previous next

Mat 28

Ajinde Jesu

(Mak 16:1-10; Luk 24:1-12; Joh 20:1-10)

1 LI opin ọjọ isimi, bi ilẹ ọjọ kini ọ̀sẹ ti bèrẹ si imọ́, Maria Magdalene ati Maria keji wá lati wò ibojì na. 2 Si wò o, ìṣẹlẹ nla ṣẹ̀: nitori angẹli Oluwa ti ọrun sọkalẹ wá, o si yi okuta na kuro, o si joko le e. 3 Oju rẹ̀ dabi manamana, aṣọ rẹ̀ si fún bi ẹ̀gbọn owu: 4 Nitori ẹ̀ru rẹ̀ awọn oluṣọ warìri, nwọn si dabi okú. 5 Angẹli na si dahùn, o si wi fun awọn obinrin na pe, Ẹ má bẹ̀ru: nitori emi mọ̀ pe ẹnyin nwá Jesu, ti a ti kàn mọ agbelebu. 6 Kò si nihinyi: nitori o ti jinde gẹgẹ bi o ti wi. Wá, ẹ wò ibiti Oluwa ti dubulẹ si. 7 Ẹ si yara lọ isọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, o ti jinde kuro ninu okú; wo o, ó ṣãju nyin lọ si Galili; nibẹ̀ li ẹnyin o gbé ri i: wo o, mo ti sọ fun nyin. 8 Nwọn si fi ibẹru pẹlu ayọ̀ nla yara lọ kuro ni ibojì; nwọn si saré lọ iròhin fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. 9 Bi nwọn si ti nlọ isọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, wo o, Jesu pade wọn, o wipe, Alafia. Nwọn si wá, nwọn si gbá a li ẹsẹ mu, nwọn si tẹriba fun u.

10 Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: ẹ lọ isọ fun awọn arakunrin mi pe, ki nwọn ki o lọ si Galili, nibẹ̀ ni nwọn o gbé ri mi.

Ìròyìn Àwọn tí Ń Ṣọ́ Ibojì


11 Njẹ bi nwọn ti nlọ, wo o, ninu awọn olusọ wá si ilu, nwọn rohin gbogbo nkan wọnyi ti o ṣe fun awọn olori alufa. 12 Nigbati awọn pẹlu awọn agbàgba pejọ, ti nwọn si gbìmọ, nwọn fi ọ̀pọ owo fun awọn ọmọ-ogun na, 13 Nwọn wi fun wọn pe, Ẹ wipe, Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá li oru, nwọn si ji i gbé lọ nigbati awa sùn. 14 Bi eyi ba de etí Bãlẹ, awa o yi i li ọkàn pada, a o si gbà nyin silẹ.

15 Bẹ̃ni nwọn gbà owo na, nwọn si ṣe gẹgẹ bi a ti kọ́ wọn: ọ̀rọ yi si di rirò kiri lọdọ awọn Ju titi di oni.

Jesu Rán Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ Níṣẹ́

(Mak 16:14-18; Luk 24:36-49; Joh 20:19-23; A. Apo 1:6-8)


16 Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mọkanla jade lọ si Galili, si ori òke ti Jesu ti sọ fun wọn. 17 Nigbati nwọn si ri i, nwọn foribalẹ fun u: ṣugbọn awọn miran ṣiyemeji. 18 Jesu si wá, o si sọ fun wọn, wipe, Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi. 19 Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ́ orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si ma baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmí Mimọ́: 20 Ki ẹ ma kọ́ wọn lati ma kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa li aṣẹ fun nyin: ẹ si kiyesi i, emi wà pẹlu nyin nigbagbogbo, titi o fi de opin aiye. Amin.

11-Feb-2009@11:05, Backup Description=11-Feb-2009@09:10, Ayo Durodola -

08-Apr-2009@14:15, Backup Description=08-Apr-2009@08:23, Ayo Durodola -

08-Apr-2009@14:52, Backup Description=08-Apr-2009@14:37, Ayo Durodola -

22-Dec-2009@14:07, Backup Description=22-Dec-2009@14:01, victor Damilare -

Matthew 28

Jesus Is Risen!

1 Now after the Sabbath, as it began to dawn toward the first day of the week, Mary Magdalene and the other Mary came to look at the grave.2 And behold, a severe earthquake had occurred, for an angel of the Lord descended from heaven and came and rolled away the stone and sat upon it.3 And his appearance was like lightning, and his clothing as white as snow.4 The guards shook for fear of him and became like dead men.5 The angel said to the women, "Do not be afraid; for I know that you are looking for Jesus who has been crucified.6 He is not here, for He has risen, just as He said. Come, see the place where He was lying.7 Go quickly and tell His disciples that He has risen from the dead; and behold, He is going ahead of you into Galilee, there you will see Him; behold, I have told you."

8 And they left the tomb quickly with fear and great joy and ran to report it to His disciples.9 And behold, Jesus met them and greeted them. And they came up and took hold of His feet and worshiped Him.10 Then Jesus *said to them, "Do not be afraid; go and take word to My brethren to leave for Galilee, and there they will see Me."

11 Now while they were on their way, some of the guard came into the city and reported to the chief priests all that had happened.12 And when they had assembled with the elders and consulted together, they gave a large sum of money to the soldiers,13 and said, "You are to say, 'His disciples came by night and stole Him away while we were asleep.'14 And if this should come to the governor's ears, we will win him over and keep you out of trouble."15 And they took the money and did as they had been instructed; and this story was widely spread among the Jews, and is to this day.

The Great Commission

16 But the eleven disciples proceeded to Galilee, to the mountain which Jesus had designated.17 When they saw Him, they worshiped Him; but some were doubtful.18 And Jesus came up and spoke to them, saying, "All authority has been given to Me in heaven and on earth.19 Go therefore and make disciples of all the nations, baptizing them in the name of the Father and the Son and the Holy Spirit,20 teaching them to observe all that I commanded you; and lo, I am with you always, even to the end of the age."