previous next

Rom 1

Ìkíni

1 PAULU, iranṣẹ Jesu Kristi, ti a pè lati jẹ aposteli, ti a yà sọ̀tọ fun ihinrere Ọlọrun, 2 (Ti o ti ṣe ileri tẹlẹ rí ninu iwe-mimọ́, lati ọwọ awọn woli rẹ̀), 3 Niti Ọmọ rẹ̀, ti a bí lati inu irú-ọmọ Dafidi nipa ti ara, 4 Ẹniti a pinnu rẹ̀ lati jẹ pẹlu agbara Ọmọ Ọlọrun, gẹgẹ bi Ẹmí iwa mimọ́, nipa ajinde kuro ninu okú, ani Jesu Kristi Oluwa wa: 5 Lati ọdọ ẹniti awa ri ore-ọfẹ ati iṣẹ aposteli gbà, fun igbọràn igbagbọ́ lãrin gbogbo orilẹ-ède, nitori orukọ rẹ̀: 6 Larin awọn ẹniti ẹnyin pẹlu ti a pè lati jẹ ti Jesu Kristi:

7 Si gbogbo ẹniti o wà ni Romu, olufẹ Ọlọrun, ti a pè lati jẹ mimọ́: Ore-ọfẹ si nyin ati alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wa wá, ati Jesu Kristi Oluwa.

Paulu Ṣàníyàn láti Lọ sí Romu


8 Mo kọ́ dupẹ na lọwọ Ọlọrun mi nipasẹ Jesu Kristi nitori gbogbo nyin, nitoripe a nròhin igbagbọ́ nyin yi gbogbo aiye ká. 9 Ọlọrun sá li ẹlẹri mi, ẹniti emi nfi ẹmi mi sìn ninu ihinrere Ọmọ rẹ̀, biotiṣepe li aisimi li emi nranti nyin nigbagbogbo ninu adura mi; 10 Emi mbẹ̀bẹ, bi lọna-kọna leke gbogbo rẹ̀, ki a le ṣe ọ̀na mi ni ire nipa ifẹ Ọlọrun, lati tọ̀ nyin wá. 11 Nitoriti emi nfẹ gidigidi lati ri nyin, ki emi ki o le fun nyin li ẹ̀bun ẹmi diẹ, ki a le fi ẹsẹ nyin mulẹ; 12 Eyini ni, ki a le jùmọ ni itunu ninu nyin nipa igbagbọ́ awa mejeji, ti nyin ati ti emi. 13 Ará, emi kò si fẹ ki ẹnyin ki o ṣe alaimọ̀ pe, nigba-pupọ li emi npinnu rẹ̀ lati tọ̀ nyin wá (ṣugbọn o di ẹtì fun mi di isisiyi,) ki emi ki o le ni eso diẹ ninu nyin pẹlu, gẹgẹ bi lãrin awọn Keferi iyokù. 14 Mo di ajigbese awọn Hellene ati awọn alaigbede; awọn ọlọ́gbọn ati awọn alaigbọn.

15 Tobẹ̃ bi o ti wà ni ipá mi, mo mura tan lati wasu ihinrere fun ẹnyin ara Romu pẹlu.

Agbára Ìyìn Rere


16 Nitori emi kò tiju ihinrere Kristi: nitori agbara Ọlọrun ni si igbala fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́; fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu.

17 Nitori ninu rẹ̀ li ododo Ọlọrun hàn lati igbagbọ́ de igbagbọ́: gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ṣugbọn olododo yio wà nipa igbagbọ́.

Gbogbo Aráyé Jẹ̀bi Ẹ̀ṣẹ̀


18 Nitori a fi ibinu Ọlọrun hàn lati ọrun wá si gbogbo aiwa-bi-Ọlọrun ati aiṣododo enia, awọn ẹniti o fi aiṣododo tẹ otitọ mọ́lẹ̀: 19 Nitori ohun ti ã le mọ̀ niti Ọlọrun o farahàn ninu wọn; nitori Ọlọrun ti fi i hàn fun wọn. 20 Nitori ohun rẹ̀ ti o farasin lati igba dida aiye a ri wọn gbangba, a nfi òye ohun ti a da mọ̀ ọ, ani agbara ati iwa-Ọlọrun rẹ̀ aiyeraiye, ki nwọn ki o le wà li airiwi: 21 Nitori igbati nwọn mọ̀ Ọlọrun, nwọn kò yìn i logo bi Ọlọrun, bẹ̃ni nwọn kò si dupẹ; ṣugbọn èro ọkàn wọn di asán, a si mu ọkàn òmúgọ wọn ṣókunkun. 22 Nwọn npè ara wọn li ọlọ́gbọn, nwọn di aṣiwere, 23 Nwọn si pa ogo Ọlọrun ti kì idibajẹ dà, si aworan ere enia ti idibajẹ, ati ti ẹiyẹ, ati ẹranko ẹlẹsẹ mẹrin, ati ohun ti nrakò. 24 Nitorina li Ọlọrun ṣe fi wọn silẹ ninu ifẹkufẹ ọkàn wọn si ìwa-ẽri lati ṣe aibọ̀wọ fun ara wọn larin ara wọn: 25 Awọn ẹniti o yi otitọ Ọlọrun pada si eke, nwọn si bọ, nwọn si sìn ẹda jù Ẹlẹda lọ, ẹniti iṣe olubukun titi lai. Amin. 26 Nitori eyiyi li Ọlọrun ṣe fi wọn fun ifẹ iwakiwa: nitori awọn obinrin wọn tilẹ yi ilo ẹda pada si eyi ti o lodi si ẹda: 27 Gẹgẹ bẹ̃ li awọn ọkunrin pẹlu, nwọn a mã fi ilò obinrin nipa ti ẹda silẹ, nwọn a mã ni ifẹkufẹ gbigbona si ara wọn; ọkunrin mba ọkunrin ṣe eyi ti kò yẹ, nwọn si njẹ ère ìṣina wọn ninu ara wọn bi o ti yẹ si. 28 Ati gẹgẹ bi nwọn ti kọ̀ lati ni ìro Ọlọrun ni ìmọ wọn, Ọlọrun fi wọn fun iyè rirà lati ṣe ohun ti kò tọ́: 29 Nwọn kún fun aiṣododo gbogbo, àgbere, ìka, ojukòkoro, arankan; nwọn kún fun ilara, ipania, ija, itanjẹ, iwa-buburu; afi-ọrọ-kẹlẹ banijẹ, 30 Asọrọ ẹni lẹhin, akorira Ọlọrun, alafojudi, agberaga, ahalẹ, alaroṣe ohun buburu, aṣaigbọran si obí, 31 Alainiyè-ninu, ọ̀dalẹ, alainifẹ, agídi, alailãnu: 32 Awọn ẹniti o mọ̀ ilana Ọlọrun pe, ẹniti o ba ṣe irú nkan wọnyi, o yẹ si ikú, nwọn kò ṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn nwọn ni inu didùn si awọn ti nṣe wọn.

Romans 1

The Gospel Exalted

1 Paul, a bond-servant of Christ Jesus, called as an apostle, set apart for the gospel of God,2 which He promised beforehand through His prophets in the holy Scriptures,3 concerning His Son, who was born of a descendant of David according to the flesh,4 who was declared the Son of God with power tby the resurrection from the dead, according to the Spirit of holiness, Jesus Christ our Lord,5 through whom we have received grace and apostleship to bring about the obedience of faith among all the Gentiles for His name's sake,6 among whom you also are the called of Jesus Christ;

7 to all who are beloved of God in Rome, called as saints: Grace to you and peace from God our Father and the Lord Jesus Christ.

8 First, I thank my God through Jesus Christ for you all, because your faith is being proclaimed throughout the whole world.9 For God, whom I serve in my spirit in the preaching of the gospel of His Son, is my witness as to how unceasingly I make mention of you,10 always in my prayers making request, if perhaps now at last by the will of God I may succeed in coming to you.11 For I long to see you so that I may impart some spiritual gift to you, that you may be established;12 that is, that I may be encouraged together with you while among you, each of us by the other's faith, both yours and mine.13 I do not want you to be unaware, brethren, that often I have planned to come to you (and have been prevented so far) so that I may obtain some fruit among you also, even as among the rest of the Gentiles.14 I am tunder obligation both to Greeks and to barbarians, both to the wise and to the foolish.15 So, for my part, I am eager to preach the gospel to you also who are in Rome.

16 For I am not ashamed of the gospel, for it is the power of God for salvation to everyone who believes, to the Jew first and also to the Greek.17 For in it the righteousness of God is revealed from faith to faith; as it is written, "BUT THE RIGHTEOUS man SHALL LIVE BY FAITH."

Unbelief and Its Consequences

18 For the wrath of God is revealed from heaven against all ungodliness and unrighteousness of men who suppress the truth in unrighteousness,19 because that which is known about God is evident within them; for God made it evident to them.20 For since the creation of the world His invisible attributes, His eternal power and divine nature, have been clearly seen, being understood through what has been made, so that they are without excuse.21 For even though they knew God, they did not thonor Him as God or give thanks, but they became futile in their speculations, and their foolish heart was darkened.22 Professing to be wise, they became fools,23 and exchanged the glory of the incorruptible God for an image in the form of corruptible man and of birds and four-footed animals and tcrawling creatures.

24 Therefore God gave them over in the lusts of their hearts to impurity, so that their bodies would be dishonored among them.25 For they exchanged the truth of God for a lie, and worshiped and served the creature rather than the Creator, who is blessed forever. Amen.

26 For this reason God gave them over to degrading passions; for their women exchanged the natural function for that which is unnatural,27 and in the same way also the men abandoned the natural function of the woman and burned in their desire toward one another, men with men committing indecent acts and receiving in their own persons the due penalty of their error.

28 And just as they did not see fit to acknowledge God any longer, God gave them over to a depraved mind, to do those things which are not proper,29 being filled with all unrighteousness, wickedness, greed, evil; full of envy, murder, strife, deceit, malice; they are gossips,30 slanderers, haters of God, insolent, arrogant, boastful, inventors of evil, disobedient to parents,31 without understanding, untrustworthy, unloving, unmerciful;32 and although they know the ordinance of God, that those who practice such things are worthy of death, they not only do the same, but also give hearty approval to those who practice them.