previous next

Mak 10

Ìbéèrè Nípa Ìkọ̀sílẹ̀

(Mat 19:1-12; Luk 16:18)

1 O si dide kuro nibẹ̀, o si wá si ẹkùn Judea niha oke odò Jordani: awọn enia si tún tọ̀ ọ wá; bi iṣe rẹ̀ ti ri, o si tún nkọ́ wọn. 2 Awọn Farisi si tọ̀ ọ wá, nwọn ndán a wò, nwọn si bi i lẽre, wipe, O tọ́ fun ọkunrin ki o fi aya rẹ̀ silẹ? 3 O si dahùn o si wi fun wọn pe, Aṣẹ kini Mose pa fun nyin? 4 Nwọn si wipe, Mose yọda fun wa lati kọ iwe ikọsilẹ fun u, ki a si fi i silẹ. 5 Jesu si da wọn lohùn, o si wi fun wọn pe, Nitori lile àiya nyin li o ṣe kọ irú ofin yi fun nyin. 6 Ṣugbọn lati igba ti aiye ti ṣẹ, Ọlọrun da wọn ti akọ ti abo. 7 Nitori eyi li ọkunrin yio ṣe fi baba ati iya rẹ̀ silẹ ti yio si faramọ aya rẹ̀; 8 Awọn mejeji a si di ara kan: nitorina nwọn kì iṣe meji mọ́, bikoṣe ara kan. 9 Nitorina ohun ti Ọlọrun ba so ṣọkan, ki enia ki o máṣe yà wọn. 10 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tun bi i lẽre ọ̀ran kanna ninu ile. 11 O si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba fi aya rẹ̀ silẹ, ti o ba si gbé omiran ni iyawo, o ṣe panṣaga si i.

12 Bi obinrin kan ba si fi ọkọ rẹ̀ silẹ, ti a ba si gbé e ni iyawo fun ẹlomiran, o ṣe panṣaga.

Jesu Súre Fun Àwọn Ọmọde

(Mat 19:13-15; Luk 18:15-17)


13 Nwọn si gbé awọn ọmọ-ọwọ tọ̀ ọ wá, ki o le fi ọwọ́ tọ́ wọn: awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ba awọn ti o gbé wọn wá wi. 14 Ṣugbọn nigbati Jesu ri i, inu bi i, o si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki awọn ọmọ kekere ki o wá sọdọ mi, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun: nitoriti irú wọn ni ijọba Ọlọrun. 15 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti kò ba gbà ijọba Ọlọrun bi ọmọ kekere, kì yio le wọ̀ inu rẹ̀ bi o ti wù o ri.

16 O si gbé wọn si apa rẹ̀, o gbé ọwọ́ rẹ̀ le wọn, o si sure fun wọn.

Ọkunrin Ọlọ́rọ̀ kan

(Mat 19:16-30; Luk 18:18-30)


17 Bi o si ti njade bọ̀ si ọ̀na, ẹnikan nsare tọ̀ ọ wá, o si kunlẹ fun u, o bi i lẽre, wipe, Olukọni rere, kili emi o ṣe ti emi o fi le jogún ìye ainipẹkun? 18 Jesu si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi npè mi li ẹni rere? ẹni rere kan ko si bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun. 19 Iwọ sá mọ̀ ofin: Máṣe panṣaga, Máṣe pania, Máṣe jale, Máṣe jẹri eke, Máṣe rẹ-ni-jẹ, Bọwọ fun baba on iya rẹ. 20 O si dahùn o si wi fun u pe, Olukọni, gbogbo nkan wọnyi li emi ti nkiyesi lati igba ewe mi wá. 21 Nigbana ni Jesu sì wò o, o fẹràn rẹ̀, o si wi fun u pe, Ohun kan li o kù ọ kù: lọ tà ohunkohun ti o ni ki o si fifun awọn talakà, iwọ ó si ni iṣura li ọrun: si wá, gbé agbelebu, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin. 22 Inu rẹ̀ si bajẹ si ọ̀rọ̀ na, o si jade lọ ni ibinujẹ: nitoriti o li ọrọ̀ pipọ. 23 Jesu si wò yiká, o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Yio ti ṣoro to fun awọn ti o li ọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun! 24 Ẹnu si yà awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ọ̀rọ rẹ̀. Ṣugbọn Jesu si tun dahùn wi fun wọn pe, Ẹnyin ọmọ, yio ti ṣoro to fun awọn ti o gbẹkẹle ọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun! 25 O rọrun fun ibakasiẹ lati wọ̀ oju abẹrẹ jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ. 26 Ẹnu si yà wọn rekọja, nwọn si mba ara wọn sọ wipe, Njẹ tali o ha le là? 27 Jesu si wò wọn o wipe, Enia li eyi ko le ṣe iṣe fun, ṣugbọn ki iṣe fun Ọlọrun: nitori ohun gbogbo ni ṣiṣe fun Ọlọrun. 28 Nigbana ni Peteru bẹ̀rẹ si iwi fun u pe, Wo o, awa ti fi gbogbo nkan silẹ awa si ti tọ̀ ọ lẹhin. 29 Jesu si dahùn, o wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Kò si ẹniti o fi ile silẹ, tabi arakunrin, tabi arabinrin, tabi baba, tabi iya, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ, nitori mi, ati nitori ihinrere, 30 Ṣugbọn nisisiyi li aiye yi on o si gbà ọgọrọrun, ile, ati arakunrin, ati arabinrin, ati iya, ati ọmọ, ati ilẹ, pẹlu inunibini, ati li aiye ti mbọ̀ ìye ainipẹkun;

31 Ṣugbọn ọ̀pọ awọn ti o ṣiwaju ni yio kẹhin; awọn ti o kẹhin ni yio si ṣiwaju.

Jesu Tún Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀ Lẹẹkẹta

(Mat 20:17-19; Luk 18:31-34)


32 Nwọn si wà li ọ̀na nwọn ngoke lọ si Jerusalemu; Jesu si nlọ niwaju wọn: ẹnu si yà wọn; bi nwọn si ti ntọ̀ ọ lẹhin, ẹ̀ru ba wọn. O si tun mu awọn mejila, o bẹ̀rẹ si isọ gbogbo ohun ti a o ṣe si i fun wọn, 33 Wipe, Sá wo o, awa ngoke lọ si Jerusalemu, a o si fi Ọmọ-enia le awọn olori alufa, ati awọn akọwe lọwọ; nwọn o si da a lẹbi ikú, nwọn o si fi i le awọn Keferi lọwọ:

34 Nwọn o si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn o si nà a, nwọn o si tutọ́ si i lara, nwọn o si pa a: ni ijọ kẹta yio si jinde.

Jakọbu ati Johanu Bèèrè Ipò Ọlá

(Mat 20:20-28)


35 Jakọbu ati Johanu awọn ọmọ Sebede si wá sọdọ rẹ̀, wipe, Olukọni, awa nfẹ ki iwọ ki o ṣe ohunkohun ti awa ba bere lọwọ rẹ fun wa. 36 O si bi wọn lẽre pe, Kili ẹnyin nfẹ ki emi ki o ṣe fun nyin? 37 Nwọn si wi fun u pe, Fifun wa ki awa ki o le joko, ọkan li ọwọ́ ọtun rẹ, ati ọkan li ọwọ́ òsi rẹ, ninu ogo rẹ. 38 Ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, Ẹnyin ko mọ̀ ohun ti ẹnyin mbère: ẹnyin le mu ago ti emi mu? tabi ki a fi baptismu ti a fi baptisi mi baptisi nyin? 39 Nwọn si wi fun u pe, Awa le ṣe e. Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin ó mu ago ti emi mu; ati baptismu ti a o fi baptisi mi li a o fi baptisi nyin: 40 Ṣugbọn lati joko li ọwọ́ ọtún mi ati li ọwọ́ òsi mi ki iṣe ti emi lati fi funni: bikoṣe fun awọn ẹniti a ti pèse rẹ̀ silẹ. 41 Nigbati awọn mẹwa iyokù gbọ́, nwọn bẹ̀re si ibinu si Jakọbu ati Johanu. 42 Ṣugbọn Jesu pè wọn sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ pe, awọn ti a nkà si olori awọn Keferi, a ma lò ipá lori wọn: ati awọn ẹni-nla wọn a ma fi ọlá tẹri wọn ba. 43 Ṣugbọn kì yio ri bẹ̃ lãrin nyin: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fẹ tobi lãrin nyin, on ni yio ṣe iranṣẹ nyin: 44 Ati ẹnikẹni ninu nyin ti o ba fẹ ṣe olori, on ni yio ṣe ọmọ-ọdọ gbogbo nyin.

45 Nitori Ọmọ-enia tikalarẹ̀ kò ti wá ki a ba mã ṣe iranṣẹ fun, bikoṣe lati mã ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi ẹmi rẹ̀ ṣe irapada fun ọ̀pọlọpọ enia.

Jesu Wo Bartimẹu Afọ́jú Sàn

(Mat 20:29-34; Luk 18:35-43)


46 Nwọn si wá si Jeriko: bi o si ti njade kuro ni Jeriko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati ọ̀pọ awọn enia, Bartimeu afọju, ọmọ Timeu, joko lẹba ọ̀na, o nṣagbe. 47 Nigbati o gbọ́ pe, Jesu ti Nasareti ni, o bẹ̀rẹ si ikigbe lohùn rara, wipe, Jesu, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi. 48 Ọpọlọpọ si ba a wipe, ki o pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣugbọn on si kigbe si i jù bẹ̃ lọ pe, Iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi. 49 Jesu si dẹsẹ duro, o si paṣẹ pe ki a pè e wá. Nwọn si pè afọju na, nwọn wi fun u pe, Tùjuka, dide; o npè ọ. 50 O si bọ ẹ̀wu rẹ́ sọnù, o dide, o si tọ̀ Jesu wá. 51 Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Kini iwọ nfẹ ki emi ki o ṣe fun ọ? Afọju na si wi fun u pe, Rabboni, ki emi ki o le riran. 52 Jesu si wi fun u pe, Mã lọ; igbagbọ́ rẹ mu ọ larada. Lojukanna, o si riran, o si tọ̀ Jesu lẹhin li ọ̀na.

Mark 10

Jesus' Teaching about Divorce

1 Getting up, He *went from there to the region of Judea and beyond the Jordan; crowds *gathered around Him again, and, according to His custom, He once more began to teach them.

2  Some Pharisees came up to Jesus, testing Him, and began to question Him whether it was lawful for a man to divorce a wife.3 And He answered and said to them, "What did Moses command you?"4 They said, "Moses permitted a man TO WRITE A CERTIFICATE OF DIVORCE AND SEND her AWAY."5 But Jesus said to them, "Because of your hardness of heart he wrote you this commandment.6 But from the beginning of creation, God MADE THEM MALE AND FEMALE.7 FOR THIS REASON A MAN SHALL LEAVE HIS FATHER AND MOTHERt,8 AND THE TWO SHALL BECOME ONE FLESH; so they are no longer two, but one flesh.9 What therefore God has joined together, let no man separate."

10 In the house the disciples began questioning Him about this again.11 And He *said to them, "Whoever divorces his wife and marries another woman commits adultery against her;12 and if she herself divorces her husband and marries another man, she is committing adultery."

Jesus Blesses Little Children

13 And they were bringing children to Him so that He might touch them; but the disciples rebuked them.14 But when Jesus saw this, He was indignant and said to them, "Permit the children to come to Me; do not hinder them; for the kingdom of God belongs to such as these.15 Truly I say to you, whoever does not receive the kingdom of God like a child will not enter it at all."16 And He took them in His arms and began blessing them, laying His hands on them.

The Rich Young Ruler

17 As He was setting out on a journey, a man ran up to Him and knelt before Him, and asked Him, "Good Teacher, what shall I do to inherit eternal life?"18 And Jesus said to him, "Why do you call Me good? No one is good except God alone.19 You know the commandments, 'DO NOT MURDER, DO NOT COMMIT ADULTERY, DO NOT STEAL, DO NOT BEAR FALSE WITNESS, Do not defraud, HONOR YOUR FATHER AND MOTHER.'"20 And he said to Him, "Teacher, I have kept all these things from my youth up."21 Looking at him, Jesus felt a love for him and said to him, "One thing you lack: go and sell all you possess and give to the poor, and you will have treasure in heaven; and come, follow Me."22 But at these words he was saddened, and he went away grieving, for he was one who owned much property.

23 And Jesus, looking around, *said to His disciples, "How hard it will be for those who are wealthy to enter the kingdom of God!"24 The disciples were amazed at His words. But Jesus *answered again and *said to them, "Children, how hard it is to enter the kingdom of God!25 It is easier for a camel to go through the eye of a needle than for a rich man to enter the kingdom of God."26 They were even more astonished and said to Him, "Then who can be saved?"27 Looking at them, Jesus *said, "With people it is impossible, but not with God; for all things are possible with God."

28 Peter began to say to Him, "Behold, we have left everything and followed You."29 Jesus said, "Truly I say to you, there is no one who has left house or brothers or sisters or mother or father or children or farms, for My sake and for the gospel's sake,30 but that he will receive a hundred times as much now in the present age, houses and brothers and sisters and mothers and children and farms, along with persecutions; and in the age to come, eternal life.31 But many who are first will be last, and the last, first."

Jesus' Sufferings Foretold

32 They were on the road going up to Jerusalem, and Jesus was walking on ahead of them; and they were amazed, and those who followed were fearful. And again He took the twelve aside and began to tell them what was going to happen to Him,33  saying, "Behold, we are going up to Jerusalem, and the Son of Man will be tdelivered to the chief priests and the scribes; and they will condemn Him to death and will hand Him over to the Gentiles.34 They will mock Him and spit on Him, and scourge Him and kill Him, and three days later He will rise again."

35 James and John, the two sons of Zebedee, *came up to Jesus, saying, "Teacher, we want You to do for us whatever we ask of You."36 And He said to them, "What do you want Me to do for you?"37 They said to Him, "Grant that we may sit, one on Your right and one on Your left, in Your glory."38 But Jesus said to them, "You do not know what you are asking. Are you able to drink the cup that I drink, or to be baptized with the baptism with which I am baptized?"39 They said to Him, "We are able." And Jesus said to them, "The cup that I drink you shall drink; and you shall be baptized with the baptism with which I am baptized.40 But to sit on My right or on My left, this is not Mine to give; but it is for those for whom it has been prepared."

41 Hearing this, the ten began to feel indignant with James and John.42 Calling them to Himself, Jesus *said to them, "You know that those who are recognized as rulers of the Gentiles lord it over them; and their great men exercise authority over them.43 But it is not this way among you, but whoever wishes to become great among you shall be your servant;44 and whoever wishes to be first among you shall be slave of all.45 For even the Son of Man did not come to be served, but to serve, and to give His life a ransom for many."

Bartimaeus Receives His Sight

46 Then they *came to Jericho. And as He was leaving Jericho with His disciples and a large crowd, a blind beggar named Bartimaeus, the son of Timaeus, was sitting by the road.47 When he heard that it was Jesus the Nazarene, he began to cry out and say, "Jesus, Son of David, have mercy on me!"48 Many were sternly telling him to be quiet, but he kept crying out all the more, "Son of David, have mercy on me!"49 And Jesus stopped and said, "Call him here." So they *called the blind man, saying to him, "Take courage, stand up! He is calling for you."50 Throwing aside his cloak, he jumped up and came to Jesus.51 And answering him, Jesus said, "What do you want Me to do for you?" And the blind man said to Him, "tRabboni, I want to regain my sight!"52 And Jesus said to him, "Go; your faith has made you well." Immediately he regained his sight and began following Him on the road.