Mak 2
Jesu Wo Arọ Sàn
(Mat 9:1-8; Luk 5:17-26)
1 NIGBATI o si tún wọ̀ Kapernaumu lọ lẹhin ijọ melokan; okikí kàn yiká pe, o wà ninu ile. 2 Lojukanna ọ̀pọ enia si pejọ tobẹ̃ ti aye kò si fun wọn mọ, kò si, titi de ẹnu-ọ̀na: o si wasu ọ̀rọ na fun wọn. 3 Nwọn si wá sọdọ rẹ̀, nwọn gbé ẹnikan ti o li ẹ̀gba tọ̀ ọ wá, ẹniti mẹrin gbé. 4 Nigbati nwọn kò si le sunmọ ọ nitori ọ̀pọ enia, nwọn si ṣí orule ile nibiti o gbé wà: nigbati nwọn si da a lu tan, nwọn sọ akete na kalẹ lori eyiti ẹlẹgba na dubulẹ. 5 Nigbati Jesu ri igbagbọ́ wọn, o wi fun ẹlẹgba na pe, Ọmọ, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ. 6 Ṣugbọn awọn kan ninu awọn akọwe wà ti nwọn joko nibẹ̀, nwọn si ngbèro li ọkàn wọn, wipe, 7 Ẽṣe ti ọkunrin yi fi sọrọ bayi? o nsọ ọrọ-odi; tali o le dari eṣẹ jìni bikoṣe ẹnikan, aní Ọlọrun? 8 Lojukanna bi Jesu ti woye li ọkàn rẹ̀ pe, nwọn ngbèro bẹ̃ ninu ara wọn, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nrò nkan wọnyi ninu ọkàn nyin? 9 Ewo li o ya jù lati wi fun ẹlẹgba na pe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide, si gbé akete rẹ, ki o si ma rìn? 10 Ṣugbọn ki ẹ le mọ̀ pe, Ọmọ-enia li agbara li aiye lati dari ẹ̀ṣẹ jìni, (o wi fun ẹlẹgba na pe,) 11 Mo wi fun ọ, Dide, gbé akete rẹ, ki o si mã lọ ile rẹ.
12 O si dide lojukanna, o si gbé akete na, o si jade lọ li oju gbogbo wọn; tobẹ̃ ti ẹnu fi yà gbogbo wọn, nwọn si yìn Ọlọrun logo, wipe, Awa ko ri irú eyi rí.Jesu Pe Lefi
(Mat 9:9-13; Luk 5:27-32)
13 O si tún jade lọ si eti okun; gbogbo ijọ enia si wá sọdọ rẹ̀, o si kọ́ wọn. 14 Bi o si ti nkọja lọ, o ri Lefi ọmọ Alfeu, o joko ni bode, o si wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. O si dide, o tọ̀ ọ lẹhin. 15 O si ṣe, bi o si ti joko tì onjẹ ni ile rẹ̀, ọ̀pọ awọn agbowode ati ẹlẹṣẹ wá bá Jesu joko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: nitoriti nwọn pọ̀ nwọn si tọ̀ ọ lẹhin. 16 Nigbati awọn akọwe ati awọn Farisi si ri i ti o mbá awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹun, nwọn wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẽtiri ti o fi mba awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹ, ti o si mba wọn mu?
17 Nigbati Jesu gbọ́, o wi fun wọn pe, Awọn ti ara wọn le kì iwá oniṣegun, bikoṣe awọn ti ara wọn ko da: Emi ko wá lati pè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada.Ìbéèrè Nípa Ààwẹ̀ Gbígbà
(Mat 9:14-17; Luk 5:33-39)
18 Awọn ọmọ-ẹhin Johanu, ati awọn ọmọ-ẹhin awọn Farisi a ma gbàwẹ: nwọn si wá, nwọn si bi i pe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin Johanu, ati awọn ọmọ-ẹhin awọn Farisi fi ngbàwẹ, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko gbàwẹ? 19 Jesu si wi fun wọn pe, Ẹnyin le mu ki awọn ọmọ ile iyawo gbàwe, nigbati ọkọ iyawo mbẹ lọdọ wọn? niwọn igbati nwọn ni ọkọ iyawo lọdọ wọn, nwọn kò le gbàwẹ. 20 Ṣugbọn ọjọ mbọ̀ nigbati a o gbà ọkọ iyawo lọwọ wọn, nigbana ni nwọn o gbàwẹ ni ijọ wọnni. 21 Ko si ẹniti ifi idãsa aṣọ titun mọ ogbologbo ẹ̀wu; bi bẹ̃ko eyi titun ti a fi lẹ ẹ a fà ogbologbo ya, aṣọ a si ma ya siwaju.
22 Ko si ẹniti ifi ọti-waini titun sinu ogbologbo ìgo; bi bẹ̃kọ ọti-waini titun a bẹ́ ìgo na, ọti-waini a si danu, ìgo na a si fàya; ṣugbọn ọti-waini titun ni ã fi sinu ìgo titun.Ìbéèrè Nípa Ọjọ́ Ìsinmi
(Mat 12:1-8; Luk 6:1-5)
23 O si ṣe, bi Jesu ti nkọja lọ lãrin oko ọkà li ọjọ isimi; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bẹ̀rẹ si ima ya ipẹ́ ọkà bi nwọn ti nlọ. 24 Awọn Farisi si wi fun u pe, Wo o, ẽṣe ti nwọn fi nṣe eyi ti kò yẹ li ọjọ isimi? 25 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò ti kà ohun ti Dafidi ṣe, nigbati o ṣe alaini, ti ebi si npa a, on, ati awọn ti o wà lọdọ rẹ̀? 26 Bi o ti wọ̀ inu ile Ọlọrun lọ li ọjọ Abiatari olori alufa, ti o si jẹ akara ifihàn, ti ko tọ́ fun u lati jẹ bikoṣe fun awọn alufa, o si fifun awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pẹlu? 27 O si wi fun wọn pe, A dá ọjọ isimi nitori enia, a kò dá enia nitori ọjọ isimi: 28 Nitorina Ọmọ-enia li oluwa ọjọ isimi pẹlu.
Mark 2
The Paralytic Healed
1 When He had come back to Capernaum several days afterward, it was heard that He was at home.2 And many were gathered together, so that there was no longer room, not even near the door; and He was speaking the word to them.3 And they *came, bringing to Him a paralytic, carried by four men.4 Being unable to get to Him because of the crowd, they removed the roof above Him; and when they had dug an opening, they let down the pallet on which the paralytic was lying.5 And Jesus seeing their faith *said to the paralytic, "tSon, your sins are forgiven."6 But some of the scribes were sitting there and reasoning in their hearts,7 "Why does this man speak that way? He is blaspheming; who can forgive sins but God alone?"8 Immediately Jesus, aware in His spirit that they were reasoning that way within themselves, *said to them, "Why are you reasoning about these things in your hearts?9 Which is easier, to say to the paralytic, 'Your sins are forgiven'; or to say, 'Get up, and pick up your pallet and walk'?10 But so that you may know that the Son of Man has authority on earth to forgive sins"-He *said to the paralytic,11 "I say to you, get up, pick up your pallet and go home."12 And he got up and immediately picked up the pallet and went out in the sight of everyone, so that they were all amazed and were glorifying God, saying, "We have never seen anything like this."
13 And He went out again by the seashore; and all the people were coming to Him, and He was teaching them.
Levi (Matthew) Called
14 As He passed by, He saw Levi the son of Alphaeus sitting in the tax booth, and He *said to him, "Follow Me!" And he got up and followed Him.
15 And it *happened that He was reclining at the table in his house, and many tax collectors and sinners were dining with Jesus and His disciples; for there were many of them, and they were following Him.16 When the scribes of the Pharisees saw that He was eating with the sinners and tax collectors, they said to His disciples, "Why is He eating and drinking with tax collectors and sinners?"17 And hearing this, Jesus *said to them, "It is not those who are healthy who need a physician, but those who are sick; I did not come to call the righteous, but sinners."
18 John's disciples and the Pharisees were fasting; and they *came and *said to Him, "Why do John's disciples and the disciples of the Pharisees fast, but Your disciples do not fast?"19 And Jesus said to them, "While the bridegroom is with them, the attendants of the bridegroom cannot fast, can they? So long as they have the bridegroom with them, they cannot fast.20 But the days will come when the bridegroom is taken away from them, and then they will fast in that day.
21 "No one sews a patch of unshrunk cloth on an old garment; otherwise the patch pulls away from it, the new from the old, and a worse tear results.22 No one puts new wine into old wineskins; otherwise the wine will burst the skins, and the wine is lost and the skins as well; but one puts new wine into fresh wineskins."
Question of the Sabbath
23 And it happened that He was passing through the grainfields on the Sabbath, and His disciples began to make their way along while picking the heads of grain. 24 The Pharisees were saying to Him, "Look, why are they doing what is not lawful on the Sabbath?"25 And He *said to them, "Have you never read what David did when he was in need and he and his companions became hungry;26 how he entered the house of God in the time of Abiathar the high priest, and ate the consecrated bread, which is not lawful for anyone to eat except the priests, and he also gave it to those who were with him?"27 Jesus said to them, "The Sabbath was made for man, and not man for the Sabbath.28 So the Son of Man is Lord even of the Sabbath."