Rom 6
Ikú sí Ẹ̀ṣẹ̀, Ìyè ninu Kristi
1 NJẸ awa o ha ti wi? Ki awa ki o ha joko ninu ẹ̀ṣẹ, ki ore-ọfẹ ki o le ma pọ̀ si i? 2 Ki a má ri. Awa ẹniti o ti kú si ẹ̀ṣẹ, awa o ha ṣe wà lãye ninu rẹ̀ mọ́? 3 Tabi ẹ kò mọ̀ pe, gbogbo wa ti a ti baptisi sinu Kristi Jesu, a ti baptisi wa sinu ikú rẹ̀? 4 Njẹ a fi baptismu sinu ikú sin wa pọ̀ pẹlu rẹ̀: pe gẹgẹ bi a ti jí Kristi dide kuro ninu okú nipa ogo Baba bẹ̃ni ki awa pẹlu ki o mã rìn li ọtun ìwa. 5 Nitori bi a ba ti so wa pọ̀ pẹlu rẹ̀ nipa afarawe ikú rẹ̀, a o si so wa pọ pẹlu nipa afarawe ajinde rẹ̀: 6 Nitori awa mọ eyi pe, a kàn ogbologbo ọkunrin wa mọ agbelebu pẹlu rẹ̀, ki a le pa ara ẹ̀ṣẹ run, ki awa maṣe sìn ẹ̀ṣẹ mọ́. 7 Nitori ẹniti o kú, o bọ́ lọwọ ẹ̀ṣẹ. 8 Ṣugbọn bi awa ba bá Kristi kú, awa gbagbọ́ pe awa ó si wà lãye pẹlu rẹ̀: 9 Nitori awa mọ̀ pé bi a ti jí Kristi dide kuro ninu okú, kò ni ikú mọ́; ikú kò ni ipa lori rẹ̀ mọ́. 10 Nitori iku ti o kú, o kú si ẹ̀ṣẹ lẹ̃kan: nitori wiwà ti o wà lãye, o wà lãye si Ọlọrun. 11 Bẹ̃ni ki ẹnyin pẹlu kà ara nyin bi okú si ẹ̀ṣẹ, ṣugbọn bi alãye si Ọlọrun ninu Kristi Jesu. 12 Nitorina ẹ maṣe jẹ ki ẹ̀ṣẹ ki o jọba ninu ara kiku nyin, ti ẹ o fi mã gbọ ti ifẹkufẹ rẹ̀; 13 Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ fun ẹ̀ṣẹ bi ohun elo aiṣododo; ṣugbọn ẹ jọwọ ara nyin lọwọ fun Ọlọrun, bi alãye kuro ninu okú, ati awọn ẹ̀ya ara nyin bi ohun elo ododo fun Ọlọrun.
14 Nitori ẹ̀ṣẹ kì yio ni ipa lori nyin: nitori ẹnyin kò si labẹ ofin, bikoṣe labẹ ore-ọfẹ.Ẹrú Òdodo
15 Njẹ kini? ki awa ki o ha ma dẹṣẹ̀, nitoriti awa kò si labẹ ofin, bikoṣe labẹ ore-ọfẹ? Ki a má ri. 16 Ẹnyin kò mọ̀ pe, ẹniti ẹnyin ba jọwọ ara nyin lọwọ fun bi ẹrú lati mã gbọ́ tirẹ̀, ẹrú ẹniti ẹnyin ba gbọ tirẹ̀ li ẹnyin iṣe; ibãṣe ti ẹ̀ṣẹ sinu ikú, tabi ti igbọran si ododo? 17 Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun pe, bi ẹnyin ti jẹ ẹrú ẹ̀ṣẹ rí, ẹnyin jẹ olugbọran lati ọkàn wá si apẹrẹ ẹkọ ti a fi nyin le lọwọ. 18 Bi a si ti sọ nyin di omnira kuro ninu ẹ̀ṣẹ, ẹnyin di ẹrú ododo. 19 Emi nsọ̀rọ bi enia nitori ailera ara nyin: nitori bi ẹnyin ti jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ bi ẹrú fun iwa-ẽri ati fun ẹ̀ṣẹ de inu ẹ̀ṣẹ; bẹ̃ gẹgẹ ni ki ẹnyin ki o jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ nisisiyi bi ẹrú fun ododo si ìwa-mimọ́. 20 Nitori nigbati ẹnyin ti jẹ ẹrú ẹ̀ṣẹ, ẹnyin wà li omnira si ododo. 21 Njẹ eso kili ẹnyin ha ni nigbana ninu ohun ti oju ntì nyin si nisisiyi? nitori opin nkan wọnni ikú ni. 22 Ṣugbọn nisisiyi ti a sọ nyin di omnira kuro ninu ẹ̀ṣẹ, ti ẹnyin si di ẹrú Ọlọrun, ẹnyin ni eso nyin si ìwa mimọ́, ati opin rẹ̀ ìye ainipẹkun. 23 Nitori ikú li ère ẹ̀ṣẹ; ṣugbọn ẹ̀bun ọfẹ Ọlọrun ni ìye ti kò nipẹkun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa.
Romans 6
Believers Are Dead to Sin, Alive to God
1 What shall we say then? Are we to continue in sin so that grace may increase?2 May it never be! How shall we who died to sin still live in it?3 Or do you not know that all of us who have been baptized into Christ Jesus have been baptized into His death?4 Therefore we have been buried with Him through baptism into death, so that as Christ was raised from the dead through the glory of the Father, so we too might walk in newness of life.5 For if we have become united with Him in the likeness of His death, certainly we shall also be in the likeness of His resurrection,6 knowing this, that our old self was crucified with Him, in order that our body of sin might be done away with, so that we would no longer be slaves to sin;7 for he who has died is freed from sin.
8 Now if we have died with Christ, we believe that we shall also live with Him,9 knowing that Christ, having been raised from the dead, is never to die again; death no longer is master over Him.10 For the death that He died, He died to sin once for all; but the life that He lives, He lives to God.11 Even so consider yourselves to be dead to sin, but alive to God in Christ Jesus.
12 Therefore do not let sin reign in your mortal body so that you obey its lusts,13 and do not go on presenting the members of your body to sin as instruments of unrighteousness; but present yourselves to God as those alive from the dead, and your members as instruments of righteousness to God.14 For sin shall not be master over you, for you are not under law but under grace.
15 What then? Shall we sin because we are not under law but under grace? May it never be!16 Do you not know that when you present yourselves to someone as slaves for obedience, you are slaves of the one whom you obey, either of sin resulting in death, or of obedience resulting in righteousness?17 But thanks be to God that though you were slaves of sin, you became obedient from the heart to that form of teaching to which you were committed,18 and having been freed from sin, you became slaves of righteousness.19 I am speaking in human terms because of the weakness of your flesh. For just as you presented your members as slaves to impurity and to lawlessness, resulting in further lawlessness, so now present your members as slaves to righteousness, resulting in sanctification.
20 For when you were slaves of sin, you were free in regard to righteousness.21 Therefore what benefit were you then deriving from the things of which you are now ashamed? For the outcome of those things is death.22 But now having been freed from sin and enslaved to God, you derive your benefit, resulting in sanctification, and the outcome, eternal life.23 For the wages of sin is death, but the free gift of God is eternal life in Christ Jesus our Lord.