previous next

Luk 23

Wọ́n Fa Jesu Lọ Siwaju Pilatu

(Mat 27:1-2, 11-14; Mak 15:1-5; Joh 18:28-38)

1 GBOGBO ijọ enia si dide, nwọn si fà a lọ si ọdọ Pilatu. 2 Nwọn si bẹ̀rẹ si ifi i sùn, wipe, Awa ri ọkunrin yi o nyi orilẹ-ede wa li ọkàn pada, o si nda wọn lẹkun lati san owode fun Kesari, o nwipe on tikara-on ni Kristi ọba. 3 Pilatu si bi i lẽre, wipe, Iwọ ha li ọba awọn Ju? O si da a lohùn wipe, Iwọ wi i. 4 Pilatu si wi fun awọn olori alufa ati fun ijọ enia pe, Emi kò ri ẹ̀ṣẹ lọwọ ọkunrin yi. 5 Nwọn si tubọ tẹnumọ ọ pe, O nrú awọn enia soke, o nkọ́ni ká gbogbo Judea, o bẹ̀rẹ lati Galili wá titi o fi de ihinyi. 6 Nigbati Pilatu gbọ́ orukọ Galili, o bère bi ọkunrin na iṣe ara Galili. 7 Nigbati o si mọ̀ pe ara ilẹ Herodu ni, o rán a si Herodu, ẹniti on tikararẹ̀ wà ni Jerusalemu li akokò na. 8 Nigbati Herodu si ri Jesu, o yọ̀ gidigidi: nitoriti o ti nfẹ ẹ ri pẹ́, o sa ti ngbọ́ ìhin pipọ nitori rẹ̀; o si tanmọ̃ ati ri ki iṣẹ iyanu diẹ ki o ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe. 9 O si bère ọ̀rọ pipọ lọwọ rẹ̀; ṣugbọn kò da a lohùn kanṣoṣo. 10 Ati awọn olori alufa ati awọn akọwe duro, nwọn si nfi i sùn gidigidi. 11 Ati Herodu ti on ti awọn ọmọ-ogun rẹ̀, nwọn kẹgan rẹ̀, nwọn si nfi i ṣẹsin, nwọn wọ̀ ọ li aṣọ daradara, o si rán a pada tọ̀ Pilatu lọ.

12 Pilatu on Herodu di ọrẹ́ ara wọn ni ijọ na: nitori latijọ ọtá ara wọn ni nwọn ti nṣe ri.

A Dá Jesu Lẹ́bi Ikú

(Mat 27:15-26; Mak 15:5-15; Joh 18:39—19:16)


13 Nigbati Pilatu si ti pè awọn olori alufa ati awọn olori ati awọn enia jọ, 14 O sọ fun wọn pe, Ẹnyin mu ọkunrin yi tọ̀ mi wá, bi ẹni ti o npa awọn enia li ọkàn dà: si kiyesi i, emi wadi ẹjọ rẹ̀ niwaju nyin, emi kò si ri ẹ̀ṣẹ lọwọ ọkunrin yi, ni gbogbo nkan wọnyi ti ẹnyin fi i sùn si: 15 Ati Herodu pẹlu: o sá rán a pada tọ̀ wa wá; si kiyesi i, ohun kan ti o yẹ si ikú a ko ṣe si i ti ọwọ́ rẹ̀ wá. 16 Njẹ emi ó nà a, emi ó si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ. 17 Ṣugbọn kò le ṣe aidá ọkan silẹ fun wọn nigba ajọ irekọja. 18 Nwọn si kigbe soke lọwọ kanna, wipe, Mu ọkunrin yi kuro, ki o si dá Barabba silẹ fun wa: 19 Ẹniti a sọ sinu tubu nitori ọ̀tẹ kan ti a ṣe ni ilu, ati nitori ipania. 20 Pilatu si tun ba wọn sọrọ, nitori o fẹ da Jesu silẹ. 21 Ṣugbọn nwọn kigbe, wipe, Kàn a mọ agbelebu, kàn a mọ agbelebu. 22 O si wi fun wọn li ẹrinkẹta pe, Ẽṣe, buburu kili ọkunrin yi ṣe? emi ko ri ọ̀ran ikú lara rẹ̀: nitorina emi o nà a, emi a si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ. 23 Nwọn tilẹ̀ kirimọ́ igbe nla, nwọn nfẹ ki a kàn a mọ agbelebu. Ohùn ti wọn ati ti awọn olori alufa bori tirẹ̀. 24 Pilatu si fi aṣẹ si i pe, ki o ri bi nwọn ti nfẹ.

25 O si dá ẹniti nwọn fẹ silẹ fun wọn, ẹniti a titori ọ̀tẹ ati ipania sọ sinu tubu; ṣugbọn o fi Jesu le wọn lọwọ.

A Kan Jesu Mọ́ Agbelebu

(Mat 27:32-44; Mak 15:21-32; Joh 19:17-27)


26 Bi nwọn si ti nfà a lọ, nwọn mu ọkunrin kan, Simoni ara Kirene, ti o nti igberiko bọ̀, on ni nwọn si gbé agbelebu na le, ki o mã rù u bọ̀ tẹle Jesu. 27 Ijọ enia pipọ li o ntọ̀ ọ lẹhin, ati awọn obinrin, ti npohùnrere ẹkún, ti nwọn si nṣe idarò rẹ̀. 28 Ṣugbọn Jesu yiju pada si wọn, o si wipe, Ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ẹ má sọkun fun mi, ṣugbọn ẹ sọkun fun ara nyin, ati fun awọn ọmọ nyin. 29 Nitori kiyesi i, ọjọ mbọ̀ li eyiti ẹnyin o wipe, Ibukun ni fun àgan, ati fun inu ti kò bímọ ri, ati fun ọmú ti kò funni mu ri. 30 Nigbana ni nwọn o bẹ̀rẹ si iwi fun awọn òke nla pe, Wó lù wa; ati fun awọn òke kekeke pe, Bò wa mọlẹ. 31 Nitori bi nwọn ba nṣe nkan wọnyi sara igi tutù, kili a o ṣe sara gbigbẹ? 32 Nwọn si fà awọn meji lọ pẹlu, awọn arufin, lati pa pẹlu rẹ̀. 33 Nigbati nwọn si de ibi ti a npè ni Agbari, nibẹ̀ ni nwọn gbé kàn a mọ agbelebu, ati awọn arufin na, ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ọkan li ọwọ́ òsi. 34 Jesu si wipe, Baba, darijì wọn; nitoriti nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn nṣe. Nwọn si pín aṣọ rẹ̀ lãrin ara wọn, nwọn di ìbo rẹ̀. 35 Awọn enia si duro nworan. Ati awọn ijoye pẹlu wọn, nwọn nyọ-ṣùti si i, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; ki o gbà ara rẹ̀ là, bi iba ṣe Kristi, ayanfẹ Ọlọrun. 36 Ati awọn ọmọ-ogun pẹlu nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn tọ̀ ọ wá, nwọn nfi ọti kikan fun u, 37 Nwọn si nwipe, Bi iwọ ba ṣe Ọba awọn Ju, gbà ara rẹ là. 38 Nwọn si kọwe akọlé si ìgbèri rẹ̀ ni ède Hellene, ati ti Latini, ati ti Heberu, EYI LI ỌBA AWỌN JU. 39 Ati ọkan ninu awọn arufin ti a gbe kọ́ nfi ṣe ẹlẹyà wipe, Bi iwọ ba ṣe Kristi, gbà ara rẹ ati awa là. 40 Ṣugbọn eyi ekeji dahùn, o mba a wipe, Iwọ kò bẹ̀ru Ọlọrun, ti iwọ wà ninu ẹbi kanna? 41 Niti wa, nwọn jare nitori ère ohun ti a ṣe li awa njẹ: ṣugbọn ọkunrin yi kò ṣe ohun buburu kan. 42 O si wipe, Jesu, ranti mi nigbati iwọ ba de ijọba rẹ.

43 Jesu si wi fun u pe, Lõtọ ni mo wi fun ọ, Loni ni iwọ o wà pẹlu mi ni Paradise.

Ikú Jesu

(Mat 27:45-56; Mak 15:33-41; Joh 19:28-30)


44 O si to ìwọn wakati kẹfa ọjọ, òkunkun si ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan ọjọ. 45 Õrùn si ṣú õkun, aṣọ ikele ti tẹmpili si ya li agbedemeji. 46 Nigbati Jesu si kigbe li ohùn rara, o ni, Baba, li ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹmí mi le: nigbati o si wi eyi tan, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ. 47 Nigbati balogun ọrún ri ohun ti o ṣe, o yìn Ọlọrun logo, wipe, Dajudaju olododo li ọkunrin yi. 48 Gbogbo ijọ enia ti o pejọ si iran yi, nigbati nwọn nwò ohun ti nṣe, nwọn a lù ara wọn li õkan àiya, nwọn a si pada.

49 Ati gbogbo awọn ojulumọ̀ rẹ̀, ati awọn obinrin ti ntọ̀ ọ lẹhin lati Galili wá, nwọn duro li òkere, nwọn nwò nkan wọnyi.

Ìsìnkú Jesu

(Mat 27:57-61; Mak 15:42-47; Joh 19:38-42)


50 Si kiyesi i, ọkunrin kan ti a npè ni Josefu, ìgbimọ, enia rere, ati olõtọ, 51 (On kò ba wọn li ohùn ni ìmọ ati iṣe wọn), ara Arimatea, ilu awọn Ju kan, ẹniti on pẹlu nreti ijọba Ọlọrun; 52 Ọkunrin yi tọ̀ Pilatu lọ, o si tọrọ okú Jesu. 53 Nigbati o si sọ̀ ọ kalẹ, o si fi aṣọ àla dì i, o si tẹ́ ẹ sinu ibojì ti a gbẹ́ ninu okuta, nibiti a kò ti itẹ́ ẹnikẹni si ri. 54 O si ṣe ọjọ Ipalẹmọ: ọjọ isimi si kù si dẹ̀dẹ. 55 Ati awọn obinrin, ti nwọn bá a ti Galili wá, ti nwọn si tẹle, nwọn kiyesi ibojì na, ati bi a ti tẹ́ okú rẹ̀ si. 56 Nigbati nwọn si pada, nwọn pèse ohun olõrun didùn ororo ikunra ati turari tutù; nwọn si simi li ọjọ isimi gẹgẹ bi ofin.

Luke 23

Jesus before Pilate

1 Then the whole body of them got up and brought Him before Pilate.2 And they began to accuse Him, saying, "We found this man misleading our nation and forbidding to pay taxes to Caesar, and saying that He Himself is Christ, a King."3 So Pilate asked Him, saying, "Are You the King of the Jews?" And He answered him and said, "It is as you say."4 Then Pilate said to the chief priests and the crowds, "I find no guilt in this man."5 But they kept on insisting, saying, "He stirs up the people, teaching all over Judea, starting from Galilee even as far as this place."

6 When Pilate heard it, he asked whether the man was a Galilean.7 And when he learned that He belonged to Herod's jurisdiction, he sent Him to Herod, who himself also was in Jerusalem at that time.

Jesus before Herod

8 Now Herod was very glad when he saw Jesus; for he had wanted to see Him for a long time, because he had been hearing about Him and was hoping to see some sign performed by Him.9 And he questioned Him at some length; but He answered him nothing.10 And the chief priests and the scribes were standing there, accusing Him vehemently.11 And Herod with his soldiers, after treating Him with contempt and mocking Him, dressed Him in a gorgeous robe and sent Him back to Pilate.12 Now Herod and Pilate became friends with one another that very day; for before they had been enemies with each other.

Pilate Seeks Jesus' Release

13 Pilate summoned the chief priests and the rulers and the people,14 and said to them, "You brought this man to me as one who incites the people to rebellion, and behold, having examined Him before you, I have found no guilt in this man regarding the charges which you make against Him.15 No, nor has Herod, for he sent Him back to us; and behold, nothing deserving death has been done by Him.16 Therefore I will punish Him and release Him."17 [tNow he was obliged to release to them at the feast one prisoner.]

18 But they cried out all together, saying, "Away with this man, and release for us Barabbas!"19 (He was one who had been thrown into prison for an insurrection made in the city, and for murder.)20 Pilate, wanting to release Jesus, addressed them again,21 but they kept on calling out, saying, "Crucify, crucify Him!"22 And he said to them the third time, "Why, what evil has this man done? I have found in Him no guilt demanding death; therefore I will punish Him and release Him."23 But they were insistent, with loud voices asking that He be crucified. And their voices began to prevail.24 And Pilate pronounced sentence that their demand be granted.25 And he released the man they were asking for who had been thrown into prison for insurrection and murder, but he delivered Jesus to their will.

Simon Bears the Cross

26 When they led Him away, they seized a man, Simon of Cyrene, coming in from the country, and placed on him the cross to carry behind Jesus.

27 And following Him was a large crowd of the people, and of women who were mourning and lamenting Him.28 But Jesus turning to them said, "Daughters of Jerusalem, stop weeping for Me, but weep for yourselves and for your children.29 For behold, the days are coming when they will say, 'Blessed are the barren, and the wombs that never bore, and the breasts that never nursed.'30 Then they will begin TO SAY TO THE MOUNTAINS, 'FALL ON US,' AND TO THE HILLS, 'COVER US.'31 For if they do these things when the tree is green, what will happen when it is dry?"

32 Two others also, who were criminals, were being led away to be put to death with Him.

The Crucifixion

33 When they came to the place called The Skull, there they crucified Him and the criminals, one on the right and the other on the left.34 But Jesus was saying, "Father, forgive them; for they do not know what they are doing." And they cast lots, dividing up His garments among themselves.35 And the people stood by, looking on. And even the rulers were sneering at Him, saying, "He saved others; let Him save Himself if this is the Christ of God, His Chosen One."36 The soldiers also mocked Him, coming up to Him, offering Him sour wine,37 and saying, "If You are the King of the Jews, save Yourself!"38 Now there was also an inscription above Him, "THIS IS THE KING OF THE JEWS."

39 One of the criminals who were hanged there was hurling abuse at Him, saying, "Are You not the Christ? Save Yourself and us!"40 But the other answered, and rebuking him said, "Do you not even fear God, since you are under the same sentence of condemnation?41 And we indeed are suffering justly, for we are receiving what we deserve for our deeds; but this man has done nothing wrong."42 And he was saying, "Jesus, remember me when You come in Your kingdom!"43 And He said to him, "Truly I say to you, today you shall be with Me in Paradise."

44 It was now about tthe sixth hour, and darkness fell over the whole land until tthe ninth hour,45 because the sun was obscured; and the veil of the temple was torn in two.46 And Jesus, crying out with a loud voice, said, "Father, INTO YOUR HANDS I COMMIT MY SPIRIT." Having said this, He breathed His last.47 Now when the centurion saw what had happened, he began praising God, saying, "Certainly this man was innocent."48 And all the crowds who came together for this spectacle, when they observed what had happened, began to return, beating their breasts.49 And all His acquaintances and the women who accompanied Him from Galilee were standing at a distance, seeing these things.

Jesus Is Buried

50 And a man named Joseph, who was a member of the Council, a good and righteous man51 (he had not consented to their plan and action), a man from Arimathea, a city of the Jews, who was waiting for the kingdom of God;52 this man went to Pilate and asked for the body of Jesus.53 And he took it down and wrapped it in a linen cloth, and laid Him in a tomb cut into the rock, where no one had ever lain.54 It was the preparation day, and the Sabbath was about to begin.55 Now the women who had come with Him out of Galilee followed, and saw the tomb and how His body was laid.

56 Then they returned and prepared spices and perfumes.
And on the Sabbath they rested according to the commandment.