previous next

Mat 23

Jesu Bá Àwọn Amòfin ati Àwọn Farisi Wí

(Mak 12:38-39; Luk 11:43, 46; 20:45-46)

1 NIGBANA ni Jesu wi fun ijọ enia, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, 2 Pe, Awọn akọwe pẹlu awọn Farisi joko ni ipò Mose: 3 Nitorina ohunkohun gbogbo ti nwọn ba wipe ki ẹ kiyesi, ẹ mã kiyesi wọn ki ẹ si mã ṣe wọn; ṣugbọn ẹ má ṣe gẹgẹ bi iṣe wọn: nitoriti nwọn a ma wi, ṣugbọn nwọn ki iṣe. 4 Nitori nwọn a di ẹrù wuwo ti o si ṣoro lati rù, nwọn a si gbé e kà awọn enia li ejika; ṣugbọn awọn tikarawọn ko jẹ fi ika wọn kàn ẹrù na. 5 Ṣugbọn gbogbo iṣẹ wọn ni nwọn nṣe nitori ki awọn enia ki o ba le ri wọn: nwọn sọ filakteri wọn di gbigbòro, nwọn fi kún iṣẹti aṣọ wọn. 6 Nwọn fẹ ipò ọlá ni ibi ase, ati ibujoko ọla ni sinagogu, 7 Ati ikíni li ọjà, ati ki awọn enia mã pè wọn pe, Rabbi, Rabbi. 8 Ṣugbọn ki a máṣe pè ẹnyin ni Rabbi: nitoripe ẹnikan ni Olukọ nyin, ani Kristi; ará si ni gbogbo nyin. 9 Ẹ má si ṣe pè ẹnikan ni baba nyin li aiye: nitori ẹnikan ni Baba nyin, ẹniti mbẹ li ọrun. 10 Ki a má si ṣe pè nyin ni olukọni: nitori ọkan li Olukọni nyin, ani Kristi. 11 Ṣugbọn ẹniti o ba pọ̀ju ninu nyin, on ni yio jẹ iranṣẹ nyin.

12 Ẹnikẹni ti o ba si gbé ara rẹ̀ ga, li a o rẹ̀ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ li a o gbé ga.

Jesu Dá Àwọn Amòfin ati Àwọn Farisi Lẹ́bi

(Mak 12:40; Luk 11:39-42, 44, 52; 20:47)


13 Ṣugbọn egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin sé ijọba ọrun mọ́ awọn enia: nitori ẹnyin tikaranyin kò wọle, bẹ̃li ẹnyin kò jẹ ki awọn ti nwọle ki o wọle. 14 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin jẹ ile awọn opó run, ati nitori aṣehan, ẹ ngbadura gigun: nitorina li ẹnyin o ṣe jẹbi pọ̀ju. 15 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin nyi okun ati ilẹ ká lati sọ enia kan di alawọṣe; nigbati o ba si di bẹ̃ tan, ẹnyin a sọ ọ di ọmọ ọrun apadi nigba meji ju ara nyin lọ. 16 Egbé ni fun nyin, ẹnyin amọ̀na afọju, ti o nwipe, Ẹnikẹni ti o ba fi tẹmpili bura, kò si nkan; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi wura tẹmpili bura, o di ajigbese. 17 Ẹnyin alaimoye ati afọju: ewo li o pọ̀ju, wura, tabi tẹmpili ti nsọ wura di mimọ́? 18 Ati pe, Ẹnikẹni ti o ba fi pẹpẹ bura, kò si nkan; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi ẹ̀bun ti o wà lori rẹ̀ bura, o di ajigbese. 19 Ẹnyin alaimoye ati afọju: ewo li o pọ̀ju, ẹ̀bun, tabi pẹpẹ ti nsọ ẹ̀bun di mimọ́? 20 Njẹ ẹniti o ba si fi pẹpẹ bura, o fi i bura, ati ohun gbogbo ti o wà lori rẹ̀. 21 Ẹniti o ba si fi tẹmpili bura, o fi i bura, ati ẹniti o ngbé inu rẹ̀. 22 Ẹniti o ba si fi ọrun bura, o fi itẹ́ Ọlọrun bura, ati ẹniti o joko lori rẹ̀. 23 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi agabagebe; nitoriti ẹnyin ngbà idamẹwa minti, ati anise, ati kumini, ẹnyin si ti fi ọ̀ran ti o tobiju ninu ofin silẹ laiṣe, idajọ, ãnu, ati igbagbọ́: wọnyi li o tọ́ ti ẹnyin iba ṣe, laisi fi iyoku silẹ laiṣe. 24 Ẹnyin afọju amọ̀na, ti nsẹ́ kantikanti ti o si ngbé ibakasiẹ mì. 25 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin nfọ̀ ode ago ati awopọkọ́ mọ́, ṣugbọn inu wọn kún fun irẹjẹ ati wọ̀bia. 26 Iwọ afọju Farisi, tetekọ fọ̀ eyi ti mbẹ ninu ago ati awopọkọ́ mọ́ na, ki ode wọn ki o le mọ́ pẹlu. 27 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin dabi ibojì funfun, ti o dara li ode, ṣugbọn ninu nwọn kún fun egungun okú, ati fun ẹgbin gbogbo.

28 Gẹgẹ bẹ̃li ẹnyin pẹlu farahàn li ode bi olododo fun enia, ṣugbọn ninu ẹ kún fun agabagebe ati ẹ̀ṣẹ.

Wọn Yóo Jèrè Ẹ̀ṣẹ̀ Wọn

(Luk 11:47-51)


29 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin kọ́ ibojì awọn wolĩ, ẹnyin si ṣe isà okú awọn olododo li ọṣọ, 30 Ẹnyin si wipe, Awa iba wà li ọjọ awọn baba wa, awa kì ba li ọwọ́ ninu ẹ̀jẹ awọn wolĩ. 31 Njẹ ẹnyin li ẹlẹri fun ara nyin pe, ẹnyin li awọn ọmọ awọn ẹniti o pa awọn wolĩ. 32 Njẹ ẹnyin kuku kún òṣuwọn baba nyin de oke. 33 Ẹnyin ejò, ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin o ti ṣe yọ ninu ẹbi ọrun apadi? 34 Nitorina ẹ kiyesi i, Emi rán awọn wolĩ, ati amoye, ati akọwe si nyin: omiran ninu wọn li ẹnyin ó pa, ti ẹnyin ó si kàn mọ agbelebu; ati omiran ninu wọn li ẹnyin o nà ni sinagogu nyin, ti ẹnyin o si ṣe inunibini si lati ilu de ilu: 35 Ki gbogbo ẹ̀jẹ awọn olõtọ, ti a ti ta silẹ li aiye, ba le wá sori nyin, lati ẹ̀jẹ Abeli olododo titi de ẹ̀jẹ Sakariah ọmọ Barakiah, ẹniti ẹnyin pa larin tẹmpili ati pẹpẹ.

36 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Gbogbo nkan wọnyi ni yio wá sori iran yi.

Jesu Kẹ́dùn fún Jerusalẹmu

(Luk 13:34-35)


37 Jerusalemu, Jerusalemu, iwọ ti o pa awọn wolĩ, ti o si sọ okuta lù awọn ti a rán si ọ pa, igba melo li emi nfẹ radọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ̀ ti iradọ bò awọn ọmọ rẹ̀ labẹ apá rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ! 38 Sawò o, a fi ile nyin silẹ fun nyin li ahoro. 39 Mo si wi fun nyin, Ẹnyin kì yio ri mi mọ́ lati isisiyi lọ, titi ẹnyin o fi wipe, Olubukún li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa.

Matthew 23

Pharisaism Exposed

1 Then Jesus spoke to the crowds and to His disciples,2 saying: "The scribes and the Pharisees have seated themselves in the chair of Moses;3 therefore all that they tell you, do and observe, but do not do according to their deeds; for they say things and do not do them.4 They tie up heavy burdens and lay them on men's shoulders, but they themselves are unwilling to move them with so much as a finger.5 But they do all their deeds to be noticed by men; for they broaden their tphylacteries and lengthen the tassels of their garments.6 They love the place of honor at banquets and the chief seats in the synagogues,7 and respectful greetings in the market places, and being called Rabbi by men.8 But do not be called Rabbi; for One is your Teacher, and you are all brothers.9 Do not call anyone on earth your father; for One is your Father, He who is in heaven.10 Do not be called leaders; for One is your Leader, that is, Christ.11 But the greatest among you shall be your servant.12 Whoever exalts himself shall be humbled; and whoever humbles himself shall be exalted.

Eight Woes

13 "But woe to you, scribes and Pharisees, hypocrites, because you shut off the kingdom of heaven from people; for you do not enter in yourselves, nor do you allow those who are entering to go in.14 [tWoe to you, scribes and Pharisees, hypocrites, because you devour widows' houses, and for a pretense you make long prayers; therefore you will receive greater condemnation.]

15 "Woe to you, scribes and Pharisees, hypocrites, because you travel around on sea and land to make one proselyte; and when he becomes one, you make him twice as much a son of hell as yourselves.

16 "Woe to you, blind guides, who say, 'Whoever swears by the temple, that is nothing; but whoever swears by the gold of the temple is obligated.'17 You fools and blind men! Which is more important, the gold or the temple that sanctified the gold?18 And, 'Whoever swears by the altar, that is nothing, but whoever swears by the offering on it, he is obligated.'19 You blind men, which is more important, the offering, or the altar that sanctifies the offering?20 Therefore, whoever swears by the altar, swears both by the altar and by everything on it.21 And whoever swears by the temple, swears both by the temple and by Him who dwells within it.22 And whoever swears by heaven, swears both by the throne of God and by Him who sits upon it.

23 "Woe to you, scribes and Pharisees, hypocrites! For you tithe mint and dill and cummin, and have neglected the weightier provisions of the law: justice and mercy and faithfulness; but these are the things you should have done without neglecting the others.24 You blind guides, who strain out a gnat and swallow a camel!

25 "Woe to you, scribes and Pharisees, hypocrites! For you clean the outside of the cup and of the dish, but inside they are full of robbery and self-indulgence.26 You blind Pharisee, first clean the inside of the cup and of the dish, so that the outside of it may become clean also.

27 "Woe to you, scribes and Pharisees, hypocrites! For you are like whitewashed tombs which on the outside appear beautiful, but inside they are full of dead men's bones and all uncleanness.28 So you, too, outwardly appear righteous to men, but inwardly you are full of hypocrisy and lawlessness.

29 "Woe to you, scribes and Pharisees, hypocrites! For you build the tombs of the prophets and adorn the monuments of the righteous,30 and say, 'If we had been living in the days of our fathers, we would not have been partners with them in shedding the blood of the prophets.'31 So you testify against yourselves, that you are sons of those who murdered the prophets.32 Fill up, then, the measure of the guilt of your fathers.33 You serpents, you brood of vipers, how will you escape the sentence of hell?

34 "Therefore, behold, I am sending you prophets and wise men and scribes; some of them you will kill and crucify, and some of them you will scourge in your synagogues, and persecute from city to city,35 so that upon you may fall the guilt of all the righteous blood shed on earth, from the blood of righteous Abel to the blood of Zechariah, the son of Berechiah, whom you murdered between the temple and the altar.36 Truly I say to you, all these things will come upon this generation.

Lament over Jerusalem

37 "Jerusalem, Jerusalem, who kills the prophets and stones those who are sent to her! How often I wanted to gather your children together, the way a hen gathers her chicks under her wings, and you were unwilling.38 Behold, your house is being left to you desolate!39 For I say to you, from now on you will not see Me until you say, 'BLESSED IS HE WHO COMES IN THE NAME OF THE LORD!'"