Rom 5
Àyọrísí Ìdáláre
1 NJẸ bi a si ti nda wa lare nipa igbagbọ́, awa ni alafia lọdọ Ọlọrun nipa Oluwa wa Jesu Kristi: 2 Nipasẹ ẹniti awa si ti ri ọ̀na gbà nipa igbagbọ́ si inu ore-ọfẹ yi ninu eyi ti awa gbé duro, awa si nyọ̀ ni ireti ogo Ọlọrun. 3 Kì si iṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn awa si nṣogo ninu wahalà pẹlu: bi a ti mọ̀ pe wahalà nṣiṣẹ sũru; 4 Ati sũru nṣiṣẹ iriri; ati iriri ni nṣiṣẹ ireti: 5 Ireti kì si idojuti ni; nitori a ti tan ifẹ Ọlọrun ká wa lọ́kàn lati ọdọ Ẹmí Mimọ́ wá ti a fifun wa. 6 Nitori igbati awa jẹ alailera, li akokò ti o yẹ, Kristi kú fun awa alaiwa-bi-Ọlọrun. 7 Nitori o ṣọ̀wọn ki ẹnikan ki o to kú fun olododo: ṣugbọn fun enia rere boya ẹlomiran tilẹ le dába ati kú. 8 Ṣugbọn Ọlọrun fi ifẹ On papa si wa hàn ni eyi pe, nigbati awa jẹ ẹlẹṣẹ, Kristi kú fun wa. 9 Melomelo si ni, ti a da wa lare nisisiyi nipa ẹ̀jẹ rẹ̀, li a o gbà wa là kuro ninu ibinu nipasẹ rẹ̀. 10 Njẹ bi, nigbati awa wà li ọtá, a mu wa ba Ọlọrun làja nipa ikú Ọmọ rẹ̀, melomelo, nigbati a là wa ni ìja tan, li a o gbà wa là nipa ìye rẹ̀.
11 Kì si iṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn awa nṣogo ninu Ọlọrun nipa Oluwa wa Jesu Kristi, nipasẹ ẹniti awa ti ri ìlaja gbà nisisiyi.Adamu ati Kristi
12 Nitori gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ ti ti ipa ọdọ enia kan wọ̀ aiye, ati ikú nipa ẹ̀ṣẹ; bẹ̃ni ikú si kọja sori enia gbogbo, lati ọdọ ẹniti gbogbo enia ti dẹṣẹ̀: 13 Nitori ki ofin ki o to de, ẹ̀ṣẹ ti wà li aiye; ṣugbọn a kò kà ẹ̀ṣẹ si ni lọrun nigbati ofin kò si. 14 Ṣugbọn ikú jọba lati igbà Adamu wá titi fi di igba ti Mose, ati lori awọn ti kò ṣẹ̀ bi afarawe irekọja Adamu, ẹniti iṣe apẹrẹ ẹniti mbọ̀. 15 Ṣugbọn kì iṣe bi ẹ̀ṣẹ bẹ̃ si li ẹ̀bun ọfẹ. Nitori bi nipa ẹ̀ṣẹ ẹnikan, ẹni pupọ kú, melomelo li ore-ọfẹ Ọlọrun, ati ẹ̀bun ninu ore-ọfẹ ọkunrin kan, Jesu Kristi, di pupọ fun ẹni pupọ. 16 Kì isi ṣe bi nipa ẹnikan ti o ṣẹ̀, li ẹ̀bun na: nitori idajọ ti ipasẹ ẹnikan wá fun idalẹbi ṣugbọn ẹ̀bun ọfẹ ti inu ẹ̀ṣẹ pupọ wá fun idalare. 17 Njẹ bi nipa ẹ̀ṣẹ ọkunrin kan ikú jọba nipasẹ ẹnikanna; melomelo li awọn ti ngbà ọ̀pọlọpọ ore-ọfẹ ati ẹ̀bun ododo yio jọba ninu ìye nipasẹ ẹnikan, Jesu Kristi. 18 Njẹ bi nipa ẹ̀ṣẹ kan idajọ de bá gbogbo enia si idalẹbi; gẹgẹ bẹ̃ni nipa iwa ododo kan, ẹ̀bun ọfẹ de sori gbogbo enia fun idalare si ìye. 19 Nitori gẹgẹ bi nipa aigbọran enia kan, enia pupọ di ẹlẹṣẹ bẹ̃ ni nipa igbọran ẹnikan, a o sọ enia pupọ di olododo. 20 Ṣugbọn ofin bọ si inu rẹ̀, ki ẹ̀ṣẹ le di pupọ. Ṣugbọn nibiti ẹ̀ṣẹ di pupọ, ore-ọfẹ di pupọ rekọja, 21 Pe, gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ ti jọba nipa ikú, bẹni ki ore-ọfẹ si le jọba nipa ododo titi ìye ainipẹkun nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa.
Romans 5
Results of Justification
1 Therefore, having been justified by faith, we have peace with God through our Lord Jesus Christ,2 through whom also we have obtained our introduction by faith into this grace in which we stand; and we exult in hope of the glory of God.3 And not only this, but we also exult in our tribulations, knowing that tribulation brings about perseverance;4 and perseverance, proven character; and proven character, hope;5 and hope does not disappoint, because the love of God has been poured out within our hearts through the Holy Spirit who was given to us.
6 For while we were still helpless, at the right time Christ died for the ungodly.7 For one will hardly die for a righteous man; though perhaps for the good man someone would dare even to die.8 But God demonstrates His own love toward us, in that while we were yet sinners, Christ died for us.9 Much more then, having now been justified by His blood, we shall be saved from the wrath of God through Him.10 For if while we were enemies we were reconciled to God through the death of His Son, much more, having been reconciled, we shall be saved by His life.11 And not only this, but we also exult in God through our Lord Jesus Christ, through whom we have now received the reconciliation.
12 Therefore, just as through one man sin entered into the world, and death through sin, and so death spread to all men, because all sinned-13 for until the Law sin was in the world, but sin is not imputed when there is no law.14 Nevertheless death reigned from Adam until Moses, even over those who had not sinned in the likeness of the offense of Adam, who is a ttype of Him who was to come.
15 But the free gift is not like the transgression. For if by the transgression of the one the many died, much more did the grace of God and the gift by the grace of the one Man, Jesus Christ, abound to the many.16 The gift is not like that which came through the one who sinned; for on the one hand the judgment arose from one transgression resulting in condemnation, but on the other hand the free gift arose from many transgressions resulting in justification.17 For if by the transgression of the one, death reigned through the one, much more those who receive the abundance of grace and of the gift of righteousness will reign in life through the One, Jesus Christ.
18 So then as through one transgression there resulted condemnation to all men, even so through one act of righteousness there resulted justification of life to all men.19 For as through the one man's disobedience the many were made sinners, even so through the obedience of the One the many will be made righteous.20 The Law came in so that the transgression would increase; but where sin increased, grace abounded all the more,21 so that, as sin reigned in death, even so grace would reign through righteousness to eternal life through Jesus Christ our Lord.