Mat 5
Iwaasu Jesu lórí Òkè
1 NIGBATI o si ri ọ̀pọ enia, o gùn ori òke lọ: nigbati o si joko, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá.
2 O si yà ẹnu rẹ̀, o si kọ́ wọn, wipe,Àwọn tí Ayọ̀ Wà fún
(Luk 6:20-23)
3 Alabukún-fun li awọn òtoṣi li ẹmí: nitori tiwọn ni ijọba ọrun. 4 Alabukún-fun li awọn ẹniti nkãnu: nitoriti a ó tù wọn ninu. 5 Alabukún-fun li awọn ọlọkàn-tutù: nitori nwọn o jogún aiye. 6 Alabukún-fun li awọn ẹniti ebi npa ati ti ongbẹ ngbẹ sipa ododo: nitori nwọn ó yo. 7 Alabukún-fun li awọn alãnu: nitori nwọn ó ri ãnu gbà. 8 Alabukún-fun li awọn oninu-funfun: nitori nwọn ó ri Ọlọrun. 9 Alabukún-fun li awọn onilaja: nitori ọmọ Ọlọrun ni a ó ma pè wọn. 10 Alabukúnfun li awọn ẹniti a ṣe inunibini si nitori ododo: nitori tiwọn ni ijọba ọrun. 11 Alabukún-fun li ẹnyin, nigbati nwọn ba nkẹgan nyin, ti nwọn ba nṣe inunibini si nyin, ti nwọn ba nfi eke sọ̀rọ buburu gbogbo si nyin nitori emi.
12 Ẹ mã yọ̀, ki ẹnyin ki o si fò fun ayọ̀: nitori ère nyin pọ̀ li ọrun: bẹ̃ni nwọn sá ṣe inunibini si awọn wolĩ ti o ti mbẹ ṣaju nyin.Iyọ̀ ati Ìmọ́lẹ̀
(Mak 9:50; Luk 14:34-35)
13 Ẹnyin ni iyọ̀ aiye: ṣugbọn bi iyọ̀ ba di obu, kini a o fi mu u dùn? kò nilari mọ́, bikoṣepe a dà a nù, ki o si di itẹmọlẹ li atẹlẹsẹ enia. 14 Ẹnyin ni imọlẹ aiye. Ilu ti a tẹ̀do lori òke ko le farasin. 15 Bẹ̃ni a kì itàn fitila tan, ki a si fi i sabẹ òṣuwọn; bikoṣe lori ọpá fitila, a si fi imọlẹ fun gbogbo ẹniti mbẹ ninu ile.
16 Ẹ jẹ ki imọlẹ nyin ki o mọlẹ tobẹ̃ niwaju enia, ki nwọn ki o le mã ri iṣẹ rere nyin, ki nwọn ki o le ma yìn Baba nyin ti mbẹ li ọrun logo.Ẹ̀kọ́ nípa Òfin Mose
17 Ẹ máṣe rò pe, emi wá lati pa ofin tabi awọn wolĩ run: emi kò wá lati parun, bikoṣe lati muṣẹ. 18 Lõtọ ni mo sá wi fun nyin, Titi ọrun on aiye yio fi kọja lọ, ohun kikini kan ninu ofin kì yio kọja, bi o ti wù ki o ri, titi gbogbo rẹ̀ yio fi ṣẹ. 19 Ẹnikẹni ti o ba rú ọkan kikini ninu ofin wọnyi, ti o ba si nkọ́ awọn enia bẹ̃, on na li a o pè ni kikini ni ijọba ọrun: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nṣe wọn ti o ba si nkọ́ wọn, on na li a o pè ni ẹni-nla ni ijọba ọrun.
20 Nitori mo wi fun nyin, bikoṣepe ododo nyin ba kọja ododo awọn akọwe ati ti awọn Farisi, ẹnyin kì yio le de ilẹ-ọba ọrun bi o ti wù ki o ri.Ẹ̀kọ́ nípa Ibinu
21 Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wi fun awọn ará igbãni pe, Iwọ ko gbọdọ pania; ẹnikẹni ti o ba pania yio wà li ewu idajọ. 22 Ṣugbọn emi wi fun nyin, ẹnikẹni ti o binu si arakunrin rẹ̀ lasan, yio wà li ewu idajọ; ati ẹnikẹni ti o ba wi fun arakunrin rẹ̀ pe, Alainilari, yio wà li ewu ajọ awọn igbimọ; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba wipe, Iwọ aṣiwere, yio wà li ewu iná ọrun apadi. 23 Nitorina bi iwọ ba nmu ẹ̀bun rẹ wá si ibi pẹpẹ, bi iwọ ba si ranti nibẹ pe, arakunrin rẹ li ohun kan ninu si ọ, 24 Fi ẹ̀bun rẹ silẹ nibẹ̀ niwaju pẹpẹ, si lọ, kọ́ ba arakunrin rẹ làja na, nigbana ni ki o to wá ibùn ẹ̀bun rẹ. 25 Ba ọtà rẹ rẹ́ kánkan nigbati iwọ wà li ọ̀na pẹlu rẹ̀; ki ọtá rẹ ki o má ba fi ọ le onidajọ lọwọ, onidajọ a si fi ọ le ẹ̀ṣọ lọwọ, a si gbè ọ sọ sinu tubu.
26 Lõtọ ni mo wi fun ọ, Iwọ kì yio jade kuro nibẹ̀, titi iwọ o fi san õkan ti o ba kù.Ẹ̀kọ́ nípa Àgbèrè
27 Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wi fun awọn ará igbãni pe, Iwọ ko gbọdọ ṣe panṣaga. 28 Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba wò obinrin kan lati ṣe ifẹkufẹ si i, o ti bá a ṣe panṣaga tan li ọkàn rẹ̀. 29 Bi oju ọtún rẹ ba mu ọ kọsẹ̀, yọ ọ jade, ki o si sọ ọ nù; o sá li ère fun ọ, ki ẹ̀ya ara rẹ kan ki o ṣegbé, jù ki a gbe gbogbo ara rẹ jù si iná ọrun apadi.
30 Bi ọwọ́ ọtún rẹ ba mu ọ kọsẹ̀, ke e kuro, ki o si sọ ọ nù; o sá li ère fun ọ, ki ẹ̀ya ara rẹ kan ki o ṣegbé, jù ki a gbe gbogbo ara rẹ jù si iná ọrun apadi.Ẹ̀kọ́ nípa Kíkọ Aya Ẹni Sílẹ̀
(Mat 19:9; Mak 10:11-12; Luk 16:18)
31 A ti wi pẹlu pe, ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, jẹ ki o fi iwe ìkọsilẹ le e lọwọ.
32 Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, bikoṣe nitori àgbere, o mu u ṣe panṣaga; ẹnikẹni ti o ba si gbé ẹniti a kọ̀ silẹ ni iyawo, o ṣe panṣaga.Ẹ̀kọ́ nípa Ìbúra
33 Ẹnyin ti gbọ́ ẹ̀wẹ bi a ti wi fun awọn ará igbãni pe, Iwọ kò gbọdọ bura, bikoṣepe ki iwọ ki o si mu ibura rẹ ṣẹ fun Oluwa. 34 Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ máṣe bura rára, iba ṣe ifi ọrun bura, nitoripe itẹ́ Ọlọrun ni, 35 Tabi aiye, nitori apoti itisẹ rẹ̀ ni, tabi Jerusalemu, nitori ilu ọba nla ni. 36 Ki o maṣe fi ori rẹ bura, nitori iwọ ko le sọ irun kan di funfun tabi dudu.
37 Ṣugbọn jẹ ki ọ̀rọ nyin jẹ, Bẹ̃ni, bẹ̃ni; Bẹ̃kọ, bẹ̃kọ; nitoripe ohunkohun ti o ba jù wọnyi lọ, nipa ibi li o ti wá.Ẹ̀kọ́ nípa Ẹ̀san Gbígbà
(Luk 6:29-30)
38 Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wipe, Oju fun oju, ati ehín fun ehín: 39 Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ máṣe kọ̀ ibi; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba gbá ọ li ẹrẹkẹ ọtún, yi ti òsi si i pẹlu. 40 Bi ẹnikan ba fẹ sùn ọ ni ile ẹjọ, ti o si gbà ọ li ẹ̀wu lọ, jọwọ agbáda rẹ fun u pẹlu. 41 Ẹnikẹni ti yio ba fi agbara mu ọ lọ si maili kan, bá a de meji.
42 Fifun ẹniti o bère lọwọ rẹ; ati lọdọ ẹniti o nfẹ win lọwọ rẹ, máṣe mu oju kuro.Ìfẹ́ sí Ọ̀tá Ẹni
(Luk 6:27-28, 32-36)
43 Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wipe, Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ, ki iwọ si korira ọtá rẹ. 44 Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin ré, ẹ ṣõre fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankàn ba nyin lò, ti nwọn nṣe inunibini si nyin; 45 Ki ẹnyin ki o le mã jẹ ọmọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun: nitoriti o nmu õrùn rẹ̀ ràn sara enia buburu ati sara enia rere, o si nrọ̀jo fun awọn olõtọ ati fun awọn alaiṣõtọ. 46 Nitori bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? bẹ̃ gẹgẹ ki awọn agbowode nṣe? 47 Bi ẹnyin ba si nkí kìki awọn arakunrin nyin, kili ẹ ṣe jù awọn ẹlomiran lọ? bẹ̃ gẹgẹ ki awọn agbowode nṣe? 48 Nitorina ki ẹnyin ki o pé, bi Baba nyin ti mbẹ li ọrun ti pé.
Matthew 5
The Sermon on the Mount; The Beatitudes
1 When Jesus saw the crowds, He went up on the mountain; and after He sat down, His disciples came to Him.2 He opened His mouth and began to teach them, saying,
3 "Blessed are the poor in spirit, for theirs is the kingdom of heaven.
4 "Blessed are those who mourn, for they shall be comforted.
5 "Blessed are the tgentle, for they shall inherit the earth.
6 "Blessed are those who hunger and thirst for righteousness, for they shall be satisfied.
7 "Blessed are the merciful, for they shall receive mercy.
8 "Blessed are the pure in heart, for they shall see God.
9 "Blessed are the peacemakers, for they shall be called sons of God.
10 "Blessed are those who have been persecuted for the sake of righteousness, for theirs is the kingdom of heaven.
11 "Blessed are you when people insult you and persecute you, and falsely say all kinds of evil against you because of Me.12 Rejoice and be glad, for your reward in heaven is great; for in the same way they persecuted the prophets who were before you.
Disciples and the World
13 "You are the salt of the earth; but if the salt has become tasteless, how can it be made salty again? It is no longer good for anything, except to be thrown out and trampled under foot by men.
14 "You are the light of the world. A city set on a hill cannot be hidden;15 nor does anyone light a lamp and put it under a basket, but on the lampstand, and it gives light to all who are in the house.16 Let your light shine before men in such a way that they may see your good works, and glorify your Father who is in heaven.
17 "Do not think that I came to abolish the Law or the Prophets; I did not come to abolish but to fulfill.18 For truly I say to you, until heaven and earth pass away, not the smallest letter or stroke shall pass from the Law until all is accomplished.19 Whoever then annuls one of the least of these commandments, and teaches others to do the same, shall be called least in the kingdom of heaven; but whoever keeps and teaches them, he shall be called great in the kingdom of heaven.
20 "For I say to you that unless your righteousness surpasses that of the scribes and Pharisees, you will not enter the kingdom of heaven.
Personal Relationships
21 "You have heard that the ancients were told, 'YOU SHALL NOT COMMIT MURDER' and 'Whoever commits murder shall be tliable to the court.'22 But I say to you that everyone who is angry with his brother shall be guilty before the court; and whoever says to his brother, 'tYou good-for-nothing,' shall be guilty before tthe supreme court; and whoever says, 'You fool,' shall be guilty enough to go into the tfiery hell.23 Therefore if you are presenting your offering at the altar, and there remember that your brother has something against you,24 leave your offering there before the altar and go; first be reconciled to your brother, and then come and present your offering.25 Make friends quickly with your opponent at law while you are with him on the way, so that your opponent may not hand you over to the judge, and the judge to the officer, and you be thrown into prison.26 Truly I say to you, you will not come out of there until you have paid up the last tcent.
27 "You have heard that it was said, 'YOU SHALL NOT COMMIT ADULTERY';28 but I say to you that everyone who looks at a woman with lust for her has already committed adultery with her in his heart.29 If your right eye makes you stumble, tear it out and throw it from you; for it is better for you to lose one of the parts of your body, than for your whole body to be thrown into hell.30 If your right hand makes you stumble, cut it off and throw it from you; for it is better for you to lose one of the parts of your body, than for your whole body to go into hell.
31 "It was said, 'WHOEVER SENDS HIS WIFE AWAY, LET HIM GIVE HER A CERTIFICATE OF DIVORCE';32 but I say to you that everyone who divorces his wife, except for the reason of unchastity, makes her commit adultery; and whoever marries a divorced woman commits adultery.
33 "Again, you have heard that the ancients were told, 'YOU SHALL NOT MAKE FALSE VOWS, BUT SHALL FULFILL YOUR VOWS TO THE LORD.'34 But I say to you, make no oath at all, either by heaven, for it is the throne of God,35 or by the earth, for it is the footstool of His feet, or by Jerusalem, for it is THE CITY OF THE GREAT KING.36 Nor shall you make an oath by your head, for you cannot make one hair white or black.37 But let your statement be, 'Yes, yes' or 'No, no'; anything beyond these is of evil.
38 "You have heard that it was said, 'AN EYE FOR AN EYE, AND A TOOTH FOR A TOOTH.'39 But I say to you, do not resist an evil person; but whoever slaps you on your right cheek, turn the other to him also.40 If anyone wants to sue you and take your tshirt, let him have your tcoat also.41 Whoever forces you to go one mile, go with him two.42 Give to him who asks of you, and do not turn away from him who wants to borrow from you.
43 "You have heard that it was said, 'YOU SHALL LOVE YOUR NEIGHBOR and hate your enemy.'44 But I say to you, love your enemies and pray for those who persecute you,45 so that you may be sons of your Father who is in heaven; for He causes His sun to rise on the evil and the good, and sends rain on the righteous and the unrighteous.46 For if you love those who love you, what reward do you have? Do not even the tax collectors do the same?47 If you greet only your brothers, what more are you doing than others? Do not even the Gentiles do the same?48 Therefore you are to be perfect, as your heavenly Father is perfect.