Mat 4
Satani Dán Jesu Wò
(Mak 1:12-13; Luk 4:1-13)
1 NIGBANA li a dari Jesu si ijù lati ọwọ́ Ẹmi lati dán a wò lọwọ Èṣu. 2 Nigbati o si ti gbàwẹ li ogoji ọsán ati ogoji oru, lẹhinna ni ebi npa a. 3 Nigbati oludanwò de ọdọ rẹ̀, o ni, Bi iwọ ba iṣe Ọmọ Ọlọrun, paṣẹ ki okuta wọnyi di akara. 4 Ṣugbọn o dahùn wipe, A ti kọwe rẹ̀ pe, Enia kì yio wà lãyè nipa akara nikan, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ ti o ti ẹnu Ọlọrun jade wá. 5 Nigbana ni Èṣu gbé e lọ soke si ilu mimọ́ nì, o gbé e le ṣonṣo tẹmpili, 6 O si wi fun u pe, Bi iwọ ba iṣe Ọmọ Ọlọrun, bẹ́ silẹ fun ara rẹ: A sá ti kọwe rẹ̀ pe, Yio paṣẹ fun awọn angẹli rẹ̀ nitori rẹ, li ọwọ́ wọn ni nwọn o si gbé ọ soke, ki iwọ ki o má ba fi ẹsẹ rẹ gbún okuta. 7 Jesu si wi fun u pe, A tún kọ ọ pe, Iwọ ko gbọdọ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò. 8 Èṣu gbé e lọ si ori òke giga-giga ẹ̀wẹ, o si fi gbogbo ilẹ ọba aiye ati gbogbo ogo wọn hàn a; 9 O si wi fun u pe, Gbogbo nkan wọnyi li emi ó fifun ọ, bi iwọ ba wolẹ, ti o si foribalẹ fun mi. 10 Nigbana ni Jesu wi fun u pe, Pada kuro lẹhin mi, Satani: nitori a kọwe rẹ̀ pe, Oluwa Ọlọrun rẹ ni ki iwọ ki o foribalẹ fun, on nikanṣoṣo ni ki iwọ mã sìn.
11 Nigbana li Èṣu fi i silẹ lọ; si kiyesi i, awọn angẹli tọ̀ ọ wá, nwọn si nṣe iranṣẹ fun u.Jesu Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ ní Galili
(Mak 1:14-15; Luk 4:14-15)
12 Nigbati Jesu gbọ́ pe, a fi Johanu le wọn lọwọ, o dide lọ si Galili; 13 Nigbati o si jade kuro ni Nasareti, o wá ijoko ni Kapernaumu, eyi ti o mbẹ leti okun li ẹkùn Sebuloni ati Neftalimu: 14 Ki eyi ti a wi lati ẹnu woli Isaiah wá le ṣẹ, pe, 15 Ilẹ Sebuloni ati ilẹ Neftalimu li ọ̀na okun, li oke Jordani, Galili awọn keferi; 16 Awọn enia ti o joko li òkunkun ri imọlẹ nla; ati awọn ti o joko ni ibi iku ati labẹ ojiji rẹ̀ ni imọlẹ là fun.
17 Lati igbana ni Jesu bẹ̀rẹ si iwasu wipe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ.Jesu Pe Apẹja Mẹrin
(Mak 1:16-20; Luk 5:1-11)
18 Jesu nrin leti okun Galili, o ri awọn arakunrin meji, Simoni, ẹniti a npè ni Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀, nwọn nsọ àwọn sinu okun: nitori nwọn jẹ apẹja. 19 O si wi fun wọn pe, Ẹ mã tọ̀ mi lẹhin, emi ó si sọ nyin di apẹja enia. 20 Nwọn si fi àwọn silẹ lojukanna, nwọn sì tọ̀ ọ lẹhin. 21 Bi o si ti ti ibẹ lọ siwaju, o ri awọn arakunrin meji, Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀, ninu ọkọ̀ pẹlu Sebede baba wọn, nwọn ndí àwọn wọn; o si pè wọn.
22 Lojukanna nwọn si fi ọkọ̀ ati baba wọn silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.Jesu Ń Ṣiṣẹ́ láàrin Ọpọlọpọ Eniyan
(Luk 6:17-19)
23 Jesu si rìn ni gbogbo ẹkùn Galili, o nkọni ni sinagogu wọn, o si nwasu ihinrere ijọba, o si nṣe iwosàn gbogbo àrun ati gbogbo àisan li ara awọn enia. 24 Okikí rẹ̀ si kàn yi gbogbo Siria ká; nwọn si gbé awọn alaisàn ti o ni onirũru àrun ati irora wá sọdọ rẹ̀, ati awọn ti o li ẹmi èṣu, ati awọn ti o nsinwin, ati awọn ti o li ẹ̀gba; o si wò wọn sàn. 25 Ọpọlọpọ enia si tọ̀ ọ lẹhin lati Galili, ati Dekapoli, ati Jerusalemu, ati lati Judea wá, ati lati oke odò Jordani.
Matthew 4
The Temptation of Jesus
1 Then Jesus was led up by the Spirit into the wilderness to be tempted by the devil.2 And after He had fasted forty days and forty nights, He tthen became hungry.3 And the tempter came and said to Him, "If You are the Son of God, command that these stones become bread."4 But He answered and said, "It is written, 'MAN SHALL NOT LIVE ON BREAD ALONE, BUT ON EVERY WORD THAT PROCEEDS OUT OF THE MOUTH OF GOD.'"
5 Then the devil *took Him into the holy city and had Him stand on the pinnacle of the temple,
6 and *said to Him, "If You are the Son of God, throw Yourself down; for it is written,
'HE WILL COMMAND HIS ANGELS CONCERNING YOU';
and
'ON their HANDS THEY WILL BEAR YOU UP,
SO THAT YOU WILL NOT STRIKE YOUR FOOT AGAINST A STONE.'"7 Jesus said to him, "On the other hand, it is written, 'YOU SHALL NOT PUT THE LORD YOUR GOD TO THE TEST.'"
8 Again, the devil *took Him to a very high mountain and *showed Him all the kingdoms of the world and their glory;9 and he said to Him, "All these things I will give You, if You fall down and worship me."10 Then Jesus *said to him, "Go, Satan! For it is written, 'YOU SHALL WORSHIP THE LORD YOUR GOD, AND SERVE HIM ONLY.'"11 Then the devil *left Him; and behold, angels came and began to minister to Him.
Jesus Begins His Ministry
12 Now when Jesus heard that John had been taken into custody, He withdrew into Galilee;13 and leaving Nazareth, He came and settled in Capernaum, which is by the sea, in the region of Zebulun and Naphtali.14 This was to fulfill what was spoken through Isaiah the prophet:
15 "THE LAND OF ZEBULUN AND THE LAND OF NAPHTALI,
BY THE WAY OF THE SEA, BEYOND THE JORDAN, GALILEE OF THE tGENTILES-
16 "THE PEOPLE WHO WERE SITTING IN DARKNESS SAW A GREAT LIGHT,
AND THOSE WHO WERE SITTING IN THE LAND AND SHADOW OF DEATH,
UPON THEM A LIGHT DAWNED."
17 From that time Jesus began to preach and say, "Repent, for the kingdom of heaven is at hand."
The First Disciples
18 Now as Jesus was walking by the Sea of Galilee, He saw two brothers, Simon who was called Peter, and Andrew his brother, casting a net into the sea; for they were fishermen.19 And He *said to them, "Follow Me, and I will make you fishers of men."20 Immediately they left their nets and followed Him.21 Going on from there He saw two other brothers, James the son of Zebedee, and John his brother, in the boat with Zebedee their father, mending their nets; and He called them.22 Immediately they left the boat and their father, and followed Him.
Ministry in Galilee
23 Jesus was going throughout all Galilee, teaching in their synagogues and proclaiming the gospel of the kingdom, and healing every kind of disease and every kind of sickness among the people.
24 The news about Him spread throughout all Syria; and they brought to Him all who were ill, those suffering with various diseases and pains, demoniacs, epileptics, paralytics; and He healed them.25 Large crowds followed Him from Galilee and the Decapolis and Jerusalem and Judea and from beyond the Jordan.