previous next

Luk 12

Jesu Ṣe Ìkìlọ̀ Nípa Àgàbàgebè

(Mat 10:26-27)

1 O si ṣe, nigbati ainiye ijọ enia pejọ pọ̀, tobẹ̃ ti nwọn ntẹ̀ ara wọn mọlẹ, o tètekọ́ wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ mã ṣọra nyin nitori iwukara awọn Farisi, ti iṣe agabagebe. 2 Kò si ohun ti a bò, ti a kì yio si fihàn; tabi ti o pamọ, ti a ki yio mọ̀.

3 Nitorina ohunkohun ti ẹnyin sọ li òkunkun, ni gbangba li a o gbé gbọ́; ati ohun ti ẹnyin ba sọ si etí ni ìkọkọ, lori orule li a o gbé kede rẹ̀.

Ẹni Tí Ó Yẹ Láti Bẹ̀rù

(Mat 10:28-31)


4 Emi si wi fun nyin ẹnyin ọrẹ́ mi, Ẹ máṣe bẹ̀ru awọn ti ipa ara enia kú, lẹhin eyini ti nwọn kò si li eyiti nwọn le ṣe mọ́. 5 Ṣugbọn emi o si sọ ẹniti ẹnyin o bẹ̀ru fun nyin: Ẹ bẹru ẹniti o lagbara lẹhin ti o ba pani tan, lati wọ́ni lọ si ọrun apadi; lõtọ ni mo wi fun nyin, On ni ki ẹ bẹru. 6 Ologoṣẹ marun ki a ntà li owo idẹ wẹ́wẹ meji? a kò si gbagbé ọkan ninu wọn niwaju Ọlọrun?

7 Ṣugbọn gbogbo irun ori nyin li a kà pé ṣanṣan. Nitorina ki ẹ máṣe bẹ̀ru: ẹnyin ni iye lori jù ologoṣẹ pipọ lọ.

Jíjẹ́wọ́ Jesu Níwájú Eniyan

(Mat 10:32-33; 12:32; 10:19-20)


8 Mo si wi fun nyin pẹlu, Ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju enia, Ọmọ-ẹnia yio si jẹwọ rẹ̀ niwaju awọn angẹli Ọlọrun: 9 Ṣugbọn ẹniti o ba sẹ́ mi niwaju enia, a o sẹ́ ẹ niwaju awọn angẹli Ọlọrun. 10 Ati ẹnikẹni ti o ba sọ̀rọ-òdi si Ọmọ-enia, a o dari rẹ̀ jì i: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, a kì yio dari rẹ̀ jì i. 11 Nigbati nwọn ba si mu nyin wá si sinagogu, ati siwaju awọn olori, ati awọn alaṣẹ, ẹ máṣe ṣàniyàn pe, bawo tabi ohùn kili ẹnyin ó da, tabi kili ẹnyin o wi:

12 Nitori Ẹmí Mimọ́ yio kọ́ nyin ni wakati kanna li ohun ti o yẹ ki ẹ wi.

Òwe Nípa Aṣiwèrè Ọlọ́rọ̀


13 Ọkan ninu awujọ si wi fun u pe, Olukọni, sọ fun arakunrin mi ki o pín mi li ogún. 14 O si wi fun u pe, ọkunrin yi, tali o fi mi jẹ onidajọ tabi olùpín-ogún wá fun nyin? 15 O si wi fun wọn pe, Kiyesara ki ẹ si mã ṣọra nitori ojukòkoro: nitori igbesi aiye enia ki iduro nipa ọ̀pọ ohun ti o ni. 16 O si pa owe kan fun wọn, wipe, Ilẹ ọkunrin kan ọlọrọ̀ so eso ọ̀pọlọpọ: 17 O si rò ninu ara rẹ̀, wipe, Emi o ti ṣe, nitoriti emi kò ni ibiti emi o gbé kó eso mi jọ si? 18 O si wipe, Eyi li emi o ṣe: emi o wó aká mi palẹ, emi o si kọ́ eyi ti o tobi; nibẹ̀ li emi o gbé tò gbogbo eso ati ọrọ̀ mi jọ si. 19 Emi o si wi fun ọkàn mi pe, Ọkàn, iwọ li ọrọ̀ pipọ ti a tò jọ fun ọ̀pọ ọdún; simi mã jẹ, mã mu, mã yọ̀. 20 Ṣugbọn Ọlọrun wi fun u pe, Iwọ aṣiwere, li oru yi li a o bère ẹmi rẹ lọwọ rẹ: njẹ titani nkan wọnni yio ha ṣe, ti iwọ ti pèse silẹ?

21 Bẹ̃ li ẹniti o tò iṣura jọ fun ara rẹ̀, ti ko si li ọrọ̀ lọdọ Ọlọrun.

Ẹ̀kọ́ Nípa Ṣíṣe Àníyàn

(Mat 6:25-34)


22 O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Nitorina mo wi fun nyin pe, ẹ máṣe ṣaniyàn nitori ẹmí nyin pe, kili ẹnyin ó jẹ; tabi nitori ara nyin pe, kili ẹnyin ó fi bora. 23 Ẹmí sa jù onjẹ lọ, ara si jù aṣọ lọ. 24 Ẹ kiyesi awọn ìwo: nwọn kì ifọnrugbin, bẹ̃ni nwọn ki kore; nwọn kò li aká, bẹ̃ni nwọn kò li abà; Ọlọrun sá mbọ́ wọn: melomelo li ẹnyin sàn jù ẹiyẹ lọ? 25 Tani ninu nyin nipa aniyan ṣiṣe ti o le fi igbọnwọ kan kún ọjọ aiyé rẹ̀? 26 Njẹ bi ẹnyin kò le ṣe eyi ti o kere julọ, ẽṣe ti ẹnyin fi nṣaniyan nitori iyokù? 27 Ẹ kiyesi awọn lili bi nwọn ti ndàgba: nwọn ki iṣiṣẹ nwọn ki iranwu; ṣugbọn ki emi wi fun nyin, a kò ṣe Solomoni pãpã li ọṣọ́ ni gbogbo ogo rẹ̀ to ọkan ninu wọnyi. 28 Njẹ bi Ọlọrun ba wọ̀ koriko igbẹ́ li aṣọ tobẹ̃ eyiti o wà loni, ti a si gbá a sinu ina lọla; melomelo ni yio wọ̀ nyin li aṣọ, ẹnyin onigbagbọ́ kekere? 29 Ẹ má si ṣe bere ohun ti ẹnyin ó jẹ, tabi ohun ti ẹnyin o mu, ki ẹnyin ki o má si ṣiyemeji. 30 Nitori gbogbo nkan wọnyi ni awọn orilẹ-ède aiye nwá kiri: Baba nyin si mọ̀ pe, ẹnyin nfẹ nkan wọnyi.

31 Ṣugbọn ẹ mã wá ijọba Ọlọrun; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún nyin.

Ìṣúra Ní Ọ̀run

(Mat 6:19-21)


32 Má bẹ̀ru, agbo kekere; nitori didùn inu Baba nyin ni lati fi ijọba fun nyin. 33 Ẹ tà ohun ti ẹnyin ni, ki ẹnyin ki o si tọrẹ ãnu; ki ẹnyin ki o si pèse àpo fun ara nyin, ti kì igbó, iṣura li ọrun ti kì itán, nibiti olè kò le sunmọ, ati ibiti kòkoro kì iba a jẹ.

34 Nitori nibiti iṣura nyin gbé wà, nibẹ̀ li ọkàn nyin yio gbé wà pẹlu.

Àwọn Ọmọ-Ọ̀dọ̀ Tí Ó Ń Ṣọ́nà


35 Ẹ di amure nyin, ki fitila nyin ki o si mã jo: 36 Ki ẹnyin tikara nyin ki o dabi ẹniti nreti oluwa wọn, nigbati on o pada ti ibi iyawo de; pe, nigbati o ba de, ti o si kànkun, ki nwọn ki o le ṣí i silẹ fun u lọgan. 37 Ibukun ni fun awọn ọmọ-ọdọ wọnni nigbati oluwa na ba de ti yio ba ki nwọn ki o ma ṣọna: lõtọ ni mo wi fun nyin, yio di ara rẹ̀ li amure, yio si mu wọn joko lati jẹun, yio si jade wá lati ṣe iranṣẹ fun wọn. 38 Bi o ba si de nigba iṣọ keji, tabi ti o si de nigba iṣọ kẹta, ti o si ba wọn bẹ̃, ibukun ni fun awọn ọmọ-ọdọ wọnni. 39 Ṣugbọn ẹ mọ̀ eyi pe, bãle ile iba mọ̀ wakati ti olè yio wá, on iba ma ṣọna, kì ba ti jẹ ki a lu ile on já.

40 Nitorina ki ẹnyin ki o mura pẹlu: Nitori Ọmọ-enia mbọ̀ ni wakati ti ẹnyin kò daba.

Ẹrú Olódodo ati Ẹrú Alaiṣododo

(Mat 24:45-51)


41 Peteru si wipe, Oluwa, iwọ pa owe yi fun wa, tabi fun gbogbo enia? 42 Oluwa si dahùn wipe, Tani olõtọ ati ọlọ́gbọn iriju na, ti oluwa rẹ̀ fi jẹ olori agbo ile rẹ̀, lati ma fi ìwọn onjẹ wọn fun wọn li akokò? 43 Ibukun ni fun ọmọ-ọdọ na, nigbati oluwa rẹ̀ ba de, ti yio ba a ki o ma ṣe bẹ̃. 44 Lõtọ ni mo wi fun nyin, yio si fi i jẹ olori ohun gbogbo ti o ni. 45 Ṣugbọn bi ọmọ-ọdọ na ba wi li ọkàn rẹ̀ pe, Oluwa mi yẹ̀ igba atibọ̀ rẹ̀; ti o si bẹ̀rẹ si ilù awọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, ti o si bẹ̀rẹ si ijẹ ati si imu amupara; 46 Oluwa ọmọ-ọdọ na yio de li ọjọ ti kò reti rẹ̀, ati ni wakati ti kò daba, yio si jẹ ẹ niya gidigidi, yio si yàn ipò rẹ̀ pẹlu awọn alaigbagbọ́. 47 Ati ọmọ-ọdọ na, ti o mọ̀ ifẹ oluwa rẹ̀, ti kò si mura silẹ ti kò si ṣe gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, on li a o nà pipọ.

48 Ṣugbọn eyi ti kò mọ̀, ti o ṣe ohun ti o yẹ si lilu, on li a o lù niwọn. Nitori ẹnikẹni ti a fun ni pipọ, lọdọ rẹ̀ li a o gbé bère pipọ: lọdọ ẹniti a ba gbé fi pipọ si, lọdọ rẹ̀ li a o gbé bère si i.

Jesu Dá Ìyapa Sílẹ̀

(Mat 10:34-37)


49 Iná li emi wá lati fọ̀n si aiye; kili emi si nfẹ bi a ba ti da a ná? 50 Ṣugbọn emi ni baptismu kan ti a o fi baptisi mi; ara ti nni mi to titi yio fi pari! 51 Ẹnyin ṣebi alafia li emi wá fi si aiye? mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ; ki a sá kuku pe iyapa: 52 Nitori lati isisiyi lọ, enia marun yio wà ni ile kanna ti a o yà ni ipa, mẹta si meji, ati meji si mẹta.

53 A o yà baba ni ipa si ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọkunrin si baba; iya si ọmọbinrin rẹ̀, ati ọmọbinrin si iya rẹ̀; iyakọ si iyawo rẹ̀, ati iyawo si iyako rẹ̀.

Àmì Àkókò

(Mat 16:2-3)


54 O si wi fun ijọ enia pẹlu pe, Nigbati ẹnyin ba ri awọsanma ti o ṣú ni ìha ìwọ-õrùn, ọgan ẹnyin a ni, Ọwara òjo mbọ̀; a si ri bẹ̃. 55 Nigbati afẹfẹ gusù ba nfẹ, ẹnyin a ni, Õru yio mu; a si ṣẹ.

56 Ẹnyin agabagebe, ẹnyin le moye oju ọrun ati ti aiye; ẽhatiṣe ti ẹnyin kò le mọ̀ akokò yi?

Ẹ Bá Ọ̀tá Yín Rẹ́

(Mat 5:25-26)


57 Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin tikara nyin ko fi rò ohun ti o tọ́? 58 Nigbati iwọ ba mbá ọtá rẹ lọ sọdọ olóri, mura li ọ̀na ki a le gbà ọ lọwọ rẹ̀; ki o máṣe fi ọ le onidajọ lọwọ, ki onidajọ máṣe fi ọ le ẹṣọ lọwọ, on a si tì ọ sinu tubu. 59 Ki emi ki o wi fun ọ, iwọ ki yio jade kuro nibẹ̀, titi iwọ o fi san õkan ti o ba kù.

Luke 12

God Knows and Cares

1 Under these circumstances, after so many thousands of people had gathered together that they were stepping on one another, He began saying to His disciples first of all, "Beware of the leaven of the Pharisees, which is hypocrisy.2 But there is nothing covered up that will not be revealed, and hidden that will not be known.3 Accordingly, whatever you have said in the dark will be heard in the light, and what you have whispered in the inner rooms will be proclaimed upon the housetops.

4 "I say to you, My friends, do not be afraid of those who kill the body and after that have no more that they can do.5 But I will warn you whom to fear: fear the One who, after He has killed, has authority to cast into hell; yes, I tell you, fear Him!6 Are not five sparrows sold for two cents? Yet not one of them is forgotten before God.7 Indeed, the very hairs of your head are all numbered. Do not fear; you are more valuable than many sparrows.

8 "And I say to you, everyone who confesses Me before men, the Son of Man will confess him also before the angels of God;9 but he who denies Me before men will be denied before the angels of God.10 And everyone who speaks a word against the Son of Man, it will be forgiven him; but he who blasphemes against the Holy Spirit, it will not be forgiven him.11 When they bring you before the synagogues and the rulers and the authorities, do not worry about how or what you are to speak in your defense, or what you are to say;12 for the Holy Spirit will teach you in that very hour what you ought to say."

Covetousness Denounced

13 Someone in the crowd said to Him, "Teacher, tell my brother to divide the family inheritance with me."14 But He said to him, "Man, who appointed Me a judge or arbitrator over you?"15 Then He said to them, "Beware, and be on your guard against every form of greed; for not even when one has an abundance does his life consist of his possessions."16 And He told them a parable, saying, "The land of a rich man was very productive.17 And he began reasoning to himself, saying, 'What shall I do, since I have no place to store my crops?'18 Then he said, 'This is what I will do: I will tear down my barns and build larger ones, and there I will store all my grain and my goods.19 And I will say to my soul, "Soul, you have many goods laid up for many years to come; take your ease, eat, drink and be merry."'20 But God said to him, 'You fool! This very night your soul is required of you; and now who will own what you have prepared?'21 So is the man who stores up treasure for himself, and is not rich toward God."

22 And He said to His disciples, "For this reason I say to you, do not worry about your life, as to what you will eat; nor for your body, as to what you will put on.23 For life is more than food, and the body more than clothing.24 Consider the ravens, for they neither sow nor reap; they have no storeroom nor barn, and yet God feeds them; how much more valuable you are than the birds!25 And which of you by worrying can add a single thour to his tlife's span?26 If then you cannot do even a very little thing, why do you worry about other matters?27 Consider the lilies, how they grow: they neither toil nor spin; but I tell you, not even Solomon in all his glory clothed himself like one of these.28 But if God so clothes the grass in the field, which is alive today and tomorrow is thrown into the furnace, how much more will He clothe you? You men of little faith!29 And do not seek what you will eat and what you will drink, and do not keep worrying.30 For all these things the nations of the world eagerly seek; but your Father knows that you need these things.31 But seek His kingdom, and these things will be added to you.32 Do not be afraid, little flock, for your Father has chosen gladly to give you the kingdom.

33 "Sell your possessions and give to charity; make yourselves money belts which do not wear out, an unfailing treasure in heaven, where no thief comes near nor moth destroys.34 For where your treasure is, there your heart will be also.

Be in Readiness

35 "Be dressed in readiness, and keep your lamps lit.36 Be like men who are waiting for their master when he returns from the wedding feast, so that they may immediately open the door to him when he comes and knocks.37 Blessed are those slaves whom the master will find on the alert when he comes; truly I say to you, that he will gird himself to serve, and have them recline at the table, and will come up and wait on them.38 Whether he comes in the tsecond watch, or even in the tthird, and finds them so, blessed are those slaves.

39 "But be sure of this, that if the head of the house had known at what hour the thief was coming, he would not have allowed his house to be broken into.40 You too, be ready; for the Son of Man is coming at an hour that you do not expect."

41 Peter said, "Lord, are You addressing this parable to us, or to everyone else as well?"42 And the Lord said, "Who then is the faithful and sensible steward, whom his master will put in charge of his servants, to give them their rations at the proper time?43 Blessed is that slave whom his master finds so doing when he comes.44 Truly I say to you that he will put him in charge of all his possessions.45 But if that slave says in his heart, 'My master will be a long time in coming,' and begins to beat the slaves, both men and women, and to eat and drink and get drunk;46 the master of that slave will come on a day when he does not expect him and at an hour he does not know, and will cut him in pieces, and assign him a place with the unbelievers.47 And that slave who knew his master's will and did not get ready or act in accord with his will, will receive many lashes,48 but the one who did not know it, and committed deeds worthy of a flogging, will receive but few. From everyone who has been given much, much will be required; and to whom they entrusted much, of him they will ask all the more.

Christ Divides Men

49 "I have come to cast fire upon the earth; and how I wish it were already kindled!50 But I have a baptism to undergo, and how distressed I am until it is accomplished!51 Do you suppose that I came to grant peace on earth? I tell you, no, but rather division;52 for from now on five members in one household will be divided, three against two and two against three.53 They will be divided, father against son and son against father, mother against daughter and daughter against mother, mother-in-law against daughter-in-law and daughter-in-law against mother-in-law."

54 And He was also saying to the crowds, "When you see a cloud rising in the west, immediately you say, 'A shower is coming,' and so it turns out.55 And when you see a south wind blowing, you say, 'It will be a hot day,' and it turns out that way.56 You hypocrites! You know how to analyze the appearance of the earth and the sky, but why do you not analyze this present time?

57 "And why do you not even on your own initiative judge what is right?58 For while you are going with your opponent to appear before the magistrate, on your way there make an effort to settle with him, so that he may not drag you before the judge, and the judge turn you over to the officer, and the officer throw you into prison.59 I say to you, you will not get out of there until you have paid the very last cent."