previous next

Luk 18

Òwe Nípa Opó Kan ati Onidajọ

1 O si pa owe kan fun wọn nitori eyiyi pe, o yẹ ki a mã gbadura nigbagbogbo, ki a má si ṣãrẹ̀; 2 Wipe, Onidajọ́ kan wà ni ilu kan, ti kò bẹ̀ru Ọlọrun, ti kò si ṣe ojusaju enia: 3 Opó kan si wà ni ilu na; o si ntọ̀ ọ wá, wipe, Gbẹsan mi lara ọtá mi. 4 Kò si ṣu si i nigba sã kan: ṣugbọn nikẹhin o wi ninu ara rẹ̀ pe, Bi emi kò tilẹ bẹ̀ru Ọlọrun, ti emi ko si ṣe ojuṣãju enia; 5 Ṣugbọn nitoriti opó yi nyọ mi lẹnu, emi o gbẹsan rẹ̀, ki o má ba fi wíwa rẹ̀ nigbakugba da mi lagãra. 6 Oluwa si wipe, Ẹ gbọ́ bi alaiṣõtọ onidajọ ti wi. 7 Ọlọrun kì yio ha si gbẹsan awọn ayanfẹ rẹ̀, ti nfi ọsán ati oru kigbe pè e, ti o si mu suru fun wọn?

8 Mo wi fun nyin, yio gbẹsan wọn kánkán. Ṣugbọn nigbati Ọmọ-enia ba de yio ha ri igbagbọ́ li aiye?

Òwe Nípa Farisi Kan ati Agbowó-odè


9 O si pa owe yi fun awọn kan ti nwọn gbẹkẹle ara wọn pe, awọn li olododo, ti nwọn si ngàn awọn ẹlomiran: 10 Pe, Awọn ọkunrin meji goke lọ si tẹmpili lati gbadura; ọkan jẹ Farisi, ekeji si jẹ agbowode. 11 Eyi Farisi dide, o si ngbadura ninu ara rẹ̀ bayi pe, Ọlọrun, mo dupẹ lọwọ rẹ, nitoriti emi kò ri bi awọn ara iyokù, awọn alọnilọwọgba, alaiṣõtọ, panṣaga, tabi emi kò tilẹ ri bi agbowode yi. 12 Emi ngbàwẹ li ẹrinmeji li ọ̀sẹ, mo nsan idamẹwa ohun gbogbo ti mo ni. 13 Ṣugbọn agbowode duro li òkere, kò tilẹ jẹ gbé oju rẹ̀ soke ọrun, ṣugbọn o lù ara rẹ̀ li õkan-àiya, o wipe, Ọlọrun ṣãnu fun mi, emi ẹlẹṣẹ.

14 Mo wi fun nyin, ọkunrin yi sọkalẹ lọ si ile rẹ̀ ni idalare jù ekeji lọ: nitori ẹnikẹni ti o ba gbé ara rẹ̀ ga, on li a o rẹ̀ silẹ; ẹniti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ on li a o gbéga.

Jesu Súre fún Àwọn Ọmọde

(Mat 19:13-15; Mak 10:13-16)


15 Nwọn si gbé awọn ọmọ-ọwọ tọ̀ ọ wá pẹlu, ki o le fi ọwọ́ le wọn; ṣugbọn nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i, nwọn mba wọn wi. 16 Ṣugbọn Jesu pè wọn sọdọ rẹ̀, o si wipe, Ẹ jẹ ki awọn ọmọ kekere wá sọdọ mi, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun: nitoriti irú wọn ni ijọba Ọlọrun. 17 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti kò ba gbà ijọba Ọlọrun bi ọmọ kekere, kì yio wọ̀ inu rẹ̀ bi o ti wù ki o ri. 18 Ijoye kan si bère lọwọ rẹ̀, wipe, Olukọni rere, kili emi o ṣe ti emi o fi jogún iye ainipẹkun? 19 Jesu si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi npè mi li ẹni rere? ẹni rere kan kò si, bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun. 20 Iwọ mọ̀ ofin wọnni, Máṣe ṣe panṣaga, máṣe pania, máṣe jale, máṣe jẹri eke, bọ̀wọ fun baba on iya rẹ. 21 O si wipe, Gbogbo nkan wọnyi li emi ti pamọ lati igba ewe mi wá. 22 Nigbati Jesu si gbọ́ eyi, o wi fun u pe, Ohun kan li o kù fun ọ sibẹ: lọ ità ohun gbogbo ti o ni, ki o si pín i fun awọn talakà, iwọ o si ni iṣura li ọrun: si wá, ki o mã tọ̀ mi lẹhin. 23 Nigbati o si gbọ́ eyi, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi: nitoriti o li ọrọ̀ pipo. 24 Nigbati Jesu ri i pe, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi, o ni, Yio ti ṣoro to fun awọn ti o li ọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun! 25 Nitori o rọrun fun ibakasiẹ lati gbà oju abẹrẹ wọle, jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ. 26 Awọn ti o si gbọ́ wipe, Njẹ tali o ha le là? 27 O si wipe, Ohun ti o ṣoro lọdọ enia, kò ṣoro lọdọ Ọlọrun. 28 Peteru si wipe, Sawõ, awa ti fi tiwa silẹ, a si tọ̀ ọ lẹhin. 29 O si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Kò si ẹniti o fi ile, tabi aya, tabi ará, tabi õbi, tabi ọmọ silẹ, nitori ijọba Ọlọrun,

30 Ti kì yio gba ilọpo pipọ si i li aiye yi, ati li aiye ti mbọ̀ ìye ainipẹkun.

Jesu Tún Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀ Lẹẹkẹta

(Mat 20:17-19; Mak 10:32-34)


31 Nigbana li o pè awọn mejila sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Sawõ, awa ngòke lọ si Jerusalemu, a o si mu ohun gbogbo ṣẹ, ti a ti kọ lati ọwọ́ awọn woli wá, nitori Ọmọ-enia. 32 Nitori a o fi i le awọn Keferi lọwọ, a o fi i ṣe ẹlẹyà, a o si fi i ṣe ẹsin, a o si tutọ́ si i lara: 33 Nwọn o si nà a, nwọn o si pa a: ni ijọ kẹta yio si jinde.

34 Ọkan ninu nkan wọnyi kò si yé wọn: ọ̀rọ yi si pamọ́ fun wọn, bẹ̃ni nwọn ko si mọ̀ ohun ti a wi.

Jesu Wo Afọ́jú Alágbe Sàn Ní Jẹriko

(Mat 20:29-34; Mak 10:46-52)


35 O si ṣe, bi on ti sunmọ Jeriko, afọju kan joko lẹba ọ̀na o nṣagbe: 36 Nigbati o gbọ́ ti ọpọ́ enia nkọja lọ, o bère pe, kili ã le mọ̀ eyi si. 37 Nwọn si wi fun u pe, Jesu ti Nasareti li o nkọja lọ. 38 O si kigbe pe, Jesu, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi. 39 Awọn ti nlọ niwaju ba a wi pe, ki o pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣugbọn on si kigbe si i kunkun pe, Iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi. 40 Jesu si dẹṣẹ duro, o ni, ki a mu u tọ̀ on wá: nigbati o si sunmọ ọ, o bi i, 41 Wipe, Kini iwọ nfẹ ti emi iba ṣe fun o? O si wipe, Oluwa, ki emi ki o le riran. 42 Jesu si wi fun u pe, Riran: igbagbọ́ rẹ gbà ọ là. 43 Lojukanna o si riran, o si ntọ̀ ọ lẹhin, o nyìn Ọlọrun logo: ati gbogbo enia nigbati nwọn ri i, nwọn fi iyìn fun Ọlọrun.

Luke 18

Parables on Prayer

1 Now He was telling them a parable to show that at all times they ought to pray and not to lose heart,2 saying, "In a certain city there was a judge who did not fear God and did not respect man.3 There was a widow in that city, and she kept coming to him, saying, 'Give me legal protection from my opponent.'4 For a while he was unwilling; but afterward he said to himself, 'Even though I do not fear God nor respect man,5 yet because this widow bothers me, I will give her legal protection, otherwise by continually coming she will wear me out.'"6 And the Lord said, "Hear what the unrighteous judge *said;7 now, will not God bring about justice for His elect who cry to Him day and night, and will He delay long over them?8 I tell you that He will bring about justice for them quickly. However, when the Son of Man comes, will He find faith on the earth?"

The Pharisee and the Publican

9 And He also told this parable to some people who trusted in themselves that they were righteous, and viewed others with contempt:10 "Two men went up into the temple to pray, one a Pharisee and the other a tax collector.11 The Pharisee stood and was praying this to himself: 'God, I thank You that I am not like other people: swindlers, unjust, adulterers, or even like this tax collector.12 I fast twice a week; I pay tithes of all that I get.'13 But the tax collector, standing some distance away, was even unwilling to lift up his eyes to heaven, but was beating his breast, saying, 'God, be merciful to me, the sinner!'14 I tell you, this man went to his house justified rather than the other; for everyone who exalts himself will be humbled, but he who humbles himself will be exalted."

15 And they were bringing even their babies to Him so that He would touch them, but when the disciples saw it, they began rebuking them.16 But Jesus called for them, saying, "Permit the children to come to Me, and do not hinder them, for the kingdom of God belongs to such as these.17 Truly I say to you, whoever does not receive the kingdom of God like a child will not enter it at all."

The Rich Young Ruler

18 A ruler questioned Him, saying, "Good Teacher, what shall I do to inherit eternal life?"19 And Jesus said to him, "Why do you call Me good? No one is good except God alone.20 You know the commandments, 'DO NOT COMMIT ADULTERY, DO NOT MURDER, DO NOT STEAL, DO NOT BEAR FALSE WITNESS, HONOR YOUR FATHER AND MOTHER.'"21 And he said, "All these things I have kept from my youth."22 When Jesus heard this, He said to him, "One thing you still lack; sell all that you possess and distribute it to the poor, and you shall have treasure in heaven; and come, follow Me."23 But when he had heard these things, he became very sad, for he was extremely rich.24 And Jesus looked at him and said, "How hard it is for those who are wealthy to enter the kingdom of God!25 For it is easier for a camel to go through the eye of a needle than for a rich man to enter the kingdom of God."26 They who heard it said, "Then who can be saved?"27 But He said, "The things that are impossible with people are possible with God."

28 Peter said, "Behold, we have left our own homes and followed You."29 And He said to them, "Truly I say to you, there is no one who has left house or wife or brothers or parents or children, for the sake of the kingdom of God,30 who will not receive many times as much at this time and in the age to come, eternal life."

31 Then He took the twelve aside and said to them, "Behold, we are going up to Jerusalem, and all things which are written through the prophets about the Son of Man will be accomplished.32 For He will be handed over to the Gentiles, and will be mocked and mistreated and spit upon,33 and after they have scourged Him, they will kill Him; and the third day He will rise again."34 But the disciples understood none of these things, and the meaning of this statement was hidden from them, and they did not comprehend the things that were said.

Bartimaeus Receives Sight

35 As Jesus was approaching Jericho, a blind man was sitting by the road begging.36 Now hearing a crowd going by, he began to inquire what this was.37 They told him that Jesus of Nazareth was passing by.38 And he called out, saying, "Jesus, Son of David, have mercy on me!"39 Those who led the way were sternly telling him to be quiet; but he kept crying out all the more, "Son of David, have mercy on me!"40 And Jesus stopped and commanded that he be brought to Him; and when he came near, He questioned him,41 "What do you want Me to do for you?" And he said, "Lord, I want to regain my sight!"42 And Jesus said to him, "Receive your sight; your faith has made you well."43 Immediately he regained his sight and began following Him, glorifying God; and when all the people saw it, they gave praise to God.