previous next

Mak 3

Ọkunrin Tí Ọwọ́ Rẹ̀ Rọ

(Mat 12:9-14; Luk 6:6-11)

1 O si tún wọ̀ inu sinagogu lọ; ọkunrin kan si mbẹ nibẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. 2 Nwọn si nṣọ ọ, bi yio mu u larada li ọjọ isimi; ki nwọn ki o le fi i sùn. 3 O si wi fun ọkunrin na ti ọwọ́ rẹ̀ rọ pe, Dide, duro larin. 4 O si wi fun wọn pe, O tọ́ lati mã ṣe rere li ọjọ isimi, tabi lati mã ṣe buburu? lati gbà ẹmí là, tabi lati pa a run? nwọn si dakẹ. 5 Nigbati o si fi ibinu wò gbogbo wọn yiká, ti inu rẹ̀ bajẹ nitori lile àiya wọn, o wi fun ọkunrin na pe, Nà ọwọ́ rẹ. O si nà a: ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò gẹgẹ bi ekeji.

6 Awọn Farisi jade lọ lojukanna lati ba awọn ọmọ-ẹhin Herodu gbìmọ pọ̀ si i, bi awọn iba ti ṣe pa a.

Ọpọlọpọ Eniyan Lẹ́bàá Òkun


7 Jesu pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si kuro nibẹ̀ lọ si eti okun: ijọ enia pipọ lati Galili ati Judea wá si tọ̀ ọ lẹhin, 8 Ati lati Jerusalemu, ati lati Idumea, ati lati oke odò Jordani, ati awọn ti o wà niha Tire on Sidoni, ijọ enia pipọ; nigbati nwọn gbọ́ ohun nla ti o ṣe, nwọn tọ̀ ọ wá. 9 O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn mu ọkọ̀ kekere kan sunmọ on, nitori ijọ enia, ki nwọn ki o má bà bilù u. 10 Nitoriti o mu ọ̀pọ enia larada; tobẹ̃ ti nwọn mbì ara wọn lù u lati fi ọwọ́ kàn a, iye awọn ti o li arùn. 11 Ati awọn ẹmi aimọ́, nigbàkugba ti nwọn ba ri i, nwọn a wolẹ niwaju rẹ̀, nwọn a kigbe soke, wipe, Iwọ li Ọmọ Ọlọrun. 12 O si kìlọ fun wọn gidigidi pe, ki nwọn ki o máṣe fi on hàn. 13 O si gùn ori òke lọ, o si npè ẹnikẹni ti o fẹ sọdọ rẹ̀: nwọn si tọ̀ ọ wá. 14 O si yàn awọn mejila, ki nwọn ki o le mã gbé ọdọ rẹ̀, ati ki o le ma rán wọn lọ lati wasu, 15 Ati lati li agbara lati wò arunkarun san, ati lati lé awọn ẹmi èṣu jade: 16 Simoni ẹniti o si sọ apele rẹ̀ ni Peteru; 17 Ati Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin Jakọbu; o si sọ apele wọn ni Boanerge, eyi ti ijẹ Awọn ọmọ ãrá: 18 Ati Anderu, ati Filippi, ati Bartolomeu, ati Matiu, ati Tomasi, ati Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Taddeu, ati Simoni ti a npè ni Selote,

19 Ati Judasi Iskariotu, ẹniti o si fi i hàn pẹlu: nwọn si wọ̀ ile kan lọ.

Jesu ati Beelisebulu

(Mat 12:22-32, Luk 11:14-23, 12:10)


20 Ijọ enia si tún wọjọ pọ̀, ani tobẹ̃ ti nwọn ko tilẹ le jẹ onjẹ. 21 Nigbati awọn ibatan rẹ̀ si gbọ́ eyini, nwọn jade lọ lati mu u: nitoriti nwọn wipe, Ori rẹ̀ bajẹ. 22 Awọn akọwe ti o ti Jerusalemu sọkalẹ wá, wipe, O ni Beelsebubu, olori awọn ẹmi èṣu li o si fi nlé awọn ẹmi èṣu jade. 23 O si pè wọn sọdọ rẹ̀, o si fi owe ba wọn sọrọ pe, Satani yio ti ṣe le lé Satani jade? 24 Bi ijọba kan ba si yàpa si ara rẹ̀, ijọba na kì yio le duro. 25 Bi ile kan ba si yàpa si ara rẹ̀, ile na kì yio le duro. 26 Bi Satani ba si dide si ara rẹ̀, ti o si yàpa, on kì yio le duro, ṣugbọn yio ni opin. 27 Kò si ẹniti o le wọ̀ ile ọkunrin alagbara kan lọ, ki o si kó o li ẹrù lọ, bikoṣepe o tètekọ dè ọkunrin alagbara na li okùn; nigbana ni yio le kó o li ẹrù ni ile. 28 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Gbogbo ẹ̀ṣẹ li a o dari wọn jì awọn ọmọ enia, ati gbogbo ọrọ-odi nipa eyiti nwọn o ma fi sọrọ-odi: 29 Ṣugbọn ẹniti o ba sọrọ-odi si Ẹmi Mimọ́ kì yio ni idariji titi lai, ṣugbọn o wà ninu ewu ẹbi ainipẹkun:

30 Nitoriti nwọn wipe, O li ẹmi aimọ́.

Àwọn Ta ni Ẹbí Jesu?

(Mat 12:46-50; Luk 8:19-21)


31 Nigbana li awọn arakunrin rẹ̀ ati iya rẹ̀ wá, nwọn duro lode, nwọn si ranṣẹ si i, nwọn npè e. 32 Awọn ọ̀pọ enia si joko lọdọ rẹ̀, nwọn si wi fun u pe, Wò o, iya rẹ ati awọn arakunrin rẹ nwá ọ lode. 33 O si da wọn lohùn, wipe, Tani iṣe iya mi, tabi awọn arakunrin mi? 34 O si wò gbogbo awọn ti o joko lọdọ rẹ̀ yiká, o si wipe, Wò iya mi ati awọn arakunrin mi: 35 Nitori ẹnikẹni ti o ba ṣe ifẹ Ọlọrun, on na li arakunrin mi, ati arabinrin mi, ati iya mi.

Mark 3

Jesus Heals on the Sabbath

1 He entered again into a synagogue; and a man was there whose hand was withered.2 They were watching Him to see if He would heal him on the Sabbath, so that they might accuse Him.3 He *said to the man with the withered hand, "Get up and come forward!"4 And He *said to them, "Is it lawful to do good or to do harm on the Sabbath, to save a life or to kill?" But they kept silent.5 After looking around at them with anger, grieved at their hardness of heart, He *said to the man, "Stretch out your hand." And he stretched it out, and his hand was restored.6 The Pharisees went out and immediately began conspiring with the Herodians against Him, as to how they might destroy Him.

7 Jesus withdrew to the sea with His disciples; and a great multitude from Galilee followed; and also from Judea,8 and from Jerusalem, and from Idumea, and beyond the Jordan, and the vicinity of Tyre and Sidon, a great number of people heard of all that He was doing and came to Him.9 And He told His disciples that a boat should stand ready for Him because of the crowd, so that they would not crowd Him;10 for He had healed many, with the result that all those who had afflictions pressed around Him in order to touch Him.11 Whenever the unclean spirits saw Him, they would fall down before Him and shout, "You are the Son of God!"12 And He earnestly warned them not to tell who He was.

The Twelve Are Chosen

13 And He *went up on the mountain and *summoned those whom He Himself wanted, and they came to Him.14 And He appointed twelve, so that they would be with Him and that He could send them out to preach,15 and to have authority to cast out the demons.16 And He appointed the twelve: Simon (to whom He gave the name Peter),17 and James, the son of Zebedee, and John the brother of James (to them He gave the name Boanerges, which means, "Sons of Thunder");18 and Andrew, and Philip, and Bartholomew, and Matthew, and Thomas, and James the son of Alphaeus, and Thaddaeus, and Simon the Zealot;19 and Judas Iscariot, who betrayed Him.

20 And He *came thome, and the crowd *gathered again, to such an extent that they could not even eat a meal.21 When His own tpeople heard of this, they went out to take custody of Him; for they were saying, "He has lost His senses."22 The scribes who came down from Jerusalem were saying, "He is possessed by Beelzebul," and "He casts out the demons by the ruler of the demons."23 And He called them to Himself and began speaking to them in parables, "How can Satan cast out Satan?24 If a kingdom is divided against itself, that kingdom cannot stand.25 If a house is divided against itself, that house will not be able to stand.26 If Satan has risen up against himself and is divided, he cannot stand, but he is finished!27 But no one can enter the strong man's house and plunder his property unless he first binds the strong man, and then he will plunder his house.

28 "Truly I say to you, all sins shall be forgiven the sons of men, and whatever blasphemies they utter;29 but whoever blasphemes against the Holy Spirit never has forgiveness, but is guilty of an eternal sin"-30 because they were saying, "He has an unclean spirit."

31 Then His mother and His brothers *arrived, and standing outside they sent word to Him and called Him.32 A crowd was sitting around Him, and they *said to Him, "Behold, Your mother and Your brothers are outside looking for You."33 Answering them, He *said, "Who are My mother and My brothers?"34 Looking about at those who were sitting around Him, He *said, "Behold My mother and My brothers!35 For whoever does the will of God, he is My brother and sister and mother."