Mat 7
Ẹ̀kọ́ nípa Dídá Ẹlòmíràn Lẹ́jọ́
(Luk 6:37-38, 41-42)
1 Ẹ máṣe dani li ẹjọ, ki a ma bà da nyin li ẹjọ. 2 Nitori irú idajọ ti ẹnyin ba ṣe, on ni a o si ṣe fun nyin; irú òṣuwọn ti ẹnyin ba fi wọ̀n, on li a o si fi wọ̀n fun nyin. 3 Etiṣe ti iwọ si nwò ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ, ṣugbọn iwọ ko kiyesi ìti igi ti mbẹ li oju ara rẹ? 4 Tabi iwọ o ti ṣe wi fun arakunrin rẹ pe, Jẹ ki emi yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju rẹ, si wò o, ìti igi mbẹ li oju iwọ tikararẹ. 5 Iwọ agabagebe, tètekọ́ yọ ìti igi jade kuro li oju ara rẹ na, nigbana ni iwọ o si to riran gbangba lati yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ kuro.
6 Ẹ máṣe fi ohun mimọ́ fun ajá, ki ẹ má si ṣe sọ ọṣọ́ nyin siwaju ẹlẹdẹ, ki nwọn má ba fi ẹsẹ tẹ̀ wọn mọlẹ, nwọn a si yipada ẹ̀wẹ, nwọn a si bù nyin ṣán.Ẹ̀kọ́ nípa Ìtẹramọ́ Adura
(Luk 11:9-13)
7 Bère, a o si fifun nyin; wá kiri, ẹnyin o si ri; kànkun, a o si ṣí i silẹ fun nyin. 8 Nitori ẹnikẹni ti o bère nri gbà; ẹniti o ba si wá kiri nri: ẹniti o ba si nkànkun, li a o ṣí i silẹ fun. 9 Tabi ọkunrin wo ni ti mbẹ ninu nyin, bi ọmọ rẹ̀ bère akara, ti o jẹ fi okuta fun u? 10 Tabi bi o bère ẹja, ti o jẹ fun u li ejò? 11 Njẹ bi ẹnyin ti iṣe enia buburu, ba mọ̀ bi ã ti fi ẹ̀bun rere fun awọn ọmọ nyin, melomelo ni Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi ohun rere fun awọn ti o bère lọwọ rẹ̀?
12 Nitorina gbogbo ohunkohun ti ẹnyin ba nfẹ ki enia ki o ṣe si nyin, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o si ṣe si wọn gẹgẹ; nitori eyi li ofin ati awọn woli.Ẹnu-ọ̀nà tí Ó Fún
(Luk 13:24)
13 Ẹ ba ẹnu-ọ̀na hihá wọle; gbòro li ẹnu-ọ̀na na, ati onibú li oju ọ̀na na ti o lọ si ibi iparun; òpọlọpọ li awọn ẹniti mba ibẹ̀ wọle.
14 Nitori pe hihá ni ẹnu-ọ̀na na, ati toro li oju-ọ̀na na, ti o lọ si ibi ìye, diẹ li awọn ẹniti o nrin i.Èso Igi ni A Fi Ń Mọ Igi
(Luk 6:43-44)
15 Ẹ mã kiyesi awọn eke woli ti o ntọ̀ nyin wá li awọ agutan, ṣugbọn apanijẹ ikõkò ni nwọn ninu. 16 Eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn. Enia a mã ká eso ajara lori ẹgún ọgàn, tabi eso ọpọtọ lara ẹ̀wọn? 17 Gẹgẹ bẹ̃ gbogbo igi rere ni iso eso rere; ṣugbọn igi buburu ni iso eso buburu. 18 Igi rere ko le so eso buburu, bẹ̃ni igi buburu ko si le so eso rere. 19 Gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a ké e lùlẹ, a si wọ́ ọ sọ sinu iná.
20 Nitorina nipa eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn.Ìjẹ́wọ́ Ẹnu Kò Tó
(Luk 13:25-27)
21 Ki iṣe gbogbo ẹniti npè mi li Oluwa, Oluwa, ni yio wọ ijọba ọrun; bikoṣe ẹniti nṣe ifẹ ti Baba mi ti mbẹ li ọrun. 22 Ọpọlọpọ enia ni yio wi fun mi li ọjọ na pe, Oluwa, Oluwa, awa ko ha sọtẹlẹ li orukọ rẹ? ati orukọ rẹ ki a fi lé awọn ẹmi èṣu jade? ati li orukọ rẹ ki a fi ṣe ọ̀pọ iṣẹ iyanu nla?
23 Nigbana li emi o si wi fun wọn pe, Emi kò mọ̀ nyin ri, ẹ kuro lọdọ mi, ẹnyin oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.Ìpìlẹ̀ Meji
(Luk 6:47-49)
24 Nitorina ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ̀rọ temi wọnyi, ti o ba si ṣe wọn, emi o fi wé ọlọ́gbọn enia kan, ti o kọ́ ile rẹ̀ si ori àpata: 25 Òjo si rọ̀, ikún omi si dé, afẹfẹ si fẹ́ nwọn si bìlu ile na; ko si wó, nitoriti a fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ lori àpata. 26 Ẹnikẹni ti o ba si gbọ́ ọ̀rọ temi wọnyi, ti kò si ṣe wọn, on li emi o fi wé aṣiwere enia kan ti o kọ́ ile rẹ̀ si ori iyanrin:
27 Òjo si rọ̀, ikún omi si de, afẹfẹ si fẹ́, nwọn si bìlu ile na, o si wó; iwó rẹ̀ si pọ̀ jọjọ.Àṣẹ Jesu
28 Nigbati o si ṣe ti Jesu pari gbogbo òrọ wọnyi tan, ẹnu yà gbogbo enia si ẹkọ́ rẹ̀: 29 Nitori o nkọ́ wọn bi ẹniti o li aṣẹ, ki si iṣe bi awọn akọwe.
Matthew 7
Judging Others
1 "Do not judge so that you will not be judged.2 For in the way you judge, you will be judged; and by your standard of measure, it will be measured to you.3 Why do you look at the speck that is in your brother's eye, but do not notice the log that is in your own eye?4 Or how can you say to your brother, 'Let me take the speck out of your eye,' and behold, the log is in your own eye?5 You hypocrite, first take the log out of your own eye, and then you will see clearly to take the speck out of your brother's eye.
6 "Do not give what is holy to dogs, and do not throw your pearls before swine, or they will trample them under their feet, and turn and tear you to pieces.
Prayer and the Golden Rule
7 "Ask, and it will be given to you; seek, and you will find; knock, and it will be opened to you.8 For everyone who asks receives, and he who seeks finds, and to him who knocks it will be opened.9 Or what man is there among you who, when his son asks for a loaf, will give him a stone?10 Or if he asks for a fish, he will not give him a snake, will he?11 If you then, being evil, know how to give good gifts to your children, how much more will your Father who is in heaven give what is good to those who ask Him!
12 "In everything, therefore, treat people the same way you want them to treat you, for this is the Law and the Prophets.
The Narrow and Wide Gates
13 "Enter through the narrow gate; for the gate is wide and the way is broad that leads to destruction, and there are many who enter through it.14 For the gate is small and the way is narrow that leads to life, and there are few who find it.
A Tree and Its Fruit
15 "Beware of the false prophets, who come to you in sheep's clothing, but inwardly are ravenous wolves.16 You will know them by their fruits. Grapes are not gathered from thorn bushes nor figs from thistles, are they?17 So every good tree bears good fruit, but the bad tree bears bad fruit.18 A good tree cannot produce bad fruit, nor can a bad tree produce good fruit.19 Every tree that does not bear good fruit is cut down and thrown into the fire.20 So then, you will know them by their fruits.
21 "Not everyone who says to Me, 'Lord, Lord,' will enter the kingdom of heaven, but he who does the will of My Father who is in heaven will enter.22 Many will say to Me on that day, 'Lord, Lord, did we not prophesy in Your name, and in Your name cast out demons, and in Your name perform many miracles?'23 And then I will declare to them, 'I never knew you; DEPART FROM ME, YOU WHO PRACTICE LAWLESSNESS.'
The Two Foundations
24 "Therefore everyone who hears these words of Mine and acts on them, may be compared to a wise man who built his house on the rock.25 And the rain fell, and the floods came, and the winds blew and slammed against that house; and yet it did not fall, for it had been founded on the rock.26 Everyone who hears these words of Mine and does not act on them, will be like a foolish man who built his house on the sand.27 The rain fell, and the floods came, and the winds blew and slammed against that house; and it fell-and great was its fall."
28 When Jesus had finished these words, the crowds were amazed at His teaching;29 for He was teaching them as one having authority, and not as their scribes.