previous next

Luk 15

Òwe Nípa Agutan tí Ó Sọnù

(Mat 18:12-14)

1 GBOGBO awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ si sunmọ ọ lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀. 2 Ati awọn Farisi ati awọn akọwe nkùn, wipe, ọkunrin yi ngbà ẹlẹṣẹ, o si mba wọn jẹun. 3 O si pa owe yi fun wọn, wipe. 4 Ọkunrin wo ni ninu nyin, ti o ni ọgọrun agutan, bi o ba sọ ọ̀kan nù ninu wọn, ti kì yio fi mọkandilọgọrun iyokù silẹ ni iju, ti kì yio si tọsẹ eyi ti o nù lọ, titi yio fi ri i? 5 Nigbati o si ri i tan, o gbé e le ejika rẹ̀, o nyọ. 6 Nigbati o si de ile, o pè awọn ọrẹ́ ati aladugbo rẹ̀ jọ, o nwi fun wọn pe, Ẹ ba mi yọ̀; nitoriti mo ri agutan mi ti o ti nù.

7 Mo wi fun nyin, gẹgẹ bẹ̃li ayọ̀ yio wà li ọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada, jù lori olõtọ mọkandilọgọrun lọ, ti kò ṣe aini ironupiwada.

Òwe Nípa Fàdákà tí Ó Sọnù


8 Tabi obinrin wo li o ni fadaka mẹwa bi o ba sọ ọkan nù, ti kì yio tàn fitilà, ki o si gbá ile, ki o si wá a gidigidi titi yio fi ri i? 9 Nigbati o si ri i, o pè awọn ọrẹ́ ati awọn aladugbo rẹ̀ jọ, o wipe, Ẹ ba mi yọ̀; nitori mo ri fadakà ti mo ti sọnù. 10 Mo wi fun nyin, gẹgẹ bẹ̃li ayọ̀ mbẹ niwaju awọn angẹli Ọlọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada. 11 O si wipe, ọkunrin kan li ọmọkunrin meji: 12 Eyi aburo ninu wọn wi fun baba rẹ̀ pe, Baba, fun mi ni ini rẹ ti o kàn mi. O si pín ohun ìni rẹ̀ fun wọn. 13 Kò si to ijọ melokan lẹhinna, eyi aburo kó ohun gbogbo ti o ni jọ, o si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n lọ si ilẹ òkere, nibẹ̀ li o si gbé fi ìwa wọ̀bia na ohun ini rẹ̀ ni inákuna. 14 Nigbati o si bà gbogbo rẹ̀ jẹ tan, ìyan nla wá imu ni ilẹ na; o si bẹ̀rẹ si idi alaini. 15 O si lọ, o da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ọlọ̀tọ kan ni ilẹ na; on si rán a lọ si oko rẹ̀ lati tọju ẹlẹdẹ. 16 Ayọ̀ ni iba fi jẹ onjẹ ti awọn ẹlẹdẹ njẹ li ajẹyó: ẹnikẹni kò si fifun u. 17 Ṣugbọn nigbati oju rẹ̀ walẹ, o ni, Awọn alagbaṣe baba mi melomelo li o ni onjẹ ajẹyó, ati ajẹtì, emi si nkú fun ebi nihin. 18 Emi o dide, emi o si tọ̀ baba mi lọ, emi o si wi fun u pe, Baba, emi ti dẹṣẹ si ọrun, ati niwaju rẹ; 19 Emi kò si yẹ, li ẹniti a ba ma pè li ọmọ rẹ mọ́; fi mi ṣe bi ọkan ninu awọn alagbaṣe rẹ. 20 O si dide, o si tọ̀ baba rẹ̀ lọ. Ṣugbọn nigbati o si wà li òkere, baba rẹ̀ ri i, ãnu ṣe e, o si sure, o rọ̀mọ́ ọ li ọrùn, o si fi ẹnu kò o li ẹnu. 21 Ọmọ na si wi fun u pe, Baba, emi ti dẹṣẹ si ọrun, ati niwaju rẹ, emi kò yẹ li ẹniti a ba ma pè li ọmọ rẹ mọ́. 22 Ṣugbọn baba na wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Ẹ mu ãyo aṣọ wá kánkán, ki ẹ si fi wọ̀ ọ; ẹ si fi oruka bọ̀ ọ lọwọ, ati bàta si ẹsẹ rẹ̀: 23 Ẹ si mu ẹgbọ̀rọ malu abọpa wá, ki ẹ si pa a; ki a mã jẹ, ki a si mã ṣe ariya: 24 Nitori ọmọ mi yi ti kú, o si tún yè; o ti nù, a si ri i. Nwọn si bẹ̀re si iṣe ariya. 25 Ṣugbọn ọmọ rẹ̀ eyi ẹgbọn ti wà li oko: bi o si ti mbọ̀, ti o sunmọ eti ile, o gbọ́ orin on ijó. 26 O si pè ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ wọn, o bère, kili ã mọ̀ nkan wọnyi si? 27 O si wi fun u pe, Aburo rẹ de; baba rẹ si pa ẹgbọ̀rọ malu abọpa, nitoriti o ri i pada li alafia ati ni ilera. 28 O si binu, o si kọ̀ lati wọle; baba rẹ̀ si jade, o si wá iṣipẹ fun u. 29 O si dahùn o wi fun baba rẹ̀ pe, Wo o, lati ọdún melo wọnyi li emi ti nsin ọ, emi kò si ru ofin rẹ ri: iwọ kò si ti ifi ọmọ ewurẹ kan fun mi, lati fi ba awọn ọrẹ́ mi ṣe ariya: 30 Ṣugbọn nigbati ọmọ rẹ yi de, ẹniti o fi panṣaga run ọrọ̀ rẹ, iwọ si ti pa ẹgbọ̀rọ malu abọpa fun u. 31 O si wi fun u pe, Ọmọ, nigbagbogbo ni iwọ mbẹ lọdọ mi, ohun gbogbo ti mo si ni, tìrẹ ni. 32 O yẹ ki a ṣe ariya ki a si yọ̀: nitori aburo rẹ yi ti kú, o si tún yè; o ti nù, a si ri i.

Luke 15

The Lost Sheep

1 Now all the tax collectors and the sinners were coming near Him to listen to Him.2 Both the Pharisees and the scribes began to grumble, saying, "This man receives sinners and eats with them."

3 So He told them this parable, saying,4 "What man among you, if he has a hundred sheep and has lost one of them, does not leave the ninety-nine in the open pasture and go after the one which is lost until he finds it?5 When he has found it, he lays it on his shoulders, rejoicing.6 And when he comes home, he calls together his friends and his neighbors, saying to them, 'Rejoice with me, for I have found my sheep which was lost!'7 I tell you that in the same way, there will be more joy in heaven over one sinner who repents than over ninety-nine righteous persons who need no repentance.

The Lost Coin

8 "Or what woman, if she has ten silver coins and loses one coin, does not light a lamp and sweep the house and search carefully until she finds it?9 When she has found it, she calls together her friends and neighbors, saying, 'Rejoice with me, for I have found the coin which I had lost!'10 In the same way, I tell you, there is joy in the presence of the angels of God over one sinner who repents."

The Prodigal Son

11 And He said, "A man had two sons.12 The younger of them said to his father, 'Father, give me the share of the estate that falls to me.' So he divided his wealth between them.13 And not many days later, the younger son gathered everything together and went on a journey into a distant country, and there he squandered his estate with loose living.14 Now when he had spent everything, a severe famine occurred in that country, and he began to be impoverished.15 So he went and hired himself out to one of the citizens of that country, and he sent him into his fields to feed swine.16 And he would have gladly filled his stomach with the pods that the swine were eating, and no one was giving anything to him.17 But when he came to his senses, he said, 'How many of my father's hired men have more than enough bread, but I am dying here with hunger!18 I will get up and go to my father, and will say to him, "Father, I have sinned against heaven, and in your sight;19 I am no longer worthy to be called your son; make me as one of your hired men."'20 So he got up and came to his father. But while he was still a long way off, his father saw him and felt compassion for him, and ran and embraced him and kissed him.21 And the son said to him, 'Father, I have sinned against heaven and in your sight; I am no longer worthy to be called your son.'22 But the father said to his slaves, 'Quickly bring out the best robe and put it on him, and put a ring on his hand and sandals on his feet;23 and bring the fattened calf, kill it, and let us eat and celebrate;24 for this son of mine was dead and has come to life again; he was lost and has been found.' And they began to celebrate.

25 "Now his older son was in the field, and when he came and approached the house, he heard music and dancing.26 And he summoned one of the servants and began inquiring what these things could be.27 And he said to him, 'Your brother has come, and your father has killed the fattened calf because he has received him back safe and sound.'28 But he became angry and was not willing to go in; and his father came out and began pleading with him.29 But he answered and said to his father, 'Look! For so many years I have been serving you and I have never neglected a command of yours; and yet you have never given me a young goat, so that I might celebrate with my friends;30 but when this son of yours came, who has devoured your wealth with prostitutes, you killed the fattened calf for him.'31 And he said to him, 'Son, you have always been with me, and all that is mine is yours.32 But we had to celebrate and rejoice, for this brother of yours was dead and has begun to live, and was lost and has been found.'"