previous next

Rom 3

1 NJẸ anfani ki ha ni ti Ju? tabi kini ère ilà kíkọ? 2 Pipọ lọna gbogbo; ekini, nitoripe awọn li a fi ọ̀rọ Ọlọrun le lọwọ. 3 Njẹ ki ha ni bi awọn kan jẹ alaigbagbọ́? aigbagbọ́ wọn yio ha sọ otitọ Ọlọrun di asan bi? 4 Ki a má ri: k'Ọlọrun jẹ olõtọ, ati olukuluku enia jẹ eke; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ki a le da ọ lare ninu ọ̀rọ rẹ, ṣugbọn ki iwọ le ṣẹgun nigbati iwọ ba wá si idajọ. 5 Ṣugbọn bi aiṣododo wa ba nyìn ododo Ọlọrun, kili awa o wi? Ọlọrun ti nfi ibinu rẹ̀ han ha ṣe alaiṣododo bi? (Mo fi ṣe akawe bi enia.) 6 Ki a má ri: bi bẹ̃ni, Ọlọrun yio ha ṣe le dajọ araiye? 7 Nitori bi otitọ Ọlọrun ba di pipọ si iyìn rẹ̀ nitori eke mi, ẽṣe ti a fi nda mi lẹjọ bi ẹlẹṣẹ mọ́ si?

8 Ẽṣe ti a kò si wipe (gẹgẹ bi a ti nsọrọ wa ni ibi, ati gẹgẹ bi awọn kan ti nsọ pe, awa nwipe,) Ẹ jẹ ki a mã ṣe buburu, ki rere ki o le jade wá? awọn ẹniti ẹ̀bi wọn tọ́.

Kò Sí Olódodo Kan


9 Njẹ ki ha ni? awa ha san jù wọn bi? Kò ri bẹ̃ rara: nitori a ti fihan ṣaju pe ati awọn Ju ati awọn Hellene, gbogbo nwọn li o wà labẹ ẹ̀ṣẹ; 10 Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Kò si ẹniti iṣe olododo, kò si ẹnikan: 11 Kò si ẹniti oyé yé, kò si ẹniti o nwá Ọlọrun. 12 Gbogbo nwọn li o ti yapa, nwọn jumọ di alailere; kò si ẹniti nṣe rere, kò tilẹ si ẹnikan. 13 Isà okú ti o ṣi silẹ li ọfun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi nṣe itanjẹ; oró pamọlẹ mbẹ labẹ ète wọn: 14 Ẹnu ẹniti o kún fun èpe ati fun ọ̀rọ kikoro: 15 Ẹsẹ wọn yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ: 16 Iparun ati ipọnju wà li ọ̀na wọn: 17 Ọ̀na alafia ni nwọn kò si mọ̀: 18 Ibẹru Ọlọrun kò si niwaju wọn. 19 Awa si mọ̀ pe ohunkohun ti ofin ba wi, o nwi fun awọn ti o wà labẹ ofin: ki gbogbo ẹnu ki o le pamọ́, ati ki a le mu gbogbo araiye wá sabẹ idajọ Ọlọrun.

20 Nitoripe nipa iṣẹ ofin, a kì yio dá ẹnikẹni lare niwaju rẹ̀: nitori nipa ofin ni ìmọ ẹ̀ṣẹ ti wá.

Ìdáláre Nípa Igbagbọ


21 Ṣugbọn nisisiyi a ti fi ododo Ọlọrun hàn laisi ofin, ti a njẹri si nipa ofin ati nipa awọn woli; 22 Ani ododo Ọlọrun nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi, si gbogbo enia, ati lara gbogbo awọn ti o gbagbọ́: nitoriti kò si ìyatọ: 23 Gbogbo enia li o sá ti ṣẹ̀, ti nwọn si kuna ogo Ọlọrun; 24 Awọn ẹniti a ndalare lọfẹ nipa ore-ọfẹ rẹ̀, nipa idande ti o wà ninu Kristi Jesu: 25 Ẹniti Ọlọrun ti gbe kalẹ lati jẹ ètutu nipa igbagbọ́ ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, lati fi ododo rẹ̀ hàn nitori idariji awọn ẹ̀ṣẹ ti o ti kọja, ninu ipamọra Ọlọrun; 26 Lati fi ododo rẹ̀ hàn ni igba isisiyi: ki o le jẹ olódodo ati oludare ẹniti o gbà Jesu gbọ́. 27 Ọna iṣogo da? A ti mu u kuro. Nipa ofin wo? ti iṣẹ? Bẹ́kọ: ṣugbọn nipa ofin igbagbọ́. 28 Nitorina a pari rẹ̀ si pe nipa igbagbọ́ li a nda enia lare laisi iṣẹ ofin. 29 Ọlọrun awọn Ju nikan ha ni bi? ki ha ṣe ti awọn Keferi pẹlu? Bẹ̃ni, ti awọn Keferi ni pẹlu: 30 Bi o ti jẹ pe Ọlọrun kan ni, ti yio da awọn akọla lare nipa igbagbọ́, ati awọn alaikọla nitori igbagbọ́ wọn. 31 Awa ha nsọ ofin dasan nipa igbagbọ́ bi? Ki a má ri: ṣugbọn a nfi ofin mulẹ.

Romans 3

All the World Guilty

1 Then what advantage has the Jew? Or what is the benefit of circumcision?2 Great in every respect. First of all, that they were entrusted with the oracles of God.3 What then? If some did not believe, their unbelief will not nullify the faithfulness of God, will it?4 May it never be! Rather, let God be found true, though every man be found a liar, as it is written,
"THAT YOU MAY BE JUSTIFIED IN YOUR WORDS,
AND PREVAIL WHEN YOU ARE JUDGED."
5 But if our unrighteousness demonstrates the righteousness of God, what shall we say? The God who inflicts wrath is not unrighteous, is He? (I am speaking in human terms.)6 May it never be! For otherwise, how will God judge the world?7 But if through my lie the truth of God abounded to His glory, why am I also still being judged as a sinner?8 And why not say (as we are slanderously reported and as some claim that we say), "Let us do evil that good may come"? Their condemnation is just.

9 What then? Are we better than they? Not at all; for we have already charged that both Jews and Greeks are all under sin;10 as it is written,
"THERE IS NONE RIGHTEOUS, NOT EVEN ONE;

11 THERE IS NONE WHO UNDERSTANDS,
THERE IS NONE WHO SEEKS FOR GOD;

12 ALL HAVE TURNED ASIDE, TOGETHER THEY HAVE BECOME USELESS;
THERE IS NONE WHO DOES GOOD,
THERE IS NOT EVEN ONE."

13 "THEIR THROAT IS AN OPEN GRAVE,
WITH THEIR TONGUES THEY KEEP DECEIVING,"
"THE POISON OF ASPS IS UNDER THEIR LIPS";

14 "WHOSE MOUTH IS FULL OF CURSING AND BITTERNESS";

15 "THEIR FEET ARE SWIFT TO SHED BLOOD,

16 DESTRUCTION AND MISERY ARE IN THEIR PATHS,

17 AND THE PATH OF PEACE THEY HAVE NOT KNOWN."

18 "THERE IS NO FEAR OF GOD BEFORE THEIR EYES."

19 Now we know that whatever the Law says, it speaks to those who are under the Law, so that every mouth may be closed and all the world may become accountable to God;20 because by the works of the Law no flesh will be justified in His sight; for through the Law comes the knowledge of sin.

Justification by Faith

21 But now apart from the Law the righteousness of God has been manifested, being witnessed by the Law and the Prophets,22 even the righteousness of God through faith in Jesus Christ for all those who believe; for there is no distinction;23 for all have sinned and fall short of the glory of God,24 being justified as a gift by His grace through the redemption which is in Christ Jesus;25 whom God displayed publicly as a propitiation in His blood through faith. This was to demonstrate His righteousness, because in the forbearance of God He passed over the sins previously committed;26 for the demonstration, I say, of His righteousness at the present time, so that He would be just and the justifier of the one who has faith in Jesus.

27 Where then is boasting? It is excluded. By what kind of law? Of works? No, but by a law of faith.28 For we maintain that a man is justified by faith apart from works of the Law.29 Or is God the God of Jews only? Is He not the God of Gentiles also? Yes, of Gentiles also,30 since indeed God who will justify the circumcised by faith and the uncircumcised through faith is one.

31 Do we then nullify the Law through faith? May it never be! On the contrary, we establish the Law.