Mat 25
Òwe nípa Àwọn Wundia Mẹ́wàá
1 NIGBANA li a o fi ijọba ọrun wé awọn wundia mẹwa, ti o mu fitila wọn, ti nwọn si jade lọ ipade ọkọ iyawo. 2 Marun ninu wọn ṣe ọlọgbọn, marun si ṣe alaigbọn. 3 Awọn ti o ṣe alaigbọ́n mu fitila wọn, nwọn kò si mu oróro lọwọ: 4 Ṣugbọn awọn ọlọgbọn mu oróro ninu kolobo pẹlu fitila wọn. 5 Nigbati ọkọ iyawo pẹ, gbogbo wọn tõgbé, nwọn si sùn. 6 Ṣugbọn lãrin ọganjọ, igbe ta soke, wipe, Wo o, ọkọ, iyawo mbọ̀; ẹ jade lọ ipade rẹ̀. 7 Nigbana ni gbogbo awọn wundia wọnni dide, nwọn, si tún fitila wọn ṣe. 8 Awọn alaigbọn si wi fun awọn ọlọgbọn pe, Fun wa ninu oróro nyin; nitori fitila wa nkú lọ. 9 Ṣugbọn awọn ọlọ́gbọn da wọn li ohùn, wipe, Bẹ̃kọ; ki o má ba ṣe alaito fun awa ati ẹnyin: ẹ kuku tọ̀ awọn ti ntà lọ, ki ẹ si rà fun ara nyin. 10 Nigbati nwọn si nlọ rà, ọkọ iyawo de; awọn ti o si mura tan bá a wọle lọ si ibi iyawo: a si tì ilẹkun. 11 Ni ikẹhin li awọn wundia iyokù si de, nwọn nwipe, Oluwa, Oluwa, ṣilẹkun fun wa. 12 Ṣugbọn o dahùn, wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, emi kò mọ̀ nyin.
13 Nitorina, ẹ ma ṣọna, bi ẹnyin ko ti mọ̀ ọjọ, tabi wakati ti Ọmọ-enia yio de.Òwe nípa Àwọn Ẹrú Mẹta
(Luk 19:11-27)
14 Nitori ijọba ọrun dabi ọkunrin kan ti o nlọ si àjo, ẹniti o pè awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, o si kó ẹrù rẹ̀ fun wọn. 15 O si fi talenti marun fun ọkan, o fi meji fun ẹnikeji, ati ọkan fun ẹnikẹta; o fifun olukuluku gẹgẹ bi agbara rẹ̀ ti ri; lẹsẹkanna o mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n. 16 Nigbana li eyi ti o gbà talenti marun lọ, ọ fi tirẹ̀ ṣòwo, o si jère talenti marun miran. 17 Gẹgẹ bẹ̃li eyi ti o gbà meji, on pẹlu si jère meji miran. 18 Ṣugbọn eyi ti o gbà talenti kan lọ, o wà ilẹ, o si rì owo oluwa rẹ̀. 19 Lẹhin igba ti o pẹ titi, oluwa awọn ọmọ-ọdọ wọnni de, o ba wọn ṣiro. 20 Eyi ti o gbà talenti marun si wá, o si mu talenti marun miran wá pẹlu, o wipe, Oluwa, iwọ fi talenti marun fun mi: si wò o, mo jère talenti marun miran. 21 Oluwa rẹ̀ wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ: iwọ ṣe olõtọ, ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwo bọ́ sinu ayọ̀ Oluwa rẹ. 22 Eyi ti o gbà talenti meji pẹlu si wá, o wipe, Oluwa, iwọ fi talenti meji fun mi: wo o, mo jère talenti meji miran. 23 Oluwa rẹ̀ si wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ; iwọ ṣe olõtọ ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwọ bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ. 24 Eyi ti o gbà talenti kan si wá, o ni, Oluwa, mo mọ̀ ọ pe onroro enia ni iwọ iṣe, iwọ nkore nibiti iwọ kò gbe funrugbin si, iwọ si nṣà nibiti iwọ kò fẹ́ka si: 25 Emi si bẹ̀ru, mo si lọ pa talenti rẹ mọ́ ninu ilẹ: wo o, nkan rẹ niyi. 26 Oluwa rẹ̀ si dahùn o wi fun u pe, Iwọ ọmọ-ọdọ buburu ati onilọra, iwọ mọ̀ pe emi nkore nibiti emi kò funrugbin si, emi si nṣà nibiti emi kò fẹ́ka si: 27 Nitorina iwọ iba fi owo mi si ọwọ́ awọn ti npowodà, nigbati emi ba de, emi iba si gbà nkan mi pẹlu elé. 28 Nitorina ẹ gbà talenti na li ọwọ́ rẹ̀, ẹ si fifun ẹniti o ni talenti mẹwa. 29 Nitori ẹnikẹni ti o ba ni, li a o fifun, yio si ni lọpọlọpọ: ṣugbọn li ọwọ́ ẹniti kò ni li a o tilẹ gbà eyi ti o ni.
30 Ẹ si gbé alailere ọmọ-ọdọ na sọ sinu òkunkun lode: nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.Ìdájọ́ Àwọn Orílẹ̀-èdè
31 Nigbati Ọmọ-enia yio wá ninu ogo rẹ̀, ati gbogbo awọn angẹli mimọ́ pẹlu rẹ̀, nigbana ni yio joko lori itẹ́ ogo rẹ̀: 32 Niwaju rẹ̀ li a o si kó gbogbo orilẹ ède jọ: yio si yà wọn si ọ̀tọ kuro ninu ara wọn gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ti iyà agutan rẹ̀ kuro ninu ewurẹ: 33 On o si fi agutan si ọwọ́ ọtún rẹ̀, ṣugbọn awọn ewurẹ si ọwọ́ òsi. 34 Nigbana li Ọba yio wi fun awọn ti o wà li ọwọ́ ọtun rẹ pe, Ẹ wá, ẹnyin alabukun-fun Baba mi, ẹ jogún ijọba, ti a ti pèse silẹ fun nyin lati ọjọ ìwa: 35 Nitori ebi pa mi, ẹnyin si fun mi li onjẹ: ongbẹ gbẹ mi, ẹnyin si fun mi li ohun mimu: mo jẹ alejò, ẹnyin si gbà mi si ile: 36 Mo wà ni ìhoho, ẹnyin si daṣọ bò mi: mo ṣe aisan, ẹnyin si bojuto mi: mo wà ninu tubu, ẹnyin si tọ̀ mi wá. 37 Nigbana li awọn olõtọ yio da a lohun wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, ti awa fun ọ li onjẹ? tabi ti ongbẹ ngbẹ ọ, ti awa fun ọ li ohun mimu? 38 Nigbawo li awa ri ọ li alejò, ti a gbà ọ si ile? tabi ti iwọ wà ni ìhoho, ti awa daṣọ bò ọ? 39 Tabi nigbawo li awa ri ti iwọ ṣe aisan, ti a bojuto ọ? tabi ti iwọ wà ninu tubu, ti awa si tọ̀ ọ wá? 40 Ọba yio si dahùn yio si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakunrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹnyin ti ṣe e fun mi. 41 Nigbana ni yio si wi fun awọn ti ọwọ́ òsi pe, Ẹ lọ kuro lọdọ mi, ẹnyin ẹni egun, sinu iná ainipẹkun, ti a ti pèse silẹ fun Eṣu ati fun awọn angẹli rẹ̀: 42 Nitori ebi pa mi, ẹnyin kò si fun mi li onjẹ: ongbẹ gbẹ mi, ẹnyin kò si fun mi li ohun mimu: 43 Mo jẹ alejò, ẹnyin kò gbà mi si ile: mo wà ni ìhoho, ẹnyin kò si daṣọ bò mi: mo ṣàisan, mo si wà ninu tubu, ẹnyin kò bojuto mi. 44 Nigbana ni awọn pẹlu yio dahùn wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, tabi ti ongbẹ ngbẹ ọ, tabi ti iwọ jẹ alejò, tabi ti iwọ wà ni ìhoho, tabi ninu aisan, tabi ninu tubu, ti awa kò si ṣe iranṣẹ fun ọ? 45 Nigbana ni yio da wọn lohun wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin kò ti ṣe e fun ọkan ninu awọn ti o kere julọ wọnyi, ẹnyin kò ṣe e fun mi. 46 Awọn wọnyi ni yio si kọja lọ sinu ìya ainipẹkun: ṣugbọn awọn olõtọ si ìye ainipẹkun.
Matthew 25
Parable of Ten Virgins
1 "Then the kingdom of heaven will be comparable to ten virgins, who took their lamps and went out to meet the bridegroom.2 Five of them were foolish, and five were prudent.3 For when the foolish took their lamps, they took no oil with them,4 but the prudent took oil in flasks along with their lamps.5 Now while the bridegroom was delaying, they all got drowsy and began to sleep.6 But at midnight there was a shout, 'Behold, the bridegroom! Come out to meet him.'7 Then all those virgins rose and trimmed their lamps.8 The foolish said to the prudent, 'Give us some of your oil, for our lamps are going out.'9 But the prudent answered, 'No, there will not be enough for us and you too; go instead to the dealers and buy some for yourselves.'10 And while they were going away to make the purchase, the bridegroom came, and those who were ready went in with him to the wedding feast; and the door was shut.11 Later the other virgins also came, saying, 'Lord, lord, open up for us.'12 But he answered, 'Truly I say to you, I do not know you.'13 Be on the alert then, for you do not know the day nor the hour.
Parable of the Talents
14 "For it is just like a man about to go on a journey, who called his own slaves and entrusted his possessions to them.15 To one he gave five talents, to another, two, and to another, one, each according to his own ability; and he went on his journey.16 Immediately the one who had received the five talents went and traded with them, and gained five more talents.17 In the same manner the one who had received the two talents gained two more.18 But he who received the one talent went away, and dug a hole in the ground and hid his master's money.
19 "Now after a long time the master of those slaves *came and *settled accounts with them.20 The one who had received the five talents came up and brought five more talents, saying, 'Master, you entrusted five talents to me. See, I have gained five more talents.'21 His master said to him, 'Well done, good and faithful slave. You were faithful with a few things, I will put you in charge of many things; enter into the joy of your master.'
22 "Also the one who had received the two talents came up and said, 'Master, you entrusted two talents to me. See, I have gained two more talents.'23 His master said to him, 'Well done, good and faithful slave. You were faithful with a few things, I will put you in charge of many things; enter into the joy of your master.'
24 "And the one also who had received the one talent came up and said, 'Master, I knew you to be a hard man, reaping where you did not sow and gathering where you scattered no seed.25 And I was afraid, and went away and hid your talent in the ground. See, you have what is yours.'
26 "But his master answered and said to him, 'You wicked, lazy slave, you knew that I reap where I did not sow and gather where I scattered no seed.27 Then you ought to have put my money in the bank, and on my arrival I would have received my money back with interest.28 Therefore take away the talent from him, and give it to the one who has the ten talents.'
29 "For to everyone who has, more shall be given, and he will have an abundance; but from the one who does not have, even what he does have shall be taken away.30 Throw out the worthless slave into the outer darkness; in that place there will be weeping and gnashing of teeth.
The Judgment
31 "But when the Son of Man comes in His glory, and all the angels with Him, then He will sit on His glorious throne.32 All the nations will be gathered before Him; and He will separate them from one another, as the shepherd separates the sheep from the goats;33 and He will put the sheep on His right, and the goats on the left.
34 "Then the King will say to those on His right, 'Come, you who are blessed of My Father, inherit the kingdom prepared for you from the foundation of the world.35 For I was hungry, and you gave Me something to eat; I was thirsty, and you gave Me something to drink; I was a stranger, and you invited Me in;36 naked, and you clothed Me; I was sick, and you visited Me; I was in prison, and you came to Me.'37 Then the righteous will answer Him, 'Lord, when did we see You hungry, and feed You, or thirsty, and give You something to drink?38 And when did we see You a stranger, and invite You in, or naked, and clothe You?39 When did we see You sick, or in prison, and come to You?'40 The King will answer and say to them, 'Truly I say to you, to the extent that you did it to one of these brothers of Mine, even the least of them, you did it to Me.'
41 "Then He will also say to those on His left, 'Depart from Me, accursed ones, into the eternal fire which has been prepared for the devil and his angels;42 for I was hungry, and you gave Me nothing to eat; I was thirsty, and you gave Me nothing to drink;43 I was a stranger, and you did not invite Me in; naked, and you did not clothe Me; sick, and in prison, and you did not visit Me.'44 Then they themselves also will answer, 'Lord, when did we see You hungry, or thirsty, or a stranger, or naked, or sick, or in prison, and did not take care of You?'45 Then He will answer them, 'Truly I say to you, to the extent that you did not do it to one of the least of these, you did not do it to Me.'46 These will go away into eternal punishment, but the righteous into eternal life."