Mat 10
Jesu fún Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Mejila Láṣẹ
(Mak 3:13-19; Luk 6:12-16)
1 NIGBATI o si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejejila si ọdọ, o fi agbara fun wọn lori awọn ẹmi aimọ́, lati ma lé wọn jade ati lati ṣe iwòsan gbogbo àrun ati gbogbo aisan. 2 Orukọ awọn aposteli mejila na ni wọnyi: Eyi ekini ni Simoni, ẹniti a npè ni Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀; Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀; 3 Filippi, ati Bartolomeu; Tomasi, ati Matiu ti iṣe agbowode; Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Lebbeu, ẹniti a si npè ni Taddeu;
4 Simoni ara Kana, ati Judasi Iskariotu, ẹniti o fi i hàn.Iṣẹ́ tí Jesu Rán Àwọn Aposteli Mejila
(Mak 6:7-13; Luk 9:1-6)
5 Awọn mejejila wọnyi ni Jesu rán lọ, o si paṣẹ fun wọn pe, Ẹ máṣe lọ si ọ̀na awọn keferi, ẹ má si ṣe wọ̀ ilu awọn ará Samaria; 6 Ṣugbọn ẹ kuku tọ̀ awọn agutan ile Israeli ti o nù lọ. 7 Bi ẹnyin ti nlọ, ẹ mã wasu, wipe, Ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ. 8 Ẹ mã ṣe dida ara fun awọn olokunrùn, ẹ sọ awọn adẹtẹ̀ di mimọ́, ẹ si jí awọn okú dide, ki ẹ si mã lé awọn ẹmi èṣu jade: ọfẹ li ẹnyin gbà, ọfẹ ni ki ẹ fi funni. 9 Ẹ máṣe pèse wura, tabi fadaka, tabi idẹ sinu aṣuwọn nyin; 10 Tabi àpo fun àjo nyin, ki ẹ máṣe mu ẹwu meji, tabi bata, tabi ọpá; onjẹ oniṣẹ yẹ fun u. 11 Ilu-kilu tabi iletò-kileto ti ẹnyin ba wọ̀, ẹ wá ẹniti o ba yẹ nibẹ ri, nibẹ̀ ni ki ẹ si gbé titi ẹnyin o fi kuro nibẹ̀. 12 Nigbati ẹnyin ba si wọ̀ ile kan, ẹ kí i. 13 Bi ile na ba si yẹ, ki alafia nyin ki o bà sori rẹ̀; ṣugbọn bi ko ba yẹ, ki alafia nyin ki o pada sọdọ nyin. 14 Ẹnikẹni ti kò ba si gbà nyin, ti kò si gbọ́ ọ̀rọ nyin, nigbati ẹnyin ba jade kuro ni ile na tabi ni ilu na, ẹ gbọ̀n ekuru ẹsẹ nyin silẹ.
15 Lõtọ ni mo wi fun nyin, yio san fun ilẹ Sodomu ati Gomorra li ọjọ idajọ jù fun ilu na lọ.Inúnibíni tí Ó Ń Bọ̀
(Mak 13:9-13; Luk 21:12-17)
16 Wo o, mo rán nyin lọ gẹgẹ bi agutan sãrin ikõkò; nitorina ki ẹnyin ki o gbọ́n bi ejò, ki ẹ si ṣe oniwà tutù bi àdaba. 17 Ṣugbọn ẹ ṣọra lọdọ enia; nitori nwọn o fi nyin le ajọ igbimọ lọwọ, nwọn o si nà nyin ninu sinagogu wọn. 18 A o si mu nyin lọ siwaju awọn bãlẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn ati si awọn keferi. 19 Nigbati nwọn ba si fi nyin le wọn lọwọ, ẹ máṣe ṣàniyan pe, bawo tabi kili ẹnyin o wi? nitoriti a o fi ohun ti ẹnyin o wi fun nyin ni wakati kanna. 20 Nitoripe ki iṣe ẹnyin li o nsọ, ṣugbọn Ẹmí Baba nyin ni nsọ ninu nyin. 21 Arakunrin yio si fi arakunrin rẹ̀ fun pipa, ati baba yio si fi ọmọ rẹ̀ fun pipa: awọn ọmọ yio si dide si awọn obi wọn nwọn o si mu ki a pa wọn. 22 Gbogbo enia yio si korira nyin nitori orukọ mi; ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na ni a ó gbalà. 23 Ṣugbọn nigbati nwọn ba ṣe inunibini si nyin ni ilu yi, ẹ sá lọ si omiran: lõtọ ni mo sá wi fun nyin, ẹnyin kì ó le rekọja gbogbo ilu Israeli tan titi Ọmọ enia ó fi de. 24 Ọmọ-ẹhin kì ijù olukọ rẹ̀ lọ, bẹ̃ni ọmọ-ọdọ ẹni ki ijù oluwa rẹ̀ lọ.
25 O to fun ọmọ-ẹhin ki o dabi olukọ rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ ki o dabi oluwa rẹ̀. Bi nwọn ba pè bãle ile ni Beelsebubu, melomelo ni awọn ara ile rẹ̀?Ẹni tí Ó Yẹ Ká Bẹ̀rù
(Luk 12:2-7)
26 Nitorina ẹ má fòiya wọn; nitoriti ko si ohun ti a bò, ti ki o farahàn; ati eyi ti o farasin, ti a ki yio mọ̀. 27 Ohun ti mo ba wi fun nyin li òkunkun, on ni ki ẹnyin ki o sọ ni imọlẹ; ati eyi ti ẹnyin gbọ́ si etí ni ki ẹ kede rẹ̀ lori ile. 28 Ẹ má fòiya awọn ẹniti ipa ara, ṣugbọn ti nwọn ko le pa ọkàn: ṣugbọn ẹ kuku fòiya ẹniti o le pa ara ati ọkàn run li ọrun apadi. 29 Ologoṣẹ meji ki a ntà ni owo idẹ kekere kan? bẹ̃ni ko si ọkan ninu wọn ti yio ṣubu silẹ lẹhin Baba nyin. 30 Ṣugbọn gbogbo irun ori nyin li a kà pé ṣanṣan.
31 Nitorina ẹ má fòiya; ẹnyin ni iye lori jù ọ̀pọ ologoṣẹ lọ.Ìjẹ́wọ́ Kristi níwájú Eniyan
(Luk 12:8-9)
32 Nitorina ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju enia, on li emi o jẹwọ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun.
33 Ṣugbọn bi ẹnikan ba si sẹ mi niwaju enia, on na li emi o sẹ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun.Ọ̀rọ̀ nípa Jesu Dá Ìyapa Sílẹ̀
(Luk 12:51-53; 14:26-27)
34 Ẹ máṣe rò pe emi wá rán alafia si aiye, emi ko wá rán alafia bikoṣe idà. 35 Mo wá lati yà ọmọkunrin ni ipa si baba rẹ̀, ati ọmọbinrin ni ipa si iya rẹ̀, ati ayamọ si iyakọ rẹ̀. 36 Awọn ara-ile enia si li ọta rẹ̀. 37 Ẹniti o ba fẹ baba tabi iya jù mi lọ, kò yẹ ni temi: ẹniti o ba si fẹ ọmọkunrin tabi ọmọbinrin jù mi lọ, kò si yẹ ni temi. 38 Ẹniti kò ba si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin, kò yẹ ni temi.
39 Ẹniti o ba ri ẹmi rẹ̀, yio sọ ọ nù; ẹniti o ba si sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi, on ni yio si ri i.Èrè
(Mak 9:41)
40 Ẹniti o ba gbà nyin, o gbà mi; ẹniti o ba si gbà mi, o gbà ẹniti o rán mi. 41 Ẹniti o ba gbà wolĩ li orukọ wolĩ, yio jẹ ère wolĩ; ẹniti o ba si gbà olododo li orukọ olododo yio jẹ ère olododo. 42 Ẹnikẹni ti o ba fi kìki ago omi tutù fun ọkan ninu awọn onirẹlẹ wọnyi mu nitori orukọ ọmọ-ẹhin, lõtọ ni mo wi fun nyin, kì o padanù ère rẹ̀.
Matthew 10
The Twelve Disciples; Instructions for Service
1 Jesus summoned His twelve disciples and gave them authority over unclean spirits, to cast them out, and to heal every kind of disease and every kind of sickness.
2 Now the names of the twelve apostles are these: The first, Simon, who is called Peter, and Andrew his brother; and James the son of Zebedee, and John his brother;3 Philip and Bartholomew; Thomas and Matthew the tax collector; James the son of Alphaeus, and Thaddaeus;4 Simon the Zealot, and Judas Iscariot, the one who betrayed Him.
5 These twelve Jesus sent out after instructing them: "Do not go in the way of the Gentiles, and do not enter any city of the Samaritans;6 but rather go to the lost sheep of the house of Israel.7 And as you go, preach, saying, 'The kingdom of heaven is at hand.'8 Heal the sick, raise the dead, cleanse the lepers, cast out demons. Freely you received, freely give.9 Do not acquire gold, or silver, or copper for your money belts,10 or a bag for your journey, or even two coats, or sandals, or a staff; for the worker is worthy of his support.11 And whatever city or village you enter, inquire who is worthy in it, and stay at his house until you leave that city.12 As you enter the house, give it your greeting.13 If the house is worthy, give it your blessing of peace. But if it is not worthy, take back your blessing of peace.14 Whoever does not receive you, nor heed your words, as you go out of that house or that city, shake the dust off your feet.15 Truly I say to you, it will be more tolerable for the land of Sodom and Gomorrah in the day of judgment than for that city.
A Hard Road before Them
16 "Behold, I send you out as sheep in the midst of wolves; so be shrewd as serpents and innocent as doves.17 But beware of men, for they will hand you over to the courts and scourge you in their synagogues;18 and you will even be brought before governors and kings for My sake, as a testimony to them and to the Gentiles.19 But when they hand you over, do not worry about how or what you are to say; for it will be given you in that hour what you are to say.20 For it is not you who speak, but it is the Spirit of your Father who speaks in you.
21 "Brother will betray brother to death, and a father his child; and children will rise up against parents and cause them to be put to death.22 You will be hated by all because of My name, but it is the one who has endured to the end who will be saved.
23 "But whenever they persecute you in one city, flee to the next; for truly I say to you, you will not finish going through the cities of Israel until the Son of Man comes.
The Meaning of Discipleship
24 "A disciple is not above his teacher, nor a slave above his master.25 It is enough for the disciple that he become like his teacher, and the slave like his master. If they have called the head of the house Beelzebul, how much more will they malign the members of his household!
26 "Therefore do not fear them, for there is nothing concealed that will not be revealed, or hidden that will not be known.27 What I tell you in the darkness, speak in the light; and what you hear whispered in your ear, proclaim upon the housetops.28 Do not fear those who kill the body but are unable to kill the soul; but rather fear Him who is able to destroy both soul and body in hell.29 Are not two sparrows sold for a tcent? And yet not one of them will fall to the ground apart from your Father.30 But the very hairs of your head are all numbered.31 So do not fear; you are more valuable than many sparrows.
32 "Therefore everyone who confesses Me before men, I will also confess him before My Father who is in heaven.33 But whoever denies Me before men, I will also deny him before My Father who is in heaven.
34 "Do not think that I came to bring peace on the earth; I did not come to bring peace, but a sword.35 For I came to SET A MAN AGAINST HIS FATHER, AND A DAUGHTER AGAINST HER MOTHER, AND A DAUGHTER-IN-LAW AGAINST HER MOTHER-IN-LAW;36 and A MAN'S ENEMIES WILL BE THE MEMBERS OF HIS HOUSEHOLD.
37 "He who loves father or mother more than Me is not worthy of Me; and he who loves son or daughter more than Me is not worthy of Me.38 And he who does not take his cross and follow after Me is not worthy of Me.39 He who has found his life will lose it, and he who has lost his life for My sake will find it.
The Reward of Service
40 "He who receives you receives Me, and he who receives Me receives Him who sent Me.41 He who receives a prophet in the name of a prophet shall receive a prophet's reward; and he who receives a righteous man in the name of a righteous man shall receive a righteous man's reward.42 And whoever in the name of a disciple gives to one of these little ones even a cup of cold water to drink, truly I say to you, he shall not lose his reward."