Lent For Everyone
-
- Previous Day
- Next Day
Fri Jun 8
Day 8 of 53 -
Mat 7
Mat 7
Ẹ̀kọ́ nípa Dídá Ẹlòmíràn Lẹ́jọ́
(Luk 6:37-38, 41-42)
1 Ẹ máṣe dani li ẹjọ, ki a ma bà da nyin li ẹjọ. 2 Nitori irú idajọ ti ẹnyin ba ṣe, on ni a o si ṣe fun nyin; irú òṣuwọn ti ẹnyin ba fi wọ̀n, on li a o si fi wọ̀n fun nyin. 3 Etiṣe ti iwọ si nwò ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ, ṣugbọn iwọ ko kiyesi ìti igi ti mbẹ li oju ara rẹ? 4 Tabi iwọ o ti ṣe wi fun arakunrin rẹ pe, Jẹ ki emi yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju rẹ, si wò o, ìti igi mbẹ li oju iwọ tikararẹ. 5 Iwọ agabagebe, tètekọ́ yọ ìti igi jade kuro li oju ara rẹ na, nigbana ni iwọ o si to riran gbangba lati yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ kuro.
6 Ẹ máṣe fi ohun mimọ́ fun ajá, ki ẹ má si ṣe sọ ọṣọ́ nyin siwaju ẹlẹdẹ, ki nwọn má ba fi ẹsẹ tẹ̀ wọn mọlẹ, nwọn a si yipada ẹ̀wẹ, nwọn a si bù nyin ṣán.
Ẹ̀kọ́ nípa Ìtẹramọ́ Adura
(Luk 11:9-13)
7 Bère, a o si fifun nyin; wá kiri, ẹnyin o si ri; kànkun, a o si ṣí i silẹ fun nyin. 8 Nitori ẹnikẹni ti o bère nri gbà; ẹniti o ba si wá kiri nri: ẹniti o ba si nkànkun, li a o ṣí i silẹ fun. 9 Tabi ọkunrin wo ni ti mbẹ ninu nyin, bi ọmọ rẹ̀ bère akara, ti o jẹ fi okuta fun u? 10 Tabi bi o bère ẹja, ti o jẹ fun u li ejò? 11 Njẹ bi ẹnyin ti iṣe enia buburu, ba mọ̀ bi ã ti fi ẹ̀bun rere fun awọn ọmọ nyin, melomelo ni Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi ohun rere fun awọn ti o bère lọwọ rẹ̀?12 Nitorina gbogbo ohunkohun ti ẹnyin ba nfẹ ki enia ki o ṣe si nyin, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o si ṣe si wọn gẹgẹ; nitori eyi li ofin ati awọn woli.
Ẹnu-ọ̀nà tí Ó Fún
(Luk 13:24)
13 Ẹ ba ẹnu-ọ̀na hihá wọle; gbòro li ẹnu-ọ̀na na, ati onibú li oju ọ̀na na ti o lọ si ibi iparun; òpọlọpọ li awọn ẹniti mba ibẹ̀ wọle.14 Nitori pe hihá ni ẹnu-ọ̀na na, ati toro li oju-ọ̀na na, ti o lọ si ibi ìye, diẹ li awọn ẹniti o nrin i.
Èso Igi ni A Fi Ń Mọ Igi
(Luk 6:43-44)
15 Ẹ mã kiyesi awọn eke woli ti o ntọ̀ nyin wá li awọ agutan, ṣugbọn apanijẹ ikõkò ni nwọn ninu. 16 Eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn. Enia a mã ká eso ajara lori ẹgún ọgàn, tabi eso ọpọtọ lara ẹ̀wọn? 17 Gẹgẹ bẹ̃ gbogbo igi rere ni iso eso rere; ṣugbọn igi buburu ni iso eso buburu. 18 Igi rere ko le so eso buburu, bẹ̃ni igi buburu ko si le so eso rere. 19 Gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a ké e lùlẹ, a si wọ́ ọ sọ sinu iná.20 Nitorina nipa eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn.
Ìjẹ́wọ́ Ẹnu Kò Tó
(Luk 13:25-27)
21 Ki iṣe gbogbo ẹniti npè mi li Oluwa, Oluwa, ni yio wọ ijọba ọrun; bikoṣe ẹniti nṣe ifẹ ti Baba mi ti mbẹ li ọrun. 22 Ọpọlọpọ enia ni yio wi fun mi li ọjọ na pe, Oluwa, Oluwa, awa ko ha sọtẹlẹ li orukọ rẹ? ati orukọ rẹ ki a fi lé awọn ẹmi èṣu jade? ati li orukọ rẹ ki a fi ṣe ọ̀pọ iṣẹ iyanu nla?23 Nigbana li emi o si wi fun wọn pe, Emi kò mọ̀ nyin ri, ẹ kuro lọdọ mi, ẹnyin oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.
Ìpìlẹ̀ Meji
(Luk 6:47-49)
24 Nitorina ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ̀rọ temi wọnyi, ti o ba si ṣe wọn, emi o fi wé ọlọ́gbọn enia kan, ti o kọ́ ile rẹ̀ si ori àpata: 25 Òjo si rọ̀, ikún omi si dé, afẹfẹ si fẹ́ nwọn si bìlu ile na; ko si wó, nitoriti a fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ lori àpata. 26 Ẹnikẹni ti o ba si gbọ́ ọ̀rọ temi wọnyi, ti kò si ṣe wọn, on li emi o fi wé aṣiwere enia kan ti o kọ́ ile rẹ̀ si ori iyanrin:27 Òjo si rọ̀, ikún omi si de, afẹfẹ si fẹ́, nwọn si bìlu ile na, o si wó; iwó rẹ̀ si pọ̀ jọjọ.
Àṣẹ Jesu
28 Nigbati o si ṣe ti Jesu pari gbogbo òrọ wọnyi tan, ẹnu yà gbogbo enia si ẹkọ́ rẹ̀: 29 Nitori o nkọ́ wọn bi ẹniti o li aṣẹ, ki si iṣe bi awọn akọwe.
WEEK 1: WEDNESDAY
One of the great lies of our time is to suppose that because Jesus brings forgiveness, and urges us to be forgiving people, meek and gentle, there is no sharp edge to his message. To hear some people, you'd think the whole of the Christian message was simply a call to accept one another, never to judge another person. Indeed, doesn't Jesus himself tell us not to judge, at the start of this very chapter (7.1)? That verse is quoted again and again by people who would do well to ponder this present passage.
Jesus is quite clear that there are such persons as false prophets, as people who appear to be his followers but who in fact have never known him. Life would be a lot simpler if we could tell at a glance who the true and the false prophets were, but the only guide Jesus offers is the picture of the tree. Sooner or later — and it may be a lot later, or it may happen quite suddenly — the fruit of someone's life will appear, and then you can tell whether they were real or whether they were fooling themselves and others.
In Jesus' own day there was no shortage of such people. Jesus spoke more than once about people who would turn up and declare that they were prophesying in his name, or in God's name, and would lead people astray. The second and third generation of the church faced the same problem, and developed an interesting rule of thumb: if someone arrives claiming to be a prophet, but asking for money, they are false. We might expand that into the usual trio: money is so often linked with sex and power. Some false teachers offer their followers sexual licence in contrast to Jesus' rigorous standard, as in 5.27—30, 15.19—20 and 19.3—12; part of the lie, today, is that Jesus didn't mind about such things. Others are eager for personal power, as you can tell when someone challenges them. And, yes, some today are in it for the money.
When Jesus uses the image of the tree, he is drawing, as so often, on an ancient biblical picture. The first Psalm speaks of God's true people like trees planted by streams of water, which will produce fruit at the right time, while the wicked are like chaff blown around by the wind. Jeremiah develops this picture (17.8), thinking of the tree that sends out its roots to look for the water it needs. Lent is a time when we should be doing that: sending out our roots to look for the water of life. The challenge of these verses isn't simply one of learning to recognize true Christian teaching from false. The challenge is to become, ourselves, trees that bear good fruit, people who not only say 'Lord, Lord' when it suits us, but who apply ourselves to the much harder task of discerning and doing God's will.
TODAY
Gracious Lord, draw our roots to yourself, the living water, so that we may grow strong and bear good fruit.