previous next

Luk 21

Ọrẹ Tí Opó Kan Ṣe

(Mak 12:41-44)

1 NIGBATI o si gbé oju soke, o ri awọn ọlọrọ̀ nfi ẹ̀bun wọn sinu apoti iṣura. 2 O si ri talakà opó kan pẹlu, o nsọ owo-idẹ wẹ́wẹ meji sibẹ. 3 O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, talakà opó yi fi si i jù gbogbo wọn lọ:

4 Nitori gbogbo awọn wọnyi fi sinu ẹ̀bun Ọlọrun lati ọ̀pọlọpọ ini wọn; ṣugbọn on ninu aìni rẹ̀ o sọ gbogbo ohun ini rẹ̀ ti o ni sinu rẹ̀.

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ Pé A Óo Wó Tẹmpili

(Mat 24:1-2; Mak 13:1-2)


5 Bi awọn kan si ti nsọ̀rọ ti tẹmpili, bi a ti fi okuta daradara ati ẹ̀bun ṣe e li ọṣọ, o ní,

6 Ohun ti ẹnyin nwò wọnyi, ọjọ mbọ̀ li eyi ti a kì yio fi okuta kan silẹ lori ekeji ti a kì yio wó lulẹ.

Àwọn Àmì Àkókò Náà

(Mat 24:3-14; Mak 13:3-13)


7 Nwọn si bère lọwọ rẹ̀, wipe, Olukọni, nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? ati àmi kini yio wà, nigbati nkan wọnyi yio fi ṣẹ? 8 O si wipe, Ẹ mã kiyesara, ki a má bà mu nyin ṣina: nitori ọpọlọpọ yio wá li orukọ mi, ti yio mã wipe, Emi ni Kristi; akokò igbana si kù si dẹ̀dẹ: ẹ máṣe tọ̀ wọn lẹhin. 9 Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba gburó ogun ati idagìri, ẹ máṣe foiya: nitori nkan wọnyi ko le ṣe áìkọ́ṣẹ: ṣugbọn opin na kì iṣe lojukanna. 10 Nigbana li o wi fun wọn pe, Orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ède, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: 11 Isẹlẹ nla yio si wà kakiri, ati ìyan ati ajakalẹ arùn; ohun ẹ̀ru, ati àmi nla yio si ti ọrun wá. 12 Ṣugbọn ṣaju gbogbo nkan wọnyi, nwọn o nawọ́ mu nyin, nwọn o si ṣe inunibini si nyin, nwọn o fi nyin le awọn oni-sinagogu lọwọ, ati sinu tubu, nwọn o mu nyin lọ sọdọ awọn ọba ati awọn ijoye nitori orukọ mi. 13 Yio si pada di ẹrí fun nyin. 14 Nitorina ẹ pinnu rẹ̀ li ọkàn nyin pe ẹ kì yio ronu ṣaju, bi ẹ o ti dahun. 15 Nitoriti emi ó fun nyin li ẹnu ati ọgbọ́n, ti gbogbo awọn ọtá nyin kì yio le sọrọ-òdi si, ti nwọn kì yio si le kò loju. 16 A o si fi nyin hàn lati ọdọ awọn õbi nyin wá, ati awọn arakunrin, ati awọn ibatan, ati awọn ọrẹ́ wá; nwọn o si mu ki a pa ninu nyin. 17 A o si korira nyin lọdọ gbogbo enia nitori orukọ mi. 18 Ṣugbọn irun ori nyin kan kì o ṣegbé.

19 Ninu sũru nyin li ẹnyin o jère ọkàn nyin.

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ Pé Ogun Yóo Kó Ìlú Jerusalẹmu

(Mat 24:15-21; Mak 13:14-19)


20 Nigbati ẹnyin ba si ri ti a fi ogun yi Jerusalemu ká, ẹ mọ̀ nigbana pe, isọdahoro rẹ̀ kù si dẹ̀dẹ. 21 Nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea ki o sá lọ sori òke; ati awọn ti mbẹ larin rẹ̀ ki nwọn jade kuro; ki awọn ti o si mbẹ ni igberiko ki o máṣe wọ̀ inu rẹ̀ lọ. 22 Nitori ọjọ ẹsan li ọjọ wọnni, ki a le mu ohun gbogbo ti a ti kọwe rẹ̀ ṣẹ. 23 Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati awọn ti o nfi ọmú fun ọmọ mu ni ijọ wọnni! nitoriti ipọnju pipọ yio wà lori ati ibinu si awọn enia wọnyi.

24 Nwọn o si ti oju idà ṣubu, a o si dì wọn ni igbekun lọ si orilẹ-ède gbogbo: Jerusalemu yio si di itẹmọlẹ li ẹsẹ awọn Keferi, titi akoko awọn Keferi yio fi kún.

Àkókò Tí Ọmọ-Eniyan Yóo Dé

(Mat 24:29-31; Mak 13:24-27)


25 Àmi yio si wà li õrùn, ati li oṣupa, ati ni irawọ; ati lori ilẹ aiye idamu fun awọn orilẹ-ede nitori ipaiya ti ariwo; 26 Aiya awọn enia yio ma já fun ibẹru, ati fun ireti nkan wọnni ti mbọ̀ sori aiye: nitori awọn agbara ọrun li a o mì titi. 27 Nigbana ni nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara ati ogo nla.

28 Ṣugbọn nigbati nkan wọnyi ba bẹ̀rẹ si iṣẹ, njẹ ki ẹ wò òke, ki ẹ si gbé ori nyin soke; nitori idande nyin kù si dẹ̀dẹ.

Ẹ̀kọ́ Tí Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Kọ́ni

(Mat 24:32-35; Mak 13:28-31)


29 O si pa owe kan fun wọn pe; Ẹ kiyesi igi ọpọtọ, ati si gbogbo igi; 30 Nigbati nwọn ba rúwe, ẹnyin ri i, ẹ si mọ̀ fun ara nyin pe, igba ẹ̀run kù fẹfẹ. 31 Gẹgẹ bẹ̃ na li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri nkan wọnyi ti nṣẹ, ki ẹnyin ki o mọ̀ pe, ijọba Ọlọrun kù si dẹ̀dẹ. 32 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Iran yi ki yio rekọja, titi gbogbo nkan wọnyi yio fi ṣẹ.

33 Ọrun on aiye yio rekọja: ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja.

Ẹ Ṣọ́ra


34 Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin, ki ọkàn nyin ki o máṣe kún fun wọ̀bia, ati fun ọti amupara, ati fun aniyan aiye yi, ti ọjọ na yio si fi de ba nyin lojijì bi ikẹkun. 35 Nitori bẹni yio de ba gbogbo awọn ti ngbe ori gbogbo ilẹ aiye. 36 Njẹ ki ẹ mã ṣọna, ki ẹ si mã gbadura nigbagbogbo, ki ẹ ba le là gbogbo nkan wọnyi ti mbọ̀ wá iṣẹ, ki ẹ si le duro niwaju Ọmọ-enia. 37 Lọsán, a si ma kọ́ni ni tẹmpili; loru, a si ma jade lọ iwọ̀ lori òke ti a npè ni oke Olifi. 38 Gbogbo enia si ntọ̀ ọ wá ni tẹmpili ni kutukutu owurọ̀, lati gbọ́rọ rẹ̀.

Luke 21

The Widow's Gift

1 And He looked up and saw the rich putting their gifts into the treasury.2 And He saw a poor widow putting in two small copper coins.3 And He said, "Truly I say to you, this poor widow put in more than all of them;4 for they all out of their surplus put into the offering; but she out of her poverty put in all that she had to live on."

5 And while some were talking about the temple, that it was adorned with beautiful stones and votive gifts, He said,6 "As for these things which you are looking at, the days will come in which there will not be left one stone upon another which will not be torn down."

7 They questioned Him, saying, "Teacher, when therefore will these things happen? And what will be the sign when these things are about to take place?"8 And He said, "See to it that you are not misled; for many will come in My name, saying, 'I am He,' and, 'The time is near.' Do not go after them.9 When you hear of wars and disturbances, do not be terrified; for these things must take place first, but the end does not follow immediately."

Things to Come

10 Then He continued by saying to them, "Nation will rise against nation and kingdom against kingdom,11 and there will be great earthquakes, and in various places plagues and famines; and there will be terrors and great signs from heaven.

12 "But before all these things, they will lay their hands on you and will persecute you, delivering you to the synagogues and prisons, bringing you before kings and governors for My name's sake.13 It will lead to an opportunity for your testimony.14 So make up your minds not to prepare beforehand to defend yourselves;15 for I will give you utterance and wisdom which none of your opponents will be able to resist or refute.16 But you will be betrayed even by parents and brothers and relatives and friends, and they will put some of you to death,17 and you will be hated by all because of My name.18 Yet not a hair of your head will perish.19 By your endurance you will gain your lives.

20 "But when you see Jerusalem surrounded by armies, then recognize that her desolation is near.21 Then those who are in Judea must flee to the mountains, and those who are in the midst of the city must leave, and those who are in the country must not enter the city;22 because these are days of vengeance, so that all things which are written will be fulfilled.23 Woe to those who are pregnant and to those who are nursing babies in those days; for there will be great distress upon the land and wrath to this people;24 and they will fall by the edge of the sword, and will be led captive into all the nations; and Jerusalem will be trampled under foot by the Gentiles until the times of the Gentiles are fulfilled.

The Return of Christ

25 "There will be signs in sun and moon and stars, and on the earth dismay among nations, in perplexity at the roaring of the sea and the waves,26 men fainting from fear and the expectation of the things which are coming upon the world; for the powers of the heavens will be shaken.27 Then they will see THE SON OF MAN COMING IN A CLOUD with power and great glory.28 But when these things begin to take place, straighten up and lift up your heads, because your redemption is drawing near."

29 Then He told them a parable: "Behold the fig tree and all the trees;30 as soon as they put forth leaves, you see it and know for yourselves that summer is now near.31 So you also, when you see these things happening, recognize that the kingdom of God is near.32 Truly I say to you, this generation will not pass away until all things take place.33 Heaven and earth will pass away, but My words will not pass away.

34 "Be on guard, so that your hearts will not be weighted down with dissipation and drunkenness and the worries of life, and that day will not come on you suddenly like a trap;35 for it will come upon all those who dwell on the face of all the earth.36 But keep on the alert at all times, praying that you may have strength to escape all these things that are about to take place, and to stand before the Son of Man."

37 Now during the day He was teaching in the temple, but at evening He would go out and spend the night on the mount that is called Olivet.38 And all the people would get up early in the morning to come to Him in the temple to listen to Him.