Mat 22
Òwe Àsè Igbeyawo
(Luk 14:15-24)
1 Jesu si dahùn, o si tún fi owe sọ̀rọ fun wọn pe, 2 Ijọba ọrun dabi ọba kan, ti o ṣe igbeyawo fun ọmọ rẹ̀. 3 O si rán awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ lọ ipè awọn ti a ti pè tẹlẹ si ibi iyawo: ṣugbọn nwọn kò fẹ wá. 4 O si tún rán awọn ọmọ-ọdọ miran, wipe, Ẹ wi fun awọn ti a pè pe, Wò o, mo se onjẹ mi tan: a pa malu ati gbogbo ẹran abọpa mi, a si ṣe ohun gbogbo tan: ẹ wá si ibi iyawo. 5 Ṣugbọn nwọn ko fi pè nkan, nwọn ba tiwọn lọ, ọkan si ọ̀na oko rẹ̀, omiran si ọ̀na òwò rẹ̀: 6 Awọn iyokù si mu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, nwọn ṣe àbuku si wọn, nwọn si lù wọn pa. 7 Nigbati ọba si gbọ́ eyi, o binu: o si rán awọn ogun rẹ̀ lọ, o pa awọn apania wọnni run, o si kun ilu wọn. 8 Nigbana li o wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, A se ase iyawo tan, ṣugbọn awọn ti a ti pè kò yẹ. 9 Nitorina ẹ lọ si ọ̀na opópo, iyekiye ẹniti ẹ ba ri, ẹ pè wọn wá si ibi iyawo. 10 Bẹ̃li awọn ọmọ-ọdọ wọnni si jade lọ si ọ̀na opópo, nwọn si kó gbogbo awọn ẹniti nwọn ri jọ, ati buburu ati rere: ibi ase iyawo si kún fun awọn ti o wá jẹun. 11 Nigbati ọba na wá iwò awọn ti o wá jẹun, o ri ọkunrin kan nibẹ̀ ti kò wọ̀ aṣọ iyawo: 12 O si bi i pe, Ọrẹ́, iwọ ti ṣe wọ̀ ìhin wá laini aṣọ iyawo? Kò si le fọhùn. 13 Nigbana li ọba wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ di i tọwọ tẹsẹ, ẹ gbé e kuro, ki ẹ si sọ ọ sinu òkunkun lode; nibẹ̀ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.
14 Nitori ọ̀pọlọpọ li a pè, ṣugbọn diẹ li a yàn.Ọ̀rọ̀ Jesu nípa Sísan Owó-orí fún Kesari
(Mak 12:13-17; Luk 20:20-26)
15 Nigbana li awọn Farisi lọ, nwọn gbìmọ bi nwọn o ti ṣe ri ọ̀rọ gbámọ ọ li ẹnu. 16 Nwọn si rán awọn ọmọ-ẹhin wọn pẹlu awọn ọmọ-ẹhin Herodu lọ sọdọ rẹ̀, wipe, Olukọni, awa mọ̀ pe olotitọ ni iwọ, iwọ̀ si nkọni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ, bẹ̃ni iwọ ki iwoju ẹnikẹni: nitoriti iwọ kì iṣe ojuṣaju enia. 17 Njẹ wi fun wa, Iwọ ti rò o si? o tọ́ lati mã san owode fun Kesari, tabi ko tọ́? 18 Ṣugbọn Jesu mọ̀ ìro buburu wọn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò, ẹnyin agabagebe? 19 Ẹ fi owodẹ kan hàn mi. Nwọn si mu owo idẹ kan tọ̀ ọ wá. 20 O si bi wọn pe, Aworan ati akọle tali eyi? 21 Nwọn wi fun u pe, Ti Kesari ni. Nigbana li o wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun.
22 Nigbati nwọn si ti gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, ẹnu yà wọn, nwọn fi i silẹ, nwọn si ba tiwọn lọ.Ìjiyàn lórí Ajinde Àwọn Òkú
(Mak 12:18-27; Luk 20:27-40)
23 Ni ijọ kanna li awọn Sadusi tọ̀ ọ wá, awọn ti o wipe ajinde okú kò si, nwọn si bi i, 24 Wipe, Olukọni, Mose wipe, Bi ẹnikan ba kú li ailọmọ, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o le gbe irú dide fun arakunrin rẹ̀. 25 Awọn arakunrin meje kan ti wà lọdọ wa: eyi ekini lẹhin igbati o gbé aya rẹ̀ ni iyawo, o kú, bi kò ti ni irúọmọ, o fi aya rẹ̀ silẹ fun arakunrin rẹ̀: 26 Gẹgẹ bẹ̃li ekeji pẹlu, ati ẹkẹta titi o fi de ekeje. 27 Nikẹhin gbogbo wọn, obinrin na kú pẹlu. 28 Njẹ li ajinde oku, aya ti tani yio ha ṣe ninu awọn mejeje? nitori gbogbo wọn li o sá ni i. 29 Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣìna, nitori ẹnyin kò mọ̀ iwe-mimọ́, ẹ kò si mọ̀ agbara Ọlọrun. 30 Nitoripe li ajinde okú, nwọn kì igbeyawo, a kì si fi wọn funni ni igbeyawo, ṣugbọn nwọn dabi awọn angẹli Ọlọrun li ọrun. 31 Ṣugbọn niti ajinde okú, ẹnyin kò ti kà eyi ti a sọ fun nyin lati ọdọ Ọlọrun wá wipe, 32 Emi li Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu? Ọlọrun ki iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe ti awọn alãye.
33 Nigbati awọn enia gbọ́ eyi, ẹnu yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀.Òfin tí Ó Ṣe Pataki Jùlọ
(Mak 12:28-34; Luk 10:25-28)
34 Ṣugbọn nigbati awọn Farisi gbọ́ pe, o pa awọn Sadusi li ẹnu mọ́, nwọn pè ara wọn jọ. 35 Nigbana li ọkan ninu wọn, ti iṣe amofin, ndán a wò, o si bi i lẽre ọ̀rọ kan, wipe, 36 Olukọni, ewo li aṣẹ nla ninu ofin? 37 Jesu si wi fun u pe, Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo inu rẹ, fẹ́ Ọlọrun Oluwa rẹ. 38 Eyi li ekini ati ofin nla. 39 Ekeji si dabi rẹ̀, Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ.
40 Ninu awọn ofin mejeji yi ni gbogbo ofin ati wolĩ rọ̀ mọ́.Ọ̀rọ̀ Iyàn lórí Ẹni tí Í Ṣe Ọmọ Dafidi
(Mak 12:35-37; Luk 20:41-44)
41 Bi awọn Farisi ti kó ara wọn jọ, Jesu bi wọn, 42 Wipe, Ẹnyin ti rò ti Kristi si? ọmọ tani iṣe? Nwọn wi fun u pe, Ọmọ Dafidi ni. 43 O wi fun wọn pe, Ẽha ti ṣe ti Dafidi nipa ẹmí fi npè e li Oluwa, wipe, 44 OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ? 45 Njẹ bi Dafidi ba npè e li Oluwa, ẽha ti ri ti o fi ṣe ọmọ rẹ̀? 46 Kò si si ẹnikan ti o le da a li ohùn ọ̀rọ kan, bẹ̃ni kò si ẹniti o jẹ bi i lẽre ohun kan mọ́ lati ọjọ na lọ.
Matthew 22
Parable of the Marriage Feast
1 Jesus spoke to them again in parables, saying,2 "The kingdom of heaven may be compared to a king who gave a wedding feast for his son.3 And he sent out his slaves to call those who had been invited to the wedding feast, and they were unwilling to come.4 Again he sent out other slaves saying, 'Tell those who have been invited, "Behold, I have prepared my dinner; my oxen and my fattened livestock are all butchered and everything is ready; come to the wedding feast."'5 But they paid no attention and went their way, one to his own farm, another to his business,6 and the rest seized his slaves and mistreated them and killed them.7 But the king was enraged, and he sent his armies and destroyed those murderers and set their city on fire.8 Then he *said to his slaves, 'The wedding is ready, but those who were invited were not worthy.9 Go therefore to the main highways, and as many as you find there, invite to the wedding feast.'10 Those slaves went out into the streets and gathered together all they found, both evil and good; and the wedding hall was filled with dinner guests.
11 "But when the king came in to look over the dinner guests, he saw a man there who was not dressed in wedding clothes,12 and he *said to him, 'Friend, how did you come in here without wedding clothes?' And the man was speechless.13 Then the king said to the servants, 'Bind him hand and foot, and throw him into the outer darkness; in that place there will be weeping and gnashing of teeth.'14 For many are called, but few are chosen."
Tribute to Caesar
15 Then the Pharisees went and plotted together how they might trap Him in what He said.16 And they *sent their disciples to Him, along with the Herodians, saying, "Teacher, we know that You are truthful and teach the way of God in truth, and defer to no one; for You are not partial to any.17 Tell us then, what do You think? Is it lawful to give a poll-tax to Caesar, or not?"18 But Jesus perceived their malice, and said, "Why are you testing Me, you hypocrites?19 Show Me the coin used for the poll-tax." And they brought Him a denarius.20 And He *said to them, "Whose likeness and inscription is this?"21 They *said to Him, "Caesar's." Then He *said to them, "Then render to Caesar the things that are Caesar's; and to God the things that are God's."22 And hearing this, they were amazed, and leaving Him, they went away.
Jesus Answers the Sadducees
23 On that day some Sadducees (who say there is no resurrection) came to Jesus and questioned Him,24 asking, "Teacher, Moses said, 'IF A MAN DIES HAVING NO CHILDREN, HIS BROTHER AS NEXT OF KIN SHALL MARRY HIS WIFE, AND RAISE UP CHILDREN FOR HIS BROTHER.'25 Now there were seven brothers with us; and the first married and died, and having no children left his wife to his brother;26 so also the second, and the third, down to the seventh.27 Last of all, the woman died.28 In the resurrection, therefore, whose wife of the seven will she be? For they all had married her."
29 But Jesus answered and said to them, "You are mistaken, not understanding the Scriptures nor the power of God.30 For in the resurrection they neither marry nor are given in marriage, but are like angels in heaven.31 But regarding the resurrection of the dead, have you not read what was spoken to you by God:32 'I AM THE GOD OF ABRAHAM, AND THE GOD OF ISAAC, AND THE GOD OF JACOB'? He is not the God of the dead but of the living."33 When the crowds heard this, they were astonished at His teaching.
34 But when the Pharisees heard that Jesus had silenced the Sadducees, they gathered themselves together.35 One of them, ta lawyer, asked Him a question, testing Him,36 "Teacher, which is the great commandment in the Law?"37 And He said to him, " 'YOU SHALL LOVE THE LORD YOUR GOD WITH ALL YOUR HEART, AND WITH ALL YOUR SOUL, AND WITH ALL YOUR MIND.'38 This is the great and foremost commandment.39 The second is like it, 'YOU SHALL LOVE YOUR NEIGHBOR AS YOURSELF.'40 On these two commandments depend the whole Law and the Prophets."
41 Now while the Pharisees were gathered together, Jesus asked them a question:42 "What do you think about the Christ, whose son is He?" They *said to Him, " The son of David."43 He *said to them, "Then how does David in the Spirit call Him 'Lord,' saying,
44 'THE LORD SAID TO MY LORD,
"SIT AT MY RIGHT HAND,
UNTIL I PUT YOUR ENEMIES BENEATH YOUR FEET"'?45 If David then calls Him 'Lord,' how is He his son?"46 No one was able to answer Him a word, nor did anyone dare from that day on to ask Him another question.