previous next

Ifi 12

Obinrin kan ati Ẹranko Ewèlè

1 ÀMI nla kan si hàn li ọrun; obinrin kan ti a fi õrùn wọ̀ li aṣọ, oṣupa si mbẹ labẹ ẹsẹ rẹ̀, ade onirawọ mejila si mbẹ li ori rẹ̀: 2 O si lóyun, o si kigbe ni irọbi, o si wà ni irora ati bimọ. 3 Àmi miran si hàn li ọrun; si kiyesi i, dragoni pupa nla kan, ti o ni ori meje ati iwo mẹwa, ati adé meje li ori rẹ̀. 4 Ìru rẹ̀ si wọ́ idamẹta awọn irawọ, o si ju wọn si ilẹ aiye, dragoni na si duro niwaju obinrin na ti o fẹ bímọ, pe nigbati o ba bí, ki o le pa ọmọ rẹ̀ jẹ. 5 O si bí ọmọkunrin kan ti yio fi ọpá irin ṣe akoso gbogbo awọn orilẹ-ède: a si gbà ọmọ rẹ̀ lọ soke si ọdọ Ọlọrun, ati si ori itẹ́ rẹ̀. 6 Obinrin na si sá lọ si aginjù, nibiti a gbé ti pèse àye silẹ dè e lati ọwọ́ Ọlọrun wá, pe ki nwọn ki o mã bọ́ ọ nibẹ̀ li ẹgbẹfa ọjọ o le ọgọta. 7 Ogun si mbẹ li ọrun: Mikaeli ati awọn angẹli rẹ̀ ba dragoni na jàgun; dragoni si jàgun ati awọn angẹli rẹ̀. 8 Nwọn kò si le ṣẹgun; bẹ̃ni a kò si ri ipo wọn mọ́ li ọrun. 9 A si lé dragoni nla na jade, ejò lailai nì, ti a npè ni Èṣu, ati Satani, ti ntàn gbogbo aiye jẹ, a si lé e jù si ilẹ aiye, a si le awọn angẹli rẹ̀ jade pẹlu rẹ̀. 10 Mo si gbọ́ ohùn rara li ọrun, nwipe, Nigbayi ni igbala de, ati agbara, ati ijọba Ọlọrun wa, ati ọla ti Kristi rẹ̀; nitori a ti lé olufisùn awọn arakunrin wa jade, ti o nfi wọn sùn niwaju Ọlọrun wa lọsán ati loru. 11 Nwọn si ṣẹgun rẹ̀ nitori ẹ̀jẹ Ọdọ-Agutan na, ati nitori ọ̀rọ ẹrí wọn, nwọn kò si fẹran ẹmi wọn ani titi de ikú. 12 Nitorina ẹ mã yọ̀, ẹnyin ọrun, ati ẹnyin ti ngbé inu wọn. Egbé ni fun aiye ati fun okun! nitori Èṣu sọkalẹ tọ̀ nyin wá ni ibinu nla, nitori o mọ̀ pe ìgba kukuru ṣá li on ni. 13 Nigbati dragoni na ri pe a lé on lọ si ilẹ aiye, o ṣe inunibini si obinrin ti o bí ọmọkunrin na. 14 A si fi apá iyẹ́ meji ti idì nla na fun obinrin na, pe ki o fò lọ si aginjù, si ipò rẹ̀, nibiti a gbé bọ́ ọ fun akoko kan ati fun awọn akoko, ati fun idaji akoko kuro lọdọ ejò na. 15 Ejò na si tú omi jade lati ẹnu rẹ̀ wá bi odo nla sẹhin obinrin na, ki o le mu ki ìṣan omi na gbá a lọ. 16 Ilẹ si ràn obinrin na lọwọ, ilẹ si yà ẹnu rẹ̀, o si fi ìṣan omi na mu, ti dragoni na tú jade lati ẹnu rẹ̀ wá. 17 Dragoni na si binu gidigidi si obinrin na, o si lọ ba awọn iru-ọmọ rẹ̀ iyokù jagun, ti nwọn npa ofin Ọlọrun mọ́, ti nwọn si di ẹrí Jesu mu.

Revelation 12

The Woman, Israel

1 A great sign appeared in heaven: a woman clothed with the sun, and the moon under her feet, and on her head a crown of twelve stars;2 and she was with child; and she *cried out, being in labor and in pain to give birth.

The Red Dragon, Satan

3 Then another sign appeared in heaven: and behold, a great red dragon having seven heads and ten horns, and on his heads were seven diadems.4 And his tail *swept away a third of the stars of heaven and threw them to the earth. And the dragon stood before the woman who was about to give birth, so that when she gave birth he might devour her child.

The Male Child, Christ

5 And she gave birth to a son, a male child, who is to rule all the nations with a rod of iron; and her child was caught up to God and to His throne.6 Then the woman fled into the wilderness where she *had a place prepared by God, so that there she would be nourished for one thousand two hundred and sixty days.

The Angel, Michael

7 And there was war in heaven, Michael and his angels waging war with the dragon. The dragon and his angels waged war,8 and they were not strong enough, and there was no longer a place found for them in heaven.9 And the great dragon was thrown down, the serpent of old who is called the devil and Satan, who deceives the whole world; he was thrown down to the earth, and his angels were thrown down with him.

10 Then I heard a loud voice in heaven, saying,
"Now the salvation, and the power, and the kingdom of our God and the authority of His Christ have come, for the accuser of our brethren has been thrown down, he who accuses them before our God day and night.
11 And they overcame him because of the blood of the Lamb and because of the word of their testimony, and they did not love their life even when faced with death.12 For this reason, rejoice, O heavens and you who dwell in them. Woe to the earth and the sea, because the devil has come down to you, having great wrath, knowing that he has only a short time."

13 And when the dragon saw that he was thrown down to the earth, he persecuted the woman who gave birth to the male child. 14 But the two wings of the great eagle were given to the woman, so that she could fly into the wilderness to her place, where she *was nourished for a time and times and half a time, from the presence of the serpent.15 And the serpent poured water like a river out of his mouth after the woman, so that he might cause her to be swept away with the flood.16 But the earth helped the woman, and the earth opened its mouth and drank up the river which the dragon poured out of his mouth.17 So the dragon was enraged with the woman, and went off to make war with the rest of her children, who keep the commandments of God and hold to the testimony of Jesus.