Project 345 Plus

Owe 2

Èrè Tó Wà ninu Ọgbọ́n

1 ỌMỌ mi, bi iwọ ba fẹ igba ọ̀rọ mi, ki iwọ si pa ofin mi mọ́ pẹlu rẹ. 2 Ti iwọ dẹti rẹ silẹ si ọgbọ́n, ti iwọ si fi ọkàn si oye; 3 Ani bi iwọ ba nke tọ̀ ìmọ lẹhin, ti iwọ si gbé ohùn rẹ soke fun oye; 4 Bi iwọ ba ṣafẹri rẹ̀ bi fadaka, ti iwọ si nwá a kiri bi iṣura ti a pamọ́; 5 Nigbana ni iwọ o mọ̀ ibẹ̀ru Oluwa, iwọ o si ri ìmọ Ọlọrun. 6 Nitori Oluwa ni ifi ọgbọ́n funni: lati ẹnu rẹ̀ jade ni ìmọ ati oye ti iwá. 7 O to igbala jọ fun awọn olododo: on li asà fun awọn ti nrìn dede. 8 O pa ipa-ọ̀na idajọ mọ́, o si pa ọ̀na awọn ayanfẹ rẹ̀ mọ́. 9 Nigbana ni iwọ o mọ̀ ododo, ati idajọ, ati aiṣegbe; ani, gbogbo ipa-ọ̀na rere. 10 Nigbati ọgbọ́n bá wọ̀ inu rẹ lọ, ti ìmọ si dùn mọ ọkàn rẹ; 11 Imoye yio pa ọ mọ́, oye yio si ma ṣọ́ ọ: 12 Lati gbà ọ li ọwọ ẹni-ibi, li ọwọ ọkunrin ti nsọrọ ayidayida; 13 Ẹniti o fi ipa-ọ̀na iduroṣinṣin silẹ, lati rìn li ọ̀na òkunkun; 14 Ẹniti o yọ̀ ni buburu iṣe, ti o ṣe inu-didùn si ayidàyidà awọn enia buburu; 15 Ọ̀na ẹniti o wọ́, nwọn si ṣe arekereke ni ipa-ọ̀na wọn: 16 Lati gbà ọ li ọwọ ajeji obinrin, ani li ọwọ ajeji obinrin ti nfi ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ pọnni; 17 Ẹniti o kọ̀ ọrẹ́ igbà-ewe rẹ̀ silẹ, ti o si gbagbe majẹmu Ọlọrun rẹ̀. 18 Nitoripe ile rẹ̀ tẹ̀ sinu ikú, ati ipa-ọ̀na rẹ̀ sọdọ awọn okú. 19 Kò si ẹniti o tọ̀ ọ lọ ti o si tun pada sẹhin, bẹ̃ni nwọn kì idé ipa-ọ̀na ìye. 20 Ki iwọ ki o le ma rin li ọ̀na enia rere, ki iwọ ki o si pa ọ̀na awọn olododo mọ́. 21 Nitoripe ẹni-iduroṣinṣin ni yio joko ni ilẹ na, awọn ti o pé yio si ma wà ninu rẹ̀. 22 Ṣugbọn awọn enia buburu li a o ke kuro ni ilẹ aiye, ati awọn olurekọja li a o si fàtu kuro ninu rẹ̀.