previous next

Rom 10

1 ARÁ, ifẹ ọkàn mi ati adura mi si Ọlọrun fun Israeli ni, fun igbala wọn. 2 Nitori mo gbà ẹri wọn jẹ pe, nwọn ni itara fun Ọlọrun, ṣugbọn kì iṣe gẹgẹ bi ìmọ. 3 Nitori bi nwọn kò ti mọ ododo Ọlọrun, ti nwọn si nwá ọna lati gbé ododo ara wọn kalẹ, nwọn kò tẹriba fun ododo Ọlọrun.

4 Nitori Kristi li opin ofin si ododo fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́.

Ìgbàlà Fún Gbogbo Eniyan


5 Mose sá kọ̀we rẹ̀ pe, ẹniti o ba ṣe ododo ti iṣe ti ofin, yio yè nipa rẹ̀. 6 Ṣugbọn ododo ti iṣe ti igbagbọ́ sọ bayi pe, Máṣe wi li ọkàn rẹ pe, tani yio goke lọ si ọrun? (eyini ni, lati mu Kristi sọkalẹ:) 7 Tabi, tani yio sọkalẹ lọ si ọgbun? (eyini ni, lati mu Kristi goke ti inu okú wá). 8 Ṣugbọn kili o wi? Ọ̀rọ na wà leti ọdọ rẹ, li ẹnu rẹ, ati li ọkan rẹ: eyini ni, ọ̀rọ igbagbọ́, ti awa nwasu; 9 Pe, bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ́ li ọkàn rẹ pe, Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú, a o gbà ọ là. 10 Nitori ọkàn li a fi igbagbọ́ si ododo; ẹnu li a si fi ijẹwọ si igbala. 11 Nitori iwe-mimọ́ wipe, Ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ oju ki yio ti i. 12 Nitori kò si ìyatọ ninu Ju ati Hellene: nitori Oluwa kanna l'Oluwa gbogbo wọn, o si pọ̀ li ọrọ̀ fun gbogbo awọn ti nkepè e. 13 Nitori ẹnikẹni ti o ba sá pè orukọ, Oluwa, li a o gbàlà. 14 Njẹ nwọn o ha ti ṣe kepe ẹniti nwọn kò gbagbọ́? nwọn o ha si ti ṣe gbà ẹniti nwọn kò gburó rẹ̀ rí gbọ́? nwọn o ha si ti ṣe gbọ́ laisi oniwasu? 15 Nwọn o ha si ti ṣe wasu, bikoṣepe a rán wọn? gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹsẹ awọn ti nwasu ihinrere alafia ti dara to, awọn ti nwãsu ihin ayọ̀ ohun rere! 16 Ṣugbọn ki iṣe gbogbo wọn li o gbọ́ ti ihinrere. Nitori Isaiah wipe, Oluwa, tali o gbà ihin wa gbọ́? 17 Njẹ nipa gbigbọ ni igbagbọ́ ti iwá, ati gbigbọ nipa ọ̀rọ Ọlọrun. 18 Ṣugbọn mo ni, Nwọn kò ha gbọ́ bi? Bẹni nitõtọ, Ohùn wọn jade lọ si gbogbo ilẹ, ati ọ̀rọ wọn si opin ilẹ aiye. 19 Ṣugbọn mo ni, Israeli kò ha mọ̀ bi? Mose li o kọ́ wipe, Emi o fi awọn ti kì iṣe enia mu nyin jowú, ati awọn alaimoye enia li emi o fi bi nyin ninu. 20 Ṣugbọn Isaiah tilẹ laiya, o si wipe, Awọn ti kò wá mi ri mi; awọn ti kò bère mi li a fi mi hàn fun. 21 Ṣugbọn nipa ti Israeli li o wipe, Ni gbogbo ọjọ ni mo nà ọwọ́ mi si awọn alaigbọran ati alariwisi enia.

Romans 10

The Word of Faith Brings Salvation

1 Brethren, my heart's desire and my prayer to God for them is for their salvation.2 For I testify about them that they have a zeal for God, but not in accordance with knowledge.3 For not knowing about God's righteousness and seeking to establish their own, they did not subject themselves to the righteousness of God.4 For Christ is the end of the law for righteousness to everyone who believes.

5 For Moses writes that the man who practices the righteousness which is based on law shall live by that righteousness.6 But the righteousness based on faith speaks as follows: "DO NOT SAY IN YOUR HEART, 'WHO WILL ASCEND INTO HEAVEN?' (that is, to bring Christ down),7 or 'WHO WILL DESCEND INTO THE ABYSS?' (that is, to bring Christ up from the dead)."8 But what does it say? "THE WORD IS NEAR YOU, IN YOUR MOUTH AND IN YOUR HEART"-that is, the word of faith which we are preaching,9 that if you confess with your mouth Jesus as Lord, and believe in your heart that God raised Him from the dead, you will be saved;10 for with the heart a person believes, resulting in righteousness, and with the mouth he confesses, resulting in salvation.11 For the Scripture says, "WHOEVER BELIEVES IN HIM WILL NOT BE DISAPPOINTED."12 For there is no distinction between Jew and Greek; for the same Lord is Lord of all, abounding in riches for all who call on Him;13 for "WHOEVER WILL CALL ON THE NAME OF THE LORD WILL BE SAVED."

14 How then will they call on Him in whom they have not believed? How will they believe in Him whom they have not heard? And how will they hear without a preacher?15 How will they preach unless they are sent? Just as it is written, "HOW BEAUTIFUL ARE THE FEET OF THOSE WHO BRING GOOD NEWS OF GOOD THINGS!"

16 However, they did not all heed the good news; for Isaiah says, "LORD, WHO HAS BELIEVED OUR REPORT?"17 So faith comes from hearing, and hearing by the word of Christ.

18 But I say, surely they have never heard, have they? Indeed they have;
"THEIR VOICE HAS GONE OUT INTO ALL THE EARTH,
AND THEIR WORDS TO THE ENDS OF THE WORLD."
19 But I say, surely Israel did not know, did they? First Moses says,
"I WILL MAKE YOU JEALOUS BY THAT WHICH IS NOT A NATION,
BY A NATION WITHOUT UNDERSTANDING WILL I ANGER YOU."
20 And Isaiah is very bold and says,
"I WAS FOUND BY THOSE WHO DID NOT SEEK ME,
I BECAME MANIFEST TO THOSE WHO DID NOT ASK FOR ME."
21 But as for Israel He says, "ALL THE DAY LONG I HAVE STRETCHED OUT MY HANDS TO A DISOBEDIENT AND OBSTINATE PEOPLE."