Rom 15
Ẹ Máa Ṣe Ohun Tí Ó Tẹ́ Ẹlòmíràn Lọ́rùn
1 NJẸ o yẹ ki awa ti o lera iba mã ru ẹrù ailera awọn alailera, ki a má si ṣe ohun ti o wù ara wa. 2 Jẹ ki olukuluku wa ki o mã ṣe ohun ti o wù ọmọnikeji rẹ̀ si rere rẹ̀ lati gbe e ró. 3 Nitori Kristi pẹlu kò ṣe ohun ti o wù ara rẹ̀; ṣugbọn gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹ̀gan awọn ti ngàn ọ ṣubu lù mi. 4 Nitori ohunkohun ti a ti kọ tẹlẹ, a ti kọ ọ fun kíkọ wa, pe nipa sũru ati itunu iwe-mimọ́ ki a le ni ireti. 5 Njẹ ki Ọlọrun sũru ati itunu ki o fi fun nyin lati ni inu kan si ara nyin gẹgẹ bi Kristi Jesu:
6 Ki ẹnyin ki o le fi ọkàn kan ati ẹnu kan yìn Ọlọrun, Baba Jesu Kristi Oluwa, logo.Bákan Náà Ni Ìyìn Rere Fún Juu Ati Fún Giriki
7 Nitorina ẹ gbá ara nyin mọra, gẹgẹ bi Kristi ti gbá wa mọra fun ogo Ọlọrun. 8 Mo si wipe, a ti fi Jesu Kristi ṣe iranṣẹ ikọla nitori otitọ Ọlọrun, ki o ba le mu awọn ileri na duro ti a ti ṣe fun awọn baba, 9 Ati ki awọn Keferi ki o le yìn Ọlọrun logo nitori ãnu rẹ̀; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Nitori eyi li emi ó ṣe yin ọ lãrin awọn Keferi, emi o si kọrin si orukọ rẹ. 10 O si tún wipe, Ẹnyin Keferi, ẹ mã yọ̀ pẹlu awọn enia rẹ̀. 11 Ati pẹlu, Ẹ yìn Oluwa gbogbo ẹnyin Keferi; ẹ si kokikí rẹ̀, ẹnyin enia gbogbo. 12 Isaiah si tún wipe, Gbòngbo Jesse kan mbọ̀ wá, ati ẹniti yio dide ṣe akoso awọn Keferi; on li awọn Keferi yio ni ireti si.
13 Njẹ ki Ọlọrun ireti ki o fi gbogbo ayọ̀ on alafia kún nyin ni gbigbagbọ, ki ẹnyin ki o le pọ̀ ni ireti nipa agbara Ẹmí Mimọ́.Iṣẹ́ Ìyìn Rere Paulu
14 Ará mi, o si da emi tikarami loju nipa ti nyin pe, ẹnyin si kun fun ore, a si fi gbogbo imọ kún nyin, ẹnyin si le mã kìlọ fun ara nyin. 15 Ṣugbọn, ará mi, mo fi igboiya kọwe si nyin li ọna kan, bi ẹni tun nrán nyin leti, nitori ore-ọfẹ ti a ti fifun mi lati ọdọ Ọlọrun wá, 16 Ki emi ki o le ṣe iranṣẹ Jesu Kristi si awọn Keferi, lati ta ọrẹ ihinrere Ọlọrun, ki ọrẹ awọn Keferi ki o le di itẹwọgbà, ti a sọ di mimọ́ nipa Ẹmí Mimọ́. 17 Nitorina mo ni iṣogo ninu Jesu Kristi nipa ohun ti iṣe ti Ọlọrun. 18 Emi kò sá gbọdọ sọ ohun kan ninu eyi ti Kristi kò ti ọwọ́ ṣe, si igbọran awọn Keferi nipa ọ̀rọ ati iṣe, 19 Nipa agbara iṣẹ-àmi ati iṣẹ-iyanu, nipa agbara Ẹmí Ọlọrun; tobẹ̃ lati Jerusalemu ati yiká kiri ani titi fi de Illirikoni, mo ti wasu ihinrere Kristi ni kikun. 20 Mo du u lati mã wasu ihinrere na, kì iṣe nibiti a gbé ti da orukọ Kristi ri, ki emi ki o máṣe mọ amọle lori ipilẹ ẹlomiran.
21 Ṣugbọn gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Awọn ẹniti a kò ti sọ̀rọ rẹ̀ fun, nwọn ó ri i: ati awọn ti kò ti gbọ́, òye yio yé wọn.Paulu Ṣe Ètò Láti Lọ Sí Romu
22 Nitorina pẹlu li àye ṣe há fun mi li akoko wọnyi lati tọ̀ nyin wá. 23 Ṣugbọn nisisiyi bi emi kò ti li àye mọ́ li ẹkùn wọnyi, bi emi si ti fẹ gidigidi lati ọdún melo wọnyi lati tọ̀ nyin wá, 24 Nigbakugba ti mo ba nlọ si Spania, ng ó tọ̀ nyin wá: nitori mo nireti pe emi o ri nyin li ọ̀na àjo mi, ati pe ẹ o mu mi já ọ̀na mi nibẹ̀ lati ọdọ nyin lọ, bi mo ba kọ kún fun ẹgbẹ nyin li apakan. 25 Ṣugbọn nisisiyi mo nlọ si Jerusalemu lati ṣe iranṣẹ fun awọn enia mimọ́. 26 Nitoriti o wù awọn ará Makedonia ati Akaia lati da owo jọ fun awọn talakà awọn enia mimọ́ ti o wà ni Jerusalemu. 27 Nitõtọ ifẹ inu rere wọn ni; ajigbese wọn ni nwọn sá ṣe. Nitori bi o ba ṣepe a fi awọn Keferi ṣe alajọni ninu ohun ẹmí wọn, ajigbese si ni wọn lati fi nkan ti ara ta wọn lọrẹ. 28 Nitorina nigbati mo ba ti ṣe eyi tan, ti mo ba si ti dí èdidi eso yi fun wọn tan, emi ó ti ọdọ nyin lọ si Spania. 29 Mo si mọ pe, nigbati mo ba de ọdọ nyin, emi o wá ni kikún ibukún ihinrere Kristi. 30 Mo si bẹ̀ nyin, ará, nitori Oluwa wa Jesu Kristi, ati nitori ifẹ Ẹmí, ki ẹnyin ki o ba mi lakaka ninu adura nyin si Ọlọrun fun mi; 31 Ki a le gbà mi lọwọ awọn alaigbọran ni Judea ati ki iṣẹ-iranṣẹ ti mo ni si Jerusalemu le jẹ itẹwọgbà lọdọ awọn enia mimọ́. 32 Ki emi ki o le fi ayọ̀ tọ̀ nyin wá nipa ifẹ Ọlọrun, ati ki emi le ni itura pọ pẹlu nyin. 33 Njẹ ki Ọlọrun alafia ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.
Romans 15
Self-denial on Behalf of Others
1 Now we who are strong ought to bear the weaknesses of those without strength and not just please ourselves.2 Each of us is to please his neighbor for his good, to his edification.3 For even Christ did not please Himself; but as it is written, "THE REPROACHES OF THOSE WHO REPROACHED YOU FELL ON ME."4 For whatever was written in earlier times was written for our instruction, so that through perseverance and the encouragement of the Scriptures we might have hope.5 Now may the God who gives perseverance and encouragement grant you to be of the same mind with one another according to Christ Jesus,6 so that with one accord you may with one voice glorify the God and Father of our Lord Jesus Christ.
7 Therefore, accept one another, just as Christ also accepted us to the glory of God.8 For I say that Christ has become a servant to the circumcision on behalf of the truth of God to confirm the promises given to the fathers,9 and for the Gentiles to glorify God for His mercy; as it is written,
"THEREFORE I WILL GIVE PRAISE TO YOU AMONG THE GENTILES,
AND I WILL SING TO YOUR NAME."10 Again he says,
"REJOICE, O GENTILES, WITH HIS PEOPLE."11 And again,
"PRAISE THE LORD ALL YOU GENTILES,
AND LET ALL THE PEOPLES PRAISE HIM."12 Again Isaiah says,
"THERE SHALL COME THE ROOT OF JESSE,
AND HE WHO ARISES TO RULE OVER THE GENTILES,
IN HIM SHALL THE GENTILES HOPE."13 Now may the God of hope fill you with all joy and peace in believing, so that you will abound in hope by the power of the Holy Spirit.
14 And concerning you, my brethren, I myself also am convinced that you yourselves are full of goodness, filled with all knowledge and able also to admonish one another.15 But I have written very boldly to you on some points so as to remind you again, because of the grace that was given me from God,16 to be a minister of Christ Jesus to the Gentiles, ministering as a priest the gospel of God, so that my offering of the Gentiles may become acceptable, sanctified by the Holy Spirit.17 Therefore in Christ Jesus I have found reason for boasting in things pertaining to God.18 For I will not presume to speak of anything except what Christ has accomplished through me, resulting in the obedience of the Gentiles by word and deed,19 in the power of signs and wonders, in the power of the Spirit; so that from Jerusalem and round about as far as Illyricum I have fully preached the gospel of Christ.20 And thus I aspired to preach the gospel, not where Christ was already named, so that I would not build on another man's foundation;21 but as it is written,
"THEY WHO HAD NO NEWS OF HIM SHALL SEE,
AND THEY WHO HAVE NOT HEARD SHALL UNDERSTAND."
22 For this reason I have often been prevented from coming to you;23 but now, with no further place for me in these regions, and since I have had for many years a longing to come to you24 whenever I go to Spain-for I hope to see you in passing, and to be helped on my way there by you, when I have first enjoyed your company for a while-25 but now, I am going to Jerusalem serving the saints.26 For Macedonia and Achaia have been pleased to make a contribution for the poor among the saints in Jerusalem.27 Yes, they were pleased to do so, and they are indebted to them. For if the Gentiles have shared in their spiritual things, they are indebted to minister to them also in material things.28 Therefore, when I have finished this, and have put my seal on this fruit of theirs, I will go on by way of you to Spain.29 I know that when I come to you, I will come in the fullness of the blessing of Christ.
30 Now I urge you, brethren, by our Lord Jesus Christ and by the love of the Spirit, to strive together with me in your prayers to God for me,31 that I may be rescued from those who are disobedient in Judea, and that my service for Jerusalem may prove acceptable to the saints;32 so that I may come to you in joy by the will of God and find refreshing rest in your company.33 Now the God of peace be with you all. Amen.