previous next

Ifi 2

Iṣẹ́ sí Ìjọ Efesu

1 SI angẹli ijọ ni Efesu kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti o mu irawọ meje na li ọwọ́ ọtún rẹ̀, ẹniti nrìn li arin ọpá wura fitila meje na wipe, 2 Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati lãlã rẹ, ati ìfarada rẹ, ati bi ara rẹ kò ti gba awọn ẹni buburu: ati bi iwọ si ti dan awọn ti npè ara wọn ni aposteli, ti nwọn kì sì iṣe bẹ̃ wo, ti iwọ si ri pe eleke ni wọn; 3 Ti iwọ si farada ìya, ati nitori orukọ mi ti o si fi aiya rán, ti ãrẹ̀ kò si mu ọ. 4 Ṣugbọn eyi ni mo ri wi si ọ, pe, iwọ ti fi ifẹ rẹ iṣaju silẹ. 5 Nitorina ranti ibiti iwọ gbé ti ṣubu, ki o si ronupiwada, ki o si ṣe iṣẹ iṣaju; bi kò si ṣe bẹ̃, emi ó si tọ̀ ọ wá, emi o si ṣí ọpá fitila rẹ kuro ni ipò rẹ̀, bikoṣe bi iwọ ba ronupiwada. 6 Ṣugbọn eyi ni iwọ ní, pe iwọ korira iṣe awọn Nikolaitani eyiti emi pẹlu si korira.

7 Ẹniti o ba li etí ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ẹniti o ba ṣẹgun ni emi o fi eso igi ìye nì fun jẹ, ti mbẹ larin Paradise Ọlọrun.

Iṣẹ́ sí Ìjọ Simana


8 Ati si angẹli ijọ ni Smirna kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti iṣe ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin wi, ẹniti o ti kú, ti o si tun yè: 9 Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati ipọnju, ati aini rẹ (ṣugbọn ọlọ́rọ̀ ni ọ) emi si mọ̀ ọ̀rọ-òdi si Ọlọrun ti awọn ti nwipe Ju li awọn tikarawọn, ti nwọn kì sì iṣe bẹ̃, ṣugbọn ti nwọn jẹ́ sinagogu ti Satani. 10 Máṣe bẹ̀ru ohunkohun tì iwọ mbọ̀ wá jiya rẹ̀: kiyesi i, Èṣu yio gbé ninu nyin jù sinu tubu, ki a le dán nyin wò; ẹnyin o si ni ipọnju ni ijọ mẹwa: iwọ sa ṣe olõtọ de oju ikú, emi ó si fi ade ìye fun ọ.

11 Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ẹniti o ba ṣẹgun kì yio farapa ninu ikú keji.

Iṣẹ́ sí Ìjọ Pẹgamu


12 Ati si angẹli ijọ ni Pergamu kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti o ni idà mimu oloju meji nì wipe, 13 Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati ibiti iwọ ngbé, ani ibiti ìtẹ Satani wà: ati pe iwọ dì orukọ mi mu ṣinṣin, ti iwọ kò si sẹ́ igbagbọ́ mi, li ọjọ wọnni ninu eyi ti Antipa iṣe olõtọ ajẹrikú mi, ẹniti nwọn pa ninu nyin, nibiti Satani ngbé. 14 Ṣugbọn mo ni nkan diẹ iwi si ọ, nitoriti iwọ ni awọn ti o dì ẹkọ́ ti Balaamu mu nibẹ̀, ẹniti o kọ́ Balaku lati mu ohun ikọsẹ̀ wá siwaju awọn ọmọ Israeli, lati mã jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa, ati lati mã ṣe àgbere. 15 Bẹ̃ni iwọ si ní awọn ti o gbà ẹkọ awọn Nikolaitani pẹlu, ohun ti mo korira. 16 Ronupiwada; bikoṣe bẹ̃ emi ó tọ̀ ọ wá nisisiyi, emi o si fi idà ẹnu mi ba wọn jà.

17 Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ẹniti o ba ṣẹgun li emi o fi manna ti o pamọ́ fun jẹ, emi o si fun u li okuta funfun kan, ati sara okuta na orukọ titun ti a o kọ si i, ti ẹnikẹni kò mọ̀ bikoṣe ẹniti o gbà a.

Iṣẹ́ sí Ìjọ Tiatira


18 Ati si angẹli ijọ ni Tiatira kọwe: Nkan wọnyi li Ọmọ Ọlọrun wi, ẹniti o ni oju rẹ̀ bi ọwọ́ iná, ti ẹsẹ rẹ̀ si dabi idẹ daradara; 19 Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati ifẹ rẹ, ati igbagbọ́, ati ìsin, ati sũru rẹ; ati pe iṣẹ rẹ ikẹhin jù ti iṣaju lọ. 20 Ṣugbọn eyi ni mo ri wi si ọ, nitoriti iwọ fi aye silẹ fun obinrin nì Jesebeli ti o pè ara rẹ̀ ni woli, o si nkọ awọn iranṣẹ mi o si ntan wọn lati mã ṣe àgbere, ati lati mã jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa. 21 Emi si fi sã fun u lati ronupiwada; kò si fẹ ronupiwada agbere rẹ̀. 22 Kiyesi i, emi ó gbe e sọ si ori akete, ati awọn ti mba a ṣe panṣaga li emi o fi sinu ipọnju nla, bikoṣe bi nwọn ba ronupiwada iṣẹ wọn. 23 Emi o si fi ikú pa awọn ọmọ rẹ̀; gbogbo ijọ ni yio si mọ̀ pe, emi li ẹniti nwadi inu ati ọkàn: emi o si fifun olukuluku nyin gẹgẹ bi iṣẹ nyin. 24 Ṣugbọn ẹnyin ni mo nsọ fun, ẹnyin iyokù ti mbẹ ni Tiatira, gbogbo ẹnyin ti kò ni ẹkọ́ yi, ti kò mọ̀ ohun ijinlẹ Satani (bi nwọn ti nwi), emi kò dì ẹrù miran rù nyin. 25 Ṣugbọn eyi ti ẹnyin ni, ẹ di i mu ṣinṣin titi emi o fi de. 26 Ẹniti o ba si ṣẹgun, ati ẹniti o ba pa iṣẹ mi mọ́ titi de opin, emi o fun u li aṣẹ lori awọn orilẹ-ède: 27 On o si mã fi ọpá irin ṣe akoso wọn; bi ã ti ifọ́ ohun elo amọ̀koko li a o fọ́ wọn tũtu: bi emi pẹlu ti gba lati ọdọ Baba mi. 28 Emi o si fi irawọ owurọ̀ fun u. 29 Ẹniti o ba li eti, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmi nsọ fun awọn ijọ.

Revelation 2

Message to Ephesus

1 "To the angel of the church in Ephesus write:
The One who holds the seven stars in His right hand, the One who walks among the seven golden lampstands, says this:

2 'I know your deeds and your toil and perseverance, and that you cannot tolerate evil men, and you put to the test those who call themselves apostles, and they are not, and you found them to be false;3 and you have perseverance and have endured for My name's sake, and have not grown weary.4 But I have this against you, that you have left your first love.5 Therefore remember from where you have fallen, and repent and do the deeds you did at first; or else I am coming to you and will remove your lampstand out of its place-unless you repent.6 Yet this you do have, that you hate the deeds of the Nicolaitans, which I also hate.7 He who has an ear, let him hear what the Spirit says to the churches. To him who overcomes, I will grant to eat of the tree of life which is in the Paradise of God.'

Message to Smyrna

8 "And to the angel of the church in Smyrna write:
The first and the last, who was dead, and has come to life, says this:

9 'I know your tribulation and your poverty (but you are rich), and the blasphemy by those who say they are Jews and are not, but are a synagogue of Satan.10 Do not fear what you are about to suffer. Behold, the devil is about to cast some of you into prison, so that you will be tested, and you will have tribulation for ten days. Be faithful until death, and I will give you the crown of life.11 He who has an ear, let him hear what the Spirit says to the churches. He who overcomes will not be hurt by the second death.'

Message to Pergamum

12 "And to the angel of the church in Pergamum write:
The One who has the sharp two-edged sword says this:

13 'I know where you dwell, where Satan's throne is; and you hold fast My name, and did not deny My faith even in the days of Antipas, My witness, My faithful one, who was killed among you, where Satan dwells.14 But I have a few things against you, because you have there some who hold the teaching of Balaam, who kept teaching Balak to put a stumbling block before the sons of Israel, to eat things sacrificed to idols and to commit acts of immorality.15 So you also have some who in the same way hold the teaching of the Nicolaitans.16 Therefore repent; or else I am coming to you quickly, and I will make war against them with the sword of My mouth.17 He who has an ear, let him hear what the Spirit says to the churches. To him who overcomes, to him I will give some of the hidden manna, and I will give him a white stone, and a new name written on the stone which no one knows but he who receives it.'

Message to Thyatira

18 "And to the angel of the church in Thyatira write:
The Son of God, who has eyes like a flame of fire, and His feet are like burnished bronze, says this:

19 'I know your deeds, and your love and faith and service and perseverance, and that your deeds of late are greater than at first.20 But I have this against you, that you tolerate the woman Jezebel, who calls herself a prophetess, and she teaches and leads My bond-servants astray so that they commit acts of immorality and eat things sacrificed to idols.21 I gave her time to repent, and she does not want to repent of her immorality.22 Behold, I will throw her on a bed of sickness, and those who commit adultery with her into great tribulation, unless they repent of ther deeds.23 And I will kill her children with pestilence, and all the churches will know that I am He who searches the minds and hearts; and I will give to each one of you according to your deeds.24 But I say to you, the rest who are in Thyatira, who do not hold this teaching, who have not known the deep things of Satan, as they call them-I place no other burden on you.25 Nevertheless what you have, hold fast until I come.26 He who overcomes, and he who keeps My deeds until the end, TO HIM I WILL GIVE AUTHORITY OVER THE NATIONS;27 AND HE SHALL RULE THEM WITH A ROD OF IRON, AS THE VESSELS OF THE POTTER ARE BROKEN TO PIECES, as I also have received authority from My Father;28 and I will give him the morning star.29 He who has an ear, let him hear what the Spirit says to the churches.'