Luk 8
Àwọn Obinrin Tí Wọn Ń Ran Jesu Lọ́wọ́
1 O si ṣe lẹhinna, ti o nlà gbogbo ilu ati iletò lọ, o nwasu, o nrò ìhin ayọ̀ ijọba Ọlọrun: awọn mejila si mbẹ lọdọ rẹ̀. 2 Ati awọn obinrin kan, ti a ti mu larada kuro lọwọ awọn ẹmi buburu, ati ninu ailera wọn, Maria ti a npè ni Magdalene, lara ẹniti ẹmi èṣu meje ti jade kuro,
3 Ati Joanna aya Kusa ti iṣe iriju Herodu, ati Susanna, ati awọn pipọ miran, ti nwọn nṣe iranṣẹ fun u ninu ohun ini wọn.Òwe Afunrugbin
(Mat 13:1-9; Mak 4:1-9)
4 Nigbati ọ̀pọ ijọ enia pejọ pọ̀, lati ilu gbogbo si tọ̀ ọ wá, o fi owe ba wọn sọ̀rọ pe: 5 Afunrugbin kan jade lọ lati fun irugbin rẹ̀: bi o si ti nfunrugbin, diẹ bọ́ si ẹba ọ̀na; a si tẹ̀ ẹ mọlẹ, awọn ẹiyẹ oju ọrun si ṣà a jẹ. 6 Omiran si bọ́ sori apata; bi o si ti hù jade, o gbẹ nitoriti kò ni irinlẹ omi. 7 Omiran si bọ́ sinu ẹgún; ẹgún si ba a rú soke, o si fun u pa.
8 Omiran si bọ́ si ilẹ rere, o si rú soke, o si so eso ọrọrun. Nigbati o si wi nkan wọnyi tan, o nahùn wipe, Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.Ìdí Tí Jesu Fi Ń Lo Òwe
(Mat 13:10-17; Mak 4:10-12)
9 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe, Kili a le mọ̀ owe yi si?
10 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li a fifun lati mọ̀ ọ̀rọ ijinlẹ ijọba Ọlọrun: ṣugbọn fun awọn miran li owe; pe ni riri, ki nwọn ki o má le ri, ati ni gbigbọ ki o má le yé wọn.Jesu Ṣe Àlàyé Òwe Nípa Afunrugbin
(Mat 13:18-23; Mak 4:13-20)
11 Njẹ owe na li eyi: Irugbin li ọ̀rọ Ọlọrun. 12 Awọn ti ẹba ọ̀na li awọn ti o gbọ́; nigbana li Èṣu wá o si mu ọ̀rọ na kuro li ọkàn wọn, ki nwọn ki o má ba gbagbọ́, ki a ma ṣe gbà wọn là. 13 Awọn ti ori apata li awọn, nigbati nwọn gbọ́, nwọn fi ayọ̀ gbà ọ̀rọ na; awọn wọnyi kò si ni gbòngbo, nwọn a gbagbọ fun sã diẹ; nigba idanwò, nwọn a pada sẹhin. 14 Awọn ti o bọ sinu ẹgún li awọn, nigbati nwọn gbọ́ tan, nwọn lọ, nwọn a si fi itọju ati ọrọ̀ ati irọra aiye fun u pa, nwọn kò si le so eso asogbo.
15 Ṣugbọn ti ilẹ rere li awọn, ti nwọn fi ọkàn otitọ ati rere gbọ ọrọ na, nwọn di i mu ṣinṣin, nwọn si fi sũru so eso.Fìtílà Tí A Bò Mọ́lẹ̀
(Mak 4:21-25)
16 Kò si ẹnikẹni, nigbati o ba tàn fitilà tan, ti yio fi ohun elò bò o mọlẹ, tabi ti yio gbé e kà abẹ akete; bikoṣe ki o gbé e kà ori ọpá fitilà, ki awọn ti nwọ̀ ile ki o le ri imọlẹ. 17 Nitori kò si ohun ti o lumọ́, ti a ki yio fi hàn, bẹ̃ni kò si ohun ti o pamọ́, ti a kì yio mọ̀, ti ki yio si yọ si gbangba.
18 Njẹ ki ẹnyin ki o mã kiyesara bi ẹnyin ti ngbọ́: nitori ẹnikẹni ti o ba ni, on li a o fifun; ati ẹnikẹni ti kò ba si ni, lọwọ rẹ̀ li a o si gbà eyi ti o ṣebi on ni.Ìyá ati Àwọn Arakunrin Jesu
(Mat 12:46-50; Mak 3:31-35)
19 Nigbana ni iya rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀ tọ̀ ọ wá, nwọn kò si le sunmọ ọ nitori ọ̀pọ enia. 20 Nwọn si wi fun u pe, Iya rẹ ati awọn arakunrin rẹ duro lode, nwọn nfẹ ri ọ.
21 O si dahùn o si wi fun wọn pe, Iya mi ati awọn arakunrin mi li awọn wọnyi ti nwọn ngbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti nwọn si nṣe e.Jesu Mú Kí Ìgbì Dákẹ́ Rọ́rọ́
(Mat 8:23-27; Mak 4:35-41)
22 O si ṣe ni ijọ kan, o si wọ̀ ọkọ̀ kan lọ ti on ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: o si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki awa ki o rekọja lọ si ìha keji adagun. Nwọn si ṣikọ̀ lọ. 23 Bi nwọn si ti nlọ, o sùn; iji nla si de, o nfẹ li oju adagun; nwọn si kún fun omi, nwọn si wà ninu ewu. 24 Nwọn si tọ̀ ọ wá, nwọn si jí i, wipe, Olukọni, Olukọni, awa gbé. Nigbana li o dide, o si ba ẹfufu on riru omi wi: nwọn si da, idakẹ-rọrọ si de.
25 O si wi fun wọn pe, Igbagbọ́ nyin dà? Bi ẹ̀ru ti mba gbogbo wọn, ti hà si nṣe wọn, nwọn mbi ara wọn pe, irú ọkunrin kili eyi! nitori o ba ẹfufu on riru omi wi, nwọn si gbọ́ tirẹ̀.Jesu Wo Wèrè Ará Geraseni Sàn
(Mat 8:28-34; Mak 5:1-20)
26 Nwọn si gúnlẹ ni ilẹ awọn ara Gadara, ti o kọju si Galili. 27 Nigbati o si sọkalẹ, ọkunrin kan pade rẹ̀ li ẹhin ilu na, ti o ti ni awọn ẹmi èṣu fun igba pipẹ, ti kì iwọ̀ aṣọ, bẹ̃ni kì ijoko ni ile kan, bikoṣe ni ìboji. 28 Nigbati o ri Jesu, o ke, o wolẹ niwaju rẹ̀, o wi li ohùn rara, pe, Kini ṣe temi tirẹ Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun Ọgá-ogo? emi bẹ̀ ọ máṣe da mi loró. 29 (Nitoriti o ti wi fun ẹmi aimọ́ na pe, ki o jade kuro lara ọkunrin na. Nigbakugba ni isá ma mu u: a si fi ẹ̀wọn ati ṣẹkẹṣẹkẹ dè e; o si da gbogbo ìde na, ẹmi èṣu na si dari rẹ̀ si ijù.) 30 Jesu si bi i pe, Orukọ rẹ? o si dahùn pe, Legioni: nitoriti ẹmi eṣu pipọ wọ̀ ọ lara lọ. 31 Nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣe rán wọn lọ sinu ibu. 32 Agbo ẹlẹdẹ pipọ si mbẹ nibẹ̀ ti njẹ li ori òke: nwọn si bẹ̀ ẹ ki o jẹ ki awọn wọ̀ inu wọn lọ. O si jọwọ wọn. 33 Nigbati awọn ẹmi èṣu si jade kuro lara ọkunrin na, nwọn si wọ̀ inu awọn ẹlẹdẹ lọ: agbo ẹlẹdẹ si tu pũ nwọn si sure lọ si ibi bèbe sinu adagun, nwọn si rì sinu omi. 34 Nigbati awọn ti mbọ́ wọn ri ohun ti o ṣe, nwọn sá, nwọn si lọ, nwọn si ròhin ni ilu ati ni ilẹ na. 35 Nigbana ni nwọn jade lọ iwò ohun na ti o ṣe; nwọn si tọ̀ Jesu wá, nwọn si ri ọkunrin na, lara ẹniti awọn ẹmi èṣu ti jade lọ, o joko lẹba ẹsẹ Jesu, o wọṣọ, iyè rẹ̀ si bọ̀ si ipò: ẹ̀ru si ba wọn. 36 Awọn ti o ri i si ròhin fun wọn bi o ti ṣe ti a fi mu ẹniti o li ẹmi èṣu larada. 37 Nigbana ni gbogbo enia lati ilẹ Gadara yiká bẹ̀ ẹ pe, ki o lọ kuro lọdọ wọn; ẹ̀ru sá ba wọn gidigidi: o si bọ sinu ọkọ̀, o pada sẹhin. 38 Njẹ ọkunrin na ti ẹmi èṣu jade kuro lara rẹ̀, o bẹ̀ ẹ ki on ki o le ma bá a gbé: ṣugbọn Jesu rán a lọ, wipe,
39 Pada lọ ile rẹ, ki o si sọ ohun ti Ọlọrun ṣe fun ọ bi o ti pọ̀ to. O si lọ, o si nròhin já gbogbo ilu na bi Jesu ti ṣe ohun nla fun on to.Ìtàn Ọmọbinrin Jairu ati Ti Obinrin Tí Ó Fọwọ́ Kan Aṣọ Jesu
(Mat 9:18-26; Mak 5:21-43)
40 O si ṣe, nigbati Jesu pada lọ, awọn enia tẹwọgbà a: nitoriti gbogbo nwọn ti nreti rẹ̀. 41 Si kiyesi i, ọkunrin kan ti a npè ni Jairu, ọkan ninu awọn olori sinagogu, o wá: o si wolẹ lẹba ẹsẹ Jesu, o bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣai wá si ile on: 42 Nitori o ni ọmọbinrin kanṣoṣo, ọmọ ìwọn ọdún mejila, o nkú lọ. Bi o si ti nlọ awọn enia nhá a li àye. 43 Obinrin kan ti o si ni isun ẹ̀jẹ lati igba ọdún mejila, ti o ná ohun gbogbo ti o ni fun awọn oniṣegun, bẹ̃ni a ko le mu u larada lati ọwọ́ ẹnikan wá, 44 O wá lẹhin rẹ̀, o fi ọwọ́ tọ́ iṣẹti aṣọ rẹ̀: lọgan ni isun ẹ̀jẹ rẹ̀ si ti gbẹ. 45 Jesu si wipe, Tali o fi ọwọ́ tọ́ mi? Nigbati gbogbo wọn sẹ́, Peteru ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ wipe, Olukọni, awọn enia nhá ọ li àye, nwọn si mbilù ọ, iwọ si wipe, Tali o fi ọwọ́ kàn mi? 46 Jesu si wipe, Ẹnikan fi ọwọ́ kàn mi: nitoriti emi mọ̀ pe aṣẹ jade lara mi. 47 Nigbati obinrin na si mọ̀ pe on ko farasin, o warìri, o wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si sọ fun u li oju awọn enia gbogbo nitori ohun ti o ṣe, ti on fi fi ọwọ́ tọ́ ọ, ati bi a ti mu on larada lojukanna. 48 O si wi fun u pe, Ọmọbinrin, tújuka: igbagbọ́ rẹ mu ọ larada; mã lọ li alafia. 49 Bi o si ti nsọ̀rọ li ẹnu, ẹnikan ti ile olori sinagogu wá, o wi fun u pe, Ọmọbinrin rẹ kú; má yọ olukọni lẹnu mọ. 50 Ṣugbọn nigbati Jesu gbọ́, o da a li ohùn, wipe, Má bẹ̀ru: gbagbọ́ nikan ṣa, a o si mu u larada. 51 Nigbati Jesu si wọ̀ ile, kò jẹ ki ẹnikẹni wọle, bikoṣe Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, ati baba on iya ọmọbinrin na. 52 Gbogbo nwọn si sọkun, nwọn pohùnrere ẹkún rẹ̀: o si wi fun wọn pe, Ẹ má sọkun mọ́; kò kú, sisùn li o sùn. 53 Nwọn si fi i ṣẹ̀fẹ, nwọn sa mọ̀ pe o kú. 54 Nigbati o si sé gbogbo wọn mọ́ ode, o mu u li ọwọ́, o si wipe, Ọmọbinrin, dide. 55 Ẹmí rẹ̀ si pada bọ̀, o si dide lọgan: o ni ki nwọn ki o fun u li onjẹ. 56 Ẹnu si yà awọn õbi rẹ̀: ṣugbọn o kilọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe wi fun ẹnikan li ohun ti a ṣe.
Luke 8
Ministering Women
1 Soon afterwards, He began going around from one city and village to another, proclaiming and preaching the kingdom of God. The twelve were with Him,2 and also some women who had been healed of evil spirits and sicknesses: Mary who was called Magdalene, from whom seven demons had gone out,3 and Joanna the wife of Chuza, Herod's steward, and Susanna, and many others who were contributing to their support out of their private means.
Parable of the Sower
4 When a large crowd was coming together, and those from the various cities were journeying to Him, He spoke by way of a parable:5 "The sower went out to sow his seed; and as he sowed, some fell beside the road, and it was trampled under foot and the birds of the air ate it up.6 Other seed fell on rocky soil, and as soon as it grew up, it withered away, because it had no moisture.7 Other seed fell among the thorns; and the thorns grew up with it and choked it out.8 Other seed fell into the good soil, and grew up, and produced a crop a hundred times as great." As He said these things, He would call out, "He who has ears to hear, let him hear."
9 His disciples began questioning Him as to what this parable meant.10 And He said, "To you it has been granted to know the mysteries of the kingdom of God, but to the rest it is in parables, so that SEEING THEY MAY NOT SEE, AND HEARING THEY MAY NOT UNDERSTAND.
11 "Now the parable is this: the seed is the word of God.12 Those beside the road are those who have heard; then the devil comes and takes away the word from their heart, so that they will not believe and be saved.13 Those on the rocky soil are those who, when they hear, receive the word with joy; and these have no firm root; they believe for a while, and in time of temptation fall away.14 The seed which fell among the thorns, these are the ones who have heard, and as they go on their way they are choked with worries and riches and pleasures of this life, and bring no fruit to maturity.15 But the seed in the good soil, these are the ones who have heard the word in an honest and good heart, and hold it fast, and bear fruit with perseverance.
Parable of the Lamp
16 "Now no one after lighting a lamp covers it over with a container, or puts it under a bed; but he puts it on a lampstand, so that those who come in may see the light.17 For nothing is hidden that will not become evident, nor anything secret that will not be known and come to light.18 So take care how you listen; for whoever has, to him more shall be given; and whoever does not have, even what he thinks he has shall be taken away from him."
19 And His mother and brothers came to Him, and they were unable to get to Him because of the crowd.20 And it was reported to Him, "Your mother and Your brothers are standing outside, wishing to see You."21 But He answered and said to them, "My mother and My brothers are these who hear the word of God and do it."
Jesus Stills the Sea
22 Now on one of those days Jesus and His disciples got into a boat, and He said to them, "Let us go over to the other side of the lake." So they launched out.23 But as they were sailing along He fell asleep; and a fierce gale of wind descended on the lake, and they began to be swamped and to be in danger.24 They came to Jesus and woke Him up, saying, "Master, Master, we are perishing!" And He got up and rebuked the wind and the surging waves, and they stopped, and it became calm.25 And He said to them, "Where is your faith?" They were fearful and amazed, saying to one another, "Who then is this, that He commands even the winds and the water, and they obey Him?"
The Demoniac Cured
26 Then they sailed to the country of the Gerasenes, which is opposite Galilee.27 And when He came out onto the land, He was met by a man from the city who was possessed with demons; and who had not put on any clothing for a long time, and was not living in a house, but in the tombs.28 Seeing Jesus, he cried out and fell before Him, and said in a loud voice, "What business do we have with each other, Jesus, Son of the Most High God? I beg You, do not torment me."29 For He had commanded the unclean spirit to come out of the man. For it had seized him many times; and he was bound with chains and shackles and kept under guard, and yet he would break his bonds and be driven by the demon into the desert.30 And Jesus asked him, "What is your name?" And he said, "Legion"; for many demons had entered him.31 They were imploring Him not to command them to go away into the abyss.
32 Now there was a herd of many swine feeding there on the mountain; and the demons implored Him to permit them to enter the swine. And He gave them permission.33 And the demons came out of the man and entered the swine; and the herd rushed down the steep bank into the lake and was drowned.
34 When the herdsmen saw what had happened, they ran away and reported it in the city and out in the country.35 The people went out to see what had happened; and they came to Jesus, and found the man from whom the demons had gone out, sitting down at the feet of Jesus, clothed and in his right mind; and they became frightened.36 Those who had seen it reported to them how the man who was demon-possessed had been made well.37 And all the people of the country of the Gerasenes and the surrounding district asked Him to leave them, for they were gripped with great fear; and He got into a boat and returned.38 But the man from whom the demons had gone out was begging Him that he might accompany Him; but He sent him away, saying,39 "Return to your house and describe what great things God has done for you." So he went away, proclaiming throughout the whole city what great things Jesus had done for him.
Miracles of Healing
40 And as Jesus returned, the people welcomed Him, for they had all been waiting for Him.41 And there came a man named Jairus, and he was an official of the synagogue; and he fell at Jesus' feet, and began to implore Him to come to his house;42 for he had an only daughter, about twelve years old, and she was dying. But as He went, the crowds were pressing against Him.
43 And a woman who had a hemorrhage for twelve years, and could not be healed by anyone,44 came up behind Him and touched the fringe of His cloak, and immediately her hemorrhage stopped.45 And Jesus said, "Who is the one who touched Me?" And while they were all denying it, Peter said, "Master, the people are crowding and pressing in on You."46 But Jesus said, "Someone did touch Me, for I was aware that power had gone out of Me."47 When the woman saw that she had not escaped notice, she came trembling and fell down before Him, and declared in the presence of all the people the reason why she had touched Him, and how she had been immediately healed.48 And He said to her, "Daughter, your faith has made you well; go in peace."
49 While He was still speaking, someone *came from the house of the synagogue official, saying, "Your daughter has died; do not trouble the Teacher anymore."50 But when Jesus heard this, He answered him, "Do not be afraid any longer; only believe, and she will be made well."51 When He came to the house, He did not allow anyone to enter with Him, except Peter and John and James, and the girl's father and mother.52 Now they were all weeping and lamenting for her; but He said, "Stop weeping, for she has not died, but is asleep."53 And they began laughing at Him, knowing that she had died.54 He, however, took her by the hand and called, saying, "Child, arise!"55 And her spirit returned, and she got up immediately; and He gave orders for something to be given her to eat.56 Her parents were amazed; but He instructed them to tell no one what had happened.