Luk 16
Òwe Ọmọ-ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n Ẹ̀wẹ́
1 O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pẹlu pe, ọkunrin ọlọrọ̀ kan wà, ti o ni iriju kan; on na ni nwọn fi sùn u pe, o ti nfi ohun-ini rẹ̀ ṣòfo. 2 Nigbati o si pè e, o wi fun u pe, Ẽṣe ti emi fi ngbọ́ eyi si ọ? siro iṣẹ iriju rẹ; nitori iwọ ko le ṣe iriju mọ́. 3 Iriju na si wi ninu ara rẹ̀ pe, Ewo li emi o ṣe? nitoriti Oluwa mi gbà iṣẹ iriju lọwọ mi: emi kò le wàlẹ; lati ṣagbe oju ntì mi. 4 Mo mọ̀ eyiti emi o ṣe, nigbati a ba mu mi kuro nibi iṣẹ iriju, ki nwọn ki o le gbà mi sinu ile wọn. 5 O si pè awọn ajigbese oluwa rẹ̀ sọdọ rẹ̀, o si wi fun ekini pe, Elo ni iwọ jẹ oluwa mi? 6 O si wipe, Ọgọrun oṣuwọn oróro. O si wi fun u pe, Mu iwe rẹ, si joko nisisiyi, ki o si kọ adọta. 7 Nigbana li o si bi ẹnikeji pe, Elo ni iwọ jẹ? On si wipe, Ọgọrun oṣuwọn alikama. O si wi fun u pe, Mu iwe rẹ, ki o si kọ ọgọrin. 8 Oluwa rẹ̀ si yìn alaiṣõtọ iriju na, nitoriti o fi ọgbọ́n ṣe e: awọn ọmọ aiye yi sá gbọ́n ni iran wọn jù awọn ọmọ imọlẹ lọ. 9 Emi si wi fun nyin, ẹ fi mammoni aiṣõtọ yàn ọrẹ́ fun ara nyin pe, nigbati yio ba yẹ̀, ki nwọn ki o le gbà nyin si ibujoko wọn titi aiye. 10 Ẹniti o ba ṣe olõtọ li ohun kikini, o ṣe olõtọ ni pipọ pẹlu: ẹniti o ba si ṣe alaiṣõtọ li ohun kikini, o ṣe alaiṣõtọ li ohun pipo pẹlu. 11 Njẹ bi ẹnyin kò ba ti jẹ olõtọ ni mammoni aiṣõtọ, tani yio fi ọrọ̀ tõtọ ṣú nyin? 12 Bi ẹnyin ko ba si ti jẹ olõtọ li ohun ti iṣe ti ẹlomiran, tani yio fun nyin li ohun ti iṣe ti ẹnyin tikara nyin?
13 Kò si iranṣẹ kan ti o le sin oluwa meji: ayaṣebi yio korira ọkan, yio si fẹ ekeji; tabi yio fi ara mọ́ ọkan, yio si yàn ekeji ni ipọsi. Ẹnyin kò le sin Ọlọrun pẹlu mammoni.Òfin ati Ìjọba Ọlọrun
(Mat 11:12-13; 5:31-32; Mak 10:11-12)
14 Awọn Farisi, ti nwọn ni ojukokoro si gbọ́ gbogbo nkan wọnyi, nwọn si yọ-ṣùti si i. 15 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li awọn ti ndare fun ara nyin niwaju enia; ṣugbọn Ọlọrun mọ̀ ọkàn nyin: nitori eyi ti a gbé niyin lọdọ enia, irira ni niwaju Ọlọrun. 16 Ofin ati awọn woli mbẹ titi di igba Johanu: lati igbana wá li a ti nwasu ijọba Ọlọrun, olukuluku si nfi ipá wọ̀ inu rẹ̀. 17 Ṣugbọn o rọrun fun ọrun on aiye lati kọja lọ, jù ki ṣonṣo kan ti ofin ki o yẹ̀.
18 Ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, ti o si gbé omiran ni iyawo, o ṣe panṣaga: ẹnikẹni ti o ba si gbé, ẹniti ọkọ rẹ̀ kọ̀ silẹ ni iyawo, o ṣe panṣaga.Ọkunrin Ọlọ́rọ̀ ati Lasaru
19 Njẹ ọkunrin ọlọrọ̀ kan wà, ti o nwọ̀ aṣọ elesè àluko ati aṣọ àla daradara, a si ma jẹ didùndidun lojojumọ́: 20 Alagbe kan si wà ti a npè ni Lasaru, ti nwọn ima gbé wá kalẹ lẹba ọ̀na ile rẹ̀, o kún fun õju, 21 On a si ma fẹ ki a fi ẹrún ti o ti ori tabili ọlọrọ̀ bọ silẹ bọ́ on: awọn ajá si wá, nwọn si fá a li õju lá. 22 O si ṣe, alagbe kú, a si ti ọwọ́ awọn angẹli gbé e lọ si õkan-àiya Abrahamu: ọlọrọ̀ na si kú pẹlu, a si sin i; 23 Ni ipo-oku li o gbé oju rẹ̀ soke, o mbẹ ninu iṣẹ oró, o si ri Abrahamu li òkere, ati Lasaru li õkan-àiya rẹ̀. 24 O si ke, o wipe, Baba Abrahamu, ṣãnu fun mi, ki o si rán Lasaru, ki o tẹ̀ orika rẹ̀ bọmi, ki o si fi tù mi li ahọn; nitori emi njoró ninu ọwọ́ iná yi. 25 Ṣugbọn Abrahamu wipe, Ọmọ, ranti pe, nigba aiye rẹ, iwọ ti gbà ohun rere tirẹ, ati Lasaru ohun buburu: ṣugbọn nisisiyi ara rọ̀ ọ, iwọ si njoro. 26 Ati pẹlu gbogbo eyi, a gbe ọgbun nla kan si agbedemeji awa ati ẹnyin, ki awọn ti nfẹ má ba le rekọja lati ìhin lọ sọdọ nyin, ki ẹnikẹni má si le ti ọ̀hun rekọja tọ̀ wa wá. 27 O si wipe, Njẹ mo bẹ̀ ọ, baba, ki iwọ ki o rán a lọ si ile baba mi: 28 Nitori mo ni arakunrin marun; ki o le rò fun wọn ki awọn ki o má ba wá si ibi oró yi pẹlu. 29 Abrahamu si wi fun u pe, Nwọn ni Mose ati awọn woli; ki nwọn ki o gbọ́ ti wọn. 30 O si wipe, Bẹ̃kọ, Abrahamu baba; ṣugbọn bi ẹnikan ba ti inu okú tọ̀ wọn lọ, nwọn ó ronupiwada. 31 O si wi fun u pe, Bi nwọn kò ba gbọ́ ti Mose ati ti awọn woli, a kì yio yi wọn li ọkan pada bi ẹnikan tilẹ ti inu okú dide.
Luke 16
The Unrighteous Steward
1 Now He was also saying to the disciples, "There was a rich man who had a manager, and this manager was reported to him as squandering his possessions.2 And he called him and said to him, 'What is this I hear about you? Give an accounting of your management, for you can no longer be manager.'3 The manager said to himself, 'What shall I do, since my master is taking the management away from me? I am not strong enough to dig; I am ashamed to beg.4 I know what I shall do, so that when I am removed from the management people will welcome me into their homes.'5 And he summoned each one of his master's debtors, and he began saying to the first, 'How much do you owe my master?'6 And he said, 'A hundred measures of oil.' And he said to him, 'Take your bill, and sit down quickly and write fifty.'7 Then he said to another, 'And how much do you owe?' And he said, 'A hundred measures of wheat.' He *said to him, 'Take your bill, and write eighty.'8 And his master praised the unrighteous manager because he had acted shrewdly; for the sons of this age are more shrewd in relation to their own kind than the sons of light.9 And I say to you, make friends for yourselves by means of the twealth of unrighteousness, so that when it fails, they will receive you into the eternal dwellings.
10 "He who is faithful in a very little thing is faithful also in much; and he who is unrighteous in a very little thing is unrighteous also in much.11 Therefore if you have not been faithful in the use of unrighteous wealth, who will entrust the true riches to you?12 And if you have not been faithful in the use of that which is another's, who will give you that which is your own?13 No servant can serve two masters; for either he will hate the one and love the other, or else he will be devoted to one and despise the other. You cannot serve God and wealth."
14 Now the Pharisees, who were lovers of money, were listening to all these things and were scoffing at Him.15 And He said to them, "You are those who justify yourselves in the sight of men, but God knows your hearts; for that which is highly esteemed among men is detestable in the sight of God.
16 "The Law and the Prophets were proclaimed until John; since that time the gospel of the kingdom of God has been preached, and everyone is forcing his way into it.17 But it is easier for heaven and earth to pass away than for one stroke of a letter of the Law to fail.
18 "Everyone who divorces his wife and marries another commits adultery, and he who marries one who is divorced from a husband commits adultery.
The Rich Man and Lazarus
19 "Now there was a rich man, and he habitually dressed in purple and fine linen, joyously living in splendor every day.20 And a poor man named Lazarus was laid at his gate, covered with sores,21 and longing to be fed with the crumbs which were falling from the rich man's table; besides, even the dogs were coming and licking his sores.22 Now the poor man died and was carried away by the angels to Abraham's bosom; and the rich man also died and was buried.23 In Hades he lifted up his eyes, being in torment, and *saw Abraham far away and Lazarus in his bosom.24 And he cried out and said, 'Father Abraham, have mercy on me, and send Lazarus so that he may dip the tip of his finger in water and cool off my tongue, for I am in agony in this flame.'25 But Abraham said, 'Child, remember that during your life you received your good things, and likewise Lazarus bad things; but now he is being comforted here, and you are in agony.26 And besides all this, between us and you there is a great chasm fixed, so that those who wish to come over from here to you will not be able, and that none may cross over from there to us.'27 And he said, 'Then I beg you, father, that you send him to my father's house-28 for I have five brothers-in order that he may warn them, so that they will not also come to this place of torment.'29 But Abraham *said, 'They have Moses and the Prophets; let them hear them.'30 But he said, 'No, father Abraham, but if someone goes to them from the dead, they will repent!'31 But he said to him, 'If they do not listen to Moses and the Prophets, they will not be persuaded even if someone rises from the dead.'"