu ẹṣẹ li a bi iwọ patapata, iwọ si nkọ́ wa bi? Nwọn si tì i sode. 35 Jesu gbọ́ pe, nwọn ti tì i sode; nigbati o si ri i, o wipe, Iwọ gbà Ọmọ Ọlọrun gbọ́ bi? 36 On si dahùn wipe, Tani, Oluwa, ki emi ki o le gbà a gbọ́? 37 Jesu wi fun u pe, Iwọ ti ri i, on na si ni ẹniti mba ọ sọ̀rọ yi. 38 O si wipe, Oluwa, mo gbagbọ́, o si wolẹ fun u. 39 Jesu si wipe, Nitori idajọ ni mo ṣe wá si aiye yi, ki awọn ti kò riran, le riran; ati ki awọn ti o riran le di afọju. 40 Ninu awọn Farisi ti o wà lọdọ rẹ̀ gbọ́ nkan wọnyi, nwọn si wi fun u pe, Awa pẹlu fọju bi? 41 Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe ẹnyin fọju, ẹnyin kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi ẹnyin wipe, Awa riran; nitorina ẹ̀ṣẹ nyin wà sibẹ̀.
John 9
Healing the Man Born Blind
1 As He passed by, He saw a man blind from birth.2 And His disciples asked Him, "Rabbi, who sinned, this man or his parents, that he would be born blind?"3 Jesus answered, "It was neither that this man sinned, nor his parents; but it was so that the works of God might be displayed in him.4 We must work the works of Him who sent Me as long as it is day; night is coming when no one can work.5 While I am in the world, I am the Light of the world."6 When He had said this, He spat on the ground, and made clay of the spittle, and applied the clay to his eyes,7 and said to him, "Go, wash in the pool of Siloam" (which is translated, Sent). So he went away and washed, and came back seeing.8 Therefore the neighbors, and those who previously saw him as a beggar, were saying, "Is not this the one who used to sit and beg?"9 Others were saying, "This is he," still others were saying, "No, but he is like him." He kept saying, "I am the one."10 So they were saying to him, "How then were your eyes opened?"11 He answered, "The man who is called Jesus made clay, and anointed my eyes, and said to me, 'Go to Siloam and wash'; so I went away and washed, and I received sight."12 They said to him, "Where is He?" He *said, "I do not know."
Controversy over the Man
13 They *brought to the Pharisees the man who was formerly blind.14 Now it was a Sabbath on the day when Jesus made the clay and opened his eyes.15 Then the Pharisees also were asking him again how he received his sight. And he said to them, "He applied clay to my eyes, and I washed, and I see."16 Therefore some of the Pharisees were saying, "This man is not from God, because He does not keep the Sabbath." But others were saying, "How can a man who is a sinner perform such signs?" And there was a division among them.17 So they *said to the blind man again, "What do you say about Him, since He opened your eyes?" And he said, "He is a prophet."
18 The Jews then did not believe it of him, that he had been blind and had received sight, until they called the parents of the very one who had received his sight,19 and questioned them, saying, "Is this your son, who you say was born blind? Then how does he now see?"20 His parents answered them and said, "We know that this is our son, and that he was born blind;21 but how he now sees, we do not know; or who opened his eyes, we do not know. Ask him; he is of age, he will speak for himself."22 His parents said this because they were afraid of the Jews; for the Jews had already agreed that if anyone confessed Him to be Christ, he was to be put out of the synagogue.23 For this reason his parents said, "He is of age; ask him."
24 So a second time they called the man who had been blind, and said to him, "Give glory to God; we know that this man is a sinner."25 He then answered, "Whether He is a sinner, I do not know; one thing I do know, that though I was blind, now I see."26 So they said to him, "What did He do to you? How did He open your eyes?"27 He answered them, "I told you already and you did not listen; why do you want to hear it again? You do not want to become His disciples too, do you?"28 They reviled him and said, "You are His disciple, but we are disciples of Moses.29 We know that God has spoken to Moses, but as for this man, we do not know where He is from."30 The man answered and said to them, "Well, here is an amazing thing, that you do not know where He is from, and yet He opened my eyes.31 We know that God does not hear sinners; but if anyone is God-fearing and does His will, He hears him.32 Since the beginning of time it has never been heard that anyone opened the eyes of a person born blind.33 If this man were not from God, He could do nothing."34 They answered him, "You were born entirely in sins, and are you teaching us?" So they put him out.
Jesus Affirms His Deity
35 Jesus heard that they had put him out, and finding him, He said, "Do you believe in the Son of Man?"36 He answered, "Who is He, Lord, that I may believe in Him?"37 Jesus said to him, "You have both seen Him, and He is the one who is talking with you."38 And he said, "Lord, I believe." And he worshiped Him.39 And Jesus said, "For judgment I came into this world, so that those who do not see may see, and that those who see may become blind."40 Those of the Pharisees who were with Him heard these things and said to Him, "We are not blind too, are we?"41 Jesus said to them, "If you were blind, you would have no sin; but since you say, 'We see,' your sin remains.