Luk 13
Ẹ Ronupiwada, Bí Bẹ́ẹ̀ Kọ̀ Ẹ Óo Ṣègbé
1 AWỌN kan si wà li akokò na ti o sọ ti awọn ara Galili fun u, ẹ̀jẹ ẹniti Pilatu dàpọ mọ ẹbọ wọn. 2 Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣebi awọn ara Galili wọnyi ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn ara Galili lọ, nitoriti nwọn jẹ irú ìya bawọnni? 3 Mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ: bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bẹ̃ gẹgẹ. 4 Tabi awọn mejidilogun, ti ile-iṣọ ni Siloamu wólu, ti o si pa wọn, ẹnyin ṣebi nwọn ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn enia ti mbẹ̀ ni Jerusalemu lọ?
5 Mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ: bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bẹ̃ gẹgẹ.Ẹ̀kọ́ Nípa Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Tí Kò Léso
6 O si pa owe yi fun wọn pe; ọkunrin kan ni igi ọpọtọ kan ti a gbìn si ọgbà ajara rẹ̀; o si de, o nwá eso lori rẹ̀, kò si ri nkan. 7 O si wi fun oluṣọgba rẹ̀ pe, Sawõ, lati ọdún mẹta li emi ti nwá iwò eso lori igi ọpọtọ yi, emi ko si ri nkan: ké e lulẹ; ẽṣe ti o fi ngbilẹ lasan pẹlu? 8 O si dahùn o wi fun u pe, Oluwa, jọwọ rẹ̀ li ọdún yi pẹlu, titi emi o fi tú ilẹ idi rẹ̀ yiká, titi emi o si fi bu ilẹdu si i: 9 Bi o ba si so eso, gẹgẹ: bi kò ba si so, njẹ lẹhin eyini ki iwọ ki o ke e lulẹ̀. 10 O si nkọ́ni ninu sinagogu kan li ọjọ isimi. 11 Si kiyesi i, obinrin kan wà nibẹ̀ ti o ni ẹmí ailera, lati ọdún mejidilogun wá, ẹniti o tẹ̀ tan, ti ko le gbé ara rẹ̀ soke bi o ti wù ki o ṣe. 12 Nigbati Jesu ri i, o pè e si ọdọ, o si wi fun u pe, Obinrin yi, a tú ọ silẹ lọwọ ailera rẹ. 13 O si fi ọwọ́ rẹ̀ le e: lojukanna a si ti sọ ọ di titọ, o si nyìn Ọlọrun logo. 14 Olori sinagogu si kun fun irunu, nitoriti Jesu muni larada li ọjọ isimi, o si wi fun ijọ enia pe, Ijọ mẹfa ni mbẹ ti a fi iṣiṣẹ: ninu wọn ni ki ẹnyin ki o wá ki a ṣe dida ara nyin, ki o máṣẹ li ọjọ isimi. 15 Nigbana li Oluwa dahùn, o si wi fun u pe, Ẹnyin agabagebe, olukuluku nyin ki itú malu tabi kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ kuro nibuso, ki si ifà a lọ imu omi li ọjọ isimi? 16 Kò si yẹ ki a tú obinrin yi ti iṣe ọmọbinrin Abrahamu silẹ ni ìde yi li ọjọ isimi, ẹniti Satani ti dè, sawõ lati ọdún mejidilogun yi wá?
17 Nigbati o si wi nkan wọnyi, oju tì gbogbo awọn ọtá rẹ̀: gbogbo ijọ enia si yọ̀ fun ohun ogo gbogbo ti o ṣe lati ọwọ́ rẹ̀ wá.Àwọn Òwe Nípa Wóró Mustardi ati Nípa Ìwúkàrà
(Mat 13:31-33; Mak 4:30-32)
18 O si wipe, Kini ijọba Ọlọrun jọ? kili emi o si fi wé? 19 O dabi wóro irugbin mustardi, ti ọkunrin kan mú, ti o si sọ sinu ọgbà rẹ̀; ti o si hù, o si di igi nla; awọn ẹiyẹ oju ọrun si ngbé ori ẹká rẹ̀. 20 O si tún wipe, Kili emi iba fi ijọba Ọlọrun wé?
21 O dabi iwukara, ti obinrin kan mu, ti o fi sinu oṣuwọn iyẹfun mẹta, titi gbogbo rẹ̀ o fi di wiwu.Ẹnu Ìlẹ̀kùn Tí Ó Há
(Mat 7:13-14, 21-23)
22 O si nlà arin ilu ati iletò lọ, o nkọ́ni, o si nrìn lọ si iha Jerusalemu. 23 Ẹnikan si bi i pe, Oluwa, diẹ ha li awọn ti a o gbalà? O si wi fun wọn pe, 24 Ẹ làkaka lati wọ̀ oju-ọ̀na tõro: nitori mo wi fun nyin, enia pipọ ni yio wá ọ̀na ati wọ̀ ọ, nwọn kì yio si le wọle. 25 Nigbati bãle ile ba dide lẹkan fũ, ti o ba si ti sé ilẹkun, ẹnyin o si bẹ̀rẹ si iduro lode, ti ẹ o ma kànkun, wipe, Oluwa, Oluwa, ṣí i fun wa; on o si dahùn wi fun nyin pe, Emi kò mọ̀ nyin nibiti ẹnyin gbé ti wá: 26 Nigbana li ẹnyin o bẹ̀rẹ si iwipe, Awa ti jẹ, awa si ti mu niwaju rẹ, iwọ si kọ́ni ni igboro ilu wa. 27 On o si wipe, Emi wi fun nyin, emi kò mọ̀ nyin nibiti ẹnyin gbé ti wá; ẹ lọ kuro lọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ. 28 Ẹkún ati ipahinkeke yio wà nibẹ̀, nigbati ẹnyin o ri Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu, ati gbogbo awọn woli, ni ijọba Ọlọrun, ti a o si tì ẹnyin sode. 29 Nwọn o si ti ìla-õrùn, ati ìwọ-õrùn wá, ati lati ariwa, ati gusù wá, nwọn o si joko ni ijọba Ọlọrun.
30 Si wo o, awọn ẹni-ẹ̀hin mbẹ ti yio di ẹni-iwaju, awọn ẹni-iwaju mbẹ, ti yio di ẹni-ẹ̀hin.Jesu Dárò Jerusalẹmu
(Mat 23:37-39)
31 Ni wakati kanna diẹ ninu awọn Farisi tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Jade, ki iwọ ki o si lọ kuro nihinyi: nitori Herodu nfẹ pa ọ. 32 O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ki ẹnyin si sọ fun kọ̀lọkọlọ nì pe, Kiyesi i, emi nlé awọn ẹmi èṣu jade, emi nṣe dida ara loni ati lọla, ati ni ijọ kẹta emi o ṣe aṣepe. 33 Ṣugbọn emi kò jẹ má rìn loni, ati lọla, ati li ọtunla: kò le jẹ bẹ̃ pe woli ṣegbé lẹhin odi Jerusalemu. 34 Jerusalemu, Jerusalemu, iwọ ti o pa awọn woli, ti o si sọ okuta lù awọn ti a rán si ọ pa; nigba melo li emi nfẹ iradọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ̀ ti iradọ bò awọn ọmọ rẹ̀ labẹ́ apá rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ! 35 Sawõ, a fi ile nyin silẹ fun nyin li ahoro: lõtọ ni mo si wi fun nyin, Ẹnyin ki yio ri mi, titi yio fi di akoko ti ẹnyin o wipe, Olubukun li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa.
Luke 13
Call to Repent
1 Now on the same occasion there were some present who reported to Him about the Galileans whose blood Pilate had mixed with their sacrifices.2 And Jesus said to them, "Do you suppose that these Galileans were greater sinners than all other Galileans because they suffered this fate?3 I tell you, no, but unless you repent, you will all likewise perish.4 Or do you suppose that those eighteen on whom the tower in Siloam fell and killed them were worse culprits than all the men who live in Jerusalem?5 I tell you, no, but unless you repent, you will all likewise perish."
6 And He began telling this parable: "A man had a fig tree which had been planted in his vineyard; and he came looking for fruit on it and did not find any.7 And he said to the vineyard-keeper, 'Behold, for three years I have come looking for fruit on this fig tree without finding any. Cut it down! Why does it even use up the ground?'8 And he answered and said to him, 'Let it alone, sir, for this year too, until I dig around it and put in fertilizer;9 and if it bears fruit next year, fine; but if not, cut it down.'"
Healing on the Sabbath
10 And He was teaching in one of the synagogues on the Sabbath.11 And there was a woman who for eighteen years had had a sickness caused by a spirit; and she was bent double, and could not straighten up at all.12 When Jesus saw her, He called her over and said to her, "Woman, you are freed from your sickness."13 And He laid His hands on her; and immediately she was made erect again and began glorifying God.14 But the synagogue official, indignant because Jesus had healed on the Sabbath, began saying to the crowd in response, "There are six days in which work should be done; so come during them and get healed, and not on the Sabbath day."15 But the Lord answered him and said, "You hypocrites, does not each of you on the Sabbath untie his ox or his donkey from the stall and lead him away to water him?16 And this woman, a daughter of Abraham as she is, whom Satan has bound for eighteen long years, should she not have been released from this bond on the Sabbath day?"17 As He said this, all His opponents were being humiliated; and the entire crowd was rejoicing over all the glorious things being done by Him.
Parables of Mustard Seed and Leaven
18 So He was saying, "What is the kingdom of God like, and to what shall I compare it?19 It is like a mustard seed, which a man took and threw into his own garden; and it grew and became a tree, and THE BIRDS OF THE AIR NESTED IN ITS BRANCHES."
20 And again He said, "To what shall I compare the kingdom of God?21 It is like leaven, which a woman took and hid in three pecks of flour until it was all leavened."
Teaching in the Villages
22 And He was passing through from one city and village to another, teaching, and proceeding on His way to Jerusalem.23 And someone said to Him, "Lord, are there just a few who are being saved?" And He said to them,24 "Strive to enter through the narrow door; for many, I tell you, will seek to enter and will not be able.25 Once the head of the house gets up and shuts the door, and you begin to stand outside and knock on the door, saying, 'Lord, open up to us!' then He will answer and say to you, 'I do not know where you are from.'26 Then you will begin to say, 'We ate and drank in Your presence, and You taught in our streets';27 and He will say, 'I tell you, I do not know where you are from; DEPART FROM ME, ALL YOU EVILDOERS.'28 In that place there will be weeping and gnashing of teeth when you see Abraham and Isaac and Jacob and all the prophets in the kingdom of God, but yourselves being thrown out.29 And they will come from east and west and from north and south, and will recline at the table in the kingdom of God.30 And behold, some are last who will be first and some are first who will be last."
31 Just at that time some Pharisees approached, saying to Him, "Go away, leave here, for Herod wants to kill You."32 And He said to them, "Go and tell that fox, 'Behold, I cast out demons and perform cures today and tomorrow, and the third day I reach My goal.'33 Nevertheless I must journey on today and tomorrow and the next day; for it cannot be that a prophet would perish outside of Jerusalem.34 O Jerusalem, Jerusalem, the city that kills the prophets and stones those sent to her! How often I wanted to gather your children together, just as a hen gathers her brood under her wings, and you would not have it!35 Behold, your house is left to you desolate; and I say to you, you will not see Me until the time comes when you say, 'BLESSED IS HE WHO COMES IN THE NAME OF THE LORD!'"