Luk 6
Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Jesu Ń Já Ọkà Ní Ọjọ́ Ìsinmi
(Mat 12:1-8; Mak 2:23-28)
1 O si ṣe li ọjọ isimi keji lẹhin ekini, Jesu kọja larin oko ọkà; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si nya ipẹ́ ọkà, nwọn nfi ọwọ́ ra a jẹ. 2 Awọn kan ninu awọn Farisi si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe eyi ti kò yẹ lati ṣe li ọjọ isimi? 3 Jesu si da wọn li ohùn, wipe, Ẹnyin kò kawe to bi eyi, bi Dafidi ti ṣe, nigbati ebi npa on tikararẹ̀ ati awọn ti o wà lọdọ rẹ̀; 4 Bi o ti wọ̀ ile Ọlọrun lọ, ti o si mu akara ifihàn ti o jẹ, ti o si fifun awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pẹlu; ti kò yẹ fun u lati jẹ, bikoṣe fun awọn alufa nikanṣoṣo?
5 O si wi fun wọn pe, Ọmọ-enia li oluwa ọjọ isimi.Ọkunrin Tí Ọwọ́ Rẹ̀ Rọ
(Mat 12:9-14; Mak 3:1-6)
6 O si ṣe li ọjọ isimi miran, ti o wọ̀ inu sinagogu lọ, o si nkọ́ni: ọkunrin kan si mbẹ nibẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ọtún rọ. 7 Ati awọn akọwe ati awọn Farisi nṣọ ọ, bi yio mu u larada li ọjọ isimi; ki nwọn ki o le ri ọna ati fi i sùn. 8 Ṣugbọn o mọ̀ ìro inu wọn, o si wi fun ọkunrin na ti ọwọ́ rẹ̀ rọ pe, Dide, ki o si duro lãrin. O si dide duro. 9 Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Emi o bi nyin lẽre ohunkan; O tọ́ lati mã ṣe ore li ọjọ isimi, tabi lati mã ṣe buburu? lati gbà ẹmí là, tabi lati pa a run? 10 Nigbati o si wò gbogbo wọn yiká, o wi fun ọkunrin na pe, Nà ọwọ́ rẹ. O si ṣe bẹ̃: ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò gẹgẹ bi ekeji.
11 Nwọn si kún fun ibinu gbigbona; nwọn si ba ara wọn rò ohun ti awọn iba ṣe si Jesu.Jesu Yan Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Mejila
(Mat 10:1-4; Mak 3:13-19)
12 O si ṣe ni ijọ wọnni, o lọ si ori òke lọ igbadura, o si fi gbogbo oru na gbadura si Ọlọrun. 13 Nigbati ilẹ si mọ́, o pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: ninu wọn li o si yàn mejila, ti o si sọ ni Aposteli; 14 Simoni, (ẹniti o si sọ ni Peteru,) ati Anderu arakunrin rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, Filippi ati Bartolomeu, 15 Matiu ati Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Simoni ti a npè ni Selote,
16 Ati Juda arakunrin Jakọbu, ati Judasi Iskariotu ti iṣe onikupani.Jesu Wo Ọ̀pọ̀ Eniyan Sàn
(Mat 4:23-25)
17 O si ba wọn sọkalẹ, o si duro ni pẹ̀tẹlẹ, pẹlu ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati ọ̀pọ ijọ enia, lati gbogbo Judea, ati Jerusalemu, ati àgbegbe Tire on Sidoni, ti nwọn wá lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, ati lati gbà dida ara kuro ninu arùn wọn; 18 Ati awọn ti ara kan fun ẹmi aimọ́: a si mu wọn larada.
19 Gbogbo ijọ enia si nfẹ fi ọwọ́ kàn a; nitoriti aṣẹ njade lara rẹ̀, o si mu gbogbo wọn larada.Ìre ati Ègún
(Mat 5:1-12)
20 Nigbati o si gbé oju rẹ̀ soke si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o ni, Alabukun-fun li ẹnyin òtoṣi: nitori ti nyin ni ijọba Ọlọrun. 21 Alabukun-fun li ẹnyin ti ebi npa nisisiyi: nitoriti ẹ ó yo. Alabukun-fun li ẹnyin ti nsọkun nisisiyi: nitoriti ẹnyin ó rẹrin. 22 Alabukun-fun li ẹnyin, nigbati awọn enia ba korira nyin, ti nwọn ba yà nyin kuro ninu ẹgbẹ wọn, ti nwọn ba gàn nyin, ti nwọn ba ta orukọ nyin nù bi ohun buburu, nitori Ọmọ-enia. 23 Ki ẹnyin ki o yọ̀ ni ijọ na, ki ẹnyin ki o si fò soke fun ayọ̀: sá wò o, ère nyin pọ̀ li ọrun: nitori bẹ̃ gẹgẹ li awọn baba wọn ṣe si awọn woli. 24 Ṣugbọn egbé ni fun ẹnyin ọlọrọ̀! nitoriti ẹnyin ti ri irọra nyin na. 25 Egbé ni fun ẹnyin ti o yó! nitoriti ebi yio pa nyin. Egbé ni fun ẹnyin ti nrẹrin nisisiyi! nitoriti ẹnyin o gbàwẹ, ẹnyin o si sọkun.
26 Egbé ni fun nyin, nigbati gbogbo enia ba nsọrọ nyin ni rere! nitori bẹ̃ gẹgẹ li awọn baba wọn ṣe si awọn eke woli.Ẹ Fẹ́ràn Àwọn Ọ̀tá Yín
(Mat 5:38-48; 7:12a)
27 Ṣugbọn mo wi fun ẹnyin ti ngbọ́, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ṣore fun awọn ti o korira nyin. 28 Sure fun awọn ti nfi nyin ré, si gbadura fun awọn ti nkẹgan nyin. 29 Ẹniti o ba si lù ọ ni ẹrẹkẹ kan, pa ekeji dà si i pẹlu; ati ẹniti o gbà agbada rẹ, máṣe da a duro lati gbà àwọtẹlẹ rẹ pẹlu. 30 Si fifun gbogbo ẹniti o tọrọ lọdọ rẹ; lọdọ ẹniti o si kó ọ li ẹrù, má si ṣe pada bère. 31 Gẹgẹ bi ẹnyin si ti fẹ ki enia ki o ṣe si nyin, ki ẹnyin ki o si ṣe bẹ̃ si wọn pẹlu. 32 Njẹ bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nfẹ́ awọn ti o fẹ wọn. 33 Bi ẹnyin si ṣore fun awọn ti o ṣore fun nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nṣe bẹ̃ gẹgẹ. 34 Bi ẹnyin si win wọn ni nkan lọwọ ẹniti ẹnyin ó reti ati ri gbà pada, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nwin ẹlẹṣẹ, ki nwọn ki o le gbà iwọn bẹ̃ pada. 35 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o fẹ awọn ọtá nyin, ki ẹnyin ki o si ṣore, ki ẹnyin ki o si winni, ki ẹnyin ki o máṣe reti ati ri nkan gbà pada; ère nyin yio si pọ̀, awọn ọmọ Ọgá-ogo li a o si ma pè nyin: nitoriti o ṣeun fun alaimore ati fun ẹni-buburu.
36 Njẹ ki ẹnyin ki o li ãnu, gẹgẹ bi Baba nyin si ti li ãnu.Ọ̀rọ̀ Nípa Ṣíṣe Ìdájọ́
(Mat 7:1-5)
37 Ẹ máṣe dani li ẹjọ, a kì yio si da nyin li ẹjọ: ẹ máṣe dani li ẹbi, a kì yio si da nyin li ẹbi: ẹ darijì, a o si darijì nyin: 38 Ẹ fifun ni, a o si fifun nyin; oṣuwọn daradara, akìmọlẹ, ati amipọ, akún-wọsilẹ, li a o wọ̀n si àiya nyin; nitori oṣuwọn na ti ẹnyin fi wọ̀n, on li a o pada fi wọ̀n fun nyin. 39 O si pa owe kan fun wọn, Afọju le ṣe amọ̀na afọju? awọn mejeji kì yio ṣubu sinu ihò? 40 Ẹniti a nkọ́ ki ijù olukọ́ rẹ̀ lọ: ṣugbọn olukuluku ẹniti o ba pé, yio dabi olukọ́ rẹ̀. 41 Ẽṣe ti iwọ si nwò ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ, ṣugbọn iwọ kò kiyesi ìti igi ti mbẹ li oju ara rẹ?
42 Tabi iwọ o ti ṣe le wi fun arakunrin rẹ pe, Arakunrin, jẹ ki emi ki o yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju rẹ, nigbati iwọ tikararẹ kò kiyesi ìti igi ti mbẹ li oju ara rẹ? iwọ agabagebe, tètekọ yọ ìti igi jade kuro li oju ara rẹ na, nigbana ni iwọ o si to riran gbangba lati yọ ẹrún igi kuro ti mbẹ li oju arakunrin rẹ.Igi ati Èso Rẹ̀
(Mat 7:16-20; 12:33-35)
43 Nitori igi rere kì iso eso buburu; bẹ̃ni igi buburu kì iso eso rere. 44 Olukuluku igi li a ifi eso rẹ̀ mọ̀; nitori lori ẹgún oṣuṣu, enia kì iká eso ọpọtọ bẹ̃ni lori ẹgún ọgàn a kì iká eso ajara.
45 Enia rere lati inu iṣura rere ọkàn rẹ̀ ni imu ohun rere jade wá; ati enia buburu lati inu iṣura buburu ọkàn rẹ̀ ni imu ohun buburu jade wá: nitori lati ọ̀pọlọpọ ohun ọkàn li ẹnu rẹ̀ isọ.Ìpìlẹ̀ Meji
(Mat 7:24-27)
46 Ẽsitiṣe ti ẹnyin npè mi li Oluwa, Oluwa, ti ẹnyin kò si ṣe ohun ti mo wi? 47 Ẹnikẹni ti o tọ̀ mi wá, ti o si ngbọ́ ọ̀rọ mi, ti o si nṣe e, emi o fi ẹniti o jọ hàn nyin: 48 O jọ ọkunrin kan ti o kọ́ ile, ti o si walẹ jìn, ti o si fi ipilẹ sọlẹ lori apata: nigbati kíkun omi de, igbi-omi bilù ile na, kò si le mì i: nitoriti a fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ lori apata. 49 Ṣugbọn ẹniti o gbọ́, ti kò si ṣe, o dabi ọkunrin ti o kọ́ ile si ori ilẹ laini ipilẹ; nigbati igbi-omi bilù u, lọgan o si wó; iwó ile na si pọ̀.
Luke 6
Jesus Is Lord of the Sabbath
1 Now it happened that He was passing through some grainfields on a Sabbath; and His disciples were picking the heads of grain, rubbing them in their hands, and eating the grain. 2 But some of the Pharisees said, "Why do you do what is not lawful on the Sabbath?"3 And Jesus answering them said, "Have you not even read what David did when he was hungry, he and those who were with him,4 how he entered the house of God, and took and ate the tconsecrated bread which is not lawful for any to eat except the priests alone, and gave it to his companions?"5 And He was saying to them, "The Son of Man is Lord of the Sabbath."
6 On another Sabbath He entered the synagogue and was teaching; and there was a man there whose right hand was withered.7 The scribes and the Pharisees were watching Him closely to see if He healed on the Sabbath, so that they might find reason to accuse Him.8 But He knew what they were thinking, and He said to the man with the withered hand, "Get up and come forward!" And he got up and came forward.9 And Jesus said to them, "I ask you, is it lawful to do good or to do harm on the Sabbath, to save a life or to destroy it?"10 After looking around at them all, He said to him, "Stretch out your hand!" And he did so; and his hand was restored.11 But they themselves were filled with rage, and discussed together what they might do to Jesus.
Choosing the Twelve
12 It was at this time that He went off to the mountain to pray, and He spent the whole night in prayer to God.13 And when day came, He called His disciples to Him and chose twelve of them, whom He also named as apostles:14 Simon, whom He also named Peter, and Andrew his brother; and James and John; and Philip and Bartholomew;15 and Matthew and Thomas; James the son of Alphaeus, and Simon who was called the Zealot;16 Judas the son of James, and Judas Iscariot, who became a traitor.
17 Jesus came down with them and stood on a level place; and there was a large crowd of His disciples, and a great throng of people from all Judea and Jerusalem and the coastal region of Tyre and Sidon,18 who had come to hear Him and to be healed of their diseases; and those who were troubled with unclean spirits were being cured.19 And all the people were trying to touch Him, for power was coming from Him and healing them all.
The Beatitudes
20 And turning His gaze toward His disciples, He began to say, "Blessed are you who are poor, for yours is the kingdom of God.21 Blessed are you who hunger now, for you shall be satisfied. Blessed are you who weep now, for you shall laugh.22 Blessed are you when men hate you, and ostracize you, and insult you, and scorn your name as evil, for the sake of the Son of Man.23 Be glad in that day and leap for joy, for behold, your reward is great in heaven. For in the same way their fathers used to treat the prophets.24 But woe to you who are rich, for you are receiving your comfort in full.25 Woe to you who are well-fed now, for you shall be hungry. Woe to you who laugh now, for you shall mourn and weep.26 Woe to you when all men speak well of you, for their fathers used to treat the false prophets in the same way.
27 "But I say to you who hear, love your enemies, do good to those who hate you,28 bless those who curse you, pray for those who mistreat you.29 Whoever hits you on the cheek, offer him the other also; and whoever takes away your coat, do not withhold your shirt from him either.30 Give to everyone who asks of you, and whoever takes away what is yours, do not demand it back.31 Treat others the same way you want them to treat you.32 If you love those who love you, what credit is that to you? For even sinners love those who love them.33 If you do good to those who do good to you, what credit is that to you? For even sinners do the same.34 If you lend to those from whom you expect to receive, what credit is that to you? Even sinners lend to sinners in order to receive back the same amount.35 But love your enemies, and do good, and lend, expecting nothing in return; and your reward will be great, and you will be sons of the Most High; for He Himself is kind to ungrateful and evil men.36 Be merciful, just as your Father is merciful.
37 "Do not judge, and you will not be judged; and do not condemn, and you will not be condemned; pardon, and you will be pardoned.38 Give, and it will be given to you. They will pour into your lap a good measure-pressed down, shaken together, and running over. For by your standard of measure it will be measured to you in return."
39 And He also spoke a parable to them: "A blind man cannot guide a blind man, can he? Will they not both fall into a pit?40 A pupil is not above his teacher; but everyone, after he has been fully trained, will be like his teacher.41 Why do you look at the speck that is in your brother's eye, but do not notice the log that is in your own eye?42 Or how can you say to your brother, 'Brother, let me take out the speck that is in your eye,' when you yourself do not see the log that is in your own eye? You hypocrite, first take the log out of your own eye, and then you will see clearly to take out the speck that is in your brother's eye.43 For there is no good tree which produces bad fruit, nor, on the other hand, a bad tree which produces good fruit.44 For each tree is known by its own fruit. For men do not gather figs from thorns, nor do they pick grapes from a briar bush.45 The good man out of the good treasure of his heart brings forth what is good; and the evil man out of the evil treasure brings forth what is evil; for his mouth speaks from that which fills his heart.
Builders and Foundations
46 "Why do you call Me, 'Lord, Lord,' and do not do what I say?47 Everyone who comes to Me and hears My words and acts on them, I will show you whom he is like:48 he is like a man building a house, who dug deep and laid a foundation on the rock; and when a flood occurred, the torrent burst against that house and could not shake it, because it had been well built.49 But the one who has heard and has not acted accordingly, is like a man who built a house on the ground without any foundation; and the torrent burst against it and immediately it collapsed, and the ruin of that house was great."