previous next

Sef 1

1 Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Sefaniah wá ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedaliah, ọmọ Amariah, ọmọ Hisikiah, li ọjọ Josiah, ọmọ Amoni ọba Juda.

Ọjọ́ Ìdájọ́ Ọlọrun


2 Oluwa wipe, emi o mu gbogbo nkan kuro lori ilẹ na patapata. 3 Emi o mu enia ati ẹranko kuro; emi o mu ẹiyẹ oju ọrun kuro, ati ẹja inu okun, ati ohun idigbòlu pẹlu awọn enia buburu; emi o si ké enia kuro lori ilẹ, ni Oluwa wi. 4 Emi o nà ọwọ́ mi pẹlu sori Juda, ati sori gbogbo ara Jerusalemu; emi o si ké iyokù Baali kuro nihinyi, ati orukọ Kemarimu pẹlu awọn alufa; 5 Ati awọn ti nsìn ogun ọrun lori orule: awọn ti nsìn, ti nfi Oluwa bura, ti si nfi Malkomu bura; 6 Ati awọn ẹniti o yipadà kuro lọdọ Oluwa; ati awọn ẹniti kò ti wá Oluwa, bẹ̃ni nwọn kò si bère rẹ̀. 7 Pa ẹnu rẹ mọ niwaju Oluwa Ọlọrun: nitoriti ọjọ Oluwa kù si dẹ̀dẹ: nitori Oluwa ti pesè ẹbọ kan silẹ̀, o si ti yà awọn alapèjẹ rẹ̀ si mimọ́. 8 Yio si ṣe li ọjọ ẹbọ Oluwa, ti emi o bẹ̀ awọn olori wò, ati awọn ọmọ ọba, ati gbogbo iru awọn ti o wọ̀ ajèji aṣọ. 9 Li ọjọ na gan li emi o bẹ̀ gbogbo awọn ti nfò le iloro wò pẹlu, ti nfi ìwà-ipá on ẹ̀tan kún ile oluwa wọn. 10 Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa wi, ohùn ẹkún yio ti ihà bodè-ẹja wá, ati hihu lati ihà keji wá, ati iro nla lati oke-kékèké wọnni wá. 11 Hu, ẹnyin ara Maktẹsi, nitoripe gbogbo enia oniṣòwo li a ti ke lu ilẹ; gbogbo awọn ẹniti o nrù fàdakà li a ke kuro. 12 Yio si ṣe li akokò na, li emi o fi fitilà wá Jerusalemu kiri, emi o si bẹ̀ awọn enia ti o silẹ sinu gẹ̀dẹgẹdẹ̀ wọn wò: awọn ti nwi li ọkàn wọn pe, Oluwa kì yio ṣe rere, bẹ̃ni kì yio ṣe buburu. 13 Nitorina ogun wọn o di ikógun, ati ilẹ wọn yio di ahoro: nwọn o kọ́ ile pẹlu, ṣugbọn nwọn kì yio gbe inu wọn, nwọn o si gbìn ọgbà àjara, ṣugbọn nwọn kì yio mu ọti-waini inu rẹ̀. 14 Ọjọ nla Oluwa kù si dẹ̀dẹ, o kù si dẹ̀dẹ̀, o si nyara kánkan, ani ohùn ọjọ Oluwa: alagbara ọkunrin yio sọkun kikorò nibẹ̀. 15 Ọjọ na ọjọ ibinu ni, ọjọ iyọnu, ati ipọnju, ọjọ ofò ati idahoro, ọjọ okùnkun ọti okùdu, ọjọ kũku ati okunkun biribiri, 16 Ọjọ ipè ati idagirì si ilu olodi wọnni ati si iṣọ giga wọnni. 17 Emi o si mu ipọnju wá bá enia, ti nwọn o ma rìn bi afọju, nitori nwọn ti dẹṣẹ si Oluwa: ẹjẹ̀ wọn li a o si tú jade bi ekuru, ati ẹran-ara wọn bi igbẹ. 18 Fàdakà wọn tabi wurà wọn kì yio lè gbà wọn li ọjọ ìbinu Oluwa: ṣugbọn gbogbo ilẹ̀ na li a o fi iná ijowu rẹ̀ parun: nitori on o fi iyara mu gbogbo awọn ti ngbe ilẹ na kuro.

Zephaniah 1

Day of Judgment on Judah

1 The word of the LORD which came to Zephaniah son of Cushi, son of Gedaliah, son of Amariah, son of Hezekiah, in the days of Josiah son of Amon, king of Judah:

2 "I will completely remove all things
From the face of the earth," declares the LORD.

3 "I will remove man and beast;
I will remove the birds of the sky
And the fish of the sea,
And the ruins along with the wicked;
And I will cut off man from the face of the earth," declares the LORD.

4 "So I will stretch out My hand against Judah
And against all the inhabitants of Jerusalem.
And I will cut off the remnant of Baal from this place,
And the names of the idolatrous priests along with the priests.

5 "And those who bow down on the housetops to the host of heaven,
And those who bow down and swear to the LORD and yet swear by Milcom,

6 And those who have turned back from following the LORD,
And those who have not sought the LORD or inquired of Him."

7 Be silent before the Lord GOD!
For the day of the LORD is near,
For the LORD has prepared a sacrifice,
He has consecrated His guests.

8 "Then it will come about on the day of the LORD'S sacrifice
That I will punish the princes, the king's sons
And all who clothe themselves with foreign garments.

9 "And I will punish on that day all who leap on the temple threshold,
Who fill the house of their lord with violence and deceit.

10 "On that day," declares the LORD,
"There will be the sound of a cry from the Fish Gate,
A wail from the tSecond Quarter,
And a loud crash from the hills.

11 "Wail, O inhabitants of the tMortar,
For all the people of Canaan will be silenced;
All who weigh out silver will be cut off.

12 "It will come about at that time
That I will search Jerusalem with lamps,
And I will punish the men
Who are stagnant in spirit,
Who say in their hearts,
'The LORD will not do good or evil!'

13 "Moreover, their wealth will become plunder
And their houses desolate;
Yes, they will build houses but not inhabit them,
And plant vineyards but not drink their wine."

14 Near is the great day of the LORD,
Near and coming very quickly;
Listen, the day of the LORD!
In it the warrior cries out bitterly.

15 A day of wrath is that day,
A day of trouble and distress,
A day of destruction and desolation,
A day of darkness and gloom,
A day of clouds and thick darkness,

16 A day of trumpet and battle cry
Against the fortified cities
And the high corner towers.

17 I will bring distress on men
So that they will walk like the blind,
Because they have sinned against the LORD;
And their blood will be poured out like dust
And their flesh like dung.

18 Neither their silver nor their gold
Will be able to deliver them
On the day of the LORD'S wrath;
And all the earth will be devoured
In the fire of His jealousy,
For He will make a complete end,
Indeed a terrifying one,
Of all the inhabitants of the earth.