Filp 2
Jesu Rẹ Ara Rẹ̀ Sílẹ̀
1 NITORINA bi itunu kan ba wà ninu Kristi, bi iṣipẹ ifẹ kan ba si wà, bi ìdapọ ti Ẹmí kan ba wà, bi ìyọ́nu-anu ati iṣeun ba wà, 2 Ẹ mu ayọ̀ mi kún, ki ẹnyin ki o le jẹ oninu kanna, ki imọ̀ nyin ki o ṣọkan, ki ẹ si ni ọkàn kan. 3 Ẹ máṣe fi ìja tabi ogo asan ṣe ohunkohun: ṣugbọn ni irẹlẹ ọkàn ki olukuluku ro awọn ẹlomiran si ẹniti o san ju on tikararẹ̀ lọ. 4 Ki olukuluku nyin ki o máṣe wo ohun tirẹ̀, ṣugbọn olukuluku ohun ti ẹlomiran. 5 Ẹ ni ero yi ninu nyin, eyi ti o ti wà pẹlu ninu Kristi Jesu: 6 Ẹniti o tilẹ jẹ aworan Ọlọrun, ti kò ka a si iwọra lati ba Ọlọrun dọgba: 7 Ṣugbọn o bọ́ ogo rẹ̀ silẹ, o si mu awọ̀ iranṣẹ, a si ṣe e ni awòran enia. 8 Nigbati a si ti ri i ni ìri enia, o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, o si tẹriba titi di oju ikú, ani ikú ori agbelebu. 9 Nitorina Ọlọrun pẹlu si ti gbé e ga gidigidi, o si ti fi orukọ kan fun u ti o bori gbogbo orukọ: 10 Pe, li orukọ Jesu ni ki gbogbo ẽkun ki o mã kunlẹ, awọn ẹniti mbẹ li ọrun, ati awọn ẹniti mbẹ ni ilẹ, ati awọn ẹniti mbẹ nisalẹ ilẹ;
11 Ati pe ki gbogbo ahọn ki o mã jẹwọ pe, Jesu Kristi ni Oluwa, fun ogo Ọlọrun Baba.Onigbagbọ Jẹ́ Ìmọ́lẹ̀ ninu Ayé
12 Nitorina ẹnyin olufẹ mi, gẹgẹ bi ẹnyin ti ngbọran nigbagbogbo, kì iṣe nigbati mo wà lọdọ nyin nikan, ṣugbọn papa nisisiyi ti emi kò si, ẹ mã ṣiṣẹ igbala nyin yọri pẹlu ìbẹru ati iwarìri, 13 Nitoripe Ọlọrun ni nṣiṣẹ ninu nyin, lati fẹ ati lati ṣiṣẹ fun ifẹ inu rere rẹ̀. 14 Ẹ mã ṣe ohun gbogbo li aisi ikùnsinu ati ijiyan. 15 Ki ẹnyin ki o le jẹ alailẹgàn ati oniwa tutu, ọmọ Ọlọrun, alailabawọn, larin oniwà wíwọ ati alarekereke orilẹ-ede, larin awọn ẹniti a nri nyin bi imọlẹ li aiye; 16 Ẹ si mã na ọwọ ọ̀rọ ìye jade; ki emi ki o le ṣogo li ọjọ Kristi pe emi kò sáre lasan, bẹni emi kò si ṣe lãlã lasan. 17 Ani, bi a tilẹ tú mi dà sori ẹbọ ati iṣẹ isin igbagbọ́ nyin, mo yọ̀, mo si mba gbogbo nyin yọ̀ pẹlu.
18 Bakanna ni ki ẹnyin ki o mã yọ̀, ki ẹ si mã ba mi yọ̀ pẹlu.Timotiu ati Epafiroditu
19 Ṣugbọn mo ni ireti ninu Jesu Oluwa, lati rán Timotiu si nyin ni lọ̃lọ yi, ki emi pẹlu le ni ifọkanbalẹ nigbati mo ba gburó ijoko nyin. 20 Nitori emi kò ni ẹni oninu kanna ti o dabi rẹ̀, ti yio ma fi tinutinu ṣe aniyan nyin. 21 Nitori gbogbo wọn ni ntọju nkan ti ara wọn, kì iṣe nkan ti iṣe ti Jesu Kristi. 22 Ṣugbọn ẹnyin ti mọ̀ ọ dajudaju, pe gẹgẹ bi ọmọ lọdọ baba rẹ̀, bẹ̃li o si ti mba mi ṣiṣẹ pọ̀ ninu ihinrere. 23 Nitorina on ni mo ni ireti lati rán si nyin nisisiyi, nigbati mo ba woye bi yio ti ri fun mi. 24 Ṣugbọn mo gbẹkẹle Oluwa, pe emi tikarami pẹlu yio wá ni lọ̃lọ. 25 Mo ka a si pe n ko le ṣairan Epafroditu arakunrin mi si nyin, ati olubaṣiṣẹ mi ati ọmọ-ogun ẹgbẹ mi, ṣugbọn iranṣẹ nyin, ati ẹniti nṣe iranṣẹ fun mi ninu aini mi. 26 Nitoriti ọkàn rẹ̀ fà si gbogbo nyin, o si kún fun ibanujẹ, nitoriti ẹnyin ti gbọ́ pe on ti ṣe aisan. 27 Nitõtọ li o ti ṣe aisan titi de oju ikú: ṣugbọn Ọlọrun ti ṣãnu fun u; kì si iṣe fun on nikan, ṣugbọn fun mi pẹlu, ki emi ki o màṣe ni ibanujẹ lori ibanujẹ. 28 Nitorina ni mo ṣe fi titara-titara rán a, pe nigbati ẹnyin ba si tún ri i, ki ẹnyin ki o le yọ̀, ati ki ibanujẹ mi ki o le dínkù. 29 Nitorina ẹ fi ayọ̀ pupọ gbà a nipa ti Oluwa; ki ẹ si ma bù ọlá fun irú awọn ẹni bẹ̃: 30 Nitoripe nitori iṣẹ Kristi li o ṣe sunmọ ẹnu-ọ̀na ikú, ti kò si kà ẹmí ara rẹ̀ si, lati mu aitó iṣẹ isin nyin si mi kun.
Philippians 2
Be Like Christ
1 Therefore if there is any encouragement in Christ, if there is any consolation of love, if there is any fellowship of the Spirit, if any affection and compassion,2 make my joy complete by being of the same mind, maintaining the same love, united in spirit, intent on one purpose.3 Do nothing from selfishness or empty conceit, but with humility of mind regard one another as more important than yourselves;4 do not merely look out for your own personal interests, but also for the interests of others.5 Have this attitude in yourselves which was also in Christ Jesus,6 who, although He existed in the form of God, did not regard equality with God a thing to be grasped,7 but temptied Himself, taking the form of a bond-servant, and being made in the likeness of men.8 Being found in appearance as a man, He humbled Himself by becoming obedient to the point of death, even death on a cross.9 For this reason also, God highly exalted Him, and bestowed on Him the name which is above every name,10 so that at the name of Jesus EVERY KNEE WILL BOW, of those who are in heaven and on earth and under the earth,11 and that every tongue will confess that Jesus Christ is Lord, to the glory of God the Father.
12 So then, my beloved, just as you have always obeyed, not as in my presence only, but now much more in my absence, work out your salvation with fear and trembling;13 for it is God who is at work in you, both to will and to work for His good pleasure.
14 Do all things without grumbling or disputing;15 so that you will prove yourselves to be blameless and innocent, children of God above reproach in the midst of a crooked and perverse generation, among whom you appear as lights in the world,16 holding fast the word of life, so that in the day of Christ I will have reason to glory because I did not run in vain nor toil in vain.17 But even if I am being poured out as a drink offering upon the sacrifice and service of your faith, I rejoice and share my joy with you all.18 You too, I urge you, rejoice in the same way and share your joy with me.
Timothy and Epaphroditus
19 But I hope in the Lord Jesus to send Timothy to you shortly, so that I also may be encouraged when I learn of your condition.20 For I have no one else of kindred spirit who will genuinely be concerned for your welfare.21 For they all seek after their own interests, not those of Christ Jesus.22 But you know of his proven worth, that he served with me in the furtherance of the gospel like a child serving his father.23 Therefore I hope to send him immediately, as soon as I see how things go with me;24 and I trust in the Lord that I myself also will be coming shortly.25 But I thought it necessary to send to you Epaphroditus, my brother and fellow worker and fellow soldier, who is also your messenger and minister to my need;26 because he was longing tfor you all and was distressed because you had heard that he was sick.27 For indeed he was sick to the point of death, but God had mercy on him, and not on him only but also on me, so that I would not have sorrow upon sorrow.28 Therefore I have sent him all the more eagerly so that when you see him again you may rejoice and I may be less concerned about you. 29 Receive him then in the Lord with all joy, and hold men like him in high regard;30 because he came close to death for the work of Christ, risking his life to complete what was deficient in your service to me.