previous next

Mat 6

Ẹ̀kọ́ nípa Ìtọrẹ Àánú

1 Ẹ kiyesi ara ki ẹ máṣe itọrẹ anu nyin niwaju enia, ki a ba le ri nyin: bi o ba ri bẹ̃, ẹnyin ko li ère lọdọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun. 2 Nitorina nigbati iwọ ba nṣe itọrẹ ãnu rẹ, máṣe fun fère niwaju rẹ, bi awọn agabagebe ti nṣe ni sinagogu ati ni ita, ki nwọn ki o le gbà iyìn enia. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na. 3 Ṣugbọn nigbati iwọ ba nṣe itọrẹ ãnu rẹ, máṣe jẹ ki ọwọ́ òsi rẹ ki o mọ̀ ohun ti ọwọ́ ọtún rẹ nṣe;

4 Ki itọrẹ ãnu rẹ ki o le wà ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ, on tikararẹ̀ yio san a fun ọ ni gbangba.

Ẹ̀kọ́ nípa Adura

(Luk 11:2-4)


5 Nigbati iwọ ba ngbadura, máṣe dabi awọn agabagebe; nitori nwọn fẹ ati mã duro gbadura ni sinagogu ati ni igun ọ̀na ita, ki enia ki o ba le ri wọn. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na. 6 Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbadura, wọ̀ iyẹwu rẹ lọ, nigbati iwọ ba si sé ilẹkùn rẹ tan, gbadura si Baba rẹ ti mbẹ ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ yio san a fun ọ ni gbangba. 7 Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba ngbadura, ẹ máṣe atunwi asan bi awọn keferi; nwọn ṣebi a o ti itori ọ̀rọ pipọ gbọ́ ti wọn. 8 Nitorina ki ẹnyin máṣe dabi wọn: Baba nyin sá mọ̀ ohun ti ẹnyin ṣe alaini, ki ẹ to bère lọwọ rẹ̀. 9 Nitorina bayi ni ki ẹnyin mã gbadura: Baba wa ti mbẹ li ọrun; Ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ. 10 Ki ijọba rẹ de; Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹ̃ni li aiye. 11 Fun wa li onjẹ õjọ wa loni. 12 Dari gbese wa jì wa, bi awa ti ndarijì awọn onigbese wa. 13 Má si fà wa sinu idẹwò, ṣugbọn gbà wa lọwọ bilisi. Nitori ijọba ni tirẹ, ati agbara, ati ogo, lailai. Amin. 14 Nitori bi ẹnyin ba fi ẹ̀ṣẹ awọn enia jì wọn, Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi ẹ̀ṣẹ ti nyin jì nyin.

15 Ṣugbọn bi ẹnyin ko ba fi ẹ̀ṣẹ awọn enia jì wọn, Baba nyin ki yio si fi ẹ̀ṣẹ ti nyin jì nyin.

Ẹ̀kọ́ nípa Ààwẹ̀ Gbígbà


16 Ati pẹlu nigbati ẹnyin ba ngbàwẹ, ẹ máṣe dabi awọn agabagebe ti nfajuro; nwọn a ba oju jẹ, nitori ki nwọn ki o ba le farahàn fun enia pe nwọn ngbàwẹ. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na. 17 Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbàwẹ, fi oróro kùn ori rẹ, ki o si bọju rẹ;

18 Ki iwọ ki o máṣe farahàn fun enia pe iwọ ngbàwẹ, bikoṣe fun Baba rẹ ti o mbẹ ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ yio san a fun ọ ni gbangba.

Ìṣúra ní Ọ̀run

(Luk 12:33-34)


19 Ẹ máṣe tò iṣura jọ fun ara nyin li aiye, nibiti kòkoro ati ipãra ibà a jẹ, ati nibiti awọn olè irunlẹ ti nwọn si ijale: 20 Ṣugbọn ẹ tò iṣura jọ fun ara nyin li ọrun, nibiti kòkoro ati ipãra ko le bà a jẹ, ati nibiti awọn olè kò le runlẹ ki nwọn si jale.

21 Nitori nibiti iṣura nyin bá gbé wà, nibẹ̀ li ọkàn nyin yio gbé wà pẹlu.

Ìmọ́lẹ̀ Ara

(Luk 11:34-36)


22 Oju ni fitila ara: nitorina bi oju rẹ ba mọ́, gbogbo ara rẹ ni yio kún fun imọlẹ.

23 Ṣugbọn bi oju rẹ ba ṣõkùn, gbogbo ara rẹ ni yio kun fun òkunkun. Njẹ bi imọlẹ ti mbẹ ninu rẹ ba jẹ́ òkunkun, òkunkun na yio ti pọ̀ to!

Ọlọrun ati Ohun Ìní Eniyan

(Luk 16:13; 12:22-31)


24 Ko si ẹniti o le sìn oluwa meji: nitori yala yio korira ọkan, yio si fẹ ekeji; tabi yio faramọ ọkan, yio si yàn ekeji ni ipọsi. Ẹnyin ko le sìn Oluwa pẹlu mammoni. 25 Nitorina mo wi fun nyin, Ẹ máṣe ṣe aniyan nitori ẹmí nyin ohun ti ẹ ó jẹ, ati fun ara nyin ohun ti ẹ o fi bora. Ẹmí kò ha jù onjẹ lọ? tabi ara ni kò jù aṣọ lọ? 26 Ẹ sá wò ẹiyẹ oju ọrun; nwọn kì ifunrugbin, bẹ̃ni nwọn kì ikore, nwọn kì isi ikójọ sinu abà, ṣugbọn Baba nyin ti mbẹ li ọrun mbọ́ wọn. Ẹnyin kò ha san jù wọn lọ? 27 Tani ninu nyin nipa aniyàn ṣiṣe ti o le fi igbọnwọ kan kún ọjọ aiyé rẹ̀? 28 Ẽṣe ti ẹnyin sì fi nṣe aniyan nitori aṣọ? Kiyesi lili ti mbẹ ni igbẹ́, bi nwọn ti ndàgba; nwọn kì iṣiṣẹ, bẹ̃ni nwọn kì irànwu: 29 Mo si wi fun nyin pe, a ko ṣe Solomoni pãpã li ọṣọ ninu gbogbo ogo rẹ̀ to bi ọkan ninu wọnyi. 30 Njẹ bi Ọlọrun ba wọ̀ koriko igbẹ́ li aṣọ bẹ̃, eyiti o wà loni, ti a si gbá a sinu iná lọla, melomelo ni ki yio fi le wọ̀ nyin li aṣọ, ẹnyin oni-kekere igbagbọ? 31 Nitorina ẹ maṣe ṣe aniyan, wipe, Kili a o jẹ? tabi, Kili a o mu? tabi, aṣọ wo li a o fi wọ̀ wa? 32 Nitori gbogbo nkan wọnyi li awọn keferi nwá kiri. Nitori Baba nyin ti mbẹ li ọrun mọ̀ pe, ẹnyin kò le ṣe alaini gbogbo nkan wọnyi. 33 Ṣugbọn ẹ tète mã wá ijọba Ọlọrun na, ati ododo rẹ̀; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún u fun nyin. 34 Nitorina ẹ máṣe ṣe aniyan nitori ọla; ọla ni yio ṣe aniyan ohun ara rẹ̀. Buburu ti õjọ to fun u.

Matthew 6

Giving to the Poor and Prayer

1 "Beware of practicing your righteousness before men to be noticed by them; otherwise you have no reward with your Father who is in heaven.

2 "So when you give to the poor, do not sound a trumpet before you, as the hypocrites do in the synagogues and in the streets, so that they may be honored by men. Truly I say to you, they have their reward in full.3 But when you give to the poor, do not let your left hand know what your right hand is doing,4 so that your giving will be in secret; and your Father who sees what is done in secret will reward you.

5 "When you pray, you are not to be like the hypocrites; for they love to stand and pray in the synagogues and on the street corners so that they may be seen by men. Truly I say to you, they have their reward in full.6 But you, when you pray, go into your inner room, close your door and pray to your Father who is in secret, and your Father who sees what is done in secret will reward you.

7 "And when you are praying, do not use meaningless repetition as the Gentiles do, for they suppose that they will be heard for their many words.8 So do not be like them; for your Father knows what you need before you ask Him.

9 "Pray, then, in this way:
'Our Father who is in heaven,
Hallowed be Your name.

10 'Your kingdom come.
Your will be done,
On earth as it is in heaven.

11 'Give us this day our daily bread.

12 'And forgive us our debts, as we also have forgiven our debtors.

13 'And do not lead us into temptation, but deliver us from evil. [For Yours is the kingdom and the power and the glory forever. Amen.']14 For if you forgive others for their transgressions, your heavenly Father will also forgive you.15 But if you do not forgive others, then your Father will not forgive your transgressions.

Fasting; The True Treasure; Wealth (Mammon)

16 "Whenever you fast, do not put on a gloomy face as the hypocrites do, for they neglect their appearance so that they will be noticed by men when they are fasting. Truly I say to you, they have their reward in full.17 But you, when you fast, anoint your head and wash your face18 so that your fasting will not be noticed by men, but by your Father who is in secret; and your Father who sees what is done in secret will reward you.

19 "Do not store up for yourselves treasures on earth, where moth and rust destroy, and where thieves break in and steal.20 But store up for yourselves treasures in heaven, where neither moth nor rust destroys, and where thieves do not break in or steal;21 for where your treasure is, there your heart will be also.

22 "The eye is the lamp of the body; so then if your eye is clear, your whole body will be full of light.23 But if your eye is bad, your whole body will be full of darkness. If then the light that is in you is darkness, how great is the darkness!

24 "No one can serve two masters; for either he will hate the one and love the other, or he will be devoted to one and despise the other. You cannot serve God and twealth.

The Cure for Anxiety

25 "For this reason I say to you, do not be worried about your life, as to what you will eat or what you will drink; nor for your body, as to what you will put on. Is not life more than food, and the body more than clothing?26 Look at the birds of the air, that they do not sow, nor reap nor gather into barns, and yet your heavenly Father feeds them. Are you not worth much more than they?27 And who of you by being worried can add a single hour to his life?28 And why are you worried about clothing? Observe how the lilies of the field grow; they do not toil nor do they spin,29 yet I say to you that not even Solomon in all his glory clothed himself like one of these.30 But if God so clothes the grass of the field, which is alive today and tomorrow is thrown into the furnace, will He not much more clothe you? You of little faith!31 Do not worry then, saying, 'What will we eat?' or 'What will we drink?' or 'What will we wear for clothing?'32 For the Gentiles eagerly seek all these things; for your heavenly Father knows that you need all these things.33 But seek first His kingdom and His righteousness, and all these things will be added to you.

34 "So do not worry about tomorrow; for tomorrow will care for itself. Each day has enough trouble of its own.