Luk 22
Àwọn Juu Dìtẹ̀ láti Pa Jesu
(Mat 26:1-5, 14-16; Mak 14:1-2, 10-11; Joh 11:45-53)
1 AJỌ ọdun aiwukara ti a npè ni Irekọja si kù fẹfẹ. 2 Ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe nwá ọ̀na bi nwọn iba ti ṣe pa a; nitoriti nwọn mbẹ̀ru awọn enia. 3 Satani si wọ̀ inu Judasi, ti a npè ni Iskariotu, ọkan ninu awọn mejila. 4 O si mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n, o lọ lati ba awọn olori alufa ati awọn olori ẹṣọ́ mọ̀ ọ pọ̀, bi on iba ti fi i le wọn lọwọ. 5 Nwọn si yọ̀, nwọn si ba a da majẹmu ati fun u li owo.
6 O si gbà: o si nwá akoko ti o wọ̀, lati fi i le wọn lọwọ laìsi ariwo.Ìpalẹ̀mọ́ fún Àsè Ìrékọjá
(Mat 26:17-25; Mak 14:12-21; Joh 13:21-30)
7 Ọjọ aiwukara pé, nigbati nwọn kò le ṣe aiṣẹbọ irekọja. 8 O si rán Peteru on Johanu, wipe, Ẹ lọ ipèse irekọja fun wa, ki awa ki o jẹ. 9 Nwọn si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a pèse sile? 10 O si wi fun wọn pe, Kiyesi i, nigbati ẹnyin ba nwọ̀ ilu lọ, ọkunrin kan ti o rù iṣa omi yio pade nyin; ẹ ba a lọ si ile ti o ba wọ̀. 11 Ki ẹ si wi fun bãle ile na pe, Olukọni wi fun ọ pe, Nibo ni gbọ̀ngan apejẹ na gbé wà, nibiti emi o gbé jẹ irekọja pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi? 12 On o si fi gbọ̀ngan nla kan loke hàn nyin, ti a ṣe lọṣọ: nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o pèse silẹ.
13 Nwọn si lọ nwọn si bá a gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: nwọn si pèse irekọja silẹ.Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa
(Mat 26:26-30; Mak 14:22-26; 1 Kọr 11:23-25)
14 Nigbati akokò si to, o joko ati awọn aposteli pẹlu rẹ̀. 15 O si wi fun wọn pe, Tinu-tinu li emi fẹ fi ba nyin jẹ irekọja yi, ki emi ki o to jìya: 16 Nitori mo wi fun nyin, Emi kì yio jẹ ninu rẹ̀ mọ́, titi a o fi mú u ṣẹ ni ijọba Ọlọrun. 17 O si gbà ago, nigbati o si ti dupẹ, o wipe, Gbà eyi, ki ẹ si pín i larin ara nyin. 18 Nitori mo wi fun nyin, Emi kì yio mu ninu eso ajara mọ́, titi ijọba Ọlọrun yio fi de. 19 O si mú akara, nigbati o si ti dupẹ o bu u, o si fifun wọn, o wipe, Eyi li ara mi ti a fifun nyin: ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi. 20 Bẹ̃ gẹgẹ lẹhin onjẹ alẹ, o si mu ago, o wipe, Ago yi ni majẹmu titun li ẹ̀jẹ mi, ti a ta silẹ fun nyin. 21 Ṣugbọn ẹ kiyesi i, ọwọ́ ẹniti o fi mi hàn wà pẹlu mi lori tabili. 22 Ọmọ-enia nlọ nitõtọ bi a ti pinnu rẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na nipasẹ ẹniti a gbé ti fi i hàn! 23 Nwọn si bẹ̀rẹ si ibère larin ara wọn, tani ninu wọn ti yio ṣe nkan yi. 24 Ijà kan si mbẹ larin wọn, niti ẹniti a kà si olori ninu wọn. 25 O si wi fun wọn pe, Awọn ọba Keferi a ma fẹla lori wọn: a si ma pè awọn alaṣẹ wọn ni olõre. 26 Ṣugbọn ẹnyin kì yio ri bẹ̃: ṣugbọn ẹniti o ba pọ̀ju ninu nyin ki o jẹ bi aburo; ẹniti o si ṣe olori, bi ẹniti nṣe iranṣẹ. 27 Nitori tali o pọ̀ju, ẹniti o joko tì onjẹ, tabi ẹniti o nṣe iranṣẹ? ẹniti o joko tì onjẹ ha kọ́? ṣugbọn emi mbẹ larin nyin bi ẹniti nṣe iranṣẹ. 28 Ẹnyin li awọn ti o ti duro tì mi ninu idanwo mi. 29 Mo si yàn ijọba fun nyin, gẹgẹ bi Baba mi ti yàn fun mi;
30 Ki ẹnyin ki o le mã jẹ, ki ẹnyin ki o si le mã mu lori tabili mi ni ijọba mi, ki ẹnyin ki o le joko lori itẹ́, ati ki ẹnyin ki o le mã ṣe idajọ fun awọn ẹ̀ya Israeli mejila.Jesu Sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru Yóo Sẹ́ Òun
(Mat 26:31-35; Mak 14:27-31; Joh 13:36-38)
31 Oluwa si wipe, Simoni, Simoni, sawõ, Satani fẹ lati ni ọ, ki o le kù ọ bi alikama: 32 Ṣugbọn mo ti gbadura fun ọ, ki igbagbọ́ rẹ ki o má yẹ̀; ati iwọ nigbati iwọ ba si yipada, mu awọn arakunrin rẹ li ọkàn le. 33 O si wi fun u pe, Oluwa, mo mura tan lati bá ọ lọ sinu tubu, ati si ikú.
34 O si wipe, Mo wi fun ọ, Peteru, akukọ ki yio kọ loni ti iwọ o fi sẹ́ mi li ẹrinmẹta pe, iwọ kò mọ̀ mi.Idà Meji
35 O si wi fun wọn pe, Nigbati mo rán nyin lọ laini asuwọn, ati àpo, ati bàta, ọdá ohun kan da nyin bi? Nwọn si wipe, Rara o. 36 Nigbana li o wi fun wọn pe, Ṣugbọn nisisiyi, ẹniti o ba li asuwọn, ki o mu u, ati àpo pẹlu: ẹniti kò ba si ni idà, ki o tà aṣọ rẹ̀, ki o si fi rà kan. 37 Nitori mo wi fun nyin pe, Eyi ti a ti kọwe rẹ̀ kò le ṣe ki o má ṣẹ lara mi, A si kà a mọ awọn arufin. Nitori ohun wọnni nipa ti emi o li opin.
38 Nwọn si wipe, Oluwa, sawõ, idà meji mbẹ nihinyi. O si wi fun wọn pe, O to.Adura Lórí Òkè Olifi
(Mat 26:36-46; Mak 14:32-42)
39 O si jade, o si lọ bi iṣe rẹ̀ si òke Olifi; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ lẹhin. 40 Nigbati o wà nibẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ sinu idẹwò. 41 O si fi wọn silẹ niwọn isọko kan, o si kunlẹ o si ngbadura, 42 Wipe, Baba, bi iwọ ba fẹ, gbà ago yi lọwọ mi: ṣugbọn ifẹ ti emi kọ́, bikoṣe tirẹ ni ki a ṣe. 43 Angẹli kan si yọ si i lati ọrun wá, o ngbà a ni iyanju. 44 Bi o si ti wà ni iwaya-ija o ngbadura si i kikankikan: õgùn rẹ̀ si dabi iro ẹ̀jẹ nla, o nkán silẹ. 45 Nigbati o si dide kuro ni ibi adura, ti o si tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o ba wọn, nwọn nsùn fun ibanujẹ,
46 O si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nsùn si? ẹ dide, ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ́ sinu idẹwò.Judasi Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá
(Mat 26:47-56; Mak 14:43-50; Joh 18:3-11)
47 Bi o si ti nsọ lọwọ, kiyesi i, ọ̀pọ enia, ati ẹniti a npè ni Judasi, ọkan ninu awọn mejila, o ṣaju wọn o sunmọ Jesu lati fi ẹnu kò o li ẹnu. 48 Jesu si wi fun u pe, Judasi, iwọ fi ifẹnukonu fi Ọmọ-enia hàn? 49 Nigbati awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ ri bi yio ti jasi, nwọn bi i pe, Oluwa, ki awa ki o fi idà ṣá wọn? 50 Ọkan ninu wọn si fi idà ṣá ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke etí ọtún rẹ̀ sọnù. 51 Ṣugbọn Jesu dahùn o wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ bayi na. O si fi ọwọ́ tọ́ ọ li etí, o si wò o sàn. 52 Jesu si wi fun awọn olori alufa, ati awọn olori ẹṣọ́ tẹmpili, ati awọn agbagba, ti nwọn jade tọ̀ ọ wá, pe, Ẹnyin ha jade wá ti ẹnyin ti idà ati ọgọ bi ẹni tọ ọlọṣa wá?
53 Nigbati emi wà pẹlu nyin lojojumọ ni tẹmpili, ẹnyin ko nà ọwọ́ mu mi: ṣugbọn akokò ti nyin li eyi, ati agbara òkunkun.Judasi Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá
(Mat 26:47-56; Mak 14:43-50; Joh 18:3-11)
54 Nwọn si gbá a mu, nwọn si fà a lọ, nwọn si mu u wá si ile olori alufa. Ṣugbọn Peteru tọ̀ ọ lẹhin li òkere. 55 Nigbati nwọn si ti dana larin gbọ̀ngan, ti nwọn si joko pọ̀, Peteru joko larin wọn. 56 Ọmọbinrin kan si ri i bi o ti joko nibi imọlẹ iná na, o si tẹjumọ́ ọ, o ni, Eleyi na wà pẹlu rẹ̀. 57 O si sẹ́, o wipe, Obinrin yi, emi ko mọ̀ ọ. 58 Kò pẹ lẹhin na ẹlomiran si ri i, o ni, Iwọ pẹlu wà ninu wọn. Ṣugbọn Peteru wipe, ọkunrin yi, Emi kọ. 59 O si to iwọn wakati kan ẹlomiran gidigidi tẹnumọ́ ọ, nwipe, Nitõtọ eleyi na wà pẹlu rẹ̀: nitori ara Galili ni iṣe. 60 Ṣugbọn Peteru wipe, ọkunrin yi, emi kò mọ̀ ohun ti iwọ nwi. Lojukanna, bi o ti nwi li ẹnu, akukọ kọ. 61 Oluwa si yipada, o wò Peteru. Peteru si ranti ọ̀rọ Oluwa, bi o ti wi fun u pe, Ki akukọ ki o to kọ, iwọ o sẹ́ mi li ẹrinmẹta.
62 Peteru si bọ si ode, o sọkun kikorò.Wọ́n Fi Jesu Ṣẹ̀sín
(Mat 26:67-68; Mak 14:65)
63 Awọn ọkunrin ti nwọn mu Jesu, si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn lù u. 64 Nigbati nwọn si dì i loju, nwọn lù u niwaju, nwọn mbi i pe, Sọtẹlẹ, tani lù ọ nì?
65 Ati nkan pipọ miran ni nwọn nfi ọ̀rọ-òdi sọ si i.Wọ́n Mú Jesu Lọ Siwaju Ìgbìmọ̀
(Mat 26:59-66; Mak 14:55-64; Joh 18:19-24)
66 Nigbati ilẹ si mọ́, awọn àgba awọn enia, ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe pejọ, nwọn si fà a wá si ajọ wọn, nwọn nwipe, 67 Bi iwọ ba iṣe Kristi na? sọ fun wa. O si wi fun wọn pe, Bi mo ba wi fun nyin, ẹnyin ki yio gbagbọ́: 68 Bi mo ba si bi nyin lẽre pẹlu, ẹnyin kì yio da mi lohùn, bẹ̃li ẹnyin kì yio jọwọ mi lọwọ lọ. 69 Ṣugbọn lati isisiyi lọ li Ọmọ-enia yio joko li ọwọ́ ọtún agbara Ọlọrun. 70 Gbogbo wọn si wipe, Iwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọrun bi? O si wi fun wọn pe, Ẹnyin wipe, emi ni. 71 Nwọn si wipe, Kili awa nfẹ ẹlẹri mọ́ si? Awa tikarawa sá ti gbọ́ li ẹnu ara rẹ̀.
Luke 22
Preparing the Passover
1 Now the Feast of Unleavened Bread, which is called the Passover, was approaching.2 The chief priests and the scribes were seeking how they might put Him to death; for they were afraid of the people.
3 And Satan entered into Judas who was called Iscariot, belonging to the number of the twelve.4 And he went away and discussed with the chief priests and officers how he might betray Him to them.5 They were glad and agreed to give him money.6 So he consented, and began seeking a good opportunity to betray Him to them apart from the crowd.
7 Then came the first day of Unleavened Bread on which the Passover lamb had to be sacrificed.8 And Jesus sent Peter and John, saying, "Go and prepare the Passover for us, so that we may eat it."9 They said to Him, "Where do You want us to prepare it?"10 And He said to them, "When you have entered the city, a man will meet you carrying a pitcher of water; follow him into the house that he enters.11 And you shall say to the owner of the house, 'The Teacher says to you, "Where is the guest room in which I may eat the Passover with My disciples?"'12 And he will show you a large, furnished upper room; prepare it there."13 And they left and found everything just as He had told them; and they prepared the Passover.
The Lord's Supper
14 When the hour had come, He reclined at the table, and the apostles with Him.15 And He said to them, "I have earnestly desired to eat this Passover with you before I suffer;16 for I say to you, I shall never again eat it until it is fulfilled in the kingdom of God."17 And when He had taken a cup and given thanks, He said, "Take this and share it among yourselves;18 for I say to you, I will not drink of the fruit of the vine from now on until the kingdom of God comes."19 And when He had taken some bread and given thanks, He broke it and gave it to them, saying, "This is My body which is given for you; do this in remembrance of Me."20 And in the same way He took the cup after they had eaten, saying, "This cup which is poured out for you is the new covenant in My blood.21 But behold, the hand of the one betraying Me is with Mine on the table.22 For indeed, the Son of Man is going as it has been determined; but woe to that man by whom He is betrayed!"23 And they began to discuss among themselves which one of them it might be who was going to do this thing.
Who Is Greatest
24 And there arose also a dispute among them as to which one of them was regarded to be greatest.25 And He said to them, "The kings of the Gentiles lord it over them; and those who have authority over them are called 'Benefactors.'26 But it is not this way with you, but the one who is the greatest among you must become like the youngest, and the leader like the servant.27 For who is greater, the one who reclines at the table or the one who serves? Is it not the one who reclines at the table? But I am among you as the one who serves.
28 "You are those who have stood by Me in My trials;29 and just as My Father has granted Me a kingdom, I grant you30 that you may eat and drink at My table in My kingdom, and you will sit on thrones judging the twelve tribes of Israel.
31 "Simon, Simon, behold, Satan has demanded permission to sift you like wheat;32 but I have prayed for you, that your faith may not fail; and you, when once you have turned again, strengthen your brothers."33 But he said to Him, "Lord, with You I am ready to go both to prison and to death!"34 And He said, "I say to you, Peter, the rooster will not crow today until you have denied three times that you know Me."
35 And He said to them, "When I sent you out without money belt and bag and sandals, you did not lack anything, did you?" They said, " No, nothing."36 And He said to them, "But now, whoever has a money belt is to take it along, likewise also a bag, and whoever has no sword is to sell his coat and buy one.37 For I tell you that this which is written must be fulfilled in Me, 'AND HE WAS NUMBERED WITH TRANSGRESSORS'; for that which refers to Me has its fulfillment."38 They said, "Lord, look, here are two swords." And He said to them, "It is enough."
The Garden of Gethsemane
39 And He came out and proceeded as was His custom to the Mount of Olives; and the disciples also followed Him.40 When He arrived at the place, He said to them, "Pray that you may not enter into temptation."41 And He withdrew from them about a stone's throw, and He knelt down and began to pray,42 saying, "Father, if You are willing, remove this cup from Me; yet not My will, but Yours be done."43 Now an angel from heaven appeared to Him, strengthening Him.44 And being in agony He was praying very fervently; and His sweat became like drops of blood, falling down upon the ground.45 When He rose from prayer, He came to the disciples and found them sleeping from sorrow,46 and said to them, "Why are you sleeping? Get up and pray that you may not enter into temptation."
Jesus Betrayed by Judas
47 While He was still speaking, behold, a crowd came, and the one called Judas, one of the twelve, was preceding them; and he approached Jesus to kiss Him.48 But Jesus said to him, "Judas, are you betraying the Son of Man with a kiss?"49 When those who were around Him saw what was going to happen, they said, "Lord, shall we strike with the sword?"50 And one of them struck the slave of the high priest and cut off his right ear.51 But Jesus answered and said, "Stop! No more of this." And He touched his ear and healed him.52 Then Jesus said to the chief priests and officers of the temple and elders who had come against Him, "Have you come out with swords and clubs as you would against a robber?53 While I was with you daily in the temple, you did not lay hands on Me; but this hour and the power of darkness are yours."
Jesus' Arrest
54 Having arrested Him, they led Him away and brought Him to the house of the high priest; but Peter was following at a distance.55 After they had kindled a fire in the middle of the courtyard and had sat down together, Peter was sitting among them.56 And a servant-girl, seeing him as he sat in the firelight and looking intently at him, said, "This man was with Him too."57 But he denied it, saying, "Woman, I do not know Him."58 A little later, another saw him and said, "You are one of them too!" But Peter said, "Man, I am not!"59 After about an hour had passed, another man began to insist, saying, "Certainly this man also was with Him, for he is a Galilean too."60 But Peter said, "Man, I do not know what you are talking about." Immediately, while he was still speaking, a rooster crowed.61 The Lord turned and looked at Peter. And Peter remembered the word of the Lord, how He had told him, "Before a rooster crows today, you will deny Me three times."62 And he went out and wept bitterly.
63 Now the men who were holding Jesus in custody were mocking Him and beating Him,64 and they blindfolded Him and were asking Him, saying, "Prophesy, who is the one who hit You?"65 And they were saying many other things against Him, blaspheming.
Jesus before the Sanhedrin
66 When it was day, the tCouncil of elders of the people assembled, both chief priests and scribes, and they led Him away to their council chamber, saying,67 "If You are the Christ, tell us." But He said to them, "If I tell you, you will not believe;68 and if I ask a question, you will not answer.69 But from now on THE SON OF MAN WILL BE SEATED AT THE RIGHT HAND of the power OF GOD."70 And they all said, "Are You the Son of God, then?" And He said to them, "Yes, I am."71 Then they said, "What further need do we have of testimony? For we have heard it ourselves from His own mouth."