Mak 12
Òwe Nípa Àwọn Alágbàro Ọgbà Àjàrà
(Mat 21:33-46; Luk 20:9-19)
1 O si bẹ̀rẹ si ifi owe ba wọn sọ̀rọ pe, ọkunrin kan gbìn ọgba ajara kan, o si ṣọgba yi i ká, o si wà ibi ifunti waini, o si kọ́ ile-isọ si i, o si fi ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba, o si lọ si àjo. 2 Nigbati o si di akokò, o rán ọmọ-ọdọ rẹ̀ kan si awọn oluṣọgba na, ki o le gbà ninu eso ọgba ajara na lọwọ awọn oluṣọgba. 3 Nwọn si mu u, nwọn lù u, nwọn si rán a pada lọwọ̀ ofo. 4 O si tún rán ọmọ-ọdọ miran si wọn, on ni nwọn si sọ okuta lù, nwọn sá a logbẹ́ li ori, nwọn si ran a lọ ni itiju. 5 O si tún rán omiran; eyini ni nwọn si pa: ati ọ̀pọ miran, nwọn lù miran, nwọn si pa miran. 6 Ṣugbọn o kù ọmọ rẹ̀ kan ti o ni, ti iṣe ayanfẹ rẹ̀, o si rán a si wọn pẹlu nikẹhin, o wipe, Nwọn ó ṣe ojuṣãju fun ọmọ mi. 7 Ṣugbọn awọn oluṣọgba wọnni wi fun ara wọn pe, Eyiyi li arole; ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ogún rẹ̀ yio si jẹ tiwa. 8 Nwọn si mu u, nwọn pa a, nwọn si wọ́ ọ jade kuro ninu ọgba ajara na. 9 Njẹ kili oluwa ọgba ajara na yio ṣe? On o wá, yio si pa awọn oluṣọgba wọnni run, yio si fi ọgba ajara rẹ̀ ṣe agbatọju fun awọn ẹlomiran. 10 Ẹnyin kò ha ti kà iwe-mimọ yi; Okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ on na li o di pàtaki igun ile: 11 Eyi ni ìṣe Oluwa, o si jẹ iyanu li oju wa?
12 Nwọn si nwá ọ̀na ati mu u, sugbọn nwọn si bẹ̀ru ijọ enia: nitori nwọn mọ̀ pe, awọn li o powe na mọ: nwọn si fi i silẹ, nwọn lọ.Ìbéèrè nípa Owó-orí ti Ìjọba Kesari
(Mat 22:15-22; Luk 20:20-26)
13 Nwọn si rán awọn kan si i ninu awọn Farisi, ati ninu awọn ọmọ-ẹhin Herodu, lati fi ọ̀rọ rẹ̀ mu u. 14 Nigbati nwọn si de, nwọn wi fun u pe, Olukọni, awa mọ̀ pe olotitọ ni iwọ bẹ̃ni iwọ kì iwoju ẹnikẹni: nitori iwọ kì iṣe ojuṣãju enia, ṣugbọn iwọ nkọ́ni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ: O tọ́ lati mã san owode fun Kesari, tabi kò tọ́? 15 Ki awa ki o fifun u, tabi ki a má fifun u? Ṣugbọn Jesu mọ̀ agabagebe wọn, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò? ẹ mu owo-idẹ kan fun mi wá ki emi ki o wò o. 16 Nwọn si mu u wá. O si bi wọn pe, Aworan ati akọle tali eyi? Nwọn si wi fun u pe, Ti Kesari ni.
17 Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti Ọlọrun fun Ọlọrun. Ẹnu si yà wọn si i gidigidi.Ìbéèrè Nípa Ajinde
(Mat 22:23-33; Luk 20:27-40)
18 Awọn Sadusi si tọ̀ ọ wá, awọn ti o wipe ajinde okú kò si; nwọn si bi i lẽre, wipe, 19 Olukọni, Mose kọwe fun wa pe, Bi arakunrin ẹnikan ba kú, ti o ba si fi aya silẹ, ti kò si fi ọmọ silẹ, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o si gbe iru-ọmọ dide fun arakunrin rẹ̀. 20 Njẹ awọn arakunrin meje kan ti wà: eyi ekini si gbé iyawo, o si kú lai fi ọmọ silẹ. 21 Eyi ekeji si ṣu u lopó, on si kú, bẹ̃li on kò si fi ọmọ silẹ: gẹgẹ bẹ̃ si li ẹkẹta. 22 Awọn mejeje si ṣu u lopó, nwọn kò si fi ọmọ silẹ: nikẹhin gbogbo wọn obinrin na kú pẹlu. 23 Njẹ li ajinde, nigbati nwọn ba jinde, aya tani yio ha ṣe ninu wọn? awọn mejeje li o sá ni i li aya? 24 Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ki ha ṣe nitori eyi li ẹ ṣe ṣina, pe ẹnyin kò mọ̀ iwe-mimọ, tabi agbara Ọlọrun? 25 Nitori nigbati nwọn o jinde kuro ninu okú, nwọn kò ni gbeyawo, bẹ̃ni nwọn kì yio sinni ni iyawo; ṣugbọn nwọn ó dabi awọn angẹli ti mbẹ li ọrun. 26 Ati niti awọn okú pe a o ji wọn dide: ẹnyin ko ti kà a ninu iwe Mose, bi Ọlọrun ti sọ fun u ninu igbẹ́, wipe, Emi li Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu?
27 On kì iṣe Ọlọrun awọn okú, bikọse Ọlọrun awọn alãye: nitorina ẹnyin ṣìna gidigidi.Òfin Tí Ó Ṣe Pataki Jùlọ
(Mat 22:34-40; Luk 10:25-28)
28 Ọkan ninu awọn akọwe tọ̀ ọ wá, nigbati o si gbọ́ bi nwọn ti mbi ara wọn li ere ọ̀rọ, ti o si woye pe, o da wọn lohùn rere, o bi i pe, Ewo li ekini ninu gbogbo ofin? 29 Jesu si da a lohùn, wipe, Ekini ninu gbogbo ofin ni, Gbọ́, Israeli; Oluwa Ọlọrun wa Oluwa kan ni. 30 Ki iwọ ki o si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo iye rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ: eyi li ofin ekini. 31 Ekeji si dabi rẹ̀, Fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ. Ko si si ofin miran, ti o tobi jù wọnyi lọ. 32 Akọwe na si wi fun u pe, Olukọni, o dara, otitọ li o sọ pe Ọlọrun kan ni mbẹ; ko si si omiran bikoṣe on: 33 Ati ki a fi gbogbo àiya, ati gbogbo òye, ati gbogbo ọkàn, ati gbogbo agbara fẹ ẹ, ati ki a fẹ ọmọnikeji ẹni bi ara-ẹni, o jù gbogbo ẹbọ-sisun ati ẹbọ lọ.
34 Nigbati Jesu ri i pe o fi òye dahùn, o wi fun u pe, Iwọ kò jìna si ijọba Ọlọrun. Lẹhin eyini, kò si ẹnikan ti o jẹ bi i lẽre ohunkan mọ́.Ìbéèrè Jesu Nípa Ọmọ Dafidi
(Mat 22:41-46; Luk 20:41-44)
35 Bi Jesu si ti nkọ́ni ni tẹmpili, o dahùn wipe, Ẽṣe ti awọn akọwe fi nwipe, Ọmọ Dafidi ni Kristi iṣe? 36 Nitori Dafidi tikararẹ̀ wi nipa Ẹmi Mimọ́ pe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ.
37 Njẹ bi Dafidi tikararẹ̀ ba pè e li Oluwa; nibo li o si ti wa ijẹ ọmọ rẹ̀? Ọpọ ijọ enia si fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀.Jesu ṣe Ìkìlọ̀ Nípa Àwọn Akọ̀wé
(Mat 23:1-36; Luk 20:45-47)
38 O si wi fun wọn ninu ẹkọ́ rẹ̀ pe, Ẹ mã kiyesara lọdọ awọn akọwe, ti nwọn fẹ lati mã rìn li aṣọ gigùn, ti nwọn si fẹ ikíni li ọjà, 39 Ati ibujoko ọlá ninu sinagogu, ati ipò ọla ni ibi ase;
40 Awọn ti o jẹ ile awọn opó run, ti nwọn si ngbadura gigun fun aṣehàn: awọn wọnyi ni yio jẹbi pọ̀ju.Ọrẹ Opó Kan
(Luk 21:1-4)
41 Jesu si joko kọjusi apoti iṣura, o si nwò bi ijọ enia ti nsọ owo sinu apoti iṣura: ọ̀pọ awọn ọlọrọ̀ si sọ pipọ si i. 42 Talakà opó kan si wá, o sọ owo idẹ wẹ́wẹ meji ti iṣe idameji owo-bàba kan sinu rẹ̀. 43 O si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, Talakà opó yi sọ sinu apoti iṣura jù gbogbo awọn ti o sọ sinu rẹ̀ lọ. 44 Nitori gbogbo nwọn sọ sinu rẹ̀ ninu ọ̀pọlọpọ ini wọn; ṣugbọn on ninu aini rẹ̀ o sọ ohun gbogbo ti o ni si i, ani gbogbo ini rẹ̀.
Mark 12
Parable of the Vine-growers
1 And He began to speak to them in parables: "A man PLANTED A VINEYARD AND PUT A WALL AROUND IT, AND DUG A VAT UNDER THE WINE PRESS AND BUILT A TOWER, and rented it out to tvine-growers and went on a journey.2 At the harvest time he sent a slave to the vine-growers, in order to receive some of the produce of the vineyard from the vine-growers.3 They took him, and beat him and sent him away empty-handed.4 Again he sent them another slave, and they wounded him in the head, and treated him shamefully.5 And he sent another, and that one they killed; and so with many others, beating some and killing others.6 He had one more to send, a beloved son; he sent him last of all to them, saying, 'They will respect my son.'7 But those vine-growers said to one another, 'This is the heir; come, let us kill him, and the inheritance will be ours!'8 They took him, and killed him and threw him out of the vineyard.9 What will the owner of the vineyard do? He will come and destroy the vine-growers, and will give the vineyard to others.10 Have you not even read this Scripture:
'THE STONE WHICH THE BUILDERS REJECTED,
THIS BECAME THE CHIEF CORNER stone;
11 THIS CAME ABOUT FROM THE LORD,
AND IT IS MARVELOUS IN OUR EYES'?"
12 And they were seeking to seize Him, and yet they feared the people, for they understood that He spoke the parable against them. And so they left Him and went away.
Jesus Answers the Pharisees, Sadducees and Scribes
13 Then they *sent some of the Pharisees and Herodians to Him in order to trap Him in a statement.14 They *came and *said to Him, "Teacher, we know that You are truthful and defer to no one; for You are not partial to any, but teach the way of God in truth. Is it lawful to pay a poll-tax to Caesar, or not?15 Shall we pay or shall we not pay?" But He, knowing their hypocrisy, said to them, "Why are you testing Me? Bring Me a tdenarius to look at."16 They brought one. And He *said to them, "Whose likeness and inscription is this?" And they said to Him, "Caesar's."17 And Jesus said to them, "Render to Caesar the things that are Caesar's, and to God the things that are God's." And they were amazed at Him.
18 Some Sadducees (who say that there is no resurrection) *came to Jesus, and began questioning Him, saying,19 "Teacher, Moses wrote for us that IF A MAN'S BROTHER DIES and leaves behind a wife AND LEAVES NO CHILD, HIS BROTHER SHOULD MARRY THE WIFE AND RAISE UP CHILDREN TO HIS BROTHER.20 There were seven brothers; and the first took a wife, and died leaving no children.21 The second one married her, and died leaving behind no children; and the third likewise;22 and so all seven left no children. Last of all the woman died also.23 In the resurrection, twhen they rise again, which one's wife will she be? For all seven had married her."24 Jesus said to them, "Is this not the reason you are mistaken, that you do not understand the Scriptures or the power of God?25 For when they rise from the dead, they neither marry nor are given in marriage, but are like angels in heaven.26 But regarding the fact that the dead rise again, have you not read in the book of Moses, in the passage about the burning bush, how God spoke to him, saying, 'I AM THE GOD OF ABRAHAM, AND THE GOD OF ISAAC, AND THE GOD OF JACOB'?27 He is not the God of the dead, but of the living; you are greatly mistaken."
28 One of the scribes came and heard them arguing, and recognizing that He had answered them well, asked Him, "What commandment is the foremost of all?"29 Jesus answered, "The foremost is, 'HEAR, O ISRAEL! THE LORD OUR GOD IS ONE LORD;30 AND YOU SHALL LOVE THE LORD YOUR GOD WITH ALL YOUR HEART, AND WITH ALL YOUR SOUL, AND WITH ALL YOUR MIND, AND WITH ALL YOUR STRENGTH.'31 The second is this, 'YOU SHALL LOVE YOUR NEIGHBOR AS YOURSELF.' There is no other commandment greater than these."32 The scribe said to Him, "Right, Teacher; You have truly stated that HE IS ONE, AND THERE IS NO ONE ELSE BESIDES HIM;33 AND TO LOVE HIM WITH ALL THE HEART AND WITH ALL THE UNDERSTANDING AND WITH ALL THE STRENGTH, AND TO LOVE ONE'S NEIGHBOR AS HIMSELF, is much more than all burnt offerings and sacrifices."34 When Jesus saw that he had answered intelligently, He said to him, "You are not far from the kingdom of God." After that, no one would venture to ask Him any more questions.
35 And Jesus began to say, as He taught in the temple, "How is it that the scribes say that the Christ is the son of David?36 David himself said in the Holy Spirit,
'THE LORD SAID TO MY LORD,
"SIT AT MY RIGHT HAND,
UNTIL I PUT YOUR ENEMIES BENEATH YOUR FEET."'37 David himself calls Him 'Lord'; so in what sense is He his son?" And the large crowd enjoyed listening to Him.
38 In His teaching He was saying: "Beware of the scribes who like to walk around in long robes, and like respectful greetings in the market places,39 and chief seats in the synagogues and places of honor at banquets,40 who devour widows' houses, and for appearance's sake offer long prayers; these will receive greater condemnation."
The Widow's Mite
41 And He sat down opposite the treasury, and began observing how the people were putting money into the treasury; and many rich people were putting in large sums.42 A poor widow came and put in two small copper coins, which amount to a cent.43 Calling His disciples to Him, He said to them, "Truly I say to you, this poor widow put in more than all the contributors to the treasury;44 for they all put in out of their surplus, but she, out of her poverty, put in all she owned, all she had to live on."