Mak 1
Iwaasu Johanu Onítẹ̀bọmi
(Mat 3:1-12; Luk 3:1-9, 15-17; Joh 1:19-28)
1 IBẸRẸ ihinrere Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun. 2 Bi a ti kọ ọ ninu iwe woli Isaiah: Kiyesi i, mo rán onṣẹ mi ṣiwaju rẹ, ẹniti yio tún ọ̀na rẹ ṣe niwaju rẹ. 3 Ohùn ẹnikan ti nkigbe ni ijù, Ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ẹ ṣe oju ọ̀na rẹ̀ tọ́. 4 Johanu de, ẹniti o mbaptisi ni iju, ti o si nwasu baptismu ironupiwada fun idariji ẹ̀ṣẹ. 5 Gbogbo ilẹ Judea, ati gbogbo awọn ará Jerusalemu jade tọ̀ ọ lọ, a si ti ọwọ́ rẹ̀ baptisi gbogbo wọn li odò Jordani, nwọn njẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn. 6 Johanu si wọ̀ aṣọ irun ibakasiẹ, o si dì amure awọ mọ ẹgbẹ rẹ̀; o si njẹ ẽṣú ati oyin ìgan. 7 O si nwasu, wipe, Ẹnikan ti o pọ̀ju mi lọ mbọ̀ lẹhin mi, okùn bata ẹsẹ ẹniti emi ko to bẹ̀rẹ tú:
8 Emi fi omi baptisi nyin; ṣugbọn on yio fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin.Jesu Ṣe Ìrìbọmi
(Mat 3:13-17; Luk 3:21-22)
9 O si ṣe li ọjọ wọnni, Jesu jade wá lati Nasareti ti Galili, a si ti ọwọ́ Johanu baptisi rẹ̀ li odò Jordani. 10 Lojukanna bi o si ti goke lati inu omi wá, o ri ọrun pinya, Ẹmi nsọkalẹ bi àdaba le e lori:
11 Ohùn kan si ti ọrun wá, wipe, Iwọ ni ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi.Satani Dán Jesu Wò
(Mat 4:1-11; Luk 4:1-13)
12 Loju kan náà Ẹmí si dari rẹ̀ si ijù.
13 O si wà ni ogoji ọjọ ni ijù, a ti ọwọ́ Satani dán an wò, o si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ́; awọn angẹli si nṣe iranṣẹ fun u.Jesu Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ ní Galili
(Mat 4:12-17; Luk 4:14-15)
14 Lẹhin igbati a fi Johanu sinu tubu tan, Jesu lọ si Galili, o nwasu ihinrere ijọba Ọlọrun,
15 O si nwipe, Akokò na de, ijọba Ọlọrun si kù si dẹ̀dẹ: ẹ ronupiwada, ki ẹ si gbà ihinrere gbọ́.Jesu Pe Apẹja Mẹrin
(Mat 4:18-22; Luk 5:1-11)
16 Bi o si ti nrìn leti okun Galili, o ri Simoni ati Anderu arakunrin rẹ̀, nwọn nsọ àwọn sinu okun: nitoriti nwọn ṣe apẹja. 17 Jesu si wi fun wọn pe, Ẹ mã tọ̀ mi lẹhin, emi o si sọ nyin di apẹja enia. 18 Lojukanna nwọn si fi àwọn wọn silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin. 19 Bi o si ti lọ siwaju diẹ, o ri Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀, nwọn wà ninu ọkọ̀, nwọn ndí àwọn wọn.
20 Lojukanna o si pè wọn: nwọn si fi Sebede baba wọn silẹ ninu ọkọ̀ pẹlu awọn alagbaṣe, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.Ọkunrin Ẹlẹ́mìí Èṣù
(Luk 4:31-37)
21 Nwọn si lọ si Kapernaumu; lojukanna o si wọ̀ inu sinagogu li ọjọ, isimi, o si nkọ́ni. 22 Ẹnu si yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀: nitoriti o nkọ́ wọn bi ẹniti o li aṣẹ, kì isi ṣe bí awọn akọwe. 23 Ọkunrin kan si wà ninu sinagogu wọn, ti o li ẹmi aimọ́; o si kigbe soke. 24 O wipe, Jọwọ wa jẹ; kini ṣe tawa tirẹ, Jesu ara Nasareti? iwọ wá lati pa wa run? emi mọ̀ ẹniti iwọ ṣe, Ẹni-Mimọ́ Ọlọrun. 25 Jesu si ba a wi, o wipe, Pa ẹnu rẹ mọ́, ki o si jade kuro lara rẹ̀. 26 Nigbati ẹmi aimọ́ na si gbé e ṣanlẹ, o ke li ohùn rara, o si jade kuro lara rẹ̀. 27 Hà si ṣe gbogbo wọn, tobẹ̃ ti nwọn fi mbi ara wọn lẽre, wipe, Kili eyi? ẹkọ́ titun li eyi? nitoriti o fi agbara paṣẹ fun awọn ẹmi aimọ́, nwọn si gbọ́ tirẹ̀.
28 Lojukanna okikí rẹ̀ si kàn yi gbogbo ẹkùn Galili ká.Jesu Wo Ọpọlọpọ Eniyan Sàn
(Mat 8:14-17; Luk 4:38-41)
29 Nigbati nwọn si jade kuro ninu sinagogu, lojukanna nwọn wọ̀ ile Simoni ati Anderu, pẹlu Jakọbu ati Johanu. 30 Iya aya Simoni si dubulẹ aìsan ibà, nwọn si sọ ọ̀ran rẹ̀ fun u. 31 O si wá, o fà a lọwọ, o si gbé e dide; lojukanna ibà na si fi i silẹ, o si nṣe iranṣẹ fun wọn. 32 Nigbati o di aṣalẹ, ti õrun wọ̀, nwọn gbe gbogbo awọn alaìsan, ati awọn ti o li ẹmi i èṣu tọ̀ ọ wá. 33 Gbogbo ilu si pejọ li ẹnu-ọ̀na.
34 O si wò ọ̀pọ awọn ti o ni onirũru àrun sàn, o si lé ọ̀pọ ẹmi èṣu jade; ko si jẹ ki awọn ẹmi èṣu na ki o fọhun, nitoriti nwọn mọ̀ ọ.Jesu Waasu ní Galili
(Luk 4:42-44)
35 O si dide li owurọ̀ ki ilẹ to mọ́, o si jade lọ si ibi iju kan, nibẹ li o si ngbadura. 36 Simoni ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ si nwá a. 37 Nigbati nwọn si ri i, nwọn wi fun u pe, Gbogbo enia nwá ọ. 38 O si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki a lọ si ilu miran, ki emi ki o le wasu nibẹ̀ pẹlu: nitori eyi li emi sá ṣe wá.
39 O si nwãsu ninu sinagogu wọn lọ ni gbogbo Galili, o si nlé awọn ẹmi èṣu jade.Jesu Wo Alárùn Ẹ̀tẹ̀ Sàn
(Mat 8:1-4; Luk 5:12-16)
40 Ọkunrin kan ti o dẹtẹ si tọ̀ ọ wá, o si kunlẹ niwaju rẹ̀, o si mbẹ̀ ẹ, o si wi fun u pe, Bi iwọ ba fẹ, iwọ le sọ mi di mimọ́. 41 Jesu ṣãnu rẹ̀, o nà ọwọ́ rẹ̀, o fi bà a, o si wi fun u pe, Mo fẹ, iwọ di mimọ́. 42 Bi o si ti sọ̀rọ, lojukanna ẹ̀tẹ na fi i silẹ; o si di mimọ́. 43 O si kìlọ fun u gidigidi, lojukanna o si rán a lọ; 44 O si wi fun u pe, Wo o, máṣe sọ ohunkohun fun ẹnikẹni: ṣugbọn lọ, fi ara rẹ hàn fun alufa, ki o si fi ẹ̀bun iwẹnumọ́ rẹ ti Mose ti palaṣẹ, ni ẹrí fun wọn. 45 Ṣugbọn o jade, o si bẹrẹ si ikokiki, ati si itàn ọ̀ran na kalẹ, tobẹ̃ ti Jesu kò si le wọ̀ ilu ni gbangba mọ́, ṣugbọn o wà lẹhin odi nibi iju: nwọn si tọ̀ ọ wá lati ìha gbogbo wá.
Mark 1
Preaching of John the Baptist
1 The beginning of the gospel of Jesus Christ, the Son of God.
2 As it is written in Isaiah the prophet:
"BEHOLD, I SEND MY MESSENGER AHEAD OF YOU,
WHO WILL PREPARE YOUR WAY;
3 THE VOICE OF ONE CRYING IN THE WILDERNESS,
'MAKE READY THE WAY OF THE LORD,
MAKE HIS PATHS STRAIGHT.'"4 John the Baptist appeared in the wilderness tpreaching a baptism of repentance for the forgiveness of sins.5 And all the country of Judea was going out to him, and all the people of Jerusalem; and they were being baptized by him in the Jordan River, confessing their sins.6 John was clothed with camel's hair and wore a leather belt around his waist, and his diet was locusts and wild honey.7 And he was preaching, and saying, "After me One is coming who is mightier than I, and I am not fit to stoop down and untie the thong of His sandals.8 I baptized you twith water; but He will baptize you with the Holy Spirit."
The Baptism of Jesus
9 In those days Jesus came from Nazareth in Galilee and was baptized by John in the Jordan.10 Immediately coming up out of the water, He saw the heavens opening, and the Spirit like a dove descending upon Him;11 and a voice came out of the heavens: "You are My beloved Son, in You I am well-pleased."
12 Immediately the Spirit *impelled Him to go out into the wilderness.13 And He was in the wilderness forty days being tempted by Satan; and He was with the wild beasts, and the angels were ministering to Him.
Jesus Preaches in Galilee
14 Now after John had been taken into custody, Jesus came into Galilee, preaching the gospel of God,15 and saying, "The time is fulfilled, and the kingdom of God is at hand; repent and believe in the gospel."
16 As He was going along by the Sea of Galilee, He saw Simon and Andrew, the brother of Simon, casting a net in the sea; for they were fishermen.17 And Jesus said to them, "Follow Me, and I will make you become fishers of men."18 Immediately they left their nets and followed Him.19 Going on a little farther, He saw James the son of Zebedee, and John his brother, who were also in the boat mending the nets.20 Immediately He called them; and they left their father Zebedee in the boat with the hired servants, and went away to follow Him.
21 They *went into Capernaum; and immediately on the Sabbath He entered the synagogue and began to teach.22 They were amazed at His teaching; for He was teaching them as one having authority, and not as the scribes.23 Just then there was a man in their synagogue with an unclean spirit; and he cried out,24 saying, "What business do we have with each other, Jesus tof Nazareth? Have You come to destroy us? I know who You are-the Holy One of God!"25 And Jesus rebuked him, saying, "Be quiet, and come out of him!"26 Throwing him into convulsions, the unclean spirit cried out with a loud voice and came out of him.27 They were all amazed, so that they debated among themselves, saying, "What is this? A new teaching with authority! He commands even the unclean spirits, and they obey Him."28 Immediately the news about Him spread everywhere into all the surrounding district of Galilee.
Crowds Healed
29 And immediately after they came out of the synagogue, they came into the house of Simon and Andrew, with James and John.30 Now Simon's mother-in-law was lying sick with a fever; and immediately they *spoke to Jesus about her.31 And He came to her and raised her up, taking her by the hand, and the fever left her, and she twaited on them.
32 When evening came, after the sun had set, they began bringing to Him all who were ill and those who were demon-possessed.33 And the whole city had gathered at the door.34 And He healed many who were ill with various diseases, and cast out many demons; and He was not permitting the demons to speak, because they knew who He was.
35 In the early morning, while it was still dark, Jesus got up, left the house, and went away to a secluded place, and was praying there.36 Simon and his companions searched for Him;37 they found Him, and *said to Him, "Everyone is looking for You."38 He *said to them, "Let us go somewhere else to the towns nearby, so that I may preach there also; for that is what I came for."39 And He went into their synagogues throughout all Galilee, preaching and casting out the demons.
40 And a leper *came to Jesus, beseeching Him and falling on his knees before Him, and saying, "If You are willing, You can make me clean."41 Moved with compassion, Jesus stretched out His hand and touched him, and *said to him, "I am willing; be cleansed."42 Immediately the leprosy left him and he was cleansed.43 And He sternly warned him and immediately sent him away,44 and He *said to him, "See that you say nothing to anyone; but go, show yourself to the priest and offer for your cleansing what Moses commanded, as a testimony to them."45 But he went out and began to proclaim it freely and to spread the news around, to such an extent that Jesus could no longer publicly enter a city, but tstayed out in unpopulated areas; and they were coming to Him from everywhere.