Tit 1
Ìkíni
1 PAULU, iranṣẹ Ọlọrun, ati Aposteli Jesu Kristi, gẹgẹ bi igbagbọ́ awọn ayanfẹ Ọlọrun, ati imọ otitọ ti mbẹ gẹgẹ bi ìwa-bi-Ọlọrun, 2 Ni ireti ìye ainipẹkun, ti Ọlọrun, Ẹniti kò le ṣèké, ti ṣe ileri ṣaju ipilẹṣẹ aiye; 3 Ṣugbọn ni akokò tirẹ̀ o fi ọ̀rọ rẹ̀ hàn ninu iwasu, ti a fi le mi lọwọ gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun Olugbala wa;
4 Si Titu, ọmọ mi nitõtọ nipa igbagbọ́ ti iṣe ti gbogbo enia: Ore-ọfẹ, ãnu, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wá ati Kristi Jesu Olugbala wa.Iṣẹ́ Titu ní Kirete
5 Nitori idi eyi ni mo ṣe fi ọ silẹ ni Krete, ki iwọ ki o le ṣe eto ohun ti o kù, ki o si yan awọn alagba ni olukuluku ilu, bi mo ti paṣẹ fun ọ. 6 Bi ẹnikan ba ṣe alailẹgan, ọkọ aya kan, ti o ni ọmọ ti o gbagbọ́, ti a kò fi sùn fun wọbia, ti nwọn kò si jẹ alagidi. 7 Nitori o yẹ ki biṣopu jẹ alailẹgàn, bi iriju Ọlọrun; ki o má jẹ aṣe-tinu-ẹni, oninu-fùfu, ọmuti, aluni, olojukokoro; 8 Bikoṣe olufẹ alejò ṣiṣe, olufẹ awọn enia rere, alairekọja, olõtọ, ẹni mimọ́, ẹni iwọntunwọnsi; 9 Ti o ndì ọ̀rọ otitọ mu ṣinṣin eyiti iṣe gẹgẹ bi ẹ̀kọ́, ki on ki o le mã gbani-niyanju ninu ẹ̀kọ́ ti o yè kõro, ki o si le mã da awọn asọrọ-odi lẹbi. 10 Nitoripe ọpọlọpọ awọn alagídi, awọn asọ̀rọ asan, ati awọn ẹlẹtàn ni mbẹ, papa awọn ti ikọla: 11 Awọn ẹniti a kò le ṣaipa li ẹnu mọ, nitoriti wọn nda odidi agbo ilé rú, ti nwọn nkọni ni ohun ti kò yẹ nitori ere aitọ́. 12 Ọkan ninu wọn, ani woli awọn tikarawọn, wipe, Eke ni awọn ará Krete nigbagbogbo, ẹranko buburu, ọlẹ alajẹki. 13 Otitọ li ẹrí yi. Nitorina bá wọn wi gidigidi, ki nwọn ki o le yè kõro ni igbagbọ́; 14 Ki nwọn máṣe fiyesi ìtan lasan ti awọn Ju, ati ofin awọn enia ti nwọn yipada kuro ninu otitọ. 15 Ohun gbogbo ni o mọ́ fun awọn ẹniti o mọ́, ṣugbọn fun awọn ti a sọ di ẹlẹgbin ati awọn alaigbagbọ́ kò si ohun ti o mọ́; ṣugbọn ati inu ati ẹ̀ri-ọkan wọn li a sọ di ẹgbin. 16 Nwọn jẹwọ pe nwọn mọ̀ Ọlọrun; ṣugbọn nipa iṣẹ nwọn nsẹ́ ẹ, nwọn jẹ ẹni irira, ati alaigbọran, ati niti iṣẹ rere gbogbo alainilari.
Titus 1
Salutation
1 Paul, a bond-servant of God and an apostle of Jesus Christ, for the faith of those chosen of God and the knowledge of the truth which is according to godliness,2 in the hope of eternal life, which God, who cannot lie, promised long ages ago,3 but at the proper time manifested, even His word, in the proclamation with which I was entrusted according to the commandment of God our Savior,
4 To Titus, my true child in a common faith: Grace and peace from God the Father and Christ Jesus our Savior.
Qualifications of Elders
5 For this reason I left you in Crete, that you would set in order what remains and appoint elders in every city as I directed you,6 namely, if any man is above reproach, the husband of one wife, having children who believe, not accused of dissipation or rebellion.7 For the overseer must be above reproach as God's steward, not self-willed, not quick-tempered, not addicted to wine, not pugnacious, not fond of sordid gain,8 but hospitable, loving what is good, sensible, just, devout, self-controlled,9 holding fast the faithful word which is in accordance with the teaching, so that he will be able both to exhort in sound doctrine and to refute those who contradict.
10 For there are many rebellious men, empty talkers and deceivers, especially those of the circumcision,11 who must be silenced because they are upsetting whole families, teaching things they should not teach for the sake of sordid gain.12 One of themselves, a prophet of their own, said, "Cretans are always liars, evil beasts, lazy gluttons."13 This testimony is true. For this reason reprove them severely so that they may be sound in the faith,14 not paying attention to Jewish myths and commandments of men who turn away from the truth.15 To the pure, all things are pure; but to those who are defiled and unbelieving, nothing is pure, but both their mind and their conscience are defiled.16 They profess to know God, but by their deeds they deny Him, being detestable and disobedient and worthless for any good deed.