previous next

Mat 24

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ nípa Wíwó Tẹmpili

(Mak 13:1-2; Luk 21:5-6)

1 JESU si jade lọ, o ti tẹmpili kuro: awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ wá lati fi kikọ́ tẹmpili hàn a.

2 Jesu si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò ri gbogbo nkan wọnyi? lõtọ ni mo wi fun nyin, Kì yio si okuta kan nihinyi ti a o fi silẹ lori ekeji, ti a kì yio wó lulẹ.

Ìbẹ̀rẹ̀ Ìrora

(Mak 13:3-13; Luk 21:7-19)


3 Bi o si ti joko lori òke Olifi, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá nikọ̀kọ, wipe, Sọ fun wa, nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? kini yio si ṣe àmi wíwa rẹ, ati ti opin aiye? 4 Jesu si dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẹ kiyesara, ki ẹnikẹni ki o máṣe tàn nyin jẹ. 5 Nitori ọpọlọpọ yio wá li orukọ mi, wipe, Emi ni Kristi; nwọn ó si tàn ọ̀pọlọpọ jẹ. 6 Ẹnyin o si gburo ogun ati idagìri ogun: ẹ kiyesi i ki ẹnyin ki o máṣe jaiyà: nitori gbogbo nkan wọnyi ko le ṣe ki o ma ṣẹ, ṣugbọn opin ki iṣe isisiyi. 7 Nitoripe orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ède, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: ìyan, ati ajakalẹ-arùn, ati iṣẹlẹ̀ yio si wà ni ibi pipọ. 8 Gbogbo nkan wọnyi ni ipilẹṣẹ ipọnju. 9 Nigbana ni nwọn o fi nyin funni lati jẹ ni ìya, nwọn o si pa nyin: a o si korira nyin lọdọ gbogbo orilẹ-ède nitori orukọ mi. 10 Nigbana li ọ̀pọlọpọ yio kọsẹ̀, nwọn o si ma ṣòfofo ara wọn, nwọn o si mã korira ara wọn. 11 Wolĩ eke pipọ ni yio si dide, nwọn o si tàn ọpọlọpọ jẹ. 12 Ati nitori ẹ̀ṣẹ yio di pipọ, ifẹ ọpọlọpọ yio di tutù. 13 Ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi de opin, on na li a o gbalà.

14 A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède; nigbana li opin yio si de.

Àkókò Iṣẹ́ Ńlá

(Mak 13:14-23; Luk 21:20-24)


15 Nitorina nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro, ti a ti ẹnu wolĩ Danieli sọ, ti o ba duro ni ibi mimọ́, (ẹniti o ba kà a, ki òye ki o yé e:) 16 Nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea ki o sálọ si ori òke: 17 Ki ẹniti mbẹ lori ile ki o maṣe sọkalẹ wá imu ohunkohun jade ninu ile rẹ̀: 18 Ki ẹniti mbẹ li oko maṣe pada sẹhin wá lati mu aṣọ rẹ̀. 19 Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati fun awọn ti o nfi ọmú fun ọmọ mu ni ijọ wọnni! 20 Ẹ si mã gbadura ki sisá nyin ki o máṣe jẹ igba otutù, tabi ọjọ isimi: 21 Nitori nigbana ni ipọnju nla yio wà, irú eyi ti kò si lati igba ibẹrẹ ọjọ ìwa di isisiyi, bẹ̃kọ, irú rẹ̀ kì yio si si. 22 Bi kò si ṣepe a ké ọjọ wọnni kuru, kò si ẹda ti iba le là a; ṣugbọn nitori awọn ayanfẹ li a o fi ké ọjọ wọnni kuru. 23 Nigbana bi ẹnikan ba wi fun nyin pe, Wo o, Kristi mbẹ nihin, tabi lọhun; ẹ máṣe gbà a gbọ́. 24 Nitori awọn eke Kristi, ati eke wolĩ yio dide, nwọn o si fi àmi ati ohun iyanu nla hàn; tobẹ̃ bi o le ṣe ṣe nwọn o tàn awọn ayanfẹ pãpã. 25 Wo o, mo wi fun nyin tẹlẹ. 26 Nitorina bi nwọn ba wi fun nyin pe, Wo o, o wà li aginjù; ẹ má lọ sibẹ̀: wo o, o wà ni iyẹwu; ẹ máṣe gbàgbọ́. 27 Nitori gẹgẹ bi manamana ti ikọ lati ila-õrun, ti isi mọlẹ de ìwọ-õrun; bẹ̃ni wiwa Ọmọ-enia yio ri pẹlu.

28 Nitori ibikibi ti oku ba gbé wà, ibẹ̀ li awọn igúnnugún ikojọ pọ̀ si.

Dídé ti Ọmọ-Eniyan

(Mak 13:24-27; Luk 21:25-28)


29 Lojukanna lẹhin ipọnju ọjọ wọnni li õrùn yio ṣõkun, oṣupá kì yio si fi imọlẹ rẹ̀ hàn, awọn irawọ yio ti oju ọrun já silẹ, agbara oju ọrun li a o si mì titi: 30 Nigbana li àmi Ọmọ-enia yio si fi ara hàn li ọrun; nigbana ni gbogbo ẹya aiye yio kãnu, nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara ati ogo nla.

31 Yio si rán awọn angẹli rẹ̀ ti awọn ti ohùn ipè nla, nwọn o si kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ̀ lati ori igun mẹrẹrin aiye jọ, lati ikangun ọrun kan lọ de ikangun keji.

Ẹ̀kọ́ Ara Igi Ọ̀pọ̀tọ́

(Mak 13:28-31; Luk 21:29-33)


32 Njẹ ẹ kọ́ owe lara igi ọpọtọ; nigbati ẹká rẹ̀ ba yọ titun, ti o ba si ru ewé, ẹnyin mọ̀ pe igba ẹ̃rùn sunmọ etile: 33 Gẹgẹ bẹ̃ li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri gbogbo nkan wọnyi, ki ẹ mọ̀ pe o sunmọ etile tan lẹhin ilẹkun. 34 Lõtọ ni mo wi fun nyin, iran yi ki yio rekọja, titi gbogbo nkan wọnyi yio fi ṣẹ.

35 Ọrun on aiye yio rekọjá, ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja.

Kò Sí Ẹni tí Ó Mọ Ọjọ́ náà Gan-an

(Mak 13:32-37; Luk 17:26-30, 34-36)


36 Ṣugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọ̀ ọ, awọn angẹli ọrun kò tilẹ mọ̀ ọ, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo. 37 Gẹgẹ bi ọjọ Noa si ti ri, bẹ̃ni wíwa Ọmọ-enia yio si ri. 38 Nitori bi ọjọ wọnni ti wà ṣiwaju kikún omi, ti nwọn njẹ, ti nwọn nmu, ti nwọn ngbé iyawo, ti a si nfa iyawo funni, titi o fi di ọjọ ti Noa fi bọ́ sinu ọkọ̀, 39 Nwọn kò si mọ̀ titi omi fi de, ti o gbá gbogbo wọn lọ; gẹgẹ bẹ̃ni wíwa Ọmọ-enia yio ri pẹlu. 40 Nigbana li ẹni meji yio wà li oko; a o mu ọkan, a o si fi èkejì silẹ. 41 Awọn obinrin meji yio jùmọ ma lọ̀ ọlọ pọ̀; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ. 42 Nitorina ẹ mã ṣọna: nitori ẹnyin kò mọ̀ wakati ti Oluwa nyin yio de. 43 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o mọ̀ eyi pe, bãle ile iba mọ̀ wakati na ti olè yio wá, iba ma ṣọna, on kì ba ti jẹ́ ki a runlẹ ile rẹ̀.

44 Nitorina ki ẹnyin ki o mura silẹ: nitori ni wakati ti ẹnyin kò rò tẹlẹ li Ọmọ-enia yio de.

Oríṣìí Ẹrú Meji

(Luk 12:41-48)


45 Tani iṣe olõtọ ati ọlọgbọn ọmọ-ọdọ, ẹniti oluwa rẹ̀ fi ṣe olori ile rẹ̀, lati fi onjẹ wọn fun wọn li akokò? 46 Alabukún-fun li ọmọ-ọdọ na, nigbati oluwa rẹ̀ ba de, ẹniti yio bá a ki o mã ṣe bẹ̃. 47 Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, On o fi ṣe olori gbogbo ohun ti o ni. 48 Ṣugbọn bi ọmọ-ọdọ buburu na ba wi li ọkàn rẹ̀ pe, Oluwa mi fà àbọ rẹ̀ sẹhin; 49 Ti o si bẹ̀rẹ si ilù awọn ọmọ-ọdọ ẹlẹgbẹ rẹ̀, ati si ijẹ ati si imu pẹlu awọn ọ̀muti; 50 Oluwa ọmọ-ọdọ na yio de li ọjọ ti kò reti, ati ni wakati ti kò daba. 51 Yio si jẹ ẹ ni ìya gidigidi, yio yàn ipa rẹ̀ pẹlu awọn agabagebe, nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.

Matthew 24

Signs of Christ's Return

1 Jesus came out from the temple and was going away when His disciples came up to point out the temple buildings to Him.2 And He said to them, "Do you not see all these things? Truly I say to you, not one stone here will be left upon another, which will not be torn down."

3 As He was sitting on the Mount of Olives, the disciples came to Him privately, saying, "Tell us, when will these things happen, and what will be the sign of Your coming, and of the end of the age?"

4 And Jesus answered and said to them, "See to it that no one misleads you.5 For many will come in My name, saying, 'I am the Christ,' and will mislead many.6 You will be hearing of wars and rumors of wars. See that you are not frightened, for those things must take place, but that is not yet the end.7 For nation will rise against nation, and kingdom against kingdom, and in various places there will be famines and earthquakes.8 But all these things are merely the beginning of birth pangs.

9 "Then they will deliver you to tribulation, and will kill you, and you will be hated by all nations because of My name.10 At that time many will fall away and will betray one another and hate one another.11 Many false prophets will arise and will mislead many.12 Because lawlessness is increased, most people's love will grow cold.13 But the one who endures to the end, he will be saved.14 This gospel of the kingdom shall be preached in the whole world as a testimony to all the nations, and then the end will come.

Perilous Times

15 "Therefore when you see the ABOMINATION OF DESOLATION which was spoken of through Daniel the prophet, standing in the holy place (let the reader understand),16 then those who are in Judea must flee to the mountains.17 Whoever is on the housetop must not go down to get the things out that are in his house.18 Whoever is in the field must not turn back to get his cloak.19 But woe to those who are pregnant and to those who are nursing babies in those days!20 But pray that your flight will not be in the winter, or on a Sabbath.21 For then there will be a great tribulation, such as has not occurred since the beginning of the world until now, nor ever will.22 Unless those days had been cut short, no life would have been saved; but for the sake of the elect those days will be cut short.23 Then if anyone says to you, 'Behold, here is the Christ,' or 'There He is,' do not believe him.24 For false Christs and false prophets will arise and will show great signs and wonders, so as to mislead, if possible, even the elect.25 Behold, I have told you in advance.26 So if they say to you, 'Behold, He is in the wilderness,' do not go out, or, 'Behold, He is in the inner rooms,' do not believe them.27 For just as the lightning comes from the east and flashes even to the west, so will the coming of the Son of Man be.28 Wherever the corpse is, there the vultures will gather.

The Glorious Return

29 "But immediately after the tribulation of those days THE SUN WILL BE DARKENED, AND THE MOON WILL NOT GIVE ITS LIGHT, AND THE STARS WILL FALL from the sky, and the powers of the heavens will be shaken.30 And then the sign of the Son of Man will appear in the sky, and then all the tribes of the earth will mourn, and they will see the SON OF MAN COMING ON THE CLOUDS OF THE SKY with power and great glory.31 And He will send forth His angels with A GREAT TRUMPET and THEY WILL GATHER TOGETHER His elect from the four winds, from one end of the sky to the other.

Parable of the Fig Tree

32 "Now learn the parable from the fig tree: when its branch has already become tender and puts forth its leaves, you know that summer is near;33 so, you too, when you see all these things, recognize that He is near, right at the door.34 Truly I say to you, this generation will not pass away until all these things take place.35 Heaven and earth will pass away, but My words will not pass away.

36 "But of that day and hour no one knows, not even the angels of heaven, nor the Son, but the Father alone.37 For the coming of the Son of Man will be just like the days of Noah.38 For as in those days before the flood they were eating and drinking, marrying and giving in marriage, until the day that Noah entered the ark,39 and they did not understand until the flood came and took them all away; so will the coming of the Son of Man be.40 Then there will be two men in the field; one will be taken and one will be left.41 Two women will be grinding at the mill; one will be taken and one will be left.

Be Ready for His Coming

42 "Therefore be on the alert, for you do not know which day your Lord is coming.43 But be sure of this, that if the head of the house had known at what time of the night the thief was coming, he would have been on the alert and would not have allowed his house to be broken into.44 For this reason you also must be ready; for the Son of Man is coming at an hour when you do not think He will.

45 "Who then is the faithful and sensible slave whom his master put in charge of his household to give them their food at the proper time?46 Blessed is that slave whom his master finds so doing when he comes.47 Truly I say to you that he will put him in charge of all his possessions.48 But if that evil slave says in his heart, 'My master is not coming for a long time,'49 and begins to beat his fellow slaves and eat and drink with drunkards;50 the master of that slave will come on a day when he does not expect him and at an hour which he does not know,51 and will cut him in pieces and assign him a place with the hypocrites; in that place there will be weeping and gnashing of teeth.