previous next

Ifi 20

Ìjọba Ẹgbẹrun Ọdún

1 MO si ri angẹli kan nti ọrun sọkalẹ wá, ti on ti ìṣika ọgbun nì, ati ẹ̀wọn nla kan li ọwọ́ rẹ̀. 2 O si di dragoni na mu, ejò atijọ nì, ti iṣe Èṣu, ati Satani, o si dè e li ẹgbẹ̀run ọdún. 3 O si gbé e sọ sinu ọgbun na, o si ti i, o si fi èdidi di i lori rẹ̀, ki o má bã tan awọn orilẹ-ède jẹ mọ́ titi ẹgbẹrun ọdún na yio fi pé: lẹhin eyi, a kò le ṣai tu u silẹ fun igba diẹ. 4 Mo si ri awọn ìtẹ́, nwọn si joko lori wọn, a si fi idajọ fun wọn: mo si ri ọkàn awọn ti a ti bẹ́ lori nitori ẹrí Jesu, ati nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati awọn ti kò si foribalẹ fun ẹranko na, ati fun aworan rẹ̀, tabi ti kò si gbà àmi rẹ̀ ni iwaju wọn ati li ọwọ́ wọn; nwọn si wà lãye, nwọn si jọba pẹlu Kristi li ẹgbẹrun ọdún. 5 Awọn okú iyokù kò wà lãye mọ́ titi ẹgbẹ̀run ọdún na yio fi pé. Eyi li ajinde ekini.

6 Olubukun ati mimọ́ ni ẹniti o ni ipa ninu ajinde ekini na: lori awọn wọnyi ikú ekeji kò li agbara, ṣugbọn nwọn o jẹ alufa Ọlọrun ati ti Kristi, nwọn o si mã jọba pẹlu rẹ̀ li ẹgbẹ̀run ọdún.

A Ṣẹgun Satani


7 Nigbati ẹgbẹrun ọdún na ba si pé, a o tú Satani silẹ kuro ninu tubu rẹ̀. 8 Yio si jade lọ lati mã tàn awọn orilẹ-ède ti mbẹ ni igun mẹrẹrin aiye jẹ, Gogu ati Magogu, lati gbá wọn jọ si ogun: awọn ti iye wọn dabi iyanrìn okun. 9 Nwọn si gòke lọ la ibú aiye ja, nwọn si yi ibudo awọn enia mimọ́ ká ati ilu ayanfẹ na: iná si ti ọrun sọkalẹ wá, o si jo wọn run.

10 A si wọ́ Èṣu ti o tàn wọn jẹ lọ sinu adagun iná ati sulfuru, nibiti ẹranko ati woli eke nì gbé wà, a o si mã dá wọn loro t'ọsan-t'oru lai ati lailai.

Ìdájọ́ Ìkẹyìn


11 Mo si ri itẹ́ funfun nla kan, ati ẹni ti o joko lori rẹ̀, niwaju ẹniti aiye ati ọrun fò lọ; a kò si ri ãye fun wọn mọ́. 12 Mo si ri awọn okú, ati ewe ati àgba, nwọn duro niwaju itẹ; a si ṣi awọn iwe silẹ; a si ṣí awọn iwe miran kan silẹ ti iṣe iwe ìye: a si ṣe idajọ fun awọn okú lati inu ohun ti a ti kọ sinu awọn iwe na, gẹgẹ bi iṣẹ wọn. 13 Okun si jọ awọn okú ti mbẹ ninu rẹ̀ lọwọ; ati ikú ati ipo-okú si jọ okú ti o wà ninu wọn lọwọ: a si ṣe idajọ wọn olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ wọn. 14 Ati ikú ati ipo-okú li a si sọ sinu adagun iná. Eyi ni ikú keji. 15 Bi a ba si ri ẹnikẹni ti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe ìye, a sọ ọ sinu adagun iná.

Revelation 20

Satan Bound

1 Then I saw an angel coming down from heaven, holding the key of the abyss and a great chain in his hand.2 And he laid hold of the dragon, the serpent of old, who is the devil and Satan, and bound him for a thousand years;3 and he threw him into the abyss, and shut it and sealed it over him, so that he would not deceive the nations any longer, until the thousand years were completed; after these things he must be released for a short time.

4 Then I saw thrones, and they sat on them, and judgment was given to them. And I saw the souls of those who had been beheaded because of their testimony of Jesus and because of the word of God, and those who had not worshiped the beast or his image, and had not received the mark on their forehead and on their hand; and they came to life and reigned with Christ for a thousand years.5 The rest of the dead did not come to life until the thousand years were completed. This is the first resurrection.6 Blessed and holy is the one who has a part in the first resurrection; over these the second death has no power, but they will be priests of God and of Christ and will reign with Him for a thousand years.

Satan Freed, Doomed

7 When the thousand years are completed, Satan will be released from his prison,8 and will come out to deceive the nations which are in the four corners of the earth, Gog and Magog, to gather them together for the war; the number of them is like the sand of the seashore.9 And they came up on the broad plain of the earth and surrounded the camp of the saints and the beloved city, and fire came down from heaven and devoured them.10 And the devil who deceived them was thrown into the lake of fire and brimstone, where the beast and the false prophet are also; and they will be tormented day and night forever and ever.

Judgment at the Throne of God

11 Then I saw a great white throne and Him who sat upon it, from whose presence earth and heaven fled away, and no place was found for them.12 And I saw the dead, the great and the small, standing before the throne, and books were opened; and another book was opened, which is the book of life; and the dead were judged from the things which were written in the books, according to their deeds.13 And the sea gave up the dead which were in it, and death and Hades gave up the dead which were in them; and they were judged, every one of them according to their deeds.14 Then death and Hades were thrown into the lake of fire. This is the second death, the lake of fire.15 And if anyone's name was not found written in the book of life, he was thrown into the lake of fire.