previous next

Filp 4

Ọ̀rọ̀ Ìyànjú

1 NITORINA, ẹnyin ará mi olufẹ, ti mo si nṣafẹri gidigidi, ayọ̀ ati ade mi, ẹ duro ṣinṣin bẹ̃ ninu Oluwa, ẹnyin olufẹ mi. 2 Emi mbẹ̀ Euodia, mo si mbẹ̀ Sintike, ki nwọn ni inu kanna ninu Oluwa. 3 Mo si bẹ ọ pẹlu, bi alajọru-ajaga mi tõtọ, ran awọn obinrin wọnni lọwọ, nitori nwọn mba mi ṣiṣẹ pọ̀ ninu ihinrere, ati Klementi pẹlu, ati awọn olubaṣiṣẹ mi iyoku pẹlu, orukọ awọn ti mbẹ ninu iwe ìye. 4 Ẹ mã yọ̀ ninu Oluwa nigbagbogbo: mo si tún wi, Ẹ mã yọ̀. 5 Ẹ jẹ ki ipamọra nyin di mimọ̀ fun gbogbo enia. Oluwa mbẹ nitosi. 6 Ẹ máṣe aniyàn ohunkohun; ṣugbọn ninu ohun gbogbo, nipa adura ati ẹbẹ pẹlu idupẹ, ẹ mã fi ìbere nyin hàn fun Ọlọrun. 7 Ati alafia Ọlọrun, ti o jù ìmọran gbogbo lọ, yio ṣọ ọkàn ati ero nyin ninu Kristi Jesu. 8 Li akotan, ará, ohunkohun ti iṣe õtọ, ohunkohun ti iṣe ọ̀wọ, ohunkohun ti iṣe titọ́, ohunkohun ti iṣe mimọ́, ohunkohun ti iṣe fifẹ, ohunkohun ti o ni irohin rere; bi ìwa titọ́ kan ba wà, bi iyìn kan ba si wà, ẹ mã gbà nkan wọnyi rò.

9 Nkan wọnni, ti ẹnyin ti kọ́, ti ẹnyin si ti gbà, ti ẹnyin si ti gbọ́, ti ẹnyin si ti ri lọwọ mi, ẹ mã ṣe wọn: Ọlọrun alafia yio si wà pẹlu nyin.

Paulu Dúpẹ́ fún Ẹ̀bùn


10 Ṣugbọn emi yọ̀ gidigidi ninu Oluwa pe, asiwá-asibọ̀ ero nyin tun sọji fun mi, eyiti ẹ ti nro nitotọ, ṣugbọn ẹnyin kò ni akokò ti o wọ̀. 11 Kì iṣe pe emi nsọ nitori aini: nitoripe ipòkipo ti mo ba wà, mo ti kọ́ lati ni itẹlọrùn ninu rẹ̀. 12 Mo mọ̀ bi ã ti iṣe di rirẹ̀-silẹ, mo mọ bi ã ti iṣe di pupọ: li ohunkohun ati li ohun gbogbo mo ti kọ́ aṣiri ati mã jẹ ajẹyó ati lati wà li aijẹ, lati mã ni anijù ati lati ṣe alaini. 13 Emi le ṣe ohun gbogbo ninu Kristi ẹniti nfi agbara fun mi. 14 Ṣugbọn ẹnyin ṣeun gidigidi niti pe ẹnyin ṣe alabapin ninu ipọnju mi. 15 Ẹnyin papa si mọ̀ pẹlu, ẹnyin ara Filippi, pe li ibẹrẹ ihinrere, nigbati mo kuro ni Makedonia, kò si ijọ kan ti o ba mi ṣe alabapin niti gbigbà ati fifunni, bikoṣe ẹnyin nikanṣoṣo. 16 Nitori ni Tessalonika gidi, ẹnyin ranṣẹ, ẹ si tun ranṣẹ fun aini mi. 17 Kì iṣe nitoriti emi nfẹ ẹ̀bun na: ṣugbọn emi nfẹ eso ti yio mã di pupọ nitori nyin. 18 Ṣugbọn mo ni ohun gbogbo, mo si ti di pupọ: mo si kún nigbati mo ti gbà nkan wọnni ti a ti rán lati ọdọ nyin wá lọwọ Epafroditu, ọrẹ olõrùn didùn, ẹbọ itẹwọgbà, ti iṣe inu didùn gidigidi si Ọlọrun. 19 Ṣugbọn Ọlọrun mi yio pèse ni kikún fun gbogbo aini nyin, gẹgẹ bi ọrọ̀ rẹ̀ ninu ogo ninu Kristi Jesu.

20 Ṣugbọn ogo ni fun Ọlọrun ati Baba wa lai ati lailai. Amin.

Ìdágbére


21 Ẹ kí olukuluku enia mimọ́ ninu Kristi Jesu. Awọn ara ti o wà pẹlu mi kí nyin. 22 Gbogbo awọn enia mimọ́ kí nyin, papa awọn ti iṣe ti agbo ile Kesari. 23 Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa, ki o wà pẹlu ẹmi nyin. Amin.

A kọ ọ si awọn ara Filippi lati Romu lọ lati ọwọ́ Epafroditu.

11-Feb-2009@11:05, Backup Description=11-Feb-2009@09:10, Ayo Durodola -

08-Apr-2009@14:15, Backup Description=08-Apr-2009@08:23, Ayo Durodola -

08-Apr-2009@14:52, Backup Description=08-Apr-2009@14:37, Ayo Durodola -

22-Dec-2009@14:07, Backup Description=22-Dec-2009@14:01, victor Damilare -

Philippians 4

Think of Excellence

1 Therefore, my beloved brethren whom I long to see, my joy and crown, in this way stand firm in the Lord, my beloved.

2 I urge Euodia and I urge Syntyche to live in harmony in the Lord.3 Indeed, true companion, I ask you also to help these women who have shared my struggle in the cause of the gospel, together with Clement also and the rest of my fellow workers, whose names are in the book of life.

4 Rejoice in the Lord always; again I will say, rejoice!5 Let your gentle spirit be known to all men. The Lord is near.6 Be anxious for nothing, but in everything by prayer and supplication with thanksgiving let your requests be made known to God.7 And the peace of God, which surpasses all comprehension, will guard your hearts and your minds in Christ Jesus.

8 Finally, brethren, whatever is true, whatever is honorable, whatever is right, whatever is pure, whatever is lovely, whatever is of good repute, if there is any excellence and if anything worthy of praise, dwell on these things.9 The things you have learned and received and heard and seen in me, practice these things, and the God of peace will be with you.

God's Provisions

10 But I rejoiced in the Lord greatly, that now at last you have revived your concern for me; indeed, you were concerned before, but you lacked opportunity.11 Not that I speak from want, for I have learned to be content in whatever circumstances I am.12 I know how to get along with humble means, and I also know how to live in prosperity; in any and every circumstance I have learned the secret of being filled and going hungry, both of having abundance and suffering need.13 I can do all things through Him who strengthens me.14 Nevertheless, you have done well to share with me in my affliction.

15 You yourselves also know, Philippians, that at the first preaching of the gospel, after I left Macedonia, no church shared with me in the matter of giving and receiving but you alone;16 for even in Thessalonica you sent a gift more than once for my needs.17 Not that I seek the gift itself, but I seek for the profit which increases to your account.18 But I have received everything in full and have an abundance; I am amply supplied, having received from Epaphroditus what you have sent, a fragrant aroma, an acceptable sacrifice, well-pleasing to God.19 And my God will supply all your needs according to His riches in glory in Christ Jesus.20 Now to our God and Father be the glory forever and ever. Amen.

21 Greet every saint in Christ Jesus. The brethren who are with me greet you.22 All the saints greet you, especially those of Caesar's household.

23 The grace of the Lord Jesus Christ be with your spirit.