Mak 4
Òwe Nípa Afunrugbin
(Mat 13:1-9; Luk 8:4-8)
1 O si tún bẹ̀rẹ si ikọni leti okun: ọ̀pọ ijọ enia si pejọ sọdọ rẹ̀, tobẹ̃ ti o bọ́ sinu ọkọ̀ kan, o si joko ninu okun; gbogbo awọn enia si wà ni ilẹ leti okun. 2 O si fi owe kọ́ wọn li ohun pipọ, o si wi fun wọn ninu ẹkọ́ rẹ̀ pe, 3 Ẹ fi eti silẹ; Wo o, afunrugbin kan jade lọ ifunrugbin; 4 O si ṣe, bi o ti nfunrugbin, diẹ bọ́ si ẹba ọ̀na, awọn ẹiyẹ si wá, nwọn si ṣà a jẹ. 5 Diẹ si bọ́ sori ilẹ apata, nibiti kò li erupẹ̀ pipọ; lojukanna o si ti hù jade, nitoriti kò ni ijinlẹ: 6 Ṣugbọn nigbati õrùn goke, o jóna; nitoriti kò ni gbongbo, o gbẹ. 7 Diẹ si bọ́ sarin ẹgún, nigbati ẹgún si dàgba soke, o fun u pa, kò si so eso. 8 Omiran si bọ́ si ilẹ rere, o si so eso, ti o ndagba ti o si npọ̀; o si mu eso jade wá, omiran ọgbọgbọn, omiran ọgọtọta, omiran ọgọrọ̀run.
9 O si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ, ki o gbọ́.Ìdí Tí Jesu Fi Ń Lo Òwe
(Mat 13:10-17; Luk 8:9-10)
10 Nigbati o kù on nikan, awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ pẹlu awọn mejila bi i lẽre idi owe na. 11 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li a fifun lati mọ̀ ohun ijinlẹ ijọba Ọlọrun: ṣugbọn fun awọn ti o wà lode, gbogbo ohun wọnyi li a nfi owe sọ fun wọn:
12 Nitori ni ríri ki nwọn ki o le ri, ki nwọn má si kiyesi; ati ni gbigbọ́ ki nwọn ki o le gbọ́, ki o má si yé wọn; ki nwọn ki o má ba yipada, ki a má ba dari jì wọn.Ìtumọ̀ Òwe Nípa Afunrugbin
(Mat 13:18-23; Luk 8:11-15)
13 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò mọ̀ owe yi? ẹnyin o ha ti ṣe le mọ̀ owe gbogbo? 14 Afunrugbin funrugbin ọ̀rọ na. 15 Awọn wọnyi si ni ti ẹba ọ̀na, nibiti a funrugbin ọ̀rọ na; nigbati nwọn si ti gbọ́, lojukanna Satani wá, o si mu ọ̀rọ na ti a fọn si àiya wọn kuro. 16 Awọn wọnyi pẹlu si li awọn ti a fun sori ilẹ apata; awọn ẹniti nigbati nwọn ba gbọ́ ọ̀rọ na, lojukanna nwọn a fi ayọ̀ gbà a; 17 Nwọn kò si ni gbongbo ninu ara wọn, ṣugbọn nwọn a wà fun ìgba diẹ: lẹhinna nigbati wahalà tabi inunibini ba dide nitori ọ̀rọ na, lojukanna nwọn a kọsẹ̀. 18 Awọn wọnyi li awọn ti a fun sarin ẹgún; awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na, 19 Aniyan aiye, ati itanjẹ ọrọ̀, ati ifẹkufẹ ohun miran si bọ sinu wọn, nwọn fún ọ̀rọ na pa, bẹ̃li o si jẹ alaileso.
20 Awọn wọnyi si li eyi ti a fún si ilẹ rere; irú awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na, ti wọn si gbà a, ti wọn si so eso, omiran ọgbọgbọ̀n, omiran ọgọtọta, omiran ọgọrọrun.Fìtílà Tí A Fi Òṣùwọ̀n Bò
(Luk 8:16-18)
21 O si wi fun wọn pe, A ha gbé fitilà wá lati fi sabẹ òṣuwọn, tabi sabẹ akete, ki a ma si ṣe gbé e kà ori ọpá fitilà? 22 Nitori kò si ohun ti o pamọ́ bikoṣe ki a le fi i hàn; bẹ̃ni kò si ohun ti o wà ni ikọkọ, bikoṣepe ki o le yọ si gbangba. 23 Bi ẹnikẹni ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́. 24 O si wi fun wọn pe, Ẹ mã kiyesi ohun ti ẹnyin ngbọ́: òṣuwọn ti ẹnyin ba fi wọ̀n, on li a o fi wọ̀n fun nyin: a o si fi kún u fun nyin.
25 Nitori ẹniti o ba ni, on li a o fifun: ati ẹniti kò ba si ni, lọwọ rẹ̀ li a o si gbà eyi na ti o ni.Òwe Nípa Ìdàgbà Irúgbìn
26 O si wipe, Bẹ̃ sá ni ijọba Ọlọrun, o dabi ẹnipe ki ọkunrin kan funrugbin sori ilẹ; 27 Ki o si sùn, ki o si dide li oru ati li ọsán, ki irugbin na ki o si sọ jade ki o si dàgba, on kò si mọ̀ bi o ti ri. 28 Nitori ilẹ a ma so eso jade fun ara rẹ̀; ekini ẽhù, lẹhinna ipẹ́, lẹhinna ikunmọ ọkà ninu ipẹ́.
29 Ṣugbọn nigbati eso ba pọ́n tan, lojukanna on a tẹ̀ doje bọ inu rẹ̀ nitori igba ikorè de.Òwe Nípa Wóró Mustardi
(Mat 13:31-32; Luk 13:18-19)
30 O si wipe, Kili a o fi ijọba Ọlọrun we? tabi kili a ba fi ṣe akawe rẹ̀? 31 O dabi wóro irugbin mustardi, eyiti, nigbati a gbin i si ilẹ, bi o tilẹ ṣe pe o kére jù gbogbo irugbin ti o wa ni ilẹ lọ,
32 Sibẹ nigbati a gbin i o dàgba soke, o si di titobi jù gbogbo ewebẹ lọ, o si pa ẹká nla; tobẹ ti awọn ẹiyẹ oju ọrun le ma gbe abẹ ojiji rẹ̀.Jesu Ń Fi Òwe Pupọ Sọ̀rọ̀
(Mat 13:34-35)
33 Irù ọ̀pọ owe bẹ̃ li o fi mba wọn nsọ̀rọ, niwọn bi nwọn ti le gbà a si.
34 Ṣugbọn on kì iba wọn sọrọ laìsi owe: nigbati o ba si kù awọn nikan, on a si sọ idi ohun gbogbo fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.Jesu Bá Ìgbì Omi Wí
(Mat 8:23-37; Luk 8:22-25)
35 Ni ijọ kanna, nigbati alẹ lẹ tan, o wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki a rekọja lọ si apá keji. 36 Nigbati nwọn si ti tu ijọ ká, nwọn si gbà a gẹgẹ bi o ti wà sinu ọkọ̀. Awọn ọkọ̀ kekere miran pẹlu si wà lọdọ rẹ̀. 37 Ìji nla si dide, ìgbi si mbù sinu ọkọ̀, tobẹ̃ ti ọkọ̀ fi bẹ̀rẹ si ikún. 38 On pãpã si wà ni idi ọkọ̀, o nsùn lori irọri: nwọn si jí i, nwọn si wi fun u pe, Olukọni, iwọ ko bikita bi awa ṣegbé? 39 O si ji, o ba afẹfẹ na wi, o si wi fun okun pe, Dakẹ jẹ. Afẹfẹ si da, iparọrọ nla si de. 40 O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe ojo bẹ̃? ẹ kò ti iní igbagbọ sibẹ? 41 Ẹru si ba wọn gidigidi, nwọn si nwi fun ara wọn pe, Irú enia kili eyi, ti ati afẹfẹ ati okun gbọ́ tirẹ̀?
Mark 4
Parable of the Sower and Soils
1 He began to teach again by the sea. And such a very large crowd gathered to Him that He got into a boat in the sea and sat down; and the whole crowd was by the sea on the land.2 And He was teaching them many things in parables, and was saying to them in His teaching,3 "Listen to this! Behold, the sower went out to sow;4 as he was sowing, some seed fell beside the road, and the birds came and ate it up.5 Other seed fell on the rocky ground where it did not have much soil; and immediately it sprang up because it had no depth of soil.6 And after the sun had risen, it was scorched; and because it had no root, it withered away.7 Other seed fell among the thorns, and the thorns came up and choked it, and it yielded no crop.8 Other seeds fell into the good soil, and as they grew up and increased, they yielded a crop and produced thirty, sixty, and a hundredfold."9 And He was saying, "He who has ears to hear, let him hear."
10 As soon as He was alone, His followers, along with the twelve, began asking Him about the parables.11 And He was saying to them, "To you has been given the mystery of the kingdom of God, but those who are outside get everything in parables,12 so that WHILE SEEING, THEY MAY SEE AND NOT PERCEIVE, AND WHILE HEARING, THEY MAY HEAR AND NOT UNDERSTAND, OTHERWISE THEY MIGHT RETURN AND BE FORGIVEN."
Explanation
13 And He *said to them, "Do you not understand this parable? How will you understand all the parables?14 The sower sows the word.15 These are the ones who are beside the road where the word is sown; and when they hear, immediately Satan comes and takes away the word which has been sown in them.16 In a similar way these are the ones on whom seed was sown on the rocky places, who, when they hear the word, immediately receive it with joy;17 and they have no firm root in themselves, but are only temporary; then, when affliction or persecution arises because of the word, immediately they fall away.18 And others are the ones on whom seed was sown among the thorns; these are the ones who have heard the word,19 but the worries of the tworld, and the deceitfulness of riches, and the desires for other things enter in and choke the word, and it becomes unfruitful.20 And those are the ones on whom seed was sown on the good soil; and they hear the word and accept it and bear fruit, thirty, sixty, and a hundredfold."
21 And He was saying to them, "A lamp is not brought to be put under a basket, is it, or under a bed? Is it not brought to be put on the lampstand?22 For nothing is hidden, except to be revealed; nor has anything been secret, but that it would come to light.23 If anyone has ears to hear, let him hear."24 And He was saying to them, "Take care what you listen to. By your standard of measure it will be measured to you; and more will be given you besides.25 For whoever has, to him more shall be given; and whoever does not have, even what he has shall be taken away from him."
Parable of the Seed
26 And He was saying, "The kingdom of God is like a man who casts seed upon the soil;27 and he goes to bed at night and gets up by day, and the seed sprouts and grows-how, he himself does not know.28 The soil produces crops by itself; first the blade, then the head, then the mature grain in the head.29 But when the crop permits, he immediately puts in the sickle, because the harvest has come."
Parable of the Mustard Seed
30 And He said, "How shall we tpicture the kingdom of God, or by what parable shall we present it?31 It is like a mustard seed, which, when sown upon the soil, though it is smaller than all the seeds that are upon the soil,32 yet when it is sown, it grows up and becomes larger than all the garden plants and forms large branches; so that THE BIRDS OF THE tAIR can NEST UNDER ITS SHADE."
33 With many such parables He was speaking the word to them, so far as they were able to hear it;34 and He did not speak to them without a parable; but He was explaining everything privately to His own disciples.
Jesus Stills the Sea
35 On that day, when evening came, He *said to them, "Let us go over to the other side."36 Leaving the crowd, they *took Him along with them in the boat, just as He was; and other boats were with Him.37 And there *arose a fierce gale of wind, and the waves were breaking over the boat so much that the boat was already filling up.38 Jesus Himself was in the stern, asleep on the cushion; and they *woke Him and *said to Him, "Teacher, do You not care that we are perishing?"39 And He got up and rebuked the wind and said to the sea, "Hush, be still." And the wind died down and it became perfectly calm.40 And He said to them, "Why are you afraid? Do you still have no faith?"41 They became very much afraid and said to one another, "Who then is this, that even the wind and the sea obey Him?"