Luk 2
Ìbí Jesu
(Mat 1:18-25)
1 O SI ṣe li ọjọ wọnni, aṣẹ ti ọdọ Kesari Augustu jade wá pe, ki a kọ orukọ gbogbo aiye sinu iwe. 2 (Eyi ni ikọsinu-iwe ikini ti a ṣe nigbati Kireniu fi jẹ Bãlẹ Siria.) 3 Gbogbo awọn enia si lọ lati kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe, olukuluku si ilu ara rẹ̀. 4 Josefu pẹlu si goke lati Nasareti ilu Galili lọ, si ilu Dafidi ni Judea, ti a npè ni Betlehemu; nitoriti iran ati idile Dafidi ni iṣe, 5 Lati kọ orukọ rẹ̀, pẹlu Maria aya rẹ̀ afẹsọna, ti o tobi fun oyún. 6 O si ṣe, nigbati nwọn wà nibẹ̀, ọjọ rẹ̀ pé ti on o bí. 7 O si bí akọbi rẹ̀ ọmọkunrin, o si fi ọja wé e, o si tẹ́ ẹ sinu ibujẹ ẹran; nitoriti àye kò si fun wọn ninu ile èro. 8 Awọn oluṣọ-agutan mbẹ ni ilu na, nwọn nṣọ agbo agutan wọn li oru ni pápá ti nwọn ngbé. 9 Sá si kiyesi i, angẹli Oluwa na yọ si wọn, ogo Oluwa si ràn yi wọn ká: ẹ̀ru si ba wọn gidigidi. 10 Angẹli na si wi fun wọn pe, Má bẹ̀ru: sawò o, mo mu ihinrere ayọ̀ nla fun nyin wá, ti yio ṣe ti enia gbogbo. 11 Nitori a bí Olugbala fun nyin loni ni ilu Dafidi, ti iṣe Kristi Oluwa. 12 Eyi ni yio si ṣe àmi fun nyin; ẹnyin ó ri ọmọ-ọwọ ti a fi ọja wé, o dubulẹ ni ibujẹ ẹran. 13 Ọpọlọpọ ogun ọrun si yọ si angẹli na li ojijì, nwọn nyìn Ọlọrun, wipe, 14 Ogo ni fun Ọlọrun loke ọrun, ati li aiye alafia, ifẹ inu rere si enia. 15 O si ṣe, nigbati awọn angẹli na pada kuro lọdọ wọn lọ si ọrun, awọn ọkunrin oluṣọ-agutan na ba ara wọn sọ pe, Ẹ jẹ ki a lọ tàra si Betlehemu, ki a le ri ohun ti o ṣẹ, ti Oluwa fihàn fun wa. 16 Nwọn si wá lọgan, nwọn si ri Maria, ati Josefu, ati ọmọ-ọwọ na, o dubulẹ ninu ibujẹ ẹran. 17 Nigbati nwọn si ti ri i, nwọn sọ ohun ti a ti wi fun wọn nipa ti ọmọ yi. 18 Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o gbọ́ si nkan wọnyi, ti a ti wi fun wọn lati ọdọ awọn oluṣọ-agutan wá. 19 Ṣugbọn Maria pa gbogbo nkan wọnyi mọ́, o nrò wọn ninu ọkàn rẹ̀.
20 Awọn oluṣọ-agutan si pada lọ, nwọn nfi ogo fun Ọlọrun, nwọn si nyìn i, nitori ohun gbogbo ti nwọn ti gbọ́ ati ti nwọn ti ri, bi a ti wi i fun wọn.A Sọ Jesu Lórúkọ
21 Nigbati ijọ mẹjọ si pé lati kọ ọmọ na nila, nwọn pè orukọ rẹ̀ ni JESU, bi a ti sọ ọ tẹlẹ lati ọdọ angẹli na wá ki a to lóyun rẹ̀ ninu. 22 Nigbati ọjọ iwẹnu Maria si pé gẹgẹ bi ofin Mose, nwọn gbé Jesu wá si Jerusalemu lati fi i fun Oluwa; 23 (Bi a ti kọ ọ sinu ofin Oluwa pe, Gbogbo ọmọ ọkunrin ti o ṣe akọbi, on li a o pè ni mimọ́ fun Oluwa;) 24 Ati lati rubọ gẹgẹ bi eyi ti a wi ninu ofin Oluwa, Àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji. 25 Si kiyesi i, ọkunrin kan wà ni Jerusalemu, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Simeoni; ọkunrin na si ṣe olõtọ ati olufọkànsin, o nreti itunu Israeli: Ẹmí Mimọ́ si bà le e. 26 A si ti fihàn a lati ọdọ Ẹmí Mimọ́ na wá pe, on kì yio ri ikú, ki o to ri Kristi Oluwa. 27 O si ti ipa Ẹmí wá sinu tẹmpili: nigbati awọn obi rẹ̀ si gbé ọmọ na Jesu wá, lati ṣe fun u bi iṣe ofin. 28 Nigbana li o gbé e li apa rẹ̀, o fi ibukun fun Ọlọrun, o ni, 29 Oluwa, nigbayi li o to jọwọ ọmọ-ọdọ rẹ lọwọ lọ li alafia, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ: 30 Nitoriti oju mi ti ri igbala rẹ na, 31 Ti iwọ ti pèse silẹ niwaju enia gbogbo; 32 Imọlẹ lati mọ́ si awọn Keferi, ati ogo Israeli enia rẹ. 33 Ẹnu si yà Josefu ati iya rẹ̀ si nkan ti a nsọ si i wọnyi. 34 Simeoni si sure fun wọn, o si wi fun Maria iya rẹ̀ pe, Kiyesi i, a gbé ọmọ yi kalẹ fun iṣubu ati idide ọ̀pọ enia ni Israeli; ati fun àmi ti a nsọ̀rọ òdi si; 35 (Idà yio si gún iwọ na li ọkàn pẹlu,) ki a le fi ironu ọ̀pọ ọkàn hàn. 36 Ẹnikan si mbẹ, Anna woli, ọmọbinrin Fanueli, li ẹ̀ya Aseri: ọjọ ogbó rẹ̀ pọ̀, o ti ba ọkọ gbé li ọdún meje lati igba wundia rẹ̀ wá; 37 O si ṣe opó ìwọn ọdún mẹrinlelọgọrin, ẹniti kò kuro ni tẹmpili, o si nfi àwẹ ati adura sìn Ọlọrun lọsán ati loru.
38 O si wọle li akokò na, o si dupẹ fun Oluwa pẹlu, o si sọ̀rọ rẹ̀ fun gbogbo awọn ti o nreti idande Jerusalemu.Àwọn Òbí Jesu Gbé e Pada Lọ sí Nasarẹti
39 Nigbati nwọn si ti ṣe nkan gbogbo tan gẹgẹ bi ofin Oluwa, nwọn pada lọ si Galili, si Nasareti ilu wọn.
40 Ọmọ na si ndàgba, o si nlagbara, o si kún fun ọgbọn: ore-ọfẹ Ọlọrun si mbẹ lara rẹ̀.Jesu lọ sí Tẹmpili Nígbà Ọ̀dọ́ Rẹ̀
41 Awọn õbi rẹ̀ a si mã lọ si Jerusalemu li ọdọdún si ajọ irekọja. 42 Nigbati o si di ọmọ ọdún mejila, nwọn goke lọ si Jerusalemu gẹgẹ bi iṣe ajọ na. 43 Nigbati ọjọ wọn si pé bi nwọn ti npada bọ̀, ọmọ na Jesu duro lẹhin ni Jerusalemu; Josefu ati iya rẹ̀ kò mọ̀. 44 Ṣugbọn nwọn ṣebi o wà li ẹgbẹ èro, nwọn rìn ìrin ọjọ kan; nwọn wá a kiri ninu awọn ará ati awọn ojulumọ̀ wọn. 45 Nigbati nwọn kò si ri i, nwọn pada si Jerusalemu, nwọn nwá a kiri. 46 O si ṣe, lẹhin ijọ mẹta nwọn ri i ninu tẹmpili o joko li arin awọn olukọni, o ngbọ́ ti wọn, o si mbi wọn lẽre. 47 Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀ fun oyé ati idahùn rẹ̀. 48 Nigbati nwọn si ri i, hà ṣe wọn: iya rẹ̀ si bi i pe, Ọmọ, ẽṣe ti iwọ fi ṣe wa bẹ̃? sawò o, baba rẹ ati emi ti nfi ibinujẹ wá ọ kiri. 49 O si dahùn wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá mi kiri? ẹnyin kò mọ pe, emi kò le ṣàima wà nibi iṣẹ Baba mi? 50 Ọrọ ti o sọ kò si yé wọn. 51 O si ba wọn sọkalẹ lọ si Nasareti, o si fi ara balẹ fun wọn: ṣugbọn iya rẹ̀ pa gbogbo nkan wọnyi mọ́ ninu ọkàn rẹ̀. 52 Jesu si npọ̀ li ọgbọ́n, o si ndàgba, o si wà li ojurere li ọdọ Ọlọrun ati enia.
Luke 2
Jesus' Birth in Bethlehem
1 Now in those days a decree went out from Caesar Augustus, that a census be taken of all tthe inhabited earth.2 This was the first census taken while tQuirinius was governor of Syria.3 And everyone was on his way to register for the census, each to his own city.4 Joseph also went up from Galilee, from the city of Nazareth, to Judea, to the city of David which is called Bethlehem, because he was of the house and family of David,5 in order to register along with Mary, who was engaged to him, and was with child.6 While they were there, the days were completed for her to give birth.7 And she gave birth to her firstborn son; and she wrapped Him in cloths, and laid Him in a manger, because there was no room for them in the inn.
8 In the same region there were some shepherds staying out in the fields and keeping watch over their flock by night.9 And an angel of the Lord suddenly stood before them, and the glory of the Lord shone around them; and they were terribly frightened.10 But the angel said to them, "Do not be afraid; for behold, I bring you good news of great joy which will be for all the people;11 for today in the city of David there has been born for you a Savior, who is tChrist the Lord.12 This will be a sign for you: you will find a baby wrapped in cloths and lying in a manger."13 And suddenly there appeared with the angel a multitude of the heavenly host praising God and saying,
14 "Glory to God in the highest,
And on earth peace among men twith whom He is pleased."
15 When the angels had gone away from them into heaven, the shepherds began saying to one another, "Let us go straight to Bethlehem then, and see this thing that has happened which the Lord has made known to us."16 So they came in a hurry and found their way to Mary and Joseph, and the baby as He lay in the manger.17 When they had seen this, they made known the statement which had been told them about this Child.18 And all who heard it wondered at the things which were told them by the shepherds.19 But Mary treasured all these things, pondering them in her heart.20 The shepherds went back, glorifying and praising God for all that they had heard and seen, just as had been told them.
Jesus Presented at the Temple
21 And when eight days had passed, before His circumcision, His name was then called Jesus, the name given by the angel before He was conceived in the womb.
22 And when the days for their purification according to the law of Moses were completed, they brought Him up to Jerusalem to present Him to the Lord23 (as it is written in the Law of the Lord, "EVERY firstborn MALE THAT OPENS THE WOMB SHALL BE CALLED HOLY TO THE LORD"),24 and to offer a sacrifice according to what was said in the Law of the Lord, "A PAIR OF TURTLEDOVES OR TWO YOUNG PIGEONS."
25 And there was a man in Jerusalem whose name was Simeon; and this man was righteous and devout, looking for the consolation of Israel; and the Holy Spirit was upon him.26 And it had been revealed to him by the Holy Spirit that he would not see death before he had seen the Lord's Christ.27 And he came in the Spirit into the temple; and when the parents brought in the child Jesus, to carry out for Him the custom of the Law,28 then he took Him into his arms, and blessed God, and said,
29 "Now Lord, You are releasing Your bond-servant to depart in peace,
According to Your word;
30 For my eyes have seen Your salvation,
31 Which You have prepared in the presence of all peoples,
32 A LIGHT OF REVELATION TO THE GENTILES,
And the glory of Your people Israel."
33 And His father and mother were amazed at the things which were being said about Him.34 And Simeon blessed them and said to Mary His mother, "Behold, this Child is appointed for the fall and rise of many in Israel, and for a sign to be opposed-35 and a sword will pierce even your own soul-to the end that thoughts from many hearts may be revealed."
36 And there was a prophetess, Anna the daughter of Phanuel, of the tribe of Asher. She was advanced in years and had lived with her husband seven years after her marriage,37 and then as a widow to the age of eighty-four. She never left the temple, serving night and day with fastings and prayers.38 At that very moment she came up and began giving thanks to God, and continued to speak of Him to all those who were looking for the redemption of Jerusalem.
Return to Nazareth
39 When they had performed everything according to the Law of the Lord, they returned to Galilee, to their own city of Nazareth.40 The Child continued to grow and become strong, increasing in wisdom; and the grace of God was upon Him.
Visit to Jerusalem
41 Now His parents went to Jerusalem every year at the Feast of the Passover.42 And when He became twelve, they went up there according to the custom of the Feast;43 and as they were returning, after spending the full number of days, the boy Jesus stayed behind in Jerusalem. But His parents were unaware of it,44 but supposed Him to be in the caravan, and went a day's journey; and they began looking for Him among their relatives and acquaintances.45 When they did not find Him, they returned to Jerusalem looking for Him.46 Then, after three days they found Him in the temple, sitting in the midst of the teachers, both listening to them and asking them questions.47 And all who heard Him were amazed at His understanding and His answers.48 When they saw Him, they were astonished; and His mother said to Him, "Son, why have You treated us this way? Behold, Your father and I have been anxiously looking for You."49 And He said to them, "Why is it that you were looking for Me? Did you not know that I had to be in My Father's house?"50 But they did not understand the statement which He had made to them.51 And He went down with them and came to Nazareth, and He continued in subjection to them; and His mother treasured all these things in her heart.
52 And Jesus kept increasing in wisdom and stature, and in favor with God and men.