previous next

Mat 21

Jesu Fi Ẹ̀yẹ Wọ Jerusalẹmu

(Mak 11:1-11; Luk 19:28-38; Joh 12:12-19)

1 NIGBATI nwọn sunmọ eti Jerusalemu, ti nwọn de Betfage li òke Olifi, nigbana ni Jesu rán awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ meji lọ. 2 O wi fun wọn pe, Ẹ lọ si iletò ti o kọju si nyin, lọgan ẹnyin o ri kẹtẹkẹtẹ kan ti a so ati ọmọ rẹ̀ pẹlu: ẹ tú wọn, ki ẹ si fà wọn fun mi wá. 3 Bi ẹnikẹni ba si wi nkan fun nyin, ẹnyin o wipe, Oluwa ni ifi wọn ṣe; lọgán ni yio si rán wọn wá. 4 Gbogbo eyi li a ṣe, ki eyi ti a ti sọ lati ẹnu wolĩ wá ki o le ṣẹ, pe, 5 Ẹ sọ fun ọmọbinrin Sioni pe, Kiyesi i, Ọba rẹ mbọ̀ wá sọdọ rẹ, o ni irẹlẹ, o joko lori kẹtẹkẹtẹ, ati lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ. 6 Awọn ọmọ-ẹhin na si lọ, nwọn ṣe bi Jesu ti wi fun wọn. 7 Nwọn si fà kẹtẹkẹtẹ na wá, ati ọmọ rẹ̀, nwọn si tẹ́ aṣọ wọn si ẹhin wọn, nwọn si gbé Jesu kà a. 8 Ọ̀pọ ijọ enia tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na; ẹlomiran ṣẹ́ ẹka igi wẹ́wẹ́, nwọn si fún wọn si ọ̀na. 9 Ijọ enia ti nlọ niwaju, ati eyi ti ntọ̀ wọn lẹhin, nkigbe wipe, Hosanna fun Ọmọ Dafidi: Olubukun li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa; Hosanna loke ọrun. 10 Nigbati o de Jerusalemu, gbogbo ilu mì titi, wipe, Tani yi?

11 Ijọ enia si wipe, Eyi ni Jesu wolĩ, lati Nasareti ti Galili.

Jesu Fòpin sí Ìwà Ìbàjẹ́ ninu Tẹmpili

(Mak 11:15-19; Luk 19:45-48; Joh 2:13-22)


12 Jesu si wọ̀ inu tẹmpili Ọlọrun lọ, o si lé gbogbo awọn ẹniti ntà, ati awọn ti nrà ni tẹmpili jade, o si yi tabili awọn onipaṣiparọ owo danù, ati ijoko awọn ti ntà ẹiyẹle. 13 O si wi fun wọn pe, A ti kọ ọ pe, Ile adura li a ó ma pè ile mi; ṣugbọn ẹnyin sọ ọ di ihò ọlọṣà. 14 Ati awọn afọju ati awọn amukun wá sọdọ rẹ̀ ni tẹmpili; o si mu wọn larada. 15 Ṣugbọn nigbati awọn olori alufa ati awọn akọwe ri ohun iyanu ti o ṣe, ati bi awọn ọmọ kekeke ti nke ni tẹmpili, wipe, Hosanna fun Ọmọ Dafidi; inu bi wọn gidigidi, 16 Nwọn si wi fun u pe, Iwọ gbọ́ eyiti awọn wọnyi nwi? Jesu si wi fun wọn pe, Bẹ̃ni; ẹnyin kò ti kà a ninu iwe pe, Lati ẹnu awọn ọmọ-ọwọ́ ati awọn ọmọ-ọmu ni iwọ ti mu iyìn pé?

17 O si fi wọn silẹ, o jade kuro ni ilu na lọ si Betani; o wọ̀ sibẹ̀.

Jesu Fi Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Gégùn-ún

(Mak 11:12-14, 20-24)


18 Nigbati o di owurọ̀, bi o ti npada bọ̀ si Jerusalemu, ebi npa a. 19 Nigbati o ri igi ọ̀pọtọ li ọ̀na, o lọ sibẹ̀, kò si ri ohun kan lori rẹ̀, bikoṣe kìki ewé, o si wi fun u pe, Ki eso ki o má so lori rẹ lati oni lọ titi lailai. Lojukanna igi ọpọtọ na gbẹ. 20 Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i, ẹnu yà wọn, nwọn wipe, Igi ọpọtọ yi mà tete gbẹ? 21 Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́, ti ẹ kò ba si ṣiyemeji, ẹnyin kì yio ṣe kìki eyi ti a ṣe si igi ọpọtọ yi, ṣugbọn bi ẹnyin ba tilẹ wi fun òke yi pe, Ṣidi, ki o si bọ́ sinu okun, yio ṣẹ.

22 Ohunkohun gbogbo ti ẹnyin ba bère ninu adura pẹlu igbagbọ́, ẹnyin o ri gbà.

Ìjiyàn Lórí Agbára Jesu

(Mak 11:27-33; Luk 20:1-8)


23 Nigbati o si de inu tẹmpili, awọn olori alufa ati awọn àgba awọn enia wá sọdọ rẹ̀ bi o ti nkọ́ awọn enia; nwọn wipe, Aṣẹ wo ni iwọ fi nṣe nkan wọnyi? tali o si fun ọ li aṣẹ yi? 24 Jesu si dahun o si wi fun wọn pe, Emi ó si bi nyin lẽre ohun kan pẹlu, bi ẹnyin ba sọ fun mi, emi o si sọ fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi: 25 Baptismu Johanu, nibo li o ti wá? lati ọrun wá ni, tabi lati ọdọ enia? Nwọn si ba ara wọn gbèro, wipe, Bi awa ba wipe, Lati ọrun wá ni, on o wi fun wa pe, Ẽha ti ṣe ti ẹnyin ko fi gbà a gbọ́? 26 Ṣugbọn bi awa ba si wipe, Lati ọdọ enia; awa mbẹ̀ru ijọ enia, nitori gbogbo wọn kà Johanu si wolĩ.

27 Nwọn si da Jesu lohùn, wipe, Awa ko mọ. O si wi fun wọn pe, Njẹ emi kì yio si wi fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi.

Òwe nípa Àwọn Ọmọ Meji


28 Ṣugbọn kili ẹnyin nrò? ọkunrin kan wà ti o li ọmọ ọkunrin meji; o tọ̀ ekini wá, o si wipe, Ọmọ, lọ iṣiṣẹ loni ninu ọgba ajara mi. 29 O si dahùn wipe, Emi kì yio lọ: ṣugbọn o ronu nikẹhin, o si lọ. 30 O si tọ̀ ekeji wá, o si wi bẹ̃ gẹgẹ. O si dahùn wi fun u pe, Emi o lọ, baba: kò si lọ. 31 Ninu awọn mejeji, ewo li o ṣe ifẹ baba rẹ̀? Nwọn wi fun u pe, Eyi ekini. Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, awọn agbowode ati awọn panṣaga ṣiwaju nyin lọ si ijọba Ọlọrun.

32 Nitori Johanu ba ọ̀na ododo tọ̀ nyin wá, ẹnyin kò si gbà a gbọ́: ṣugbọn awọn agbowode ati awọn panṣaga gbà a gbọ́: ṣugbọn ẹnyin, nigbati ẹnyin si ri i, ẹ kò ronupiwada nikẹhin, ki ẹ le gbà a gbọ́.

Òwe nípa Àwọn Alágbàro Ọgbà Àjàrà

(Mak 12:1-12; Luk 20:9-19)


33 Ẹ gbọ́ owe miran; Bãle ile kan wà ti o gbìn ajara, o si sọgba yi i ká, o wà ibi ifunti sinu rẹ̀, o kọ́ ile-iṣọ, o si fi ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba, o si lọ si ajò. 34 Nigbati akokò eso sunmọ etile, o ràn awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ si awọn oluṣọgba na, ki nwọn ki o le gbà wá ninu eso rẹ̀. 35 Awọn oluṣọgba si mu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, nwọn lù ekini, nwọn pa ekeji, nwọn si sọ ẹkẹta li okuta. 36 O si tun rán awọn ọmọ-ọdọ miran ti o jù awọn ti iṣaju lọ: nwọn si ṣe bẹ̃ si wọn gẹgẹ. 37 Ṣugbọn ni ikẹhin gbogbo wọn, o rán ọmọ rẹ̀ si wọn, o wipe, Nwọn o ṣe ojuṣãju fun ọmọ mi. 38 Ṣugbọn nigbati awọn oluṣọgba ri ọmọ na, nwọn wi fun ara wọn pe, Eyiyi li arole; ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki a si kó ogún rẹ̀. 39 Nwọn si mu u, nwọn wọ́ ọ jade kuro ninu ọgbà ajara na, nwọn si pa a. 40 Njẹ nigbati oluwa ọgbà ajara ba de, kini yio ṣe si awọn oluṣọgba wọnni? 41 Nwọn wi fun u pe, Yio pa awọn enia buburu wọnni run ni ipa òṣi, yio si fi ọgbà ajara rẹ̀ ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba miran, awọn ti o ma fi eso rẹ̀ fun u lakokò. 42 Jesu wi fun wọn pe, Ẹnyin ko ti kà a ninu iwe mimọ́ pe, Okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ, on na li o si di pàtaki igun ile: eyi ni iṣẹ Oluwa, o si jẹ iyanu li oju wa? 43 Nitorina emi wi fun nyin pe, A o gbà ijọba Ọlọrun lọwọ nyin, a o si fifun orilẹ-ede ti yio ma mu eso rẹ̀ wá. 44 Ẹnikẹni ti o ba ṣubu lù okuta yi yio fọ́: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ṣubu lù, yio lọ̀ ọ lũlu. 45 Nigbati awọn olori alufa ati awọn Farisi gbọ́ owe rẹ̀ nwọn woye pe awọn li o mba wi. 46 Ṣugbọn nigbati nwọn nwá ọ̀na ati gbé ọwọ́ le e, nwọn bẹ̀ru ijọ enia, nitoriti nwọn kà a si wolĩ.

Matthew 21

The Triumphal Entry

1 When they had approached Jerusalem and had come to Bethphage, at the Mount of Olives, then Jesus sent two disciples,2 saying to them, "Go into the village opposite you, and immediately you will find a donkey tied there and a colt with her; untie them and bring them to Me.3 If anyone says anything to you, you shall say, 'The Lord has need of them,' and immediately he will send them."4 This took place to fulfill what was spoken through the prophet:

5 "SAY TO THE DAUGHTER OF ZION,
'BEHOLD YOUR KING IS COMING TO YOU,
GENTLE, AND MOUNTED ON A DONKEY,
EVEN ON A COLT, THE FOAL OF A BEAST OF BURDEN.'"
6 The disciples went and did just as Jesus had instructed them,7 and brought the donkey and the colt, and laid their coats on them; and He sat on the coats.8 Most of the crowd spread their coats in the road, and others were cutting branches from the trees and spreading them in the road.9 The crowds going ahead of Him, and those who followed, were shouting,
"Hosanna to the Son of David;
BLESSED IS HE WHO COMES IN THE NAME OF THE LORD;
Hosanna in the highest!"
10 When He had entered Jerusalem, all the city was stirred, saying, "Who is this?"11 And the crowds were saying, "This is the prophet Jesus, from Nazareth in Galilee."

Cleansing the Temple

12 And Jesus entered the temple and drove out all those who were buying and selling in the temple, and overturned the tables of the money changers and the seats of those who were selling doves.13 And He *said to them, "It is written, 'MY HOUSE SHALL BE CALLED A HOUSE OF PRAYER'; but you are making it a ROBBERS' DEN."

14 And the blind and the lame came to Him in the temple, and He healed them.15 But when the chief priests and the scribes saw the wonderful things that He had done, and the children who were shouting in the temple, "Hosanna to the Son of David," they became indignant16 and said to Him, "Do You hear what these children are saying?" And Jesus *said to them, "Yes; have you never read, 'OUT OF THE MOUTH OF INFANTS AND NURSING BABIES YOU HAVE PREPARED PRAISE FOR YOURSELF'?"17 And He left them and went out of the city to Bethany, and spent the night there.

The Barren Fig Tree

18 Now in the morning, when He was returning to the city, He became hungry.19 Seeing a lone fig tree by the road, He came to it and found nothing on it except leaves only; and He *said to it, "No longer shall there ever be any fruit from you." And at once the fig tree withered.

20 Seeing this, the disciples were amazed and asked, "How did the fig tree wither all at once?"21 And Jesus answered and said to them, "Truly I say to you, if you have faith and do not doubt, you will not only do what was done to the fig tree, but even if you say to this mountain, 'Be taken up and cast into the sea,' it will happen.22 And all things you ask in prayer, believing, you will receive."

Authority Challenged

23 When He entered the temple, the chief priests and the elders of the people came to Him while He was teaching, and said, "By what authority are You doing these things, and who gave You this authority?"24 Jesus said to them, "I will also ask you one thing, which if you tell Me, I will also tell you by what authority I do these things.25 The baptism of John was from what source, from heaven or from men?" And they began reasoning among themselves, saying, "If we say, 'From heaven,' He will say to us, 'Then why did you not believe him?'26 But if we say, 'From men,' we fear the people; for they all regard John as a prophet."27 And answering Jesus, they said, "We do not know." He also said to them, "Neither will I tell you by what authority I do these things.

Parable of Two Sons

28 "But what do you think? A man had two sons, and he came to the first and said, 'Son, go work today in the vineyard.'29 And he answered, 'I will not'; but afterward he regretted it and went.30 The man came to the second and said the same thing; and he answered, 'I will, sir'; but he did not go.31 Which of the two did the will of his father?" They *said, "The first." Jesus *said to them, "Truly I say to you that the tax collectors and prostitutes will get into the kingdom of God before you.32 For John came to you in the way of righteousness and you did not believe him; but the tax collectors and prostitutes did believe him; and you, seeing this, did not even feel remorse afterward so as to believe him.

Parable of the Landowner

33 "Listen to another parable. There was a landowner who PLANTED A VINEYARD AND PUT A WALL AROUND IT AND DUG A WINE PRESS IN IT, AND BUILT A TOWER, and rented it out to vine-growers and went on a journey.34 When the harvest time approached, he sent his slaves to the vine-growers to receive his produce.35 The vine-growers took his slaves and beat one, and killed another, and stoned a third.36 Again he sent another group of slaves larger than the first; and they did the same thing to them.37 But afterward he sent his son to them, saying, 'They will respect my son.'38 But when the vine-growers saw the son, they said among themselves, 'This is the heir; come, let us kill him and seize his inheritance.'39 They took him, and threw him out of the vineyard and killed him.40 Therefore when the owner of the vineyard comes, what will he do to those vine-growers?"41 They *said to Him, "He will bring those wretches to a wretched end, and will rent out the vineyard to other vine-growers who will pay him the proceeds at the proper seasons."

42 Jesus *said to them, "Did you never read in the Scriptures,
'THE STONE WHICH THE BUILDERS REJECTED,
THIS BECAME THE CHIEF CORNER stone;
THIS CAME ABOUT FROM THE LORD,
AND IT IS MARVELOUS IN OUR EYES'?
43 Therefore I say to you, the kingdom of God will be taken away from you and given to a people, producing the fruit of it.44 And he who falls on this stone will be broken to pieces; but on whomever it falls, it will scatter him like dust."

45 When the chief priests and the Pharisees heard His parables, they understood that He was speaking about them.46 When they sought to seize Him, they feared the people, because they considered Him to be a prophet.